Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Lẹni Tó Kúnjú Ìwọ̀n Láti Ṣàkóso Aráyé?

Ta Lẹni Tó Kúnjú Ìwọ̀n Láti Ṣàkóso Aráyé?

Àkànṣe Àsọyé Fún Gbogbo Èèyàn

Ta Lẹni Tó Kúnjú Ìwọ̀n Láti Ṣàkóso Aráyé?

Alákòóso wo ló lè

• gba aráyé lọ́wọ́ àìríná àìrílò, tí gbogbo èèyàn á máa rí oúnjẹ gidi jẹ kánú, tí wọ́n á sì rílé tó yẹ ọmọlúwàbí gbé?

• ṣe é tí ò ní í sí àjálù mọ́, táráyé á bọ́ lọ́wọ́ omíyalé, ìjì líle àti ìmìtìtì ilẹ̀?

• sọ gbogbo àìsàn di ohun àtijọ́, tó sì máa mú kí ara àwọn arúgbó rí bíi tìgbà tí wọ́n wà lọ́dọ̀ọ́?

• sọ ogun dìtàn, tá a wá mú kí àlàáfíà jọba, kó má sì sí ohunkóhun tó lè fa ìpáyà mọ́?

• mú kí ilẹ̀ ayé yìí, omi, afẹ́fẹ́, igbó àti gbogbo ohun abẹ̀mí àti aláìlẹ́mìí tí Ọlọ́run dá padà dára bíi tìgbà tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá wọn, tá a sì sọ ayé yìí di ọgbà ẹlẹ́wà níbi tí gbogbo nǹkan á ti rọ̀ ṣọ̀mù?

Alákòóso kan ṣoṣo ló wà tó lè ṣe gbogbo ohun rere tá a sọ yìí. Tá wá ni Alákòóso ọ̀hún? Inú àsọyé kan tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ta Lẹni Tó Kúnjú Ìwọ̀n Láti Ṣàkóso Aráyé?” la ti máa mọ onítọ̀hún. Àsọyé yìí máa wáyé ní ilẹ̀ tí ó ju igba ó lé ọgbọ̀n lọ kárí ayé. Lọ́pọ̀ ibi Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ti máa sọ àsọyé yìí lọ́jọ́ Sunday, April 6, 2008. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ̀ á dùn láti sọ àkókò àti àdírẹ́sì ibi tí wọ́n ti máa sọ àsọyé náà fún ọ. A ó máa retí rẹ o.