Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù
Nípa Ìjọba Ọlọ́run
Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?
Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan tí yóò ṣàkóso lórí gbogbo ayé. Jésù sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: . . . ‘Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’”—Mátíù 6:9, 10; Dáníẹ́lì 2:44.
Àwọn wo ni yóò jẹ́ alákòóso Ìjọba Ọlọ́run?
Nítorí kí Jésù lè jẹ́ Alákòóso Ìjọba Ọlọ́run ni wọ́n ṣe bí i. Áńgẹ́lì kan sọ fún ìyá Jésù pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba.” (Lúùkù 1:30-33) Jésù yan àwọn kan nínú àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀. Ó sọ fáwọn àpọ́sítèlí rẹ̀ pé: “Ẹ̀yin ni ẹ ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi; èmi sì bá yín dá májẹ̀mú kan, gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba mi ṣe bá mi dá májẹ̀mú kan, fún ìjọba kan.” (Lúùkù 22:28, 29; Dáníẹ́lì 7:27) Iye àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó máa ṣàkóso pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000].—Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1.
Ibo ló máa jẹ́ ibùjókòó Ìjọba Ọlọ́run?
Ìjọba Ọlọ́run yóò máa ṣàkóso láti ọ̀run wá. Jésù sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí mo bá bá ọ̀nà mi lọ, tí mo sì pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín [ní ọ̀run], èmi tún ń bọ̀ wá, èmi yóò sì gbà yín sí ilé sọ́dọ̀ ara mi, pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀. . . . Mo ń bá ọ̀nà mi lọ sọ́dọ̀ Baba.”—Jòhánù 14:2, 3, 12; Dáníẹ́lì 7:13, 14.
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe sí ìwà ibi tó ń ṣẹlẹ̀ láyé?
Jésù máa palẹ̀ àwọn èèyàn búburú mọ́ kúrò lórí ilẹ̀ ayé. Jésù sọ pé: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn [Jésù] bá dé Mátíù 25:31-34, 46.
nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì . . . Àwọn wọ̀nyí yóò sì lọ sínú ìkékúrò àìnípẹ̀kun, ṣùgbọ́n àwọn olódodo sínú ìyè àìnípẹ̀kun.”—Àwọn wo ló máa wà lórí ilẹ̀ ayé tí Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣàkóso lé lórí?
Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5; Sáàmù 37:29; 72:8) Àwọn èèyàn tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti máa fìfẹ́ hàn sí ọmọnìkejì wọn ni yóò kún inú ayé. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:34, 35.
Kí ni Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún aráyé?
Jésù yóò mú àìsàn kúrò láyé. Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó bá ogunlọ́gọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ “nípa ìjọba Ọlọ́run, ó sì mú àwọn tí wọ́n nílò ìwòsàn lára dá.” (Lúùkù 9:11) Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Jòhánù rí Jésù tí Ọlọ́run ti jíǹde nínú ìran, ó sọ pé: “Mo sì rí ọ̀run tuntun kan àti ilẹ̀ ayé tuntun kan . . . mo gbọ́ tí ohùn rara láti orí ìtẹ́ náà wí pé: ‘Wò ó! Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́.’”—Ìṣípayá 21:1-4.
Ìjọba Ọlọ́run yóò sọ ayé di Párádísè. Ọ̀daràn kan tí wọ́n pa lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù sọ pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Jésù sì wí fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:42, 43; Aísáyà 11:4-9.
Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo orí kẹjọ nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.