Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayọ̀ Mi Ò Lópin Bí Mo Ti Ń Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

Ayọ̀ Mi Ò Lópin Bí Mo Ti Ń Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

Ayọ̀ Mi Ò Lópin Bí Mo Ti Ń Ṣe Ìfẹ́ Ọlọ́run

Gẹ́gẹ́ bí Bill Yaremchuk ṣe sọ ọ́

Lóṣù March ọdún 1947, mo gbéra ìrìn àjò lọ síbi tí wọ́n rán mi lọ gẹ́gẹ́ bí míṣọ́nnárì lorílẹ̀-èdè Singapore tó jìnnà réré. Ìrìn àjò náà bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ mélòó kan lẹ́yìn tí mo ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹjọ ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó wà ní South Lansing, nígbà yẹn, ní ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà

ẸNI tá a jọ máa ṣiṣẹ́ nílẹ̀ òkèèrè ni Arákùnrin Dave Farmer, ọmọ ilẹ̀ Kánádà bíi tèmi tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì keje ti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. A wọ ọkọ̀ òkun tó ń jẹ́ Marine Adder, táwọn ológun ti lò nígbà kan rí, tó gbéra láti ìlú San Francisco, ní ìpínlẹ̀ California lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.

Ibi àkọ́kọ́ tá a ti dúró lójú ọ̀nà ni ìlú Hong Kong tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé. Ohun tá a rí níbẹ̀ mà bani nínú jẹ́ o! Ogun Àgbáyé Kejì ti ba gbogbo ibẹ̀ jẹ́. Àwọn èèyàn sún sílẹ̀ bẹẹrẹbẹ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ebi ń pa wọ́n, ó dà bíi pé wọ́n ti fẹ́rẹ̀ẹ́ kú. Kíá la wọnú ọkọ̀ náà padà tá a sì forí lé ìlú Manila, olú ìlú orílẹ̀-èdè Philippines.

Níbí yìí náà, a tún rí ọṣẹ́ tí ogun náà ṣe. Ní èbúté Manila, a rí àwọn ìgbòkun ọkọ̀ táwọn orílẹ̀-èdè tó ń bá àwọn ọmọ ogun Jámánì jà ju bọ́ǹbù lù tí wọ́n sì rì sómi. Ìṣẹ́ ń ṣẹ́ àwọn èèyàn ibẹ̀ gan-an ni. A pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bíi mélòó kan tí wọ́n mú wa lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ní àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá yí.

Ibi kejì tá a ti dúró lójú ọ̀nà ni etíkun Batavia (tí wọ́n ń pè ní Jakarta nísinsìnyí) lórílẹ̀-èdè Indonesia. Ogun abẹ́lé ń lọ lọ́wọ́ nílùú yẹn wọ́n sì ń jà nítòsí ibi tá a wà, nítorí èyí wọn ò jẹ́ ká bọ́ sílẹ̀ nínú ọkọ̀ náà. Bí ọkọ̀ wa ṣe forí lé orílẹ̀-èdè Singapore, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ohun tá a máa bá pàdé níbẹ̀. Ṣé báwọn ìlú Ìlà Oòrùn ayé tó lẹ́wà gan-an tá a má ń rí àwòrán wọn nínú ìwé ṣe dà rèé?

Nígbà tó máa fi di ọjọ́ bíi mélòó kan, ńṣe ni gbogbo ohun tí mò ń ṣàníyàn lé lórí ti fò lọ. Ohun kan wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà tó mú kó dá wa lójú hán-ún pé Ọlọ́run fọwọ́ sí iṣẹ́ témi àti Dave fẹ́ lọ ṣe.

Bí Wọ́n Ṣe Gbà Wá Láyè Láti Gbé Orílẹ̀-Èdè Náà

Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù kan tá a ti kúrò nílùú San Francisco lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọkọ̀ wa gúnlẹ̀ sí erékùṣù St. John tó jẹ́ ibi tí wọ́n tí máa ń dá ọkọ̀ òkun dúró fún àyẹ̀wò kí wọ́n tó fún wọn láṣẹ láti gúnlẹ̀ sí orílẹ̀-èdè Singapore. Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba tí wọ́n máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn àlejò tó fẹ́ wọ̀lú wá sínú ọkọ̀ wa láti wo àwọn èrò ọkọ̀ náà, wọ́n sì lu ìwé ìwọ̀lú wa ní òǹtẹ̀ “A Gbà Yín Láyè.” Lówùúrọ̀ ọjọ́ kejì ọkọ̀ wa gúnlẹ̀ sí èbúté. Lẹ́yìn tí aláṣẹ kan nínú ọkọ̀ náà yẹ àwọn ìwé wa wò, a jáde kúrò nínú ọkọ̀.

Lọ́jọ́ kejì, a padà lọ sí èbúté láti lọ dágbére fún àwọn míṣọ́nnárì tá a jọ ń rìnrìn àjò bọ̀ tẹ́lẹ̀. Wọ́n ń bá ìrìn àjò wọn lọ sí ilẹ̀ Íńdíà àti Ceylon (tó ń jẹ́ Sri Lanka nísinsìnyí). Nígbà tí ọ̀gá ọkọ̀ náà rí wa, ó sọ̀kalẹ̀ wá sí èbúté láti kò wá lójú. Inú bí i gan-an, ó sì jágbe mọ́ wa pé kò yẹ ká jáde kúrò nínú ọkọ̀ náà. Ká tó dé èbúté, ọ̀gá àwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sọ́ràn àwọn àlejò tó fẹ́ wọ̀lú, Ọ̀gbẹ́ni Haxworth, ti pàṣẹ fún un pé kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ká jáde kúrò nínú ọkọ̀ náà nígbà tá a bá dé èbúté ní Singapore. Àwa ò mọ̀ pé ọ̀gá yẹn ti pàṣẹ bẹ́ẹ̀, aláṣẹ inú ọkọ̀ tó jẹ́ ká kúrò nínú ọkọ̀ náà ò sì mọ̀.

Nígbà tí wọ́n mú wa dé iwájú Ọ̀gbẹ́ni Haxworth ńṣe ló fárígá. Ó pariwo mọ́ wa pé wọ́n ti ní ká má wọ orílẹ̀-èdè Singapore. Nítorí pé a kò mọ̀ pé wọn ò fẹ́ ká wọ̀lú wọn, a fi ìwé ìwọ̀lú wa tí wọ́n lù ní òǹtẹ̀ “A Gbà Yín Láyè” hàn án. Ó fìbínú já ìwé ìwọ̀lú náà gbà lọ́wọ́ wa, ó sì wọ́gi lé òǹtẹ̀ “A Gbà Yín Láyè” náà. Àmọ́, ẹ̀pa ò bóró mọ́, ọkọ̀ òkun náà ti lọ! Ọdún kan gbáko ni Ọ̀gbẹ́ni Haxworth fi fàwọn ìwé ìwọ̀lú wa pa mọ́. Níkẹyìn, ó fi òǹtẹ̀ “A Gbà Yín Láyè” lù wọ́n, ó sì dá wọn padà fún wa.

Iṣẹ́ Ìwàásù Wa Sèso Rere Nílẹ̀ Singapore

Nígbà tá a dé síbẹ̀ lóṣù April ọdún 1947, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Joshua ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣoṣo tó wà lórílẹ̀-èdè Singapore. Iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, ìyẹn àwọn tó máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù ló ń ṣe títí di ìgbà ikú rẹ̀ ní ọdún mélòó kan lẹ́yìn ọdún1970. Láìpẹ́, àwọn kan tí wọ́n ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ohun tí wọ́n kọ́ fáwọn èèyàn. Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ àdúrà wa pé káwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i wá sínú iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí náà.—Mátíù 9:37, 38.

Lọ́dún 1949, àwọn míṣọ́nnárì mẹ́fà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kọkànlá ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì dé sí orílẹ̀-èdè Singapore nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni Haxworth ti lọ sí ìlú England fún ìsinmi ọlọ́jọ́ gbọọrọ. Ìgbà yẹn ni Dave tá a ti jọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì fún ọdún mélòó kan rí i pé ó di dandan kóun fi orílẹ̀-èdè Singapore sílẹ̀ nítorí àìlera. Ó ṣí lọ sí orílẹ̀-èdè Australia, níbi tó ti ń sìn tọkàntọkàn títí dìgbà ikú rẹ̀ ní ọdún 1973. Lára àwọn mẹ́fà tó dé yẹn ni Aileen Franks, ẹni tí mo fi ṣaya lọ́dún 1956.

Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá, a ti kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí àwọn àti ọmọ wọn sì ti di olùjọ́sìn Jèhófà. Àní títí di báyìí, àwọn kan lára wọn wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún nílẹ̀ òkèèrè. Ìrírí kan tó ń múnú mi dùn ni ti Lester àti Joanie Haynes, tọkọtaya ará Amẹ́ríkà tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Singapore. A bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà kan láàárín ọdún 1950 sí 1959. Tọkọtaya náà tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì ṣèrìbọmi nígbà tí wọ́n padà sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Nígbà tó yá, Lester àti Joanie ṣe iṣẹ́ ìwàásù tó sèso rere tó sì ń fún wọn láyọ̀. Wọ́n ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà títí kan àwọn ọmọ wọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta.

Joanie kọ̀wé sí mi pé: “Nígbà tí mó bá rántí ọdún tá a fi wà lórílẹ̀-èdè Singapore, mo rí i pé ó yí ìgbésí ayé wa padà gan-an ni. Ká ní o ò ṣìkẹ́ wa bí ọmọ ni, a ò bá ṣì máa rìn gbéregbère nínú ayé. Inú mi dùn pé ìwọ ló kọ́ Lester lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, nítorí láti ìbẹ̀rẹ̀ ni ìwọ olùkọ́ rẹ̀ ti gbin ìfẹ́ Jèhófà àti ìfẹ́ àwọn ará wa sọ́kàn rẹ̀. Ìfẹ́ náà ṣì wà lọ́kàn rẹ̀ síbẹ̀.”

Ìdílé Wa Sìn Nílẹ̀ Singapore

Lọ́dún 1962 ohun àìròtẹ́lẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ tó wá mú ìyípadà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ bá iṣẹ́ wa. Dókítà tó máa ń tọ́jú ìdílé wa sọ fún Aileen pé ó ti lóyún. Ó wù wá láti máa ṣíṣẹ́ míṣọ́nnárì nìṣó, àmọ́ báwo la ṣe lè máa ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì ká sì tún máa tọ́mọ? Arákùnrin Nathan H. Knorr, tó ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé nígbà yẹn kọ̀wé sí wa ó sì gbà mí níyànjú pé kí n wá iṣẹ́ kan, kí n má bàa kúrò nílẹ̀ Singapore. Èyí kì í ṣohun tó rọrùn rárá.

Ọ̀pọ̀ jù lọ ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó wà nílẹ̀ Singapore ni wọ́n gbà síṣẹ́ láti máa ṣe ọ̀gá nílé iṣẹ́ tó jẹ́ táwọn ará ilẹ̀ òkèèrè. Mi ò ní òye iṣẹ́ kankan nínú iṣẹ́ ajé, nítorí lẹ́yìn tí mo fi ilé ẹ̀kọ́ sílẹ̀ ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàlélógún sẹ́yìn ni mo ti wọṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Nítorí náà, mo san owó fún ilé iṣẹ́ tó máa ń bá èèyàn wáṣẹ́ tó wà nílùú London láti bá mi ṣe ìwé ìwáṣẹ́ tó dá lórí iṣẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ ìsìn nílẹ̀ òkèèrè, wọ́n sì fìwé náà ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ ilé iṣẹ́ ilẹ̀ òkèèrè tó wà nílẹ̀ Singapore.

Èsì tí wọ́n ń kọ ránṣẹ́ sí mi ni pé: “Ó dùn wá pé a ò lè rí àyè nílé iṣẹ́ wa fún ẹni tó nírú ìmọ̀ tó o ní yìí.” Wọ́n sọ pé ìmọ̀ iṣẹ́ tí mo ní ti pọ̀ ju ohun táwọn nílò lọ! Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ oṣù, a bí ọmọ wa, tá a sọ ní Judy. Arákùnrin Knorr ṣèbẹ̀wò sílẹ̀ Singapore nígbà yẹn, ó sì lọ wo Judy àti ìyá rẹ̀ nílé ìwòsàn. Ó fi wá lọ́kàn balẹ̀, ó ní: “Ẹ lè wà nílé àwọn míṣọ́nnárì títí dìgbà tí Bill yóò fi ríṣẹ́.”

Oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, mó rí iṣẹ́ kan síbi tí màá ti máa ṣe alukoro fún ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú kan tó ń ná orílẹ̀-èdè kan sí òmíràn. Owó iṣẹ́ náà tó láti fi gbọ́ bùkátà èmi àti ìdílé mi dé ìwọ̀n àyè kan. Ọdún méjì lẹ́yìn náà ni ilé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú ti Amẹ́ríkà kan gbà mí síṣẹ́, wọ́n sì ń san owó tó jẹ́ ìlọ́po méjì owó iṣẹ́ mi ti tẹ́lẹ̀. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn wá mọ̀ mí dáadáa nílé iṣẹ́ ọkọ̀ òfuurufú yìí, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti lo àkókò tó pọ̀ fún ìdílé mi àti iṣẹ́ ìwàásù.

Iṣẹ́ ìsìn Jèhófà là ń lo ìgbésí ayé wa fún, a sì ń fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́. Èyí wá mú kó ṣeé ṣe fún mi láti ní ọ̀pọ̀ àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ètò Ọlọ́run. Ìyàwó mi wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún padà. Nígbà yẹn iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run ń tẹ̀síwájú gan-an nílẹ̀ Singapore. Ní nǹkan bí ọdún 1965 a ra ilé pẹ̀tẹ́ẹ̀sì kan tó dára gan-an sí àárín ìlú, a sì ń lò ó fún Gbọ̀ngàn Ìjọba wa. Ìjọ mẹ́rin ló ń ṣèpàdé níbẹ̀.

Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa!

Nígbà tó yá, àtakò tó gbóná janjan bẹ́ sílẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù January ọdún 1972, a lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa láti lọ ṣèpàdé gẹ́gẹ́ bí ìṣe wa. Àmọ́, ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi àgádágodo tì pa la bá lẹ́nu ọ̀nà. Wọ́n lẹ ìwé kan mọ́bẹ̀ tó sọ pé wọn kò gba ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láyè mọ́ ní Singapore. Wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa! a

Bí wọ́n ṣe ti Gbọ̀ngàn Ìjọba wa kò dá ìjọsìn wa sí Jèhófà dúró, àmọ́ ìbéèrè tó wà lọ́kàn mi ni pé, ‘Kí ni Ọlọ́run máa fẹ́ kí ìdílé mi ṣe báyìí?’ Mo ronú pé tí wọ́n bá lé wa kúrò ní Singapore, a ò ní lè wá kí àwọn ọ̀rẹ́ wa mọ́. Nítorí náà, mo sọ fún ọ̀gá ilé iṣẹ́ mi pé ṣé ó lè jẹ́ kí n lọ sí Kuala Lumpur, lórílẹ̀-èdè Malaysia láti máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Ìyẹn á wá mú kó rọrùn fún ìdílé wa láti máa wá sí Singapore ká sì tún padà. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé ọ̀gá mi sọ pé kí n lọ ṣe ọ̀gá ilé iṣẹ́ wa tó wà ní Kuala Lumpur. Owó iṣẹ́ yẹn á sọ owó oṣù mi di ìlọ́po méjì tí màá sì tún máa gba àwọn àjẹmọ́nú mìíràn.

Lẹ́yìn náà, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rò ó pé, ‘Ṣé ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé ká kúrò ní Singapore ká sì fi àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa sílẹ̀?’ Ìdílé wa gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀rọ̀ náà. Ohun tá a pinnu ni pé Jèhófà ló mú wa wá síbí yìí. Nítorí náà, mo pinnu pé a ò ní kúrò. Ẹnu ya ọ̀gá mi gidigidi pé mi ò gba iṣẹ́ tó máa mówó gọbọi wọlé fún mi yìí.

Gbígbé tá à ń gbé nílùú tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, tá a sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ kò rọrùn rárá, nítorí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn á mú wa, àwọn á sì jù wá sẹ́wọ̀n. Àwọn ohun kan sì ṣẹlẹ̀ tó mú wa mọyì ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 34:7, ó ní: “Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”

Wọ́n Yàn Wá sí Ibòmíràn

Níkẹyìn lọ́dún 1993, lẹ́yìn tá a ti fi ohun tó lé ní ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta sìn nílẹ̀ Singapore, wọ́n sọ fún wa pé ká lọ sílẹ̀ New Zealand, níbi tá a ó ti máa sìn láìsí kòókòó jàn-ánjàn-án. Ṣé ẹ rí i, ó dùn wá gan-an láti fi àwọn ọ̀rẹ́ wa àtàtà tá a ti wá nífẹ̀ẹ́ gidigidi ní Singapore sílẹ̀. Síbẹ̀, inú wa dùn láti mọ̀ pé ìgbàgbọ́ wọn dúró digbí lórí ìpìlẹ̀ tó lágbára gan-an. Èyí jẹ́ kí wọ́n lè dúró gbọn-in lójú àdánwò.—1 Kọ́ríńtì 3:12-14.

Ní báyìí tá a ti lo ohun tó jú ọdún mẹ́rìnlá lọ nílẹ̀ New Zealand, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara wa ti dara àgbà, èmi àti Aileen ìyàwó mi ṣì ń gbádùn iṣẹ́ ìwàásù wa gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Méjì lára àwọn ọmọ ìyá mi, ìyẹn Mike tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́rìnléláàádọ́rùn-ún [94], àti Peter tó jẹ́ ẹni àádọ́rùn-ún [90] ọdún ṣì ń bẹ láàyè, tí wọ́n ń sin Jèhófà tọkàntọkàn nílẹ̀ Kánádà.

Lọ́dún 1998 ọmọbìnrin wa, Judy, padà sí ibì kan ní Ìlà Oòrùn ayé, ó sì sìn níbẹ̀ fún ọdún mélòó kan. Ó sọ nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà tó kọ sí wa pé: “Ojoojúmọ́ ni mò ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní tó ga lọ́lá tó fún mi láti máa sìn níbì yìí! Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ ẹ̀yin méjèèjì pẹ̀lú, fún gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ onífẹ̀ẹ́ tẹ́ ẹ fún mi àti gbogbo ìsapá àrà ọ̀tọ̀ tẹ́ ẹ ṣe lórí mi, tẹ́ ò sì jáwọ́ lọ́rọ̀ mi.” Lọ́dún 2003 ọmọ wa yìí padà sílẹ̀ New Zealand láti ran èmi àti Aileen lọ́wọ́. b

A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé a wà ní ipò tá a fi lè jẹ́ ìpè Ọ̀gá náà nígbà tó pe àwọn òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i láti ṣe iṣẹ́ ìkórè náà. Ṣíṣe tá a ṣe bẹ́ẹ̀ ti mú ká ní ayọ̀ tó kọjá àfẹnusọ. Nígbà tí ‘ayé yìí bá sì kọjá lọ’ gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, a óò wà níbẹ̀ nígbà tí àgbàyanu ìlérí Ọlọ́run bá ṣẹ pé: “Ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:17.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo Ile-Iṣọ Na ti January 1, 1973 ojú ìwé 20 sí 27.

b Aileen sùn nínú ikú ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù January ọdún 2008, nígbà tá à ń ṣàkójọ àpilẹ̀kọ yìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Joshua ni Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ṣoṣo tó wà nílẹ̀ Singapore nígbà tá a dé síbẹ̀ lọ́dún 1947

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Dave Farmer nílùú Hong Kong, nígbà tá à ń lọ sórílẹ̀-èdè Singapore, lọ́dún 1947

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Èmi àti Aileen rèé lọ́dún 1958

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwa àti ọmọbìnrin wa, Judy rèé

[Credit Line]

Kimroy Photography

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 28]

Kimroy Photography