Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ló mú kí owó òróró onílọ́fínńdà tí Màríà lò wọ́n tó bẹ́ẹ̀?

Ọjọ́ díẹ̀ ṣáájú kí Jésù tó kú, Màríà arábìnrin Lásárù, mú “orùba alabásítà òróró onílọ́fínńdà, ojúlówó náádì, olówó ńlá gan-an” wá, ó sì dà á sí orí Jésù. (Máàkù 14:3-5; Mátíù 26:6, 7; Jòhánù 12:3-5) Máàkù àti Jòhánù sọ pé owó lọ́fínńdà náà tó ọ̀ọ́dúnrún owó dínárì, ìyẹn nǹkan bí owó iṣẹ́ alágbàṣe fọ́dún kan.

Ibo ni wọ́n ti máa ń rí lọ́fínńdà olówó ńlá yìí? Ewéko kékeré olóòórùn dídùn kan (ìyẹn Nardostachys jatamansi), tí wọ́n sábà máa ń rí lórí Òkè Himalaya, ni wọ́n fi ń ṣe náádì yìí tàbí sípíkénádì tí wọ́n dárúkọ nínú Bíbélì. Wọ́n sábà máa ń dọ́gbọ́n fi nǹkan míì lú náádì olówó ńlá yìí tàbí kí wọ́n tiẹ̀ ṣe ayédèrú pàápàá. Àmọ́, “ojúlówó náádì” ni Máàkù àti Jòhánù pe èyí tóbìnrin yìí gbé wá. Bí wọ́n ṣe pè é ní lọ́fínńdà olówó ńlá fi hàn pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilẹ̀ Íńdíà tó jìnnà gan-an ni lọ́fínńdà náà ti wá.

Kí nìdí tí Máàkù fi sọ pé Màríà “já orùba alabásítà náà”? Ọrùn tóóró ni orùba alabásítà sábà máa ń ní, tí wọ́n á fi lè dé e pa kí ìtasánsán lọ́fínńdà iyebíye inú rẹ̀ má bàa lọ. Lórí kókó yìí, Alan Millard sọ nínú ìwé kan tó pè ní Discoveries From the Time of Jesus, pé: “Kò ṣòro láti lóye bí obìnrin tínú rẹ̀ ń dùn yìí ṣe fi ìtara já [orùba alabásítà náà], tó sì da gbogbo lọ́fínńdà inú rẹ̀ tán pátá.” Èyí ló jẹ́ ká mọ ìdí tí “ilé náà [fi] wá kún fún ìtasánsán òróró onílọ́fínńdà náà.” (Jòhánù 12:3) Lóòótọ́, ẹ̀bùn olówó ńlá ni, àmọ́ ohun tí Màríà ṣe tó bẹ́ẹ̀ ó jú bẹ́ẹ̀ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé kò tíì pẹ́ tí Jésù jí Lásárù tó jẹ́ arákùnrin rẹ̀ ọ̀wọ́n dìde. Èyí fi hàn pé ńṣe ló ń fi ìmọrírì hàn fún ohun tí Jésù ṣe.—Jòhánù 11:32-45.

Ṣé ìlú Jẹ́ríkò méjì ló wà ni àbí ẹyọ kan?

Mátíù, Máàkù àti Lúùkù ṣàkọsílẹ̀ iṣẹ́ ìyanu kan tí Jésù ṣe nítòsí ìlú Jẹ́ríkò. (Mátíù 20:29-34; Máàkù 10:46-52; Lúùkù 18:35-43) Mátíù àti Máàkù sọ pé Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu yẹn nígbà tó “ń jáde kúrò” ní ìlú Jẹ́ríkò. Àmọ́, ohun tí Lúùkù sọ ni pé ìgbà tí Jésù “ń sún mọ́” ìlú Jẹ́ríkò ló ṣe iṣẹ́ ìyanu yẹn.

Nígbà tí Jésù wà láyé, ṣé ìlú Jẹ́ríkò méjì ló wà àbí ẹyọ kan? Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, ìyẹn ìwé Bible Then & Now, sọ pé: “Nígbà ayé Jésù, wọ́n ti tún ìlú Jẹ́ríkò míì kọ́ sí nǹkan bíi máìlì kan sápá gúúsù ìlú Jẹ́ríkò ti tẹ́lẹ̀. Ọba Hẹ́rọ́dù Ńlá sì kọ́ ààfin ìgbà òtútù síbẹ̀.” Ìwé mìíràn tó sọ̀rọ̀ nípa bí ìwalẹ̀pìtàn ṣe jẹ́ ká mọ àwọn ìtàn Bíbélì, ìyẹn ìwé tí wọ́n pè ní Archaeology and Bible History, jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Ìlú méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń jẹ́ Jẹ́ríkò nígbà ayé Jésù. . . . Èyí tó jẹ́ tàwọn Júù tó ti wà tẹ́lẹ̀ jẹ́ nǹkan bíi máìlì kan sí ìlú Jẹ́ríkò tàwọn ará Róòmù.”

Nítorí náà, ó lè jẹ́ pé, ìgbà tí Jésù ń jáde kúrò nílùú Jẹ́ríkò tàwọn Júù ló ṣe iṣẹ́ ìyanu yẹn tàbí kó jẹ́ ìgbà tó sún mọ́ ìlú Jẹ́ríkò tàwọn ará Róòmù. Ó sì tún lè jẹ́ ìgbà tó ń jáde kúrò nílùú Jẹ́ríkò tàwọn ará Róòmù tàbí ìgbà tó sún mọ́ tàwọn Júù ló ṣe é. Ó ṣe kedere pé, ohun tá a ti wá mọ̀ báyìí nípa nǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n kọ ọ̀rọ̀ yìí ti jẹ́ ká lóye ohun tó dà bíi pé ó fẹ́ ta kora yẹn dáadáa.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ìgò lọ́fínńdà alabásítà

[Credit Line]

© Réunion des Musées Nationaux/Art Resource, NY