Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé “Orúkọ Tá Ò Gbọ́dọ̀ Pè” Ni?

Ṣé “Orúkọ Tá Ò Gbọ́dọ̀ Pè” Ni?

Ṣé “Orúkọ Tá Ò Gbọ́dọ̀ Pè” Ni?

ỌWỌ̀N bìrìkìtì onírin kan wà tí wọ́n ń pè ní Gateway Arch ní etí odò Mississippi nílùú St. Louis, ní ìpínlẹ̀ Missouri. Òun ni ohun ìrántí tó ga jù lọ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó ga tó ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ọgbọ̀n [630] ẹsẹ̀ bàtà. Ẹ̀gbẹ́ ọwọ̀n yìí ni wọ́n kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ńlá kan tí kò ga tó ọwọ̀n yìí, tí wọ́n ń pè ní Old Cathedral sí.

Nígbà tí ìwé pẹlẹbẹ kan táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì yẹn fi sọ ìtàn rẹ̀, èyí tí wọ́n pè ní The Story of the Old Cathedral, ń ṣàlàyé iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe sókè àbáwọlé ṣọ́ọ̀ṣì náà, ó ní: “Wọ́n fi wúrà fín lẹ́tà ọ̀rọ̀ Hébérù mẹ́rin kan tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run, èyí tó jẹ́ orúkọ tá ò gbọ́dọ̀ pè, sí ọ̀gangan iwájú ṣọ́ọ̀ṣì yẹn lókè.” Lẹ́tà Hébérù mẹ́rin yìí יהוה (YHWH) tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run lédè Hébérù wà níwájú ṣọ́ọ̀ṣì yẹn kedere, bá a ṣe ń wò ó nínú àwòrán yìí.

Ó ní láti jẹ́ pé, nígbà tí wọ́n kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ńlá yẹn lọ́dún 1834, àwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì St. Louis yẹn gbà pé ó yẹ kí orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n fi lẹ́tà Hébérù kọ náà wà níbi tó ti máa hàn kedere. Kí ló wá dé tí wọ́n fi wá ka orúkọ Ọlọ́run yìí sí “orúkọ tá ò gbọ́dọ̀ pè”?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó ń jẹ́ New Catholic Encyclopedia sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà táwọn Júù padà dé láti ìgbèkùn Bábílónì ní ọ̀rúndún kẹfà ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó ní: “Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ki àṣejù bọ bí wọ́n ṣe láwọn ń bọ̀wọ̀ fún orúkọ náà Yahweh, [ìyẹn lẹ́tà Hébérù mẹ́rin náà YHWH, tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n fi fáwẹ̀lì ‘a’ àti ‘e’ sí kó lè ṣeé pè], wọ́n wá ń fi àwọn ọ̀rọ̀ bí ÁDÓNÁÌ [Olúwa] tàbí ÉLÓHÍMÙ [Ọlọ́run] rọ́pò rẹ̀. . . . Àṣà tí wọ́n ń dá yìí ló mú káwọn èèyàn gbàgbé bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ náà Yahweh.” Bó ṣe di pé àwọn èèyàn kò lo orúkọ Ọlọ́run mọ́ nìyẹn. Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọn ò mọ bí wọ́n ṣe ń pe orúkọ yẹn ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ mọ́, bí orúkọ Ọlọ́run ṣe wá di ohun tí wọ́n ò lè pè mọ́ nìyẹn.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè sọ pé báyìí ni wọ́n ṣe ń pe orúkọ Ọlọ́run gan-an ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ohun tó ṣe pàtàkì ni pé, lílo orúkọ yẹn yóò jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ wàá fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ kàn máa pè ọ́ ní “ọ̀gbẹ́ni” tàbí “omidan,” àbí wàá fẹ́ kí wọ́n máa fi orúkọ rẹ gan-an pè ọ́? Kódà, kó jẹ́ pé èdè míì ni wọ́n ń sọ, tí wọn ò sì lè pe orúkọ rẹ dáadáa, wàá ṣì fẹ́ kí wọ́n máa pè ẹ́ lórúkọ tó ò ń jẹ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe náà nìyẹn. Ó fẹ́ ká máa lo orúkọ òun, ìyẹn Jèhófà.

Lédè Yorùbá, ọ̀pọ̀ èèyàn ló mọ orúkọ Ọlọ́run sí “Jèhófà.” Ǹjẹ́ kò yẹ kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run máa fi orúkọ rẹ̀ yìí pè é, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sún mọ́ ọn? Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.”—Jákọ́bù 4:8.