Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá

Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Jésù Fi Iṣẹ́ Ìyanu Mú Àwọn Aláìsàn Lára Dá

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó pé o wà níbi tí ohun tó ò ń kà náà ti ṣẹlẹ̀, kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA MÁTÍÙ 15:21-28.

Báwo lo ṣe rò pé nǹkan máa rí lára ìyá yìí?

․․․․․

Irú ohùn wo lo “gbọ́” tí Jésù fi sọ̀rọ̀ ní àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé e yìí?

24 ․․․․․ 26 ․․․․․ 28 ․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Ìgbà mélòó ni Jésù fi hàn nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe rẹ̀ pé òun kò ní wo ọmọ obìnrin yìí sàn?

․․․․․

Kí nìdí tí Jésù fi kọ́kọ́ fẹ́ wo ọmọdébìnrin yẹn sàn?

․․․․․

Kí wá nìdí tí Jésù fi wo ọmọ yẹn sàn?

․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Bí Jésù ṣe jẹ́ afòyebánilò.

․․․․․

Bí ìwọ náà ṣe lè máa lo irú ànímọ́ yìí nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú àwọn èèyàn.

․․․․․

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA MÁÀKÙ 8:22-25.

Kí lohun tó o rò pé o máa rí, tó o sì máa gbọ́ nínú abúlé yẹn àti nígbà tó o bá kúrò láàárín abúlé yẹn?

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Kí lo rò pé ó fà á tí Jésù fi mú ọkùnrin yìí kúrò láàárín abúlé kó tó la ojú rẹ̀?

․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Bí ọ̀rọ̀ àwọn aláàbọ̀ ara ṣe rí lára Jésù, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò fìgbà kan rí jẹ́ aláàbọ̀ ara.

․․․․․

ÈWO LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ LÁRA ÀWỌN ÌTÀN INÚ ẸSẸ BÍBÉLÌ MÉJÈÈJÌ YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․