Ta Ló Máa Gbà Wá O?
Ta Ló Máa Gbà Wá O?
ALAGBALÚGBÚ omi dédé ya wá síbì kan tí wọ́n ti ń wa èédú ní ìlú Pittsburgh, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Èyí mú káwọn awakùsà mẹ́sàn-án já sínú ihò kan tó jìn tó òjìlérúgba [240] ẹsẹ̀ bàtà, níbi tí wọn ò ti lè rí nǹkan kan dì mú. Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta, wọ́n jáde kúrò níbi tí wọ́n há sí láìfarapa. Báwo ni wọ́n ṣe jáde?
Àwọn tó yọ wọ́n jáde kọ́kọ́ fi ẹ̀rọ sátẹ́láìtì kan àti ìwé àwòrán ilẹ̀ wá ibi táwọn awakùsà yẹn há sí, wọ́n wá gbẹ́ ihò tó fẹ̀ tó ẹsẹ̀ bàtà méjì ààbọ̀, wọ́n sì fi okùn gbé àgò gbọọrọ kan lọ síbi táwọn ọkùnrin tó ń wa kùsà yẹn wà, tó há gádígádí. Àwọn awakùsà yẹn ń wọnú àgò náà, àwọn tó yọ wọ́n sì ń gbé wọn kúrò nínú kòtò yẹn lọ́kọ̀ọ̀kan. Ká ní wọn ò rí wọn yọ ni, ibẹ̀ ni wọn ì bá kú sí. Inú gbogbo wọn ló dùn nígbà tí wọ́n padà dórí ilẹ̀, ojú wọn wálẹ̀, wọ́n sì dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó yọ wọ́n jáde.
Ọ̀pọ̀ nínú wa ni kò ní já sínú kòtò bíi tàwọn awakùsà mẹ́sàn-án tó ń wa èédú yẹn, a sì lè ṣaláì kó sínú ewu tó lè gbẹ̀mí wa. Síbẹ̀, gbogbo wa la nílò ẹni tó máa gbà wá, torí pé a ti há sọ́wọ́ àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú táá gbẹ̀mí èèyàn bópẹ́ bóyá. Jóòbù, adúróṣinṣin tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà ayé ọjọ́un, sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo. Ó jáde wá bí ìtànná, a sì ké e kúrò, ó sì fẹsẹ̀ fẹ bí òjìji, kò sì sí mọ́.” (Jóòbù 14:1, 2) Láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ọdún lẹ́yìn tí Jóòbù ti sọ̀rọ̀ yẹn, la ṣì ń rí ẹ̀rí pé òótọ́ ni. Àbí, ta ni nínú wa tó lè bọ́ lọ́wọ́ ikú tó jẹ́ àtúbọ̀tán gbogbo èèyàn? Ibi yòówù ká máa gbé, bó ti wù ká mọ ara wa tọ́jú tó, a ṣì nílò ẹni tó máa gbà wá lọ́wọ́ ìjìyà, ọjọ́ ogbó àti ikú.
Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì àtàwọn míì ń tiraka láti mú kí ẹ̀mí àwọn èèyàn máa gùn ju bó ṣe ń gùn nísinsìnyí lọ. Àwọn kan gbé àjọ kan kalẹ̀ pẹ̀lú èròǹgbà “bíbọ́ agbádá ikú kúrò lọ́rùn gbogbo èèyàn.” Wọ́n sọ pé àjọ yẹn “máa ran àwọn tó wà nínú àjọ náà lọ́wọ́ débi pé, tó bá ṣeé ṣe, wọn ò ní máa kú.” Àmọ́ títí di ìsinsìnyí, pẹ̀lú gbogbo ibi tí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ti tẹ̀ síwájú dé àti ìpinnu àwọn èèyàn láti ṣẹ́gun ikú, wọn ò tíì fi bẹ́ẹ̀ mú kí ẹ̀mí èèyàn gùn ju àádọ́rin sí ọgọ́rin ọdún tí Mósè sọ ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ ọdún sẹ́yìn.—Sáàmù 90:10.
Yálà o fara mọ́ ohun tí Jóòbù sọ nípa bí ikú ṣe ń gba ẹ̀mí èèyàn, àbí o ò fara mọ́ ọn, bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, bópẹ́ bóyá ìwọ náà á “fẹsẹ̀ fẹ bí òjìji.” Wàá fi ilé àtọ̀nà, ọ̀rẹ́ àtiyèkan sílẹ̀; ikú á sì pa ojú rẹ dé. Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọ̀wé pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá, wọn kò sì ní owó ọ̀yà mọ́, nítorí pé a ti gbàgbé ìrántí wọn.”— Oníwàásù 9:5.
Ohun kan tó ṣeni láàánú tí Bíbélì sọ nípa ikú ni pé ikú ti “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba,” ó dà bí ìkà alákòóso tó jẹ gàba lé ọmọ aráyé lórí. Ibi à ń lọ la dé yìí, ikú gan-an ni ọ̀tá alénimádẹ̀yìn tọ́mọ aráyé ń wá ẹni tó máa gba àwọn lọ́wọ́ ẹ̀. (Róòmù 5:14; 1 Kọ́ríńtì 15:26) Àwọn tó ní irin iṣẹ́ tó dára jù tó sì mọṣẹ́ jù lọ lára àwọn òṣìṣẹ́ tó máa ń yọ àwọn tó bá kó sínú jàǹbá kò lè gba èèyàn lọ́wọ́ ikú. Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa ti ṣètò ohun tó máa gbà èèyàn lọ́wọ́ ikú.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]
Ọ̀dọ̀ Gene J. Puskar-Pool/Getty Images la ti rí Fọ́tò yìí