Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹni Tó Mọ Ìnira Wa

Ẹni Tó Mọ Ìnira Wa

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ẹni Tó Mọ Ìnira Wa

Jòhánù 11:33-35

“Ẹ̀MÍ ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò ni kéèyàn mọ bí nǹkan ṣe rí lára ọmọnìkejì ẹni.” Ohun tí àgbàlagbà kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ nípa ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tó jẹ́ ànímọ́ àtàtà nìyẹn. Àmọ́, Jèhófà Ọlọ́run ló lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò jù lọ. Ó máa ń mọ̀ ọ́n lára táwọn èèyàn rẹ̀ bá ń jìyà. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Jèhófà ní hàn nínú àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ àtàwọn ohun tó ṣe nígbà tó wà láyé. (Jòhánù 5:19) Àpẹẹrẹ kan ni ti ìṣẹ̀lẹ̀ tó wà nínú Jòhánù 11:33-35.

Nígbà tí ikú dá ẹ̀mí Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù légbodò, Jésù lọ sí abúlé táwọn arábìnrin Lásárù ń gbé. Ó dájú pé ìbànújẹ́ ńlá ni ikú Lásárù jẹ́ fáwọn arábìnrin rẹ̀, Màríà àti Màtá. Jésù nífẹ̀ẹ́ ìdílé yìí gan-an ni. (Jòhánù 11:5) Kí ni Jésù máa wá ṣe? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí [Jésù] rí i tí [Màríà] ń sunkún àti àwọn Júù tí wọ́n bá a wá tí wọ́n ń sunkún, ó kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú; ó sì wí pé: ‘Ibo ni ẹ tẹ́ ẹ sí?’ Wọ́n wí fún un pé: ‘Olúwa, wá wò ó.’ Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” (Jòhánù 11:33-35) Kí nìdí tí Jésù fi sunkún? Òótọ́ ni pé Lásárù ọ̀rẹ́ Jésù àtàtà kú, àmọ́ ó máa tó jí i dìde. (Jòhánù 11:41-44) Kí ló wá mú kí Jésù sunkún?

Tún wo ohun tó wà nínú ẹsẹ Bíbélì tá a fà yọ lókè yìí. Wàá rí i pé nígbà tí Jésù rí i tí Màríà àtàwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ń sunkún, Jésù “kérora,” ó sì “dààmú.” Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n lò níhìn-ín ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ tọ́ka sí ohun tó dun èèyàn wọra. a Ohun tí Jésù rí yẹn dun Jésù wọra gan-an. Bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Jésù hàn kedere nígbà tí omijé bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú rẹ̀. Dájúdájú, Jésù máa ń mọ̀ ọ́n lára tó bá rí i táwọn èèyàn ń jẹ̀rora. Ǹjẹ́ ìwọ náà ti sunkún rí nígbà tó o rí i tí ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ ń sunkún?—Róòmù 12:15.

Ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò tí Jésù ní jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Baba rẹ̀, Jèhófà dáadáa. Má gbàgbé pé Jésù gbé ànímọ́ Baba rẹ̀ yọ lọ́nà pípé pérépéré, débi tó fi sọ pé: “Ẹni tí ó ti rí mi ti rí Baba pẹ̀lú.” (Jòhánù 14:9) Nítorí náà, tá a bá kà á pé “Jésù bẹ̀rẹ̀ sí da omijé,” ó yẹ kí èyí mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ń mọ̀ ọ́n lára táwọn tó ń sìn ín bá ń jìyà. Àní àwọn míì lára àwọn tó kọ Bíbélì jẹ́rìí sí èyí pàápàá. (Aísáyà 63:9; Sekaráyà 2:8) Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ni Jèhófà?

A máa ń fẹ́ sún mọ́ ẹni tó bá lẹ́mìí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò. Tá a bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí tọ́kàn wa bá bà jẹ́, a sábà máa ń fẹ́ sún mọ́ àwọn èèyàn tó mọ ohun tó jẹ́ ìṣòro wa tó sì lè tù wá nínú. Ẹ ò rí i pé, ó yẹ ká sún mọ́ Jèhófà jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọlọ́run tó jẹ́ aláàánú, tó máa ń mọ ìnira wa lára, tó sì tún mọ ohun tó ń pa wá lẹ́kún?—Sáàmù 56:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n tú sí “da omijé” sábà máa ń túmọ̀ sí kéèyàn “rọra máa sunkún.” Èyí yàtọ̀ sí ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò fún ẹkún Màríà àtàwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀, torí ìyẹn lè túmọ̀ sí kéèyàn máa “ké tàbí kígbe gan-an.”