Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Gbígba Ara Olúwa

Ohun Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Gbígba Ara Olúwa

Ohun Tó Yẹ Ká Mọ̀ Nípa Gbígba Ara Olúwa

KÁRÍ ayé làwọn èèyàn ti máa ń gba ará Olúwa déédéé. Wọ́n lè gbà á nígbà mélòó kan lọ́dún, wọ́n sì tún lè máa gbà á lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, tàbí lójoojúmọ́ pàápàá. Síbẹ̀ wọ́n pè é ní nǹkan àdìtú nínú ìgbàgbọ́. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń gbà á ni ò mọ ohun tó túmọ̀ sí. Wọ́n kà á sí ohun mímọ́, kódà wọ́n sọ pé ohun ìyanu ni.

Gbígba ara Olúwa wà lára ààtò Ìsìn táwọn Kátólíìkì máa ń ṣe, tí àlùfáà bá súre sórí àkàrà àti wáìnì tán, á ní káwọn ìjọ wá gba Kristi nínú Ìdàpọ̀ Mímọ́. a Póòpù Benedict Kẹrìndínlógún sọ pé, gbígba ara Olúwa jẹ́ “òpó tó di ìgbàgbọ́ àwa Kátólíìkì mú.” Lẹ́nu àìpẹ́ yìí àwọn Kátólíìkì ya ọdún kan sọ́tọ̀ tí wọ́n pè ní “Ọdún Ara Olúwa,” ìyẹn sì jẹ́ ara ìsapá wọn láti “mú ìgbàgbọ́ nínú ara Olúwa sọ jí kí ìgbàgbọ náà sì máa lágbára sí i.”

Àní àwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì tí wọn ò fara mọ́ gbogbo ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì pàápàá kì í fi ààtò yìí ṣeré. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀rọ̀ tí ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ Kátólíìkì ìgbàlódé kọ sínú ìwé ìròyìn Time, ó sọ pé: “Kò sí bí àríyànjiyàn tó wà láàárín àwa Kátólíìkì ṣe lè pọ̀ tó lórí ohun tá a gbà gbọ́, a ṣì dìrọ̀ mọ́ ohun tó so wá pọ̀ nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì, ìyẹn gbígba ara Olúwa.”

Àmọ́, kí ni gbígba ara Olúwa? Ǹjẹ́ ó yẹ káwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa ṣe é? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo bí ààtò gbígba ara Olúwa ṣe bẹ̀rẹ̀. Lẹ́yìn náà ká wá dáhùn ìbéèrè pàtàkì kan. Ìbéèrè náà ni: Ǹjẹ́ ààtò gbígba ara Olúwa tí wọ́n ń ṣe yìí ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa tí Jésù dá sílẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn?

Ọwọ́ Táwọn Ṣọ́ọ̀ṣì Fi Mú Gbígba Ara Olúwa

Kò ṣòro láti rí ìdí tí wọ́n fi ka ààtò gbígba ara Olúwa sí ohun ìyànu. Ìgbà tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ààtò gbígba ara Olúwa ni ìgbà tí wọ́n bá ń gbàdúra sórí àkàrà àti wáìnì. Ìwé ẹ̀kọ́ Kátólíìkì náà, Catechism of the Catholic Church, tó sọ̀rọ̀ nípa kókó yẹn sọ pé, ìgbà yẹn gan-an ni “agbára ọ̀rọ̀ àti ìṣe Kristi, àti Ẹ̀mí Mímọ́” máa “sọ ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù kalẹ̀.” Lẹ́yìn tí àlùfáà bá jẹ lára àkàrà tó sì mu wáìnì, yóò ní káwọn tó fẹ́ gba ara Olúwa wá máa gbà á nípa jíjẹ àkàrà nìkan.

Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì máa ń fi kọ́ni pé àkàrà àti wáìnì máa ń di ara àti ẹ̀jẹ̀ Kristi lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. Díẹ̀díẹ̀ ni ẹ̀kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ sí í gbilẹ̀, tó sì wá di ohun tí wọ́n kà mọ́ ara ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì láti nǹkan bí ọdún 1200 títí di báyìí. Láwọn àkókò táwọn kan ń ṣàtúnṣe sí ẹ̀sìn Kátólíìkì, àwọn kan ta ko apá kan nínú ààtò gbígba ara Olúwa táwọn Kátólíìkì máa ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ Martin Luther ta ko ẹ̀kọ́ pé wáìnì àti àkàrà di ẹ̀jẹ̀ àti ara Jésù, ẹ̀kọ́ tóun fara mọ́ ni pé àkàrà àti wáìnì jọ wà pa pọ̀ pẹ̀lú ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù. Ìyàtọ̀ díẹ̀ ló wà láàárín ẹ̀kọ́ méjèèjì yìí. Luther kọ́ni pé kì í ṣe pé àkàrà àti wáìnì yí padà di ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù, àmọ̀ ńṣe ni ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù wá dà pọ̀ mọ́ àkàrà àti wáìnì.

Bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́, àlàyé nípa gbígba ara Olúwa àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ayẹyẹ rẹ̀ àti ìgbà tó yẹ kí wọ́n ṣe é wá bẹ̀rẹ̀ sí í yí padà láti ṣọ́ọ̀ṣì kan sí ìkejì. Láìfi gbogbo ìyẹn pè, ààtò náà ṣì ṣe pàtàkì gan-an lọ́nà kan tàbí òmíràn nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì. Báwo wá ni Jésù ṣe dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀?

Bí Jésù Ṣe Dá “Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa” Sílẹ̀

Jésù fúnra rẹ̀ ló dá “oúnjẹ alẹ́ Olúwa,” tá a tún ń pè ní Ìrántí Ikú Kristi, sílẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 11:20, 24) Àmọ́, ṣé ó dá àdìtú ààtò kan sílẹ̀ léyìí tí àwọn ọmọléyìn rẹ̀ yóò ti máa jẹ ara rẹ̀ tí wọ́n á sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ ní ti gidi?

Ẹ̀yìn tí Jésù ṣàjọyọ̀ Ìrékọjá àwọn Júù tán tó sì lé Júdásì Ísíkáríọ́tù jáde, ìyẹn àpọ́sítélì tó máa tó dà á, ló dá oúnjẹ alẹ́ Olúwa sílẹ̀. Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àpọ́sítélì mọ́kànlá wà níbẹ̀, ó sọ pé: “Bí wọ́n ti ń jẹun lọ, Jésù mú ìṣù búrẹ́dì kan, lẹ́yìn sísúre, ó bù ú, ní fífi í fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn, ó sì wí pé: ‘Ẹ gbà, ẹ jẹ. Èyí túmọ̀ sí ara mi.’ Pẹ̀lúpẹ̀lù, ó mú ife kan àti pé, lẹ́yìn dídúpẹ́ ó fi í fún wọn, ó wí pé: ‘Ẹ mu nínú rẹ̀, gbogbo yín; nítorí èyí túmọ̀ sí “ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú” mi, tí a óò tú jáde nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.’”—Mátíù 26:26-28.

Bíi ti Jésù, gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló gbà pé gbígbàdúrà sórí oúnjẹ jẹ́ ohun tó yẹ. (Diutarónómì 8:10; Mátíù 6:11; 14:19; 15:36; Máàkù 6:41; 8:6; Jòhánù 6:11, 23; Ìṣe 27:35; Róòmù 14:6) Ǹjẹ́ ìdí kankan wà láti gbà gbọ́ pé bí Jésù ṣe dúpẹ́ yẹn ńṣe ló ṣe iṣẹ́ ìyanu, tó mú káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jẹ ara rẹ̀ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀?

Èwo Ló Tọ̀nà Nínú “Èyí Túmọ̀ Sí” àti “Èyí Ni”?

Lóòótọ́ àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù yẹn báyìí pé: “Gba, jẹ: eyiyii ni ara mi,” àti “Gbogbo yin ẹ mu ninu rẹ̀; Nitori eyi ni ẹjẹ mi.” (Mátíù 26:26-28, Bibeli Ajuwe àti Bibeli Mimọ) Àti pé lédè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ náà, e·stin΄ ní ìtumọ̀ tó pọ̀. Lákọ̀ọ́kọ́, ó túmọ̀ sí “ni.” Àmọ́ ó tún tumọ̀ sí “ṣàpẹẹrẹ.” Ohun kan tó sì tún gbàfiyèsí ni pé ọ̀pọ̀ Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà, “túmọ̀ sí” tàbí “dúró fún,” láti fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ yẹn. b Àwọn ọ̀rọ̀ tó bá wà níwájú ọ̀rọ̀ náà tàbí àwọn tó wà lẹ́yìn rẹ̀ ló máa sọ bá a ṣe máa túmọ̀ rẹ̀ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì, “túmọ̀ sí” [tàbí ìtumọ̀] ni ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún ọ̀rọ̀ náà e·stin΄Mátíù 12:7. Ó kà pé: “Bí ó bá jẹ́ pé ẹ mọ ìtúmọ̀ gbolohun yǐ: ‘Àánú ṣiṣe ni mo fẹ́ kì í ṣe ẹbọ rírú,’ ẹ kì bá tí dá ẹ̀bi fun aláìṣẹ̀.” (Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀) Láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, e·stin ni ọ̀rọ̀ tí ẹsẹ Bíbélì yẹn pè ní “ìtúmọ̀” ti wá.

Lórí ọ̀rọ̀ yìí, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀mọ̀wé táwọn èèyàn wárí fún lára àwọn tó ṣèwádìí nípa Bíbélì ti gbà pé ọ̀rọ̀ náà, “ni” kò túmọ̀ ohun tí Jésù ń sọ níbí yìí dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Jacques Dupont ṣàyẹ̀wò àṣà ìbílẹ̀ ibi tí Jésù gbé, ó sọ èrò rẹ̀ pé “ọ̀nà tó dára jù lọ” láti gbà túmọ̀ ẹsẹ náà ni: “Èyí túmọ̀ sí ara mi” tàbí “Èyí dúró fún ara mi.”

Bó ti wù kó rí, Jésù ò lè ní in lọ́kàn pé káwọn ọmọlẹ́yìn òun jẹ ara òun kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ oùn gan-gan. Kí nìdí? Lẹ́yìn Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, Ọlọ́run gba àwọn èèyàn láyè láti máa jẹ ẹran, àmọ́ kò sọ pé kí wọ́n máa jẹ ẹran èèyàn. Yàtọ̀ síyẹn, Ọlọ́run sọ ní pàtó pé èèyàn kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Ọlọ́run tún àṣẹ yẹn pa nínú Òfin Mósè, èyí tí Jésù tẹ̀ lé délẹ̀délẹ̀. (Diutarónómì 12:23; 1 Pétérù 2:22) Ẹ̀mí mímọ́ mí sí àwọn àpọ́sítélì láti tún àṣẹ yẹn pa, pé káwọn Kristẹni má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀, gbogbo àwọn Kristẹni títí kan àwọn tòde òní lòfin yẹn sì kàn. (Ìṣe 15:20, 29) Ǹjẹ́ Jésù yóò tìtorí pé káwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè máa rántí rẹ̀ kó wá dá ohun kan sílẹ̀ tí yóò mú kí wọ́n máa rú òfin mímọ́ tó jẹ́ òfin Ọlọ́run Olódùmarè? Ká má rí i!

Ó ṣe kedere nígbà náà pé ohun ìṣàpẹẹrẹ ni Jésù lo búrẹ́dì àti wáìnì fún. Búrẹ́dì aláìwú ṣàpẹẹrẹ ara rẹ̀ tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ tí yóò fi rúbọ. Wáìnì pupa dúró fún ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tí yóò tú jáde “nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn fún ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀.”—Mátíù 26:28.

Ìdí Tí Jésù Fi Dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa Sílẹ̀

Gbólóhùn tí Jésù fi kádìí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa àkọ́kọ́ rèé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Oúnjẹ yẹn jẹ́ ká máa rántí Jésù àtàwọn ohun àgbàyanu tí ikú rẹ̀ mú kó ṣeé ṣe. Ó rán wa létí pé Jésù ṣe ohun tó fi hàn pé Jèhófà Baba rẹ̀ ni Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run. Ó tún rán wa létí pé nípasẹ̀ ikú Jésù gẹ́gẹ́ bí ẹni pípé, tí kò lẹ́ṣẹ̀, Jésù fi “ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” Ìràpadà yìí mú kó ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni tó bá lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù láti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ kó sì ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Mátíù 20:28.

Òótọ́ ni pé ohun tí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa jẹ́ ní ti gidi ni oúnjẹ ìdàpọ̀. Àwọn tí ọ̀rọ̀ oúnjẹ náà dà pọ̀ ni (1) Jèhófà Ọlọ́run tó ṣètò ìràpadà, (2) Jésù Kristi, “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run,” tó pèsè ìràpadà náà, àti (3) àwọn arákùnrin Jésù nípa tẹ̀mí. Nípa jíjẹ búrẹ́dì àti mímú wáìnì, àwọn arákùnrin Jésù ń fi hàn pé àwọn wà níṣọ̀kan pátápátá pẹ̀lú Kristi. (Jòhánù 1:29; 1 Kọ́ríńtì 10:16, 17) Wọ́n tún fi hàn pé àwọ́n wà nínú “májẹ̀mú tuntun” gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí Ọlọ́run fẹ̀mí yàn. Àwọn ni yóò bá Kristi jọba lọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba àti àlùfáà.—Lúùkù 22:20; Jòhánù 14:2, 3; Ìṣípayá 5:9, 10.

Ìgbà wo ló yẹ ká máa ṣe Ìrántí Ikú Kristi? Ìdáhùn náà á ṣe kedere tá a bá rántí pé Jésù yan ọjọ́ kan ní pàtó tó fi ṣe ayẹyẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, ìyẹn ọjọ́ àjọyọ Ìrékọjá. Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún làwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń ṣàjọyọ̀ Ìrékọjá nígbà yẹn, ìyẹn jẹ́ lọ́jọ́ Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà àwọn Hébérù. Ó sì ti lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún tí wọ́n ti ń ṣe é láti máa fi ṣèrántí ọjọ́ tí Jèhófà gbà wọ́n là lọ́nà ìyanu. Ó ṣe kedere pé ohun tí Jésù ń sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni pé kí wọ́n máa fi ọjọ́ kan náà yẹn ṣèrántí ọjọ́ tí Ọlọ́run tipasẹ̀ ikú Kristi ṣètò ohun tó máa mú káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù rí ìgbàlà tó ju tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ. Ìdí nìyẹn táwọn Kristẹni tòótọ́ fi máa ń lọ sí ibi Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa lẹ́ẹ̀kan lọ́dún ní àyájọ́ ọjọ́ tó bọ́ sí Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà àwọn Hébérù.

Ṣé torí pé wọ́n kàn fẹ́ máa tẹ̀ lé ààtò ìsìn kan ni wọ́n ṣe ń ṣe é ni? Ká sòótọ́, ńṣe làwọn èèyàn tí wọ́n ń ṣe ààtò gbígba ara Olúwa ń ṣe é torí pé wọ́n kàn fẹ́ máa tẹ̀ lé ààtò ìsìn kan. Obìnrin tó kọ ọ̀rọ̀ sínú ìwé ìròyìn tá a mẹ́nu kàn níṣáájú, ìyẹn ìwé ìròyìn Time sọ pé: “Ohun kan wà tó máa ń mú kí àwọn ààtò ìsìn tó ti wà látọdúnmọdún tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe máa dùn mọ́ èèyàn.” Bíi tàwọn Kátólíìkì kan lóde òní, obìnrin yẹn fẹ́ kí wọ́n máa ṣayẹyẹ náà ní èdè Látìn bí wọ́n ti ń ṣe é nígbà àtijọ́. Kí nìdí? Ó sọ pé: “Mo fẹ́ máa gbọ́ orin Ìsìn Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa ní èdè tí mi ò gbọ́ nítorí ọ̀pọ̀ ìgbà ni kì í dùn mọ́ mi tí wọ́n bá fi èdè Gẹ̀ẹ́sì kọ orin náà.”

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ọ̀kẹ́ àìmoye èèyàn tó mọyì Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa máa ń gbádùn ṣíṣe é lédè abínibi wọn níbikíbi tí wọ́n bá ń gbé. Inú wọ́n máa ń dùn láti túbọ̀ lóye ohun tí ikú Kristi túmọ̀ sí àti bó ti ṣeyebíye tó. Irú àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ bẹ́ẹ̀ yẹ ní ṣíṣe àṣàrò lé lórí ká sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn jálẹ̀ ọdún. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé ṣíṣe Ìrántí Ikú Kristi ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti máa rántí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ ní sí wọn. Ó ń mú kí wọ́n lè máa “pòkìkí ikú Olúwa, títí yóò fi dé.”—1 Kọ́ríńtì 11:26.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ara nǹkan tí wọ́n tún máa ń pe ayẹyẹ náà ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, Ẹbọ Mímọ́, Ìdàpọ̀ Mímọ́ àti Ìsìn Mímọ́. Ohun táwọn kan tó ń ṣayẹyẹ yìí sọ ni pé, ó túmọ̀ sí ìdúpẹ́ oore.

b Bí àpẹẹrẹ, wo Mátíù 27:46; Lúùkù 8:11; nínú Bíbélì Ìròyìn Ayọ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Báwo ni Jésù ṣe dá Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa sílẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Jésù ló dá Ìrántí ikú rẹ̀ sílẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Wọ́n ń ṣe Ìrántí Ikú Jésù Kristi