Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tímótì Ti Ṣe Tán, Ó sì Wù Ú Láti Sin Jèhófà

Tímótì Ti Ṣe Tán, Ó sì Wù Ú Láti Sin Jèhófà

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Tímótì Ti Ṣe Tán, Ó sì Wù Ú Láti Sin Jèhófà

“ṢÓ O ti ṣe tán?” Ǹjẹ́ ẹni kẹ́ni tí ì béèrè irú ìbéèrè yìí lọ́wọ́ rẹ rí?— Ó dájú pé ṣe lẹni tó bá bi ọ́ bẹ́ẹ̀ fẹ́ mọ̀ bóyá o ti ṣe tán ni. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣeé ṣe kẹ́ni yẹn fẹ́ mọ̀ bóyá o ti mú ìwé tó o fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ dání, tàbí bóyá o ti múra ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn sílẹ̀. A óò ri í nínú àpilẹ̀kọ yìí pé Tímótì ti ṣe tán.

Yàtọ̀ síyẹn, ó ń wu Tímótì láti sin Jèhófà. Ṣé o mọ ohun tíyẹn náà túmọ̀ sí?—Nígbà tí wọ́n pe Tímótì pé kó wá sin Ọlọ́run, ńṣe ló ṣe bíi ti ìránṣẹ́ Ọlọ́run kan tó sọ pé: “Èmi nìyí! Rán mi.” (Aísáyà 6:8) Tímótì gbádùn ayé ẹ dọ́ba nítorí pé ó wù ú, ó sì ṣe tán láti sin Jèhófà. Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ bó ṣe rí bẹ́ẹ̀?—

Kò pẹ́ sígbà tí wọ́n pa Jésù ní Jerúsálẹ́mù ni wọ́n bí Tímótì sí ìlú kan tó ń jẹ́ Lísírà. Ìlú ọ̀hún jìnnà díẹ̀ sí Jerúsálẹ́mù. Ìyá rẹ̀ àgbà tó ń jẹ́ Lọ́ìsì àti ìyá rẹ̀ tó ń jẹ́ Yùníìsì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ tí òtítọ́ inú Ìwé Mímọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀. Kódà, láti kékeré ni wọ́n ti ń kọ́ Tímótì ní Ìwé Mímọ́.—2 Tímótì 1:5; 3:15.

Nígbà tí Tímótì wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà dé Lísírà, ẹnu iṣẹ́ ìwàásù wọn àkọ́kọ́ tó gbé wọn dé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibi ni wọ́n wà nígbà náà. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà yìí gan-an ni ìyá-ìyá Tímótì àti ìyá rẹ̀ di Kristẹni. Ṣé o fẹ́ mọ̀ nípa inúnibíni tó dé bá Pọ́ọ̀lù àti Bánábà?— Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé, àwọn ọ̀tá àwọn Kristẹni sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n lù ú bolẹ̀, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn òde ìlú. Wọ́n rò pó ti kú ni.

Àwọn tó gba ohun tí Pọ́ọ̀lù ń kọ́ wọn gbọ́ ló sún mọ́ ọn, tí wọ́n sì ṣaájò rẹ̀ tó fi tún dìde. Ọjọ́ kejì ni Pọ́ọ̀lù àti Bánábà fi Lísírà sílẹ̀, ṣùgbọ́n kò pẹ́ tí wọ́n fi tún padà wá síbẹ̀. Nígbà tí wọ́n padà dé, Pọ́ọ̀lù sọ àsọyé kan, èyí tó fi sọ fáwọn tó ti di onígbàgbọ́ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ ìjọba Ọlọ́run.” (Ìṣe 14:8-22) Ṣó o mọ ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn?— Ohun tó ní lọ́kàn ni pé àwọn kan á máa han àwọn tó ń sin Ọlọ́run léèmọ̀. Nígbà tó yá, Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí Tímótì pé: ‘Gbogbo ẹni tó bá fẹ́ fayé rẹ̀ sin Ọlọ́run ni wọ́n máa ṣe inúnibíni sí.’—2 Tímótì 3:12; Jòhánù 15:20.

Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù òun Bánábà kúrò ní Lísírà, ìlú wọn ni wọ́n forí lé. Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn ni Pọ́ọ̀lù òun Sílà padà lọ sọ́dọ̀ àwọn tó di onígbàgbọ́ láwọn ibi tí Pọ́ọ̀lù òun Bánábà ti wàásù tẹ́lẹ̀, kí wọ́n lè lọ fún wọn lókun. Nígbà tí wọ́n dé Lísírà, inú Tímótì dùn gan-an láti rí wọn lẹ́ẹ̀kan sí i! Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà tiẹ̀ wá sọ pé kí Tímótì jẹ́ káwọn jọ máa lọ, inú rẹ̀ dùn gan-an ni. Ojú ẹsẹ̀ ni Tímótì gbà láti tẹ̀ lé wọn nítorí pé ó ṣe tán, ó sì wù ú láti tẹ̀ lé wọn.—Ìṣe 15:40–16:5.

Àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta gbéra, wọ́n fẹsẹ̀ rin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ibùsọ̀ kí wọ́n tó débi tí wọ́n ti wọkọ̀ ojú omi. Lẹ́yìn tí wọ́n gúnlẹ̀ èbùté, wọ́n rìn lọ sí Tẹsalóníkà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ló di Kristẹni ní Tẹsalóníkà. Ṣùgbọ́n inú bí àwọn kan, wọ́n sì fẹ́ dá wàhálà sílẹ̀. Nígbà tó di pé ẹ̀mí Pọ́ọ̀lù, Sílà àti Tímótì wà nínú ewu, wọ́n yáa forí lé Bèróà.—Ìṣe 17:1-10.

Ọ̀kan Pọ́ọ̀lù ò balẹ̀ rárá nítorí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́ ní Tẹsalóníkà, ó yáa rán Tímótì padà síbẹ̀. Ṣé o mọ ohun tó mú kó ṣe bẹ́ẹ̀?— Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ sọ nígbà tó yá fáwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà, ó ní òun ṣe bẹ́ẹ̀ ‘láti fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in àti láti tù yín nínú kí ẹnì kankan máa bàa yẹsẹ̀.’ Ṣé o sì mọ̀dí tí Pọ́ọ̀lù fi rán Tímótì tó jẹ́ ọmọdé ní irú iṣẹ́ tó lágbára bẹ́ẹ̀?— Ìdí ni pé àwọn alátakò yẹn ò fi bẹ́ẹ̀ mọ Tímótì, ó sì wu òun náà láti lọ. Ìwà onígboyà gbáà nìyẹn! Kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tó débẹ̀? Nígbà tí Tímótì padà dé ọ̀dọ̀ Pọ́ọ̀lù, ó ròyìn báwọn ará Tẹsalóníkà ṣe nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tó. Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé sí wọn pé: ‘A ti tù wá nínú nítorí yín.’—1 Tẹsalóníkà 3:2-7.

Láti ìgbà yẹn ni Tímótì àti Pọ́ọ̀lù ti jọ ń ṣe iṣẹ́ Jèhófà, ó sì tó ọdún mẹ́wàá tí wọ́n fi jọ wà. Ẹ̀yin ìgbà yẹn ni wọ́n fi Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní Róòmù, Tímótì tó jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n sì lọ dúró tì í. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n, ó kọ lẹ́tà kan sáwọn ará tó wà ní Fílípì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ Tímótì gan-an ló bá a kọ̀wé ọ̀hún. Pọ́ọ̀lù sọ pé: ‘Màá rán Tímótì sí yín láìpẹ́, nítorí èmi kò ní ẹlòmíràn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run bíi tirẹ̀, tí yóò sì bójú tó yín dáadáa.’—Fílípì 2:19-22; Hébérù 13:23.

Ẹ wo bí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí á ṣe wú Tímótì lórí tó! Ohun tó mú kí Pọ́ọ̀lù fẹ́ràn Tímótì tó báyẹn ni pé Tímótì ṣe tán, ó sì tún wù ú láti sin Ọlọ́run. Ó yẹ kí ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìbéèrè:

Ibo ni Tímótì dàgbà sí, kí ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ débẹ̀?

Kí ni Tímótì ṣe nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà sọ fún un pé kó máa bá àwọn lọ?

Báwo ni Tímótì ṣe hùwà onígboyà, kí sì ló mú kí Pọ́ọ̀lù nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Kí ló ń ṣẹlẹ̀ níbí?