Ohun Tó Mú Kí Nóà Rójú Rere Ọlọ́run—Ìdí Tó Fi Kàn Wá
Ohun Tó Mú Kí Nóà Rójú Rere Ọlọ́run—Ìdí Tó Fi Kàn Wá
Ọ̀PỌ̀ nínú wa máa rántí ìgbà tá a gbọ́ ìròyìn pàtàkì kan. A ò ní gbàgbé gbogbo bá a ṣe gbọ́ ìròyìn náà; irú bí ibi tá a wà nígbà tá a gbọ́ ọ, ohun tá à ń ṣe lọ́wọ́ àti bá a ṣe ṣe nígbà tá a gbọ́ ọ. Ó dájú pé bó ṣe rí fún Nóà náà nìyẹn, kò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ tó gbọ́ ìròyìn kan látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ìròyìn wo ló tún lè ṣe pàtàkì ju èyí tí Nóà gbọ́ yẹn lọ? Jèhófà sọ pé òun ti pinnu láti run “gbogbo ẹlẹ́ran ara.” Ó ní kí Nóà kan ọkọ̀ áàkì ràgàjì kan tó lè gba òun àti ìdílé rẹ̀ àti gbogbo onírúurú ẹranko.—Jẹ́nẹ́sísì 6:9-21.
Báwo ni Nóà ṣe ṣe nígbà tó gbọ́ ìròyìn yẹn? Ṣé inú rẹ̀ dùn ni àbí ó ń ráhùn? Báwo ló ṣe sọ ìròyìn yẹn fún ìdílé rẹ̀? Bíbélì ò sọ ìyẹn fún wa. Ohun tó sọ fún wa ni pé: “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún un. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:22.
Kókó pàtàkì nìyẹn o, torí pé gbólóhùn yẹn jẹ́ ká rí ọ̀kan lára ìdí tí Nóà fi rí ojú rere Ọlọ́run, ìyẹn bó ṣe múra tán láti ṣohun tí Ọlọ́run sọ pé kó ṣe. (Jẹ́nẹ́sísì 6:8) Kí lohun míì tó mú kí Ọlọ́run ṣojúure sí Nóà? Ìdáhùn sí ìbéèrè yẹn ṣe pàtàkì torí pé a gbọ́dọ̀ dà bíi Nóà ká tó lè là á já nígbà tí Ọlọ́run bá fẹ́ mú ìwà ibi kúrò láyé lẹ́ẹ̀kan sí i. Àmọ́ ṣá, ẹ jẹ́ ká wo báyé ṣe rí lákòókò Nóà kó tó di pé Ìkún-omi dé.
Àwọn Ẹ̀mí Èṣù Wá Sáyé
Nóà wà lára ìran èèyàn tó kọ́kọ́ gbélé ayé. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Jẹ́nẹ́sísì 4:20-22; Lúùkù 17:26-28.
ọkùnrin àkọ́kọ́ ni wọ́n bí Nóà. Àwọn ará ìgbà yẹn kò rí bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rò pé wọ́n rí; inú hòrò kọ́ ni wọ́n ń gbé, wọn ò luko, irun kò sì bo gbogbo ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í ká gúọ́gúọ́ kiri pẹ̀lú ọ̀gọ lọ́wọ́. Wọ́n ti mọ bí wọ́n ṣe ń fi irin àti bàbà ṣe ohun èlò lákòókò yẹn, ó sì ṣeé ṣe kí Nóà lò lára àwọn ohun èlò yìí nígbà tó ń kan ọkọ̀ áàkì. Àwọn ohun èlò orin pàápàá ti wà. Àwọn èèyàn ń gbéyàwó, wọ́n ń bímọ, wọ́n ń dáko, wọ́n sì máa ń ní ẹran ọ̀sìn. Wọ́n ń tà, wọ́n sì ń rà. Ayé ìgbà yẹn fi nǹkan wọ̀nyẹn dà bí ayé ìsinsìnyí.—Àwọn ọ̀nà míì wà tí nǹkan fi yàtọ̀ sí ti ayé ìsinsìnyí. Ìyàtọ̀ kan ni pé ẹ̀mí àwọn èèyàn máa ń gùn nígbà yẹn ju ti ìsinsìnyí lọ. Kì í ṣe nǹkan bàbàrà láyé ìgbà yẹn pé kẹ́nì kan lo ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rin [800] ọdún láyé. Nóà lò tó àádọ́ta-dín-lẹ́gbẹ̀rún [950] ọdún; Ádámù lo ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ọdún ó lé ọgbọ̀n [930]; Mètúsélà bàbá bàbá Nóà lo ẹgbẹ̀rún ọdún ó dín mọ́kànlélọ́gbọ̀n [969] ní tiẹ̀. a—Jẹ́nẹ́sísì 5:5, 27; 9:29.
Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2 sọ ìyàtọ̀ míì, ó ní: “Wàyí o, ó ṣẹlẹ̀ pé, nígbà tí àwọn ènìyàn bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ ní iye lórí ilẹ̀, tí a sì ń bí àwọn ọmọbìnrin fún wọn, nígbà náà ni àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ bẹ̀rẹ̀ sí kíyè sí àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, pé wọ́n dára ní ìrísí; wọ́n sì ń mú aya fún ara wọn, èyíinì ni, gbogbo ẹni tí wọ́n bá yàn.” Àwọn tí ẹsẹ yìí pè ní “àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́” ni àwọn áńgẹ́lì tó tọ̀run wá tí wọ́n di èèyàn tí wọ́n sì ń gbé lórí ilẹ̀ ayé. Ọlọ́run kọ́ ló rán wọn wá sáyé, kì í sì í ṣe pé wọ́n wá ṣe ọmọ aráyé lóore. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni “wọ́n ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì” ní ọ̀run, wọ́n sì wá sáyé láti wá máa ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn arẹwà obìnrin. Bí wọ́n ṣe di ẹ̀mí èṣù nìyẹn.—Júúdà 6.
Àwọn áńgẹ́lì ẹ̀mí èṣù tí wọ́n ṣàìgbọràn, tí wọ́n sì ti yàyàkuyà yìí ṣàkóbá tó pọ̀ fáwọn ọmọ aráyé, níwọ̀n bí agbára wọn àti ọgbọ́n wọn ti ju ti èèyàn lọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ló ń darí ayé ìgbà yẹn tí wọ́n sì jẹ gàba lé e lórí. Wọn ò ṣe bí ẹni tó ń yọ́ láabi ṣe tó tafà sókè tó yídó borí. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbangba gbàǹgbà ni wọ́n ń fìwà ìbàjẹ́ ṣayọ̀ bí wọ́n ṣe ń ṣohun tó lòdì sí ìfẹ́ Ọlọ́run.
Àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run yìí ń bá àwọn obìnrin lò pọ̀, àwọn obìnrin yẹn sì ń bí àwọn ọmọ tí wọ́n di akọni nígbà tí wọ́n dàgbà tán. Àwọn ni wọ́n ń pè ní “Néfílímù” lédè Hébérù. Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Àwọn Néfílímù sì wà ní ilẹ̀ ayé ní ọjọ́ wọnnì, àti lẹ́yìn ìyẹn pẹ̀lú, nígbà tí àwọn ọmọ Ọlọ́run tòótọ́ ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin ènìyàn, tí wọ́n sì bí ọmọkùnrin fún wọn, àwọn ni alágbára ńlá tí wọ́n wà ní ìgbà láéláé, àwọn ọkùnrin olókìkí.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:4) Àkòtagìrì ẹ̀dá làwọn Néfílímù. Ohun tí ọ̀rọ̀ náà “Néfílímù” túmọ̀ sí ni “Abiniṣubú,” ìyẹn àwọn tó ń mú káwọn èèyàn ṣubú. Apààyàn ni wọ́n, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà apanilẹ́kún-jayé wọn ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ bá nínú ìtàn àròsọ àti àlọ́ ayé ọjọ́un tó dá lórí àwọn akọni oníwàkiwà.
Ó Ń Ba Olódodo Lọ́kàn Jẹ́
Bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ohun táwọn èèyàn ń ṣe láyé ìgbà yẹn fi hàn pé ìwà jẹgúdújẹrá ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù. Ó sọ pé: “Ìwà búburú ènìyàn pọ̀ yanturu ní ilẹ̀ ayé, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú ọkàn-àyà rẹ̀ sì jẹ́ kìkì búburú ní gbogbo ìgbà. . . . Ilẹ̀ ayé sì wá kún fún ìwà ipá. . . . Gbogbo ẹlẹ́ran ara ti ba ọ̀nà ara rẹ̀ jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 6:5, 11, 12.
Bí ayé ṣe rí nìyẹn nígbà ayé Nóà. Àmọ́ Nóà yàtọ̀ Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Kò rọrùn fún olódodo kan láti máa gbé inú ayé tó kún fún ìwà àìṣòdodo. Ẹ ò rí bí nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe àtohun tí wọ́n ń sọ yóò ṣe máa ba Nóà nínú jẹ́ tó! Ó ṣeé ṣe kó máa dun òun náà bó ṣe ń dun Lọ́ọ̀tì, ọkùnrin olódodo míì tó gbé láyé lẹ́yìn Ìkún-omi. Lọ́ọ̀tì, tó ń gbé láàárín àwọn ará Sódómù tí ìwà ìbàjẹ́ ti wọ̀ lẹ́wù, jẹ́ “ẹni tí ìkẹ́ra-ẹni-bàjẹ́ nínú ìwà àìníjàánu àwọn aṣàyàgbàǹgbà pe òfin níjà kó wàhálà-ọkàn bá gidigidi” àti pé ohun tó “rí, tí ó sì gbọ́ nígbà tí ó ń gbé láàárín wọn láti ọjọ́ dé ọjọ́ ń mú ọkàn òdodo rẹ̀ joró nítorí àwọn ìṣe àìlófin wọn.” (2 Pétérù 2:7, 8) Bó ṣe ti ní láti rí fún Nóà náà nìyẹn.
sáwọn tí wọ́n jọ wà láyé nígbà náà, “Nóà jẹ́ olódodo” tó “bá Ọlọ́run tòótọ́ rìn.” (Ṣé àwọn ìròyìn tó ń ṣeni ní kàyéfì tá à ń gbọ́ àti ìwà tínú Ọlọ́run ò dùn sí táwọn èèyàn ń hù nísinsìnyí kò máa ba ìwọ náà lọ́kàn jẹ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé wàá mọ bọ́rọ̀ náà á ṣe máa dun Nóà tó. Tiẹ̀ wo bó ti ṣe máa ṣòro fún un tó láti fara dà á. Ọmọ ẹgbẹ̀ta [600] ọdún ni Nóà nígbà tí Ìkún-omi yẹn dé. Ìyẹn fi hàn pé odindi ẹgbẹ̀ta [600] ọdún ni Nóà fi wà nínú ayé táwọn èèyàn ti ń hùwà àìṣòdodo. Ẹ ò rí i pé á ti máa retí ìtura lójú méjèèjì!—Jẹ́nẹ́sísì 7:6.
Nóà Ní Ìgboyà Tó Mú Kó Lè Dá Yàtọ̀
Nóà “fi ara rẹ̀ hàn ní aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:9) Kíyè sí i pé ohun tí Bíbélì sọ ni pé ó jẹ́ aláìní-àléébù láàárín àwọn alájọgbáyé rẹ̀, kì í ṣe lójú wọn. Ìyẹn ni pé Nóà jẹ́ aláìní-àléébù lójú Ọlọ́run, àmọ́ lójú àwọn èèyàn tó wà láyé ṣáájú Ìkún-omi, Nóà ò dákan mọ̀. Ó dá wa lójú pé Nóà ò fara mọ́ ohun táwọn èèyàn ìgbà yẹn kà sóhun tó tọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò bá wọn lọ́wọ́ sí àwọn eré ìnàjú tínú Ọlọ́run ò dùn sí àti afẹ́ ayé ìgbà yẹn. Tiẹ̀ wo irú ojú táwọn èèyàn á fi máa wò ó bó ṣe ń kan ọkọ̀ áàkì yẹn! Ó ṣeé ṣe kí wọ́n máa pẹ̀gàn rẹ̀, kí wọ́n máa fi rẹ́rìn-ín, torí pé wọn ò gbà pé òótọ́ lohun tó ń sọ.
Yàtọ̀ síyẹn, Nóà ní ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ lọ́kàn rẹ̀, kò sì lè pa á mọ́ra. Bíbélì sọ pé “oníwàásù òdodo” ni Nóà. (2 Pétérù 2:5) Ó dájú pé Nóà mọ̀ pé wọ́n á ṣe inúnibíni sóun. Énọ́kù, bàbá tó bí bàbá bàbá Nóà jẹ́ olódodo, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ pé Ọlọ́run máa pa àwọn ẹni ibi run. Ó dájú pé wọ́n ṣenúnibíni sí Énọ́kù torí ìyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ò jẹ́ kí àwọn ọ̀tá ẹ̀ rí i pa. (Jẹ́nẹ́sísì 5:18, 21-24; Hébérù 11:5; 12:1; Júúdà 14, 15) Nóà nílò ìgboyà, ó sì ní láti ní ìgbàgbọ́ pé Jèhófà lágbára láti dáàbò bo òun. Ìdí ni pé Sátánì, àwọn ẹ̀mí èṣù, àwọn Néfílímù àti ọ̀pọ̀ èèyàn ń ta kò ó, àwọn míì ò sì fetí sóhun tó ń sọ.
Ọjọ́ pẹ́ táwọn tí kò sin Ọlọ́run ti máa ń ta ko àwọn tó ń sin Ọlọ́run. Kódà wọ́n kórìíra Jésù Kristi àtàwọn tó bá ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn. (Mátíù 10:22; Jòhánù 15:18) Nóà ní ìgboyà tó mú kó lè sin Ọlọ́run bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í sin Ọlọ́run lákòókò yẹn. Ó mọ̀ pé kóun rójú rere Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju kóun rójú rere àwọn tó ń ta ko Ọlọ́run. Torí ìdí èyí, Ọlọ́run ṣojú rere sí i.
Nóà Fiyè Sí I
Gẹ́gẹ́ bá a ti ṣe rí i, Nóà fìgboyà wàásù fáwọn èèyàn. Kí ni wọ́n ṣe sí iṣẹ́ tó jẹ́ fún wọn? Bíbélì sọ pé ṣáájú Ìkún-omi, àwọn èèyàn ń “jẹ, wọ́n sì ń mu, àwọn ọkùnrin ń gbéyàwó, a sì ń fi àwọn obìnrin fúnni nínú ìgbéyàwó, títí di ọjọ́ tí Nóà wọ ọkọ̀ áàkì; wọn kò sì fiyè sí i títí ìkún omi fi dé, tí ó sì gbá gbogbo wọn lọ.” Wọn ò gba ìkìlọ̀.—Mátíù 24:38, 39.
Jésù sọ pé bọ́rọ̀ àkókò wa yìí ṣe máa rí náà nìyẹn. Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń kìlọ̀ pé Jèhófà yóò gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì kan láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, pé òun á dá ayé tuntun òdodo kan. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn èèyàn ti gba ìkìlọ̀ yìí, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó wà láyé ni kò fiyè sí i. “Ní ìbámu pẹ̀lú ìdàníyàn wọn,” wọ́n ṣe bí ẹni pé ọ̀rọ̀ Ìkún-omi yẹn ò kan àwọn àti pé Ìkún-omi kankan kò tíì wáyé rí.—2 Pétérù 3:5, 13.
Àmọ́, Nóà ní tiẹ̀ fiyè sí i nígbà yẹn. Ó gba ohun tí Jèhófà Ọlọ́run sọ fún un gbọ́. Ìgbọràn tó ṣe yẹn ló jẹ́ kó rí ìgbàlà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nípa ìgbàgbọ́ ni Nóà, lẹ́yìn fífún un ní ìkìlọ̀ àtọ̀runwá nípa àwọn ohun tí a kò tíì rí, fi ìbẹ̀rù Hébérù 11:7.
Ọlọ́run hàn, ó sì kan ọkọ̀ áàkì fún ìgbàlà agbo ilé rẹ̀.”—Ó Yẹ Ká Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Rẹ̀
Ọkọ̀ ràgàjì ni áàkì tí Nóà kàn. Ó gùn ju pápá ìṣeré tí wọ́n ti ń gbá bọ́ọ̀lù lọ, ó sì ga ju ilé alájà mẹ́ta. Ó fi ọgọ́rùn-ún ẹsẹ̀ bàtà [ọgbọ̀n mítà] gùn ju ọkọ̀ ojú omi ńlá kan tó ń jẹ́ Wyoming lọ, ọkọ̀ yìí ni wọ́n sọ pé ó tóbi jù lọ lára àwọn ọkọ̀ ojú omi onígi tó wà láyé. Ọkọ̀ áàkì kì í ṣe ọkọ̀ ojú omi ṣá o; ó kàn ní láti léfòó lórí omi ni. Síbẹ̀ iṣẹ́ kíkan ọkọ̀ yẹn gba pé kéèyàn ní ìmọ̀ tó jinlẹ̀ nípa ilé kíkọ́ àti ọkọ̀ kíkàn. Nóà ní láti fi ọ̀dà bítúmẹ́nì bò ó nínú àti lóde. Ó ṣeé ṣe kó gbà ju àádọ́ta ọdún kí Nóà tó kan ọkọ̀ yẹn tán.—Jẹ́nẹ́sísì 6:14-16.
Kò tán síbẹ̀ o. Nóà tún ní láti kó oúnjẹ tí òun àti ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹranko á jẹ lọ́dún kan sínú áàkì. Kó tó di pé Ìkún-omi yẹn dé, ó ní láti kó àwọn ẹranko sínú áàkì náà. “Nóà sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí Jèhófà ti pa láṣẹ fún un.” Ẹ ò rí i pé pẹ̀sẹ̀ lọkàn rẹ̀ á balẹ̀ nígbà tó rí i pé ohun gbogbo ti wà ní sẹpẹ́, tí Jèhófà sì ti ilẹ̀kùn ọkọ̀ náà!—Jẹ́nẹ́sísì 6:19-21; 7:5, 16.
Nígbà tí Ìkún-omi dé, ogójì ọ̀sán àti ogójì òru ni òjò fi rọ̀. Odindi ọdún kan ní gbogbo wọn fi wà nínú áàkì títí tómi fi gbẹ. (Jẹ́nẹ́sísì 7:11, 12; 8:13-16) Gbogbo àwọn ẹni burúkú yẹn ló pa run. Nóà àti ìdílé rẹ̀ nìkan ló là á já sí ayé tí Jèhófà ti fọ̀ mọ́.
Bíbélì sọ pé Ìkún-omi ọjọ́ Nóà jẹ́ “àpẹẹrẹ kan . . . nípa àwọn ohun tí ń bọ̀.” Lọ́nà wo? A kà á pé: “Àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé tí ó wà nísinsìnyí ni a tò jọ pa mọ́ fún iná, a sì ń fi wọ́n pa mọ́ de ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.” Àmọ́ gẹ́gẹ́ bíi tọjọ́ Nóà, àwọn tó máa là á já máa wà. Jẹ́ kó dá ọ lójú pé “Jèhófà mọ bí a ti ń dá àwọn ènìyàn tí ń fọkàn sin Ọlọ́run nídè kúrò nínú àdánwò.”—2 Pétérù 2:5, 6, 9; 3:7.
Nóà jẹ́ ẹnì kan tó ń fọkàn sin Ọlọ́run, olódodo ni láàárín ìran burúkú. Ó ṣègbọràn sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Ó nígboyà láti ṣohun tó tọ́ bó tilẹ̀ mọ̀ pé èyí á mú káwọn tí kò fẹ́ láti sin Ọlọ́run kẹ́gàn òun, kí wọ́n sì kórìíra òun. Tá a bá ń fara wé Nóà láwọn ọ̀nà yìí, àwa náà á rí ojúure Ọlọ́run, ìyẹn á sì mú ká ní ìrètí ìdáǹdè sínú ayé tuntun tí kò ní pẹ́ dé.—Sáàmù 37:9, 10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpilẹ̀kọ náà, “Ṣóòótọ́ Ni Wọ́n Pẹ́ Tó Bẹ́ẹ̀ Láyé?” nínú Jí! July–September, 2007 ojú ìwé 24.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà apanilẹ́kún-jayé àwọn Néfílímù ni wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ bá nínú ìtàn àròsọ àti àlọ́ ayé ọjọ́un tó dá lórí àwọn akọni oníwàkiwà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Tá a bá nígbàgbọ́ bíi ti Nóà, a óò rí ojú rere Ọlọ́run
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Alinari/Art Resource, NY