Àwọn Ará Ilẹ̀ Lìdíà Ayé Ọjọ́un Ṣe Ohun Kan Tó Là Wá Lóye
Àwọn Ará Ilẹ̀ Lìdíà Ayé Ọjọ́un Ṣe Ohun Kan Tó Là Wá Lóye
ÓṢEÉ ṣe kó o má tíì gbọ́ ọ rí pé ibì kan wà tó ń jẹ́ Lìdíà láyé àtijọ́. Èyí lè mú kó yà ẹ́ lẹ́nu láti gbọ́ pé wọ́n ṣe ohun kan níbẹ̀ tó mú àyípadà bá ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń ṣòwò kárí ayé. Ó tún lè ya àwọn tó ń ka Bíbélì pàápàá lẹ́nu láti mọ̀ pé ohun kan táwọn ará Lìdíà ṣe mú kí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì kan tó ṣòroó lóye túbọ̀ yéni. Kí lohun táwọn ará Lìdíà ṣe yìí? Ká tó dáhùn ìbéèrè yìí, á dáa ká kọ́kọ́ mọ àwọn nǹkan kan nípa ilẹ̀ Lìdíà tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dohun ìgbàgbé yìí.
Láti Sádísì tó jẹ́ olú ìlú Lìdíà, làwọn ọba tó máa ń jẹ ní ilẹ̀ Lìdíà ti máa ń ṣàkóso nígbà yẹn. Sádísì jẹ́ ìlú kan tó wà ní ìwọ̀ oòrùn àgbègbè tí wọ́n ń pè ní Éṣíà Kékeré tẹ́lẹ̀, àmọ́ tó ti wá di orílẹ̀-èdè Tọ́kì báyìí. Kiroésù ọba tó jẹ kẹ́yìn nílẹ̀ Lìdíà lọ́rọ̀ gan-an, àmọ́ nígbà tó di nǹkan bí ọdún 546 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Kírúsì Ńlá, Ọba Páṣíà ṣẹ́gun rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ gba ìjọba náà mọ́ ọn lọ́wọ́. Kírúsì yìí kan náà ló ṣẹ́gun ilẹ̀ Bábílónì ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà.
Àwọn oníṣòwò ará ilẹ̀ Lìdíà tórí wọn pé la gbọ́ pé wọ́n wà lára àwọn tó kọ́kọ́ ná owó ẹyọ. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti máa ń ná wúrà àti fàdákà gẹ́gẹ́ bí owó, àmọ́ nítorí pé àwọn ègé wúrà tí wọ́n máa ń lò kì í bára dọ́gba, ńṣe làwọn èèyàn máa ń wọn owó yẹn lórí òṣùwọ̀n tí wọ́n bá ń ṣe káràkátà. Bí àpẹẹrẹ, ní Ísírẹ́lì nígbà tí Jeremáyà wòlíì Ọlọ́run ra ilẹ̀ kan, ó sọ pé: “Mo sì wọn owó fún un, ṣékélì méje àti ẹyọ fàdákà mẹ́wàá.”—Jeremáyà 32:9.
Lákòókò tí Jeremáyà wà láyé, àwọn ará ilẹ̀ Lìdíà, bẹ̀rẹ̀ sí í lo ohun kan tó mú kí òwò ṣíṣe rọrùn, ìyẹn owó ẹyọ tí wọ́n fi òǹtẹ̀ ìjọba lù, tó sì ní ìwọ̀n bó ṣe yẹ kó wúwo tó. Wúrà àti fàdákà tí wọ́n yọ́ pọ̀ ni wọ́n fi ṣe owó ẹyọ táwọn ará Lìdíà kọ́kọ́ ná. Àmọ́ nígbà tí Kiroésù gorí ìtẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ná owó ẹyọ oríṣi méjì, ìyẹn owó ẹyọ wúrà àti owó ẹyọ fàdákà, méjèèjì sì sún mọ́ ògidì owó gan-an. Èyí ló fi rọ́pò àyọ́pọ̀ wúrà àti fàdákà tí wọ́n ń ná tẹ́lẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń ná owó wúrà àti fàdákà tuntun yìí rèé: ẹyọ owó fàdákà méjìlá ló dọ́gba pẹ̀lú ẹyọ owó wúrà kan ṣoṣo. Àmọ́ nígbà tó yá, àwọn kan wá ń fi àdàpọ̀ wúrà àti nǹkan míì ṣe ayédèrú owó. Èyí ló mú káwọn oníṣòwò máa wá ọ̀nà kan tó rọrùn tí wọ́n lè gbà mọ ògidì wúrà.
Àwọn ará Lìdíà rí i pé òkúta dúdú kan tí wọ́n ń pè ní òkúta àwọn ará Lìdíà yóò yanjú ìṣòro ayédèrú owó yìí. Wọ́n ń fi owó ẹyọ ògidì wúrà ṣe àmì sára òkúta tí kò fi bẹ́ẹ̀ jọ̀lọ̀ náà. Tí wọ́n bá fẹ́ mọ bí wúrà tó wà nínú owó ẹyọ kan ṣe pọ̀ tó, wọ́n á fi owó ẹyọ ọ̀hún ṣe àmì sára òkúta náà. Wọ́n á wá fi àmì méjèèjì wéra. Ọgbọ́n táwọn ará Lìdíà ta láti máa lo òkúta dúdú yìí ló jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ wàhálà ayédèrú owó ẹyọ. Báwo lohun tá a mọ̀ nípa òkúta yìí ṣe lè mú ká lóye Bíbélì?
Bí Bíbélì Ṣe Lo Òkúta Náà Lọ́nà Ìṣàpẹẹrẹ
Nígbà tó ti di pé àwọn oníṣòwò ń lo òkúta dúdú yẹn láti fi dán wúrà wò kí wọ́n lè mọ èyí tó jẹ́ ògidì, làwọn èèyàn bá wá ń lò ó láti fi ṣàlàyé ọ̀nà tí wọ́n ń gbà dán nǹkan wò. Lédè Gíríìkì, tó jẹ́ ara èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, wọ́n tún máa ń lò ó láti ṣàlàyé bí wọ́n ṣe máa ń dá àwọn èèyàn lóró láti wádìí wọn wò.
Bákan náà, torí pé àwọn onítúbú ló máa ń dá àwọn ẹlẹ́wọ̀n lóró, wọ́n tún máa ń lo òkúta dúdú tí wọ́n máa fi ń dán wúrà wò yìí láti fi ṣàlàyé iṣẹ́ àwọn onítúbú. A lè rí èyí nínú àkọsílẹ̀ Bíbélì nípa àkàwé Jésù tó dá lórí ẹrú aláìmoore kan, tí ẹni tó jẹ ní gbèsè fà á lé “àwọn onítúbú lọ́wọ́,” èyí táwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan pè ní “àwọn adánilóró.” (Mátíù 18:34; American Standard Version, Darby, King James Version) Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, The International Standard Bible Encyclopædia, ń ṣàlàyé lórí ẹsẹ Bíbélì yìí, ó ní: “Ó jọ pé fífi tí wọ́n fèèyàn sẹ́wọ̀n gan-an ni wọ́n kà sí ‘ìdálóró’ (bọ́rọ̀ sì ṣe rí gan-an nìyẹn). Ọ̀rọ̀ náà, ‘àwọn adánilóró’ kò túmọ̀ sí ohun mìíràn bí kò ṣe àwọn onítúbú.” Èyí wá jẹ́ ká lóye ẹsẹ Bíbélì kan tó ṣe pàtàkì.
Àdìtú Kan Tá A Rí Ìtumọ̀ Rẹ̀
Ọjọ́ pẹ́ táwọn tó ń fòótọ́ inú ka Bíbélì ti máa ń ronú nípa ohun tó máa gbẹ̀yìn Sátánì. Bíbélì Ìṣípayá 20:10) Láìsí àní-àní, tó bá jẹ́ pé ńṣe ni Jèhófà máa dá ẹnì kan lóró títí ayé, èyí lòdì sí ohun tí Bíbélì sọ, pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́ ó sì jẹ́ onídàájọ́ òdodo. (Jeremáyà 7:31) Yàtọ̀ síyẹn, ẹ̀bùn ni Bíbélì pe ìyè àìnípẹ̀kun kì í ṣe ìyà. (Róòmù 6:23) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé àpẹẹrẹ ni ohun tó wà nínú Ìṣípayá 20:10 jẹ́. Bákan náà, ohun ìṣàpẹẹrẹ ni ẹranko ẹhànnà àti adágún iná náà jẹ́. (Ìṣípayá 13:2; 20:14) Ṣé àpẹẹrẹ náà ni ìdálóró yẹn jẹ́? Kí ló ṣeé ṣe kí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí?
sọ pé “A . . . fi Èṣù . . . sọ̀kò sínú adágún iná àti imí ọjọ́, níbi tí ẹranko ẹhànnà náà àti wòlíì èké náà ti wà nísinsìnyí; a ó sì máa mú wọn joró tọ̀sán-tòru títí láé àti láéláé.” (Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i, ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n ń lò fún òkúta dúdú tí wọ́n fi ń dán ògidì wúrà wò yẹn ni wọ́n ń lò fún “ìdálóró.” Ó sì lè túmọ̀ sí ìyà tí wọ́n máa fi ń jẹni lẹ́wọ̀n. Nípa bẹ́ẹ̀, dídá tí Ọlọ́run máa dá Sátánì lóró títí ayé lè túmọ̀ sí bí Ọlọ́run ṣe máa sọ ọ́ sẹ́wọ̀n gbére, ìyẹn ikú àkúrun tó máa kú.
Òkúta dúdú táwọn ará Lìdíà fi máa ń dán wúrà wò yìí tún mú ká lóye nǹkan míì nípa ‘dídá tí Ọlọ́run máa dá Sátánì lóró’ títí ayé, èyí tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ní àwọn èdè kan, tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa òkúta dúdú tí wọ́n fi ń dán wúrà wò, ọ̀nà tí wọ́n gbà ń dán nǹkan wò ni wọ́n ní lọ́kàn. Bí àpẹẹrẹ, ní èdè Gẹ̀ẹ́sì, ohun tó túmọ̀ sí ni “ìdánwò tàbí ohun ìdíwọ̀n tá a fi ń mọ̀ bóyá ohun kan jẹ́ òótọ́ tàbí ojúlówó.” Nípa bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn ará Lìdíà ṣe máa ń lo òkúta dúdú yẹn láti mọ ojúlówó owó ẹyọ, dídá tí Jèhófà máa ‘dá Sátánì lóró’ títí ayé, ìyẹn ikú àkúrun tó máa gbẹ̀yìn ẹ̀ lè túmọ̀ sí pé ẹjọ́ tí Ọlọ́run máa dá a yìí á dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí láé fún ẹnikẹ́ni tó bá ń gbèrò àtiṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Bí ẹnikẹ́ni bá tiẹ̀ tún gbìyànjú láti ta ko ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti máa ṣàkóso, kò tún ní gba àkókò gígùn mọ́ láti fi ẹ̀rí hàn pé alátakò náà kò tọ̀nà.
Mímọ̀ tá a mọ ìdí táwọn oníṣòwò fi ń lo òkúta dúdú àwọn ará Lìdíà yẹn láti fi mọ ojúlówó owó ẹyọ, àti bá a ṣe lóye àwọn ohun tí òkúta yẹn ń ṣàpẹẹrẹ, mú ká túbọ̀ lóye ohun tó máa gbẹ̀yìn Sátánì. Títí ayé ni ìdájọ́ Sátánì yìí máa dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé Ọlọ́run kò ní fàyè gba ìwà ọ̀tẹ̀ mọ́.—Róòmù 8:20.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 23]
Dídá tí Ọlọ́run yóò dá Sátánì lóró lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ máa dúró gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí títí láé
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 21]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Òkun Dúdú
LÌDÍÀ
SÁDÍSÌ
Òkun Mẹditaréníà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Ìlú Sádísì àtijọ́ tó ti dahoro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]
Láyé ọjọ́un, òṣùwọ̀n ni wọ́n máa fi ń wọn owó
[Credit Line]
E. Strouhal/Werner Forman/Art Resource, NY
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]
Àwọn èèyàn ṣì ń lo òkúta dúdú tí wọ́n fi ń mọ ògidì wúrà yẹn lóde òní
[Àwọn Credit Line]
Owó ẹyọ: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Classical Numismatic Group, Inc.; òkúta dúdú tí wọ́n fi ń mọ ògidì wúrà: Science Museum/Science & Society Picture Library
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]
Àyọ́pọ̀ owó ẹyọ wúrà àti fàdákà: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Classical Numismatic Group, Inc.