Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ìkún-omi Ìgbà Ayé Nóà Kárí Ayé Lóòótọ́?

Ṣé Ìkún-omi Ìgbà Ayé Nóà Kárí Ayé Lóòótọ́?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Ìkún-omi Ìgbà Ayé Nóà Kárí Ayé Lóòótọ́?

Ó ti ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ọdún lọ báyìí tí Ìkún-omi ìgbà ayé Nóà ti wáyé. Torí náà, kò sẹ́nì kankan tí Ìkún-omi náà ṣojú rẹ̀ tó wà láyé báyìí tó lè sọ fún wa nípa rẹ̀. Àmọ́, àkọsílẹ̀ kan wà tó sọ nípa àjálù yẹn. Ó ní Ìkún-omi náà bo òkè tó ga jù lọ nígbà yẹn mọ́lẹ̀.

Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Àkúnya omi náà sì ń bá a lọ fún ogójì ọjọ́ lórí ilẹ̀ ayé . . . Omi náà sì kún bo ilẹ̀ ayé mọ́lẹ̀ lọ́pọ̀lọ́pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo òkè ńlá gíga lábẹ́ gbogbo ọ̀run fi wá di èyí tí a bò mọ́lẹ̀. Títí dé ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [nǹkan bí ẹsẹ bàtà méjìlélógún] ni omi náà fi kún bò wọ́n mọ́lẹ̀, àwọn òkè ńlá sì di bíbò mọ́lẹ̀.”—Jẹ́nẹ́sísì 7:17-20.

Ìtàn omi tó kún bo gbogbo ayé mọ́lẹ̀ yìí lè máa ṣe àwọn kan ní kàyéfì. Wọ́n lè máa rò pé àbùmọ́ ní láti wà nínú ìtàn yẹn tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ àròsọ. Kò rí bẹ́ẹ̀ o, òótọ́ pọ́ńbélé ni! Àní títí di ìsinsìnyí omi ló ṣì gba apá ibi tó pọ̀ jù lọ láyé. Tá a bá wọn bí ayé ṣe fẹ̀ tó, tá a wá pín in sọ́nà mẹ́wàá, ibi tí omi òkun gbà níbẹ̀ á tó nǹkan bíi méje. Nítorí náà, tá a bá ní ká sọ ọ́, omi tó bo ayé mọ́lẹ̀ nígbà yẹn ṣì wà títí dòní. Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé àwọn òkìtì yìnyín tó wà láyé yọ́, omi òkun á kún débi táá fi lè bo àwọn ìlú bíi New York àti Tokyo mọ́lẹ̀ bámúbámú.

Àwọn onímọ̀ nípa ilẹ̀ ayé tí wọ́n ń ṣàyẹ̀wò bí ojú ilẹ̀ ṣe rí lápá ìwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé ó tó ọgọ́rùn-ún ìkún-omi tó ti wáyé rí lágbègbè náà. Wọ́n ní ńṣe ni ọ̀kan lára irú ìkún-omi bẹ́ẹ̀ dédé rọ́ lu àgbègbè náà. Wọ́n sọ pé omi náà ga tó ẹgbẹ̀ta mítà [ẹgbẹ̀rún méjì ẹsẹ bàtà], ṣíṣàn rẹ̀ sì yára tó ọkọ̀ tó ń sá eré ọgọ́rùn-ún ó lé márùn-ún kìlómítà láàárín wákàtí kan. Irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n ṣàwárí ti mú káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé ó ṣeé ṣe kí ìkún-omi tó kárí ayé ti ṣẹlẹ̀ rí lóòótọ́.

Àmọ́ ṣá, ó dá àwọn tó gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì lójú ṣáká pé ìkún-omi kan ti wà rí tó kárí ayé. Ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ni. Jésù sọ fún Ọlọ́run pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là, kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tímótì 2:3, 4) Ibo ni Pọ́ọ̀lù ti máa rí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó máa kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó bá jẹ́ pé ìtàn àròsọ ló wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?

Yàtọ̀ sí pé Jésù gbà pé Ìkún-omi wáyé, ó tún gbà pé ó kárí ayé. Nígbà tó ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ tó pabanbarì nípa wíwàníhìn rẹ̀ àti ìparí ètò àwọn nǹkan, ó fi àwọn nǹkan tí yóò máa ṣẹlẹ̀ nígbà náà wé ìgbà ayé Nóà. (Mátíù 24:37-39) Àpọ́sítélì Pétérù náà sọ nípa Ìkún-omi tó wáyé nígbà ayé Nóà, ó ní: “Nípasẹ̀ ohun wọnnì, ayé ìgbà yẹn jìyà ìparun nígbà tí a fi àkúnya omi bò ó mọ́lẹ̀.”—2 Pétérù 3:6.

Tó bá jẹ́ pé ìtàn àròsọ ni ìtàn nípa Nóà àti Ìkún-omi tó wáyé nígbà ayé rẹ̀, a jẹ́ pé ìkìlọ̀ tí Pétérù àti Jésù fún àwọn tó ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn kò ṣeé tẹ̀ lé nìyẹn. Dípò kí ìtàn Ìkún-omi jẹ́ ìkìlọ̀ fáwọn èèyàn, èrò pé ó jẹ́ ìtàn àròsọ kò ní jẹ́ kéèyàn lóye ìkìlọ̀ Bíbélì yìí, èyí sì léwu fún èèyàn torí pé ó lè mú kéèyàn pa run nígbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀, èyí tó lágbára ju Ìkún-omi ọjọ́ Nóà lọ.—2 Pétérù 3:1-7.

Nígbà tí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípa àánú tó ń fi hàn sáwọn èèyàn rẹ̀ nígbà gbogbo, ó sọ̀rọ̀ lọ síbi Ìkún-omi, ó sọ pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti búra pé omi Nóà kì yóò tún kọjá lórí ilẹ̀ ayé mọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni mo búra pé dájúdájú, ìkannú mi kì yóò ru sí ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí lọ́nà mímúná.” Bó ṣe dájú pé Ìkún-omi ìgbà ayé Nóà bo ayé mọ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ló dájú pé inú rere onífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run náà máa wà pẹ̀lú àwọn tó bá ń gbẹ́kẹ̀ lé e.—Aísáyà 54:9.