Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ogun Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun”

“Ogun Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun”

“Ogun Tó Máa Fòpin Sí Gbogbo Ogun”

‘Mo ṣèlérí fún yín pé ogun yìí la máa jà kẹ́yìn, òun ni ogun tó máa fòpin sí gbogbo ogun.’—WOODROW WILSON, TÓ JẸ́ ÀÀRẸ ORÍLẸ̀-ÈDÈ AMẸ́RÍKÀ (ỌDÚN 1913 SÍ 1921).

NǸKAN pàtàkì tí ọ̀kan lára àwọn alákòóso ayé ń retí pé kó ṣẹlẹ̀ nìyẹn lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní tí wọ́n jà ní nǹkan bíi àádọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn. Ìpakúpa tó wáyé nígbà Ogun Àgbáyé yẹn burú jáì débi pé àwọn tó ṣẹ́gun gbà pé pẹ̀lú gbogbo wàhálà àti ẹ̀mí àwọn ọmọ ogun tó bógun yìí lọ nǹkan gbọ́dọ̀ dáa lẹ́yìn ogun yìí. Ṣùgbọ́n ogun táráyé ń jà kì í yanjú ìṣòro, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe logun sábà máa ń dá ìṣòro ńlá míì sílẹ̀.

Ogún ọdún lẹ́yìn tí Ààrẹ Wilson fi ìwàǹwára ṣèlérí yìí ni Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀. Ẹ̀mí àti dúkìá tó run sí ogun yẹn pọ̀ gan-an ju ti Ogun Àgbáyé Kìíní lọ. Ìdí ni pé, lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kìíní, àwọn èèyàn jágbọ́n àwọn ohun ìjà aṣekúpani tó lè pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ní wàràǹṣeṣà. Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì sì parí, àwọn aṣáájú ayé wá rí i pé ńṣe laráyé tiẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá rugi oyin lórí ọ̀rọ̀ ogun.

Lọ́dún 1945, Ọ̀gágun Douglas MacArthur ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Àsìkò tó yẹ ká fòpin sógun ló ti kọjá lọ yìí. Bá ò bá tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá, ńṣe la kàn máa bá ara wa nínú ogun Amágẹ́dọ́nì.”

Ọ̀gágun MacArthur mọ ọṣẹ́ ńláǹlà tí bọ́ǹbù átọ́míìkì méjì péré ṣe nígbà tí wọ́n jù wọ́n sí ìlú Nagasaki àti Hiroshima ní ilẹ̀ Japan nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń parí lọ. Bí bọ́ǹbù yìí ṣe runlérùnnà tó nílùú méjì yìí ló mú kí ọ̀gágun yìí fún ọ̀rọ̀ náà Amágẹ́dọ́nì ní ìtumọ̀ tó yàtọ̀ sí tàtẹ̀yìnwá, pé ó jẹ́ ìgbà tí ogun átọ́míìkì arunlérùnnà máa jó gbogbo nǹkan deérú, èyí tó lè yọrí sí ìparun gbogbo ẹ̀dá alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé.

Ìrònú pé ogun átọ́míìkì arunlérùnnà lè jà nígbàkigbà ń kó ìpayà bá aráyé. Nígbà tó fi máa di àwọn ọdún 1960, àwọn alágbára ayé tí gbogbo wọn jẹ́ ọ̀tá ara wọn wá hùmọ̀ ọ̀nà kan tí wọ́n rò pé wọ́n lè máa fi dẹ́rù ba ara wọn kí wọ́n má bàa ja ogun átọ́míìkì. Ohun tí wọ́n ń lépa ni pé àwọn máa ní àwọn bọ́ǹbù olóró tó lágbára tó lọ́wọ́ táwọn á lè fi pa, ó kéré tán, ìdà mẹ́rin àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè alágbára tó bá jẹ́ ọ̀tá wọn àti ìdajì gbogbo ilé iṣẹ́ ńláńlá tí orílẹ̀-èdè náà bá ní, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè ọ̀tá yẹn ló kọ́kọ́ yin bọ́ǹbù tirẹ̀. Síbẹ̀ ọ̀nà tí wọ́n dáwọ́ lé láti fi wá àlàáfíà yìí kò fi ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lọ́kàn balẹ̀.

Lóde òní, ńṣe làwọn ohun tí wọ́n lè fi ja ogun arunlérùnnà túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí ogun abẹ́lé sì ń pa ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn. Àwọn èèyàn sì tún ń bẹ̀rù pé ogun átọ́míìkì tó lè pa gbogbo nǹkan run deérú lè bẹ́ sílẹ̀ nígbàkigbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń wu àwọn èèyàn gan-an pé kí ogun dópin, ọ̀pọ̀ jù lọ ni ò gbà pé ogun tàbí àwọn ìhùmọ̀ ẹ̀dá èyíkéyìí ló máa fòpin sí ogun.

Àmọ́ o, Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ogun àrà ọ̀tọ̀ kan tó máa fòpin sí gbogbo ogun. Ó pe ogun yìí ní “Amágẹ́dọ́nì.” Orúkọ yìí làwọn èèyàn wá fi ń ṣàpèjúwe ogun átọ́míìkì arunlérùnnà. Báwo ló ṣe jẹ́ pé Amágẹ́dọ́nì ló máa fòpin sí gbogbo ogun? Àpilẹ̀kọ́ tó tẹ̀ lé èyí yóò dáhùn ìbéèrè yìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Fọ́tò DTRA

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Ìlú Nagasaki, nílẹ̀ Japan, lọ́dún 1945: Fọ́tò USAF