Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Màá Rí I Pé Mo Kà Á Létí Iná Àgọ́ Lálẹ́ Òní”

“Màá Rí I Pé Mo Kà Á Létí Iná Àgọ́ Lálẹ́ Òní”

Lẹ́tà Kan Láti Ilẹ̀ Ọsirélíà

“Màá Rí I Pé Mo Kà Á Létí Iná Àgọ́ Lálẹ́ Òní”

OHUN tó máa ń wá sí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́kàn nípa àwọn ibi tó jẹ́ ìgbèríko nílẹ̀ Ọsirélíà ni pé ó jẹ́ aṣálẹ̀ gbalasa, àti ibi olóoru tó gbóná gan-an, tó sì gbẹ táútáú. Àmọ́, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án èèyàn [180,000] ló ń gbébẹ̀, ìyẹn ni pé tá a bá pín iye olùgbé ilẹ̀ Ọsirélíà sọ́nà ọgọ́rùn-ún wọ́n á kó ìdá kan nínú rẹ̀.

Àwọn òbí mi tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà mú mi dání lọ wàásù láwọn ìgbèríko yìí nígbà tí mo wà lọ́mọdé. Bí ilẹ̀ ibẹ̀ ṣe lọ salalu tó sì jẹ́ aginjù tó dùn-ún wò wù mí gan-an. Mo sì tún fẹ́ràn àwọn tó ń gbébẹ̀, torí pé ẹ̀mí wọn yi, wọn ò sì fayé ni ara wọn lára. Ní báyìí tí mo ti wá ní ìdílé tèmi, mo fẹ́ kí aya mi àti ọmọ mi méjèèjì, tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá àtọmọ ọdún méjìlá náà ní irú ìrírí yẹn.

Bá A Ṣe Gbára Dì fún Ìrìn Àjò Náà

Lákọ̀ọ́kọ́, a jókòó a gbéṣirò lé ohun tá a fẹ́ ṣe. A ronú nípa: Báwo la ṣe máa rìn jìnnà tó? Báwo la ṣe fẹ́ pẹ́ tó ká tó padà? Tọkọtaya kan àti obìnrin méjì tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù nínú ìjọ wa náà sọ pé àwọn máa bá wa lọ. Gbogbo wa jọ gbà pé ká lọ nígbà ọlidé àwọn ọmọ iléèwé lóṣù July sí August. A wá kọ̀wé sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Sydney nílẹ̀ Ọsirélíà, pé kí wọ́n fún wa ní ìpínlẹ̀ tá a ti máa lọ wàásù. Wọ́n ní ká lọ sí ìgbèríko kan nítòsí ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Goondiwindi, tó wà ní nǹkan bí irinwó [400] kìlómítà lápá ìwọ̀ oòrùn ìlú Brisbane tá à ń gbé.

A gbọ́ pé ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kékeré kan wà nílùú Goondiwindi yìí. Ìyẹn túbọ̀ jẹ́ kára wa yá gágá láti lọ. Apá pàtàkì lára ìrìn àjò wa yìí ló máa jẹ́ láti rí àwọn ará wa lọ́kùnrin lóbìnrin. Nítorí náà, a kàn sí ìjọ yẹn pé à ń bọ̀. Bí wọ́n ṣe fi ìdùnnú fèsì jẹ́ ká mọ̀ pé ara wọn wà lọ́nà láti rí wa.

Nígbà tó kù díẹ̀ ká lọ, àwa tá a fẹ́ lọ jíròrò ọ̀nà tá a máa gbà wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn èèyàn tó wà ní ìgbèríko. Ní pàtàkì, a fẹ́ rí i pé a ò tẹ àṣà ìbílẹ̀ àwọn ẹ̀yà Aborigine, ìyẹn àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Ọsirélíà, tá a bá bá pàdé lójú. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹ̀yà kan ka gbogbo ilẹ̀ wọn sì ibùgbé wọn lápapọ̀. Nítorí náà, kò ní bójú mu láti kàn já wọ abúlé wọn láìgbàṣẹ lọ́wọ́ wọn.

A Lọ sí Ìgbèríko

Níkẹyìn ọjọ́ àtilọ pé. A kó sí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ méjì tí ìdílé méjèèjì ní, àwa àtàwọn ohun tá a nílò sì kúnnú àwọn ọkọ̀ náà bámú. A gbéra, ó di ìlú Goondiwindi. A kọjá àwọn ibi tí wọ́n dáko sí, a wá kan pápá gbalasa táwọn igi eucalyptus kọ̀ọ̀kan wà. Ojú ọjọ́ mọ́ lóló, oòrùn ìgbà òtútù yẹn sì mọ́lẹ̀ rekete. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ wákàtí a dé ìlú Goondiwindi, a wá kó sí ibùwọ̀ kó-kò-kó tá a háyà níbi tí wọ́n ń gbé ọkọ̀ àfiṣelé sí, a sì lọ sùn.

Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ìyẹn ọjọ́ Sunday, oòrùn yọ tòun tafẹ́fẹ́ tó tura. Irú ojú ọjọ́ bẹ́ẹ̀ ti lọ wà jù fún iṣẹ́ ìwàásù! Ká ní ìgbà ẹ̀rùn ni, ńṣe ni ibẹ̀ máa gbóná janjan. Abúlé àwọn ẹ̀yà Aborigine kan, ìyẹn àwọn ọmọ ìbílẹ̀ orílẹ̀-èdè náà, la ti kọ́kọ́ dúró. Ó jẹ́ nǹkan bí ọgbọ̀n kìlómítà sí ibùwọ̀ wa. Wọ́n darí wa sọ́dọ̀ obìnrin àgbàlagbà kan tó ń jẹ́ Jenny, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olóyè abúlé náà. Ó fara balẹ̀ gbọ́ ìwàásù wa, ó sì gba ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. a Ó wá yọ̀ǹda ká lọ wàásù fáwọn ará abúlé náà.

Ńṣe làwọn ọmọ kan lábúlé náà ń sáré lọ ṣáájú wa láti lọ sọ fáwọn èèyàn pé à ń bọ̀. Gbogbo àwọn tá a bá sọ̀rọ̀ ló tẹ́tí sí wa tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tí wọ́n sì gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò sì pẹ́ tí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa fi tán. Àsìkò sì tó láti padà sígboro láti lọ múra ìpàdé ìjọ. Ká tó kúrò lábúlé náà, a ṣèlérí pé a máa padà wá wo àwọn tá ò bá nílé.

Lọ́sàn ọjọ́ yẹn, ìdùnnú ṣubú layọ̀ nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, báwọn ará ìjọ ibẹ̀ àtàwa àlejò ṣe ń kíra tọ̀yàyà-tọ̀yàyà, tá a sì ń dọ̀rẹ́. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó wà níbẹ̀ ló ń wàásù fáwọn ẹ̀ẹ́dẹ́gbàafà [11,000] èèyàn tó ń gbé káàkiri inú àgbègbè tó fẹ̀ tó ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ [30,000] kìlómítà. Ẹlẹ́rìí kan dúpẹ́ lọ́wọ́ wa pé: “Ẹ ṣé gan-an tẹ́ ẹ wá ràn wá lọ́wọ́.” Lẹ́yìn ìpàdé alárinrin, a wá lọ jẹun. Ká tó lọ sùn lálẹ́ ọjọ́ yẹn, a fáwọn ẹranko bí eku tí wọ́n ń pè ní possum, tó ń jẹ̀ káàkiri ibi ìgbọ́kọ̀sí tá a wà lóúnjẹ.

“Létí Iná Àgọ́ Lálẹ́ Òní”

Lọ́jọ́ kẹta àti ìkẹrin, a gbé mọ́tò wa méjèèjì a lọ wàásù láwọn abúléko tó jìnnà síra létí ààlà ìpínlẹ̀ Queensland àti New South Wales. Igi eucalyptus kéékèèké tó ti wọ́wé ló pọ̀ jù nínú pápá gbalasa táwọn àgùntàn àti màlúù ti ń jẹko ní àyíká àwọn abúléko yẹn. A rí àwọn ẹranko kangaroo mélòó kan bá ṣe ń kọjá, wọ́n sì ń yí etí wọn síwá sẹ́yìn láti lè mọ apá ibi tá à ń gbà. A tún rí àwọn ẹyẹ emu tó jẹ́ ẹyẹ tó ga gan-an tí wọ́n sáré gba inú ọgbà ẹṣin kọjá lọ́ọ̀ọ́kán.

Lọ́sàn-án ọjọ́ Tuesday, a rí agbo màlúù kan tí wọ́n ń dà lọ lẹ́bàá ọ̀nà. Ọjọ́ pẹ́ táwọn darandaran tí wọ́n háyà ti máa ń da ọ̀wọ́ ẹran gbabẹ̀ kọjá, pàápàá nígbà ọ̀dá. Kò sì pẹ́ tá a fi bá àgbà darandaran kan tó gun ẹṣin pàdé. Mo dá mọ́tò mi dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, mo jáde, mo sì nahùn kí i. Òun náà fèsì pé: “Ǹlẹ́ o, ọ̀gbẹ́ni.” Bí ọkùnrin yẹn ṣe dúró ká jọ sọ̀rọ̀ nìyẹn, ajá tó ń bá a darí ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

A sọ̀rọ̀ díẹ̀ nípa àkókò ọ̀dá tá a wà, mo sì wá dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ Bíbélì tá à ń wàásù. Ló bá sọ pé: “Ẹ jẹ́ mọ̀ pé ìgbà tí mo wà lọ́mọdé ni mo ti gbọ́rọ̀ Bíbélì gbẹ̀yìn.” Ó ní àwọn aṣáájú ẹ̀sìn gan-an ló ń fa ìwà ìbàjẹ́ inú ayé. Àmọ́ ṣá, ó bọ̀wọ̀ fún Bíbélì gan-an. Mo wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún un dáadáa, mo sì fi ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? b lọ̀ ọ́. Ó gbà á, ó fi sínú àpò ẹ̀wù rẹ̀, ó sì sọ pé: “Tó bá sọ ohun tí Bíbélì kọ́ni lóòótọ́, màá rí i pé mo kà á létí iná àgọ́ lálẹ́ òní.”

A Padà Lọ Sílé

Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, a sọ ìrírí wa fáwọn ará nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba. Wọ́n ṣèlérí pé àwọn máa padà lọ bẹ àwọn tá a sọ pé wọ́n fìfẹ́ hàn wò. Nígbà tí ìpàdé parí, ńṣe ló dà bíi pé ká má lọ mọ́. A ti wá fẹ́ràn ara wa gan-an. Gbogbo wa la ti rí ọ̀pọ̀ ìṣírí gbà lọ́dọ̀ ara wa.—Róòmù 1:12.

Nígbà tí ojú mọ́, a padà lọ sílé. Bá a ṣe wá ń wo gbogbo bí ìrìn àjò yẹn ṣe rí, a gbà pé Jèhófà bù kún ìsápa wa gan-an ni. Inú wa dùn pé a ṣe ohun tó ń múnú Jèhófà dùn. Nígbà tá a padà délé, mo bi àwọn ọmọ pé: “Ibo lẹ fẹ́ ká lọ nígbà míì tá a bá tún gba ìsìnmi? Ṣé ká lọ ṣeré níbi òkè kan?” Wọ́n ní: “Rárá o, Dádì. Ẹ jẹ́ ká tún padà lọ wàásù ní ìgbèríko.” Ìyàwó mi náà báwọn fohùn sí i, ó ní: “Bẹ́ẹ̀ ni o, ìgbèríkò ni ká lọ. Èyí tá a lọ yìí ni àkókò ìsinmi tá a gbádùn jù!”

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.