Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì Ti Máa Wáyé Gan-an?

Ibo Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì Ti Máa Wáyé Gan-an?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ibo Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì Ti Máa Wáyé Gan-an?

Kì í kúkú ṣe ibi kan pàtó ló máa jẹ́ ojú ogun tí ogún amágẹ́dọ́nì ti máa wáyé. Gbogbo orí ilẹ̀ ayé pátá ló máa jẹ́ ojú ogun tí ìjà náà á ti wáyé. Kí nìdí tó fi máa rí bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé, àwọn méjèèjì tó fẹ́ fìjà pẹẹ́ta yìí lọ́mọ lẹ́yìn débi pé kò síbi kan pàtó láyé yìí tó ní àyè tó láti gbà wọ́n.

Orúkọ míì táwọn èèyàn fi mọ amágẹ́dọ́nì tàbí Ha-Mágẹ́dọ́nì ni “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” Ńṣe ni Jèhófà Ọlọ́run máa lo Ọmọ rẹ, Kristi Jésù láti kó àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogún tó jẹ́ àwọn áńgẹ́lì jọ, tí wọ́n á sì bá àgbáríjọ àwọn ìkà alákòóso ayé yìí jà lẹ́ẹ̀kan náà.—Ìṣípayá 16:14; 19:11-16.

Sátánì ti fẹ̀tàn kó àwọn orílẹ̀-èdè sòdí kí wọ́n lè jọ jagun náà. Bíbélì sọ nípa “àwọn àgbéjáde tí àwọn ẹ̀mí èṣù mí sí,” pé ohun ló jáde lọ bá “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá, láti kó wọn jọpọ̀ sí . . . ibi tí a ń pè ní Ha-Mágẹ́dọ́nì lédè Hébérù.”—Ìṣípayá 16:14-16.

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ìwé míì tó tíì kó àìmọye àwọn tó ń ka Bíbélì sí ṣìbáṣìbo bí ìwé Ìṣípayá. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń ka Bíbélì lóréfèé yìí ló ti tọ́ka síbi tí wọ́n gbà gbọ́ pé ó máa jẹ́ ojú ogun tí ìjà náà ti máa bẹ̀rẹ̀, tọ̀sán tòru ni wọ́n sì ń kíyè sí gbogbo ohun tó ń wáyé lágbègbè ibi tí wọ́n fojú sùn náà. Ó pẹ́ táwọn èèyàn ti gbà gbọ́ pé ibì kan pàtó máa wà tó máa jẹ́ ojú ogun tí ogun Amágẹ́dọ́nì ti máa jà, kódà ó wà nínú àlàyé tó tíì pẹ́ jù tó wà lọ́wọ́ báyìí tí ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì náà, Oecumenius, ṣe lórí ìwé Ìṣípayá, nínú ìwé tó kọ ní ọ̀rúndún kẹfà Sànmánì Kristẹni.

Nígbà tí John F. Walvoord, tó jẹ́ ààrẹ ilé ẹ̀kọ́ àwọn àlùfáà nígbà kan rí ní ìpínlẹ̀ Dallas lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ń gbẹnu sọ fáwọn aṣáájú ìsìn Agbẹ́sìnkarí, ó pe Amágẹ́dọ́nì ní: “ìjà àjàkú akátá tí aráyé tí nǹkan ti sú máa jà ní àárín gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé.” Walvoord wá kúkú là á mọ́lẹ̀ pé “‘Òkè Mẹ́gídò,’ tó jẹ́ òkè kékeré kan lápá àríwá ilẹ̀ Palẹ́sìnì níbi tí àfonífojì kan tó tẹ́ pẹrẹsẹ parí sí” ló máa jẹ́ ojú ogun náà.

Àmọ́, ìwé Ìṣípayá kò fi hàn pé ibì kan pàtó tó máa jẹ́ ojú ogun ni Amágẹ́dọ́nì o. Gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ ìwé náà jẹ́ ká mọ̀ pé “àmì” làwọn ìran náà. (Ìṣípayá 1:1) Ó pẹ́ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti sọ ọ́ nínú ìwé wọn kan tó ń jẹ́ Studies in the Scriptures, Ẹ̀dà Kẹrin, pé: “Àwa ò retí pé káwọn èèyàn wá lọ kóra jọ sórí òkè Mẹ́gídò.”

Ńṣe làwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní Mẹ́gídò ìgbàanì jẹ́ àpẹẹrẹ bí Ọlọ́run ṣe máa jagun mólú, tì kò fi ní sí àsálà fún èyíkéyìí lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Nítorí náà, nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, Ọlọ́run máa rí i dájú pé gbogbo àwọn oníwà ìbàjẹ́ àtàwọn èèyàn búburú pátá, níbi yòówù kí wọ́n wà, máa pa run, tí wọ́n á sì dàwáàrí.—Ìṣípayá 21:8.

Kò sídìí fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi láti máa fòyà nítorí ogun Amágẹ́dọ́nì. Kìkì àwọn èèyàn tí wọ́n ti jẹ́ kí Ọlọ́run mọ̀ pé àwọn ò lè jáwọ́ nínú ìwà burúkú ni ogun Ọlọ́run yìí fẹ́ mú kúrò. Ogun Ọlọ́run yìí mojú àwọn tó máa pa run. Bíbélì ṣáà sọ pé: “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè.” (2 Pétérù 2:9) Ìlérí amọ́kànyọ̀ kan rèé nínú Sáàmù 37:34, ó kà pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé. Nígbà tí a bá ké àwọn ẹni burúkú kúrò, ìwọ yóò rí i.”