Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọmọbìnrin Kan Tó Ṣe Bí Ọmọdébìnrin Ilẹ̀ Ísírẹ́lì Àtijọ́

Ọmọbìnrin Kan Tó Ṣe Bí Ọmọdébìnrin Ilẹ̀ Ísírẹ́lì Àtijọ́

Ọmọbìnrin Kan Tó Ṣe Bí Ọmọdébìnrin Ilẹ̀ Ísírẹ́lì Àtijọ́

NÍGBÀ tí Ìrántí Ikú Kristi ku ọ̀sẹ̀ méjì, gbogbo ìdílé arákùnrin kan tó ń jẹ́ Sales tí wọ́n ń gbé nílùú Praia Grande lórílẹ̀-èdè Brazil, ṣàkọsílẹ̀ orúkọ àwọn tí wọ́n fẹ́ pè wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Wọ́n fún Abigayl tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà ní ìwé ìkésíni kan ṣoṣo, wọ́n sì bí i pé ta ló fẹ́ pè wá síbi Ìrántí Ikú Kristi.

Abigayl fèsì pé: “Ọkùnrin kan tó máa ń rẹ́rìn-ín sí mi ni.”

Àwọn òbí rẹ̀ wá bi í pé: “Ta lọkùnrin náà?”

Abigayl fèsì pé: “Ọkùnrin kan tó máa ń jókòó sórí kẹ̀kẹ́ àwọn aláàbọ̀ ara ni.”

Ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà, Abigayl fi ọkùnrin náà han àwọn òbí rẹ̀. Orúkọ ọkùnrin náà ni Walter, ilé rẹ̀ kò jìnnà rárá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Lọ́dún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sẹ́yìn, nígbà tí ọkùnrin yìí wà lẹ́ni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n, jàǹbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀ sí i, èyí sì mú kí ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rọ. Ó ní àwọn ẹ̀ṣọ́ méjì, nítorí pé olówó ni. Lẹ́yìn táwọn ẹ̀ṣọ́ náà ti gba Abigayl láyè láti bá Walter sọ̀rọ̀, àwọn òbí Abigayl sọ fún Walter pé ọmọbìnrin àwọn fẹ́ fún un ní ìwé ìkésíni kan.

Lẹ́yìn tí Abigayl fún Walter ní ìwé ìkésíni náà tán, ó sọ fún un pé: “Ìwé ìkésíni tó pọ̀ ni wọ́n fún gbogbo àwọn tó wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, àmọ́ ẹyọ kan ṣoṣo ni wọ́n fún èmi. Nítorí náà, ẹ̀yin nìkan ni mo pè. Tẹ́ ò bá wá, á jẹ́ pé mi ò rí èèyàn kankan pè nìyẹn. Ṣùgbọ́n tẹ́ ẹ bá wá, inú mi á dùn gan-an ni, àmọ́ inú Jèhófà ló máa dùn jù.”

Nígbà tó di ọjọ́ Ìrántí Ikú Kristi, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn ṣe láti múra sílẹ̀ fún Ìrántí Ikú Kristi tó máa wáyé nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, Abigayl pẹ̀lú sì wà níbẹ̀. Nígbà tí Walter ń kọjá lọ lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rẹ̀, ó rí Abigayl níbi tó ti ń ṣiṣẹ́, ló bá sọ fún awakọ̀ rẹ̀ pé kó dúró. Walter ṣí wíńdò ọkọ̀, ó sì béèrè ohun tí Abigayl ń ṣe. Abigayl sọ fún un pé àwọn ń tún Gbọ̀ngàn Ìjọba ṣe ni, nítorí tiẹ̀ làwọn sì ṣe ń ṣe é.

Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn ara Abigayl ò balẹ̀ rárá. Bí àsọyé ṣe bẹ̀rẹ̀ báyìí, ńṣe ló ń wọ̀tún-wòsì bóyá Walter ti dé. Láìpẹ́, Walter àtàwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ dé. Ẹ̀rín bọ́ lẹ́nu Abigayl. Lẹ́yìn tí àsọyé yẹn parí, Walter sọ pé òun tiẹ̀ ti múra láti rìnrìn àjò lọ sí ìlú mìíràn àmọ́ nítorí Abigayl lòun ṣe yí èrò òun padà tóun sì wá síbi Ìrántí Ikú Kristi. Walter wá sọ pé: “Àsọyé yẹn tù mí lára gan-an ni.” Ó ní kí wọ́n fún òun ní Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, látìgbà yẹn ló sì ti ń wá sí ìpàdé.

Nígbà tó yá, obìnrin kan tó jẹ́ àbúrò Walter sọ pé òun fẹ́ mọ Abigayl tí ẹ̀gbọ́n òun máa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ nígbà gbogbo yìí. Nígbà tó rí Abigayl, inú rẹ̀ dùn gan-an nítorí pé ọmọ àtàtà ni. Obìnrin náà sọ pé: “Mo ti wá rí ìdí tí inú ẹ̀gbọ́n mi fi máa ń dùn.”

Walter ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ ó sì ń wá sáwọn ìpàdé. Kódà, ó máa ń dáhùn nípàdé, ó sì máa ń sọ àwọn ohun tó ti kọ́ fáwọn èèyàn. Kò sí àní-àní pé ọmọbìnrin tó ń jẹ́ Abigayl yìí rán wa létí ọmọdébìnrin kan nílẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́ tó ran Náámánì lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ náà.—2 Àwọn Ọba 5:2-14.