Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ló mú kí ẹ̀rù ba Pọ́ńtíù Pílátù nígbà tó gbọ́ pé wọ́n fẹ̀sùn kan Jésù pé “ó fi ara rẹ̀ ṣe ọmọ Ọlọ́run”?—Jòhánù 19:7.
Lẹ́yìn ikú Júlíọ̀sì Késárì, Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ilẹ̀ Róòmù kéde pé ó ti di ọlọ́run kan. Ẹni tó gbà ṣọmọ tó sì wá rọ́pò rẹ̀ ni Ọkitéfíà. Nígbà tó yá wọ́n kéde pé Ọkitéfíà ti di divi filius, èyí tó túmọ̀ sí “Ọmọ Olú Ọ̀run” tàbí “Ọmọ Ọlọ́run.” Bó ṣe di pé orúkọ yìí wá di orúkọ oyè ìsìn àti ti àwọn olú ọba tó ń jẹ nílẹ̀ Róòmù nìyẹn. A rí ẹ̀rí èyí nínú àwọn ohun tí wọ́n kọ sára àwọn pẹpẹ, tẹ́ńpìlì, ère, àtàwọn owó ẹyọ ilẹ̀ Róòmù. Nígbà táwọn Júù fẹ̀sùn kan Jésù pé ó fi ara rẹ̀ ṣe “ọmọ Ọlọ́run,” ohun tí wọ́n ń sọ ni pé ó fẹ́ gba orúkọ oyè ti ìjọba, èyí tó túmọ̀ sí pé ó fẹ́ dìtẹ̀ sí ìjọba.
Nígbà tó fi máa di pé wọ́n ń gbẹ́jọ́ Jésù, olú ọba kan tó ń jẹ́ Tìbéríù ti jogún oyè divi filius. Àwọn èèyàn máa ń bẹ̀rù olú ọba yìí gan-an nítorí pé ńṣe ló máa ń pa ẹni tó bá ti kà sí ọ̀tá rẹ̀. Nitórí náà, àwọn Júù sọ fún Pílátù pé tó bá kọ̀ tí kò dá Jésù lẹ́bi ikú, á jẹ́ pé ó dalẹ̀ Késárì nìyẹn, èyí ló mú kí “ẹ̀rù túbọ̀ ba” gómìnà Róòmù náa. Níkẹyìn, ó gbà fún wọn, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa Jésù.—Jòhánù 19:7, 8, 12-16.
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé tipẹ́tipẹ́ lẹ́yìn táwọn ará Bábílónì ti pa ìlú Tírè run ni wòlíì Sekaráyà ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìparun rẹ̀?
Apá méjì ni ìlú Tírè àtijọ́ tó wà ní Etíkun Mẹditaréníà pín sí. Ọ̀kan wà lórí ilẹ̀, èkejì sì wà lórí omi.
Nígbà kan, àwọn tó ń gbé Tírè jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àmọ́, nígbà tó yá, ìlú Tírè di ọlọ́rọ̀, àwọn èèyàn ibẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàfojúdi sí Jèhófà Ọlọ́run débi pé wọ́n jí wúrà àti fàdákà àwon èèyàn Jèhófà, wọ́n sì tà lára àwọn èèyàn rẹ̀ sí oko ẹrú. (Jóẹ́lì 3:4-6) Èyí mú kí ìdájọ́ Jèhófà wá sórí ìlú Tírè. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé Nebukadinésárì Ọba Bábílónì yóò pa ìlú Tírè run, yóò sì kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wá sí ìlú Tírè lẹ́yìn tó bá ti pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.—Aísáyà 23:13, 14; Jeremáyà 27:2-7; Ìsíkíẹ́lì 28:1-19.
Nígbà táwọn èèyàn ìlú Tírè rí i pé àwọn ará Bábílónì fẹ́ ṣẹ́gun àwọn, ni wọ́n bá kó ẹrù wọn sá lọ sí ìlú Tírè ti orí omi. Àwọn ará Bábílónì pa ìlú Tírè orí ilẹ̀ run, wọ́n sì fi í sílẹ̀ lọ. Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún [100] ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà mí sí wòlíì Sekaráyà láti kéde ìdájọ́ Ọlọ́run lòdì sí Tírè, ó ní: “Wò ó! Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò lé e kúrò, inú òkun ni òun yóò sì ṣá ẹgbẹ́ ológun rẹ̀ balẹ̀ sí; inú iná ni a ó sì ti jẹ òun fúnra rẹ̀ run.”—Sekaráyà 9:3, 4.
Lọ́dún 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Alẹkisáńdà Ńlá pa ìlú Tírè orí omi run, ó sì tipa báyìí mú àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà ṣẹ. Kó bàa lè rọrùn fún Alẹkisáńdà láti pa ìlú náà run, ó ṣe ọ̀nà kan láti ìlú Tírè orí ilẹ̀ lọ sí ìlú Tírè orí omi, ọ̀nà ọ̀hún fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó kìlómítà kan. Látinú ìlú Tírè orí ilẹ̀ tó ti di àwókù ló ti kó igi àti òkúta tó fi ṣe ọ̀nà náà. Èyí tún mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìsíkíẹ́lì ṣẹ.—Ìsíkíẹ́lì 26:4, 12.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
“Bí wọ́n ṣe sàga ti ìlú Tírè”
[Credit Line]
Àwòrán yìí wá látọwọ́ Andre Castaigne (1898-1899)