Ṣé Bó Ṣe Wù Wá La Ṣe Lè Sin Ọlọ́run?
Ṣé Bó Ṣe Wù Wá La Ṣe Lè Sin Ọlọ́run?
“Ẹ̀SÌN ti wà nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ ènìyàn.” Ọ̀jọ̀gbọ́n Alister Hardy ló sọ̀rọ̀ yìí nínú ìwé kan tó ń jẹ́ The Spiritual Nature of Man. Ó sì dà bíi pé àbájáde ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí kín ọ̀rọ̀ yẹn lẹ́yìn. Ìwádìí náà fi hàn pé tí wọ́n bá kó ọgọ́rùn-ún èèyàn jọ, èèyàn mẹ́rìndínláàádọ́rùn ló máa sọ pé àwọn ń ṣe ẹ̀sìn kan.
Ìwádìí náà tún fi hàn pé oríṣi ẹ̀sìn mọ́kàndínlógún làwọn èèyàn ń ṣe, ó sì yani lẹ́nu pé àwọn tí wọ́n sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni lára wọn pín sínú oríṣiríṣi ìjọ tó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlógójì [37,000]. Ǹjẹ́ èyí kò máa ṣe ọ́ ní kàyéfì pé bóyá gbogbo ìjọsìn táwọn èèyàn ń ṣe yìí ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà? Ṣé bó bá ṣe wu kálukú wa la ṣe lè sin Ọlọ́run?
A ò kàn lè sọ pé ohun tí olúkúlùkù wa bá rò lórí ọ̀ràn pàtàkì yìí ló tọ́. Ó bọ́gbọ́n mu pé ká mọ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ ká tó lè mọ̀ ọ́n, a ní láti wo ohun tí Bíbélì tó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé Jésù Kristi fúnra rẹ̀ sọ nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” (Jòhánù 17:17) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ olóòótọ́ sì jẹ́rìí sí èyí nígbà tó sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́.”—2 Tímótì 3:16.
Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìjọsìn ni Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Nínú ìtàn, a rí àpẹẹrẹ irú àwọn ìjọsìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà àtèyí tí kò tẹ́wọ́ gbà. Tá a bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí, a ó lè mọ ohun tá a gbọ́dọ̀ ṣe àti ohun tí a kò gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run bàa lè tẹ́wọ́ gba ìjọsìn wa.
Àpẹẹrẹ Kan Láyé Ìgbàanì
Jèhófà Ọlọ́run tipasẹ̀ wòlíì Mósè fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láwọn òfin tó jẹ́ kí wọ́n mọ ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. Òfin yìí la mọ̀ sí Òfin Mósè. Nígbà táwọn èèyàn náà bá ṣohun tó wà nínú Òfin Mósè, Ọlọ́run máa ń tẹ́wọ́ gbà wọ́n gẹ́gẹ́ bí èèyàn rẹ̀, ó sì máa ń bù kún wọn. (Ẹ́kísódù 19:5, 6) Pẹ̀lú bí Ọlọ́run ṣe ń bù kún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó, gbogbo ìgbà kọ́ ni wọ́n ń fi tọkàntọkàn ṣe ìjọsìn tí inú Ọlọ́run dùn sí. Àìmọye ìgbà ni wọ́n pa ìjọsìn Jèhófà tì, tí wọ́n wá lọ ń lọ́wọ́ nínú ẹ̀sìn àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wọn.
Ní ọ̀rúndún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni, nígbà ayé wòlíì Ìsíkíẹ́lì àti wòlíì Jeremáyà, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò tẹ̀ lé Òfin Ọlọ́run, wọ́n ń bá àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè tó wà láyìíká wọn ṣe wọléwọ̀de. Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń tẹ̀ lé àṣà wọn, tí wọ́n sì ń bá wọn ṣayẹyẹ ọdún, ńṣe ni wọ́n ń ṣe àmúlùmálà ìjọsìn. Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ń sọ pé: “Kí a dà bí àwọn orílẹ̀-èdè, bí ìdílé àwọn ilẹ̀, ní ṣíṣe ìránṣẹ́ fún igi àti òkúta.” (Ìsíkíẹ́lì 20:32; Jeremáyà 2:28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n sọ pé àwọn ń jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run, wọ́n tún lọ ń forí balẹ̀ fún “òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ,” àní wọ́n tiẹ̀ ń fi àwọn ọmọ wọn rúbọ sáwọn òrìṣà wọ̀nyí.—Ìsíkíẹ́lì 23:37-39; Jeremáyà 19:3-5.
Àwọn awalẹ̀pìtàn pe irú ìjọsìn yìí ní àmúlùmálà ẹ̀sìn, ìyẹn ni bíbọ ọ̀kan-ò-jọ̀kan òrìṣà pa pọ̀. Nínú ayé lónìí, tí àyè wà fún olúkúlùkù èèyàn láti gba ohun tó bá wù ú gbọ́, ìgbàgbọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ó yẹ ká fara mọ́ èrò èyíkéyìí tí ẹnikẹ́ni bá gbé kalẹ̀, kódà bó bá jẹ́ lórí ọ̀ràn ẹ̀sìn. Nítorí náà, wọ́n rò pé kò burú kéèyàn máa sin Ọlọ́run lọ́nà tó bá wuni. Ṣé bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn lóòótọ́? Ṣé ọ̀rọ̀ pé kéèyàn fara mọ́ èrò àwọn ẹlòmíì ni? Jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì aláìṣòótọ́ ń ṣe nínú ẹ̀sìn kan tó gbilẹ̀ láàárín wọn, ká sì wá wo ibi tọ́rọ̀ wọn já sí.
Àmúlùmálà Ẹ̀sìn Táwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Ń Ṣe
“Àwọn ibi gíga” ni wọ́n ń pe àwọn ojúbọ òrìṣà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń ṣe àmúlùmálà ìjọsìn wọn. Lára àwọn ohun tó wà níbẹ̀ ni pẹpẹ, ọ̀pá tùràrí, ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ tí wọ́n fi òkúta ṣe àti òpó ọlọ́wọ̀, ó sì tún hàn gbangba pé ère Áṣérà tí wọ́n fi igi gbẹ́ wà níbẹ̀, ìyẹn abo òrìṣà àwọn ará Kénáánì tí wọ́n gbà pé ó ń fáwọn àgàn lọ́mọ. Irú àwọn ojúbọ yìí pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ Júdà. Àwọn Ọba kejì orí kẹtàlélógún ẹsẹ karùn-ún àti ìkẹjọ mẹ́nu kan “àwọn ibi gíga nínú àwọn ìlú ńlá Júdà àti ní àwọn àyíká Jerúsálẹ́mù, . . . láti Gébà [ibodè ìhà àríwá] títí dé Bíá-ṣébà [ibodè ìhà gúúsù].”
Àwọn ibi gíga wọ̀nyí tún ni ibi táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti “ń rú èéfín ẹbọ sí Báálì, sí oòrùn àti sí òṣùpá àti sí àwọn àgbájọ ìràwọ̀ sódíákì àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run.” Wọ́n ní ilé fáwọn “kárùwà ọkùnrin inú tẹ́ńpìlì . . . nínú ilé Jèhófà,” wọ́n sì ń mú àwọn ọmọ wọn “la iná kọjá sí Mólékì.”—2 Àwọn Ọba 23:4-10.
Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ère tí wọ́n fi amọ̀ ṣe ní ìlú Jerúsálẹ́mù àti gbogbo ilẹ̀ Júdà, èyí tó sì pọ̀ jù ni wọ́n rí nínú àwọn àwókù ilé àdáni. Obìnrin tó wà níhòòhò tó sì ní ọmú ńlá ni wọ́n fi èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn ère kéékèèké yìí mọ. Àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé àwọn ère wọ̀nyí jọ Áṣítórétì àti ti Áṣérà, ìyẹn abo òrìṣà tí wọ́n ló máa ń fáwọn àgàn lọ́mọ. Àwọn ère wọ̀nyí ni wọ́n gbà gbọ́ pé wọ́n jẹ́ “ṣìgìdì tó ń sọ àgàn dọlọ́mọ.”
Kí lèrò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípa àwọn ibi tí wọ́n ti ń ṣe àmúlùmálà ìjọsìn yìí? Ọ̀jọ̀gbọ́n Ephraim Stern, láti ilé ìwé gíga Hebrew University ṣàlàyé pé púpọ̀ nínú àwọn ibi gíga yìí ni wọ́n “yà sí mímọ́ fún Yahweh [ìyẹn Jèhófà].” Ó sì dà bíi pé àwọn ìkọ̀wé tí wọ́n rí lára àwọn ohun tí wọ́n hú jáde nínú ilẹ̀ ibẹ̀ kín ọ̀rọ̀ ọ̀jọ̀gbọ́n yìí lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀kan sọ pé, “mo súre fún ọ lórúkọ Yahweh ti Samáríà àti áṣérà rẹ̀,” òmíràn tún sọ pé, “mo súre fún ọ lórúkọ Yahweh ti Téménì àti áṣérà rẹ̀!”
Àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń da ìjọsìn mímọ́ ti Jèhófà Ọlọ́run pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn àwọn kèfèrí tó ń tini lójú. Ìyọrísí rẹ̀ ni pé wọ́n di oníwà ìbàjẹ́, ìjọsìn wọn sì di ẹlẹ́gbin. Ojú wo ni Ọlọ́run fi wo bí wọ́n ṣe ń da ìjọsìn mímọ́ pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kèfèrí yìí?
Ohun Tí Ọlọ́run Ṣe sí Àmúlùmálà Ìjọsìn
Ọlọ́run gbẹnu wòlíì Ìsíkíẹ́lì sọ bí inú ṣe bí Òun sí sísọ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ ìjọsìn mímọ́ di aláìmọ́, ó sì tún bẹnu àtẹ́ lù ú. Ó sọ pé: “Ní gbogbo ibi gbígbé yín, àwọn ìlú ńlá pàápàá yóò pa run di ahoro, àwọn ibi gíga yóò sì di ahoro, kí wọ́n lè wà ní ìparundahoro, kí àwọn pẹpẹ yín lè di ahoro, kí a sì wó wọn ní ti tòótọ́, kí a lè mú kí àwọn òrìṣà ẹlẹ́bọ́tọ yín kásẹ̀ nílẹ̀, kí a sì ké àwọn pẹpẹ tùràrí yín lulẹ̀, kí a sì nu àwọn iṣẹ́ yín kúrò.” (Ìsíkíẹ́lì 6:6) Kò sí àníàní pé Jèhófà kò fojúure wo irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀, kò sì tẹ́wọ́ gbà á rárá àti rárá.
Jèhófà Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìparun wọn ṣe máa wáyé. Ó ní: “Kíyè sí i, èmi yóò ránṣẹ́, . . . sí Nebukadirésárì ọba Bábílónì, ìránṣẹ́ mi, ṣe ni èmi yóò mú wọn wá láti gbéjà ko ilẹ̀ yìí, àti láti gbéjà ko àwọn olùgbé rẹ̀ àti láti gbéjà ko gbogbo orílẹ̀-èdè wọ̀nyí tí ó yí i ká; dájúdájú, èmi yóò yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun . . . Gbogbo ilẹ̀ yìí yóò sì di ibi ìparundahoro.” (Jeremáyà 25:9-11) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí nìyẹn. Lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì wá kógun ja Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì pa ìlú yẹn àti tẹ́ńpìlì rẹ̀ run yán-ányán-án.
Nígbà tí ọ̀jọ́gbọ́n Stern tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lẹ́ẹ̀kan ń sọ̀rọ̀ nípa ìparun Jerúsálẹ́mù, ó sọ pé àwọn àwókù táwọn awalẹ̀pìtàn rí “jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ (nínú 2 Àwọn Ọba 25:8 àti 2 Kíróníkà 36:18-19) nípa bí ìlú náà ṣe pa run, bí wọ́n ṣe fi iná sun ún, tí wọ́n sì wó àwọn ilé ibẹ̀ àtàwọn ògiri rẹ̀.” Ó tún sọ pé: “Ẹ̀rí yìí táwọn awalẹ̀pìtàn rí nípa ìtàn ìparun Jerúsálẹ́mù . . . wà lára àwọn ẹ̀rí tó jọni lójú jù lọ láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti lọ ṣèwádìí nípa Bíbélì.”
Ẹ̀kọ́ Wo Léyí Kọ́ Wa?
Ẹ̀kọ́ pàtàkì tó kọ́ wa ni pé Ọlọ́run kò fara mọ́ ìjọsìn tó bá ń da àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́, àṣà tàbí ààtò ẹ̀sìn èyíkéyìí mìíràn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pẹ̀lú lóye kókó pàtàkì yìí dáadáa, ó sì fi í sọ́kàn. Nígbà tó ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bíi Júù kan, ńṣe ló kẹ́kọ̀ọ́ láti di Farisí, ó kàwé dáadáa, ó sì tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa òfin àwọn Farisí. Àmọ́ kí ló wá ṣe lẹ́yìn tó kẹ́kọ̀ọ́ tó sì gbà pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí? Ó sọ pé: “Àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi.” Ó pa irú ìgbésí ayé tó ti ń gbé tẹ́lẹ̀ tì, ó sì dẹni tó ń tọ Kristi lẹ́yìn tọkàntọkàn.—Fílípì 3:5-7.
Nítorí pé Pọ́ọ̀lù jẹ́ míṣọ́nnárì tó ń rìnrìn àjò, àṣà tí wọ́n ń tẹ̀ lé nínú onírúurú ẹ̀sìn àti èrò oríṣiríṣi àwọn ọ̀mọ̀ràn kì í ṣàìmọ̀ fún un. Ìdí nìyẹn tó fi sọ fáwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Kọ́ríńtì pé: “Àjọpín wo ni ìmọ́lẹ̀ ní pẹ̀lú òkùnkùn? Síwájú sí i, ìbáramu wo ni ó wà láàárín Kristi àti Bélíálì? Tàbí ìpín wo ni olùṣòtítọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? Ìfohùnṣọ̀kan wo sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní pẹ̀lú àwọn òrìṣà? . . . ‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà wí, ‘kí ẹ sì jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́’; ‘dájúdájú, èmi yóò sì gbà yín wọlé.’”—2 Kọ́ríńtì 6:14-17.
Ní báyìí tá a ti wá mọ̀ pé kì í ṣe bó bá ṣe wu kálukú ló ṣe lè sin Ọlọ́run, ẹ jẹ́ ká bi ara wa pé: ‘Irú ìjọsìn wo ni Ọlọ́run fọwọ́ sí? Báwo ni mo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run? Kí sì lohun tó yẹ kí n ṣe láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu?’
Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn ìbéèrè míì tó o lè ní látinú Bíbélì. A rọ̀ ọ́ pé kó o kàn sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bá sún mọ́ ọ jù lọ tàbí kó o kọ̀wé sáwa tá a tẹ ìwé ìròyìn yìí láti béèrè pé kẹ́nì kan wá máa kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ ní àkókò àti ibi tó bá rọrùn fún ẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Ojúbọ tí wọ́n ti ń bọ òrìṣà láyé àtijọ́, ní Tel Arad, lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì
[Credit Line]
Garo Nalbandian
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Àwọn ère Áṣítórétì tí wọ́n rí nínú ilé àwọn ará Jùdíà láyé àtijọ́
[Credit Line]
Fọ́tò © Israel Museum, ní ìlú Jerúsálẹ́mù; Israel Antiquities Authority ló yọ̀ǹda fọ́tò yìí