Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Báwo ni owó ẹyọ méjì tí obìnrin opó yẹn sọ sínú àpótí ṣe níye lórí tó?

Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, “dírákímà méjì” tó tó owó iṣẹ́ ọjọ́ méjì làwọn Júù máa ń san lọ́dọọdún gẹ́gẹ́ bí owó orí tẹ́ńpìlì. (Mátíù 17:24) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa irú owó ẹyọ míì, ó sọ pé wọ́n ń ta ẹyẹ ológoṣẹ́ méjì “ní ẹyọ owó kan tí ìníyelórí rẹ̀ kéré,” èyí tó tó owó iṣẹ́ téèyàn á fi ṣe fún nǹkan bí ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta ṣe. Kódà, èèyàn lè rí ẹyẹ ológoṣẹ́ márùn-ún rà téèyàn bá ní méjì ẹyọ owó yẹn, ìyẹn owó iṣẹ́ téèyàn á fi bíi wákàtí kan ààbọ̀ ṣe.—Mátíù 10:29; Lúùkù 12:6.

Owó tí opó aláìní tí Jésù rí sọ sínú àpótí ní tẹ́ńpìlì kéré púpọ̀ sí owó ológoṣẹ́ márùn-ún lọ. Owó ẹyọ méjì yìí, tó jẹ́ owó lẹ́bítọ́ọ̀nù, ni owó bàbà tí ìníyelórí rẹ̀ kéré jù lọ lára owó tí wọ́n ń ná nílẹ̀ Ísírẹ́lì nígbà yẹn. Lẹ́bítọ́ọ̀nù méjì jẹ́ ìdá kan péré nínú mẹ́rìnlélọ́gọ́ta owó iṣẹ́ ojúmọ́, tó bá jẹ́ pé wákàtí méjìlá ni wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ lóòjọ́. Ìyẹn túmọ̀ sí pé téèyàn bá fi ìṣẹ́jú méjìlá ṣiṣẹ́, yóò gbà ju lẹ́bítọ́ọ̀nù méjì lọ.

Jésù Kristi sọ pé owó tí opó yẹn sọ sínú àpótí níye lórí ju ti gbogbo àwọn tó dáwó ńláńlá lọ, tó jẹ́ pé “láti inú àṣẹ́kùsílẹ̀ wọn” ni wọ́n ti mówó. Kí nìdí ẹ̀? Ìtàn yẹn sọ pé opó yẹn ní “ẹyọ owó kéékèèké méjì,” torí náà, ó lè fi ọ̀kan sínú àpótí kó sì tọ́jú èkejì fún ara rẹ̀ tó bá fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó sọ “gbogbo ohun tí ó ní sínú rẹ̀, gbogbo ohun ìní ìgbésí ayé rẹ̀.”—Máàkù 12:41-44; Lúùkù 21:2-4.

Ìgbà wo làwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í mọ Sọ́ọ̀lù sí Pọ́ọ̀lù?

Hébérù làwọn òbí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, àmọ́ ó tún jẹ́ ará ilẹ̀ Róòmù. (Ìṣe 22:27, 28; Fílípì 3:5) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtikékeré ló ti ní orúkọ Hébérù tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù àti orúkọ Róòmù tó ń jẹ́ Pọ́ọ̀lù. Àwọn kan lára àwọn ìbátan Pọ́ọ̀lù náà ní orúkọ Róòmù àti Gíríìkì. (Róòmù 16:7, 21) Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣohun tó ṣàjèjì fáwọn Júù ìgbà yẹn, pàápàá àwọn Júù tí kì í gbé nílẹ̀ Ísírẹ́lì, pé kí wọ́n ní orúkọ méjì.—Ìṣe 12:12; 13:1.

Ó dà bíi pé Sọ́ọ̀lù, tó jẹ́ orúkọ Hébérù, làwọn tó pọ̀ jù fi mọ àpọ́sítélì yìí fún nǹkan tó lé lọ́dún mẹ́wàá lẹ́yìn tó di Kristẹni. (Ìṣe 13:1, 2) Àmọ́, nígbà tó ń rin ìrìn àjò rẹ̀ àkọ́kọ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní nǹkan bí ọdún 47 sí 48 Sànmánì Kristẹni, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó wù ú kí wọ́n máa fi orúkọ Róòmù, ìyẹn Pọ́ọ̀lù pe òun. Olúwa yàn án láti kede ìhìn rere fáwọn tí kì í ṣe Júù, ó sì lè wò ó pé orúkọ Róòmù òun ló máa tẹ́ wọn lọ́rùn jù. (Ìṣe 9:15; 13:9; Gálátíà 2:7, 8) Ó tún lè jẹ́ ìdí tó fi lo Pọ́ọ̀lù ni pé báwọn Gíríìkì ṣe ń pe orúkọ náà, Sọ́ọ̀lù, jọ ọ̀rọ̀ kan tó nítumọ̀ tí kò dáa lédè Gíríìkì. Ohun yòówù kó fà á tí Pọ́ọ̀lù fi pa orúkọ dà, Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun ṣe tán láti “di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí [ó] lè rí i dájú pé [ó] gba àwọn kan là.”—1 Kọ́ríńtì 9:22.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Bí owó lẹ́bítọ́ọ̀nù ṣe tóbi tó rèé