Ẹni Tó Máa Ń Dárí Jini
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ẹni Tó Máa Ń Dárí Jini
“ẸNI rere ni ọ́, Jèhófà, o sì ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Gbólóhùn tó ń tuni lára yìí ni Bíbélì fi mú un dá wa lójú pé Jèhófà Ọlọ́run máa ń dárí jini lọ́pọ̀lọpọ̀. Ohun kan tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù fi hàn gbangba pé Jèhófà máa ń dárí jini “lọ́nà títóbi.”—Aísáyà 55:7.
Ọ̀kan lára àwọn tó sún mọ́ Jésù jù lọ ni Pétérù. Àmọ́, lálẹ́ ọjọ́ tó ku ọ̀la kí wọ́n pa Jésù, Pétérù jẹ́ kí ìbẹ̀rù èèyàn mú òun dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá kan. Nínú àgbàlá kan tó wà nítòsí ibi tí wọ́n ti ń gbẹ́jọ́ Jésù lọ́nà tí kò bófin mu, Pétérù sẹ́ Jésù gbangba gbàǹgbà pé òun ò mọ̀ ọ́n rí, ẹ̀ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sì ṣe bẹ́ẹ̀. Kété tí Pétérù sẹ́ kanlẹ̀ nígbà kẹta pé òun ò mọ Jésù rí, Jésù “yí padà, ó sì bojú wo Pétérù.” (Lúùkù 22:55-61) Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára Pétérù nígbà tí Jésù bojú wò ó? Nígbà tí Pétérù rí bí ẹ̀ṣẹ̀ tóun dá ṣe wúwo tó, ó “bara jẹ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sunkún.” (Máàkù 14:72) Ó ṣeé ṣe kí àpọ́sítélì tó ronú pìwà dà yìí ronú pé bóyá ni Ọlọ́run á dárí ji òun bóun ṣe sẹ́ Jésù lẹ́ẹ̀mẹta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí.
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó bá Pétérù sọ ọ̀rọ̀ kan, èyí tó fi hàn pé Ọlọ́run ti dárí jì Pétérù lóòótọ́. Jésù ò sọ̀kò ọ̀rọ̀ lu Pétérù, bẹ́ẹ̀ ni kò dá a lẹ́bi. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó bi Pétérù pé: “Ìwọ ha nífẹ̀ẹ́ mi bí?” Pétérù fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa, ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Jésù wá fèsì pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” Jésù tún béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì bóyá ó nífẹ̀ẹ́ òun, Pétérù tún fún un lésì kan náà. Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn ẹlẹ́ẹ̀kejì tiẹ̀ lágbára ju tàkọ́kọ́ lọ. Jésù tún sọ pé: “Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké.” Lẹ́yìn èyí ni Jésù tún wá béèrè ìbéèrè kan náà yìí lọ́wọ́ Pétérù lẹ́ẹ̀kẹta pé: “Ìwọ ha ní ìfẹ́ni fún mi bí?” Wàyí o, “ẹ̀dùn-ọkàn” bá Pétérù, ó sì sọ pé: “Olúwa, ìwọ mọ ohun gbogbo; ìwọ mọ̀ pé mo ní ìfẹ́ni fún ọ.” Jésù wí fún un pé: “Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké.”—Jòhánù 21:15-17.
Kí nìdí tí Jésù fi béèrè ìbéèrè tó ti mọ ìdáhùn rẹ̀ tẹ́lẹ̀? Jésù máa ń mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn, nítorí náà, ó mọ̀ pé Pétérù nífẹ̀ẹ́ òun. (Máàkù 2:8) Ìbéèrè tí Jésù bi Pétérù yẹn fún Pétérù láǹfààní láti fi dá Jésù lójú lẹ́ẹ̀mẹ́ta pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù fi dá Pétérù lóhùn, ìyẹn, “Máa bọ́ àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn mi. . . . Máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn àgùntàn mi kéékèèké. . . . Máa bọ́ àwọn àgùntàn mi kéékèèké,” mú kó dá àpọ́sítélì tó ronú pìwà dà náà lójú pé Jésù ṣì fọkàn tán òun. Ẹ wo iṣẹ́ pàtàkì tí Jésù gbé lé Pétérù lọ́wọ́, pé kó máa bójú tó ohun kan tó ṣeyebíye gan-an, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí wọ́n jẹ́ ẹni bí àgùntàn! (Jòhánù 10:14, 15) Ó dájú pé ara máa tu Pétérù gan-an nígbà tó wá mọ̀ pé Jésù ṣì fọkàn tán òun!
Ó hàn gbangba pé Jésù dárí ji àpọ́sítélì Pétérù. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù máa ń gbé àwọn ànímọ́ Bàbá rẹ̀ yọ lọ́nà pípé, tó sì máa ń ṣe nǹkan bíi ti Bàbá rẹ̀, a lè gbà pé Jèhófà pẹ̀lú dárí ji Pétérù. (Jòhánù 5:19) Jèhófà kì í lọ́tìkọ̀ láti dárí jini, Ọlọ́run aláàánú ni, ‘ó sì ṣe tán láti dárí ji’ ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà. Ìtura gbáà lèyí jẹ́!