Ẹ̀gbọ́n Bínú sí Àbúrò
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Ẹ̀gbọ́n Bínú sí Àbúrò
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó pé o wà níbi tí ohun tó ò ń kà náà ti ṣẹlẹ̀, kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 4:1-12.
Tó o bá fojú inú wò ó, báwo lo ṣe lè ṣàlàyé ìrísí Kéènì àti irú ìwà tó ní? Báwo lo ṣe máa ṣàlàyé ti Ébẹ́lì náà?
․․․․․
Àwọn “iṣẹ́ ti ara” wo ni Kéènì lọwọ́ sí, báwo la sì ṣe mọ̀? (Gálátíà 5:19-21)
․․․․․
ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.—KA ẸSẸ 4 SÍ 7 LẸ́Ẹ̀KAN SÍ I.
Ṣé torí pé ẹbọ Ébẹ́lì dára, tí ẹbọ Kéènì kò sì dára nìkan ni Jèhófà ṣe tẹ́wọ́ gba ẹbọ Ébẹ́lì ni, àbí nǹkan míì tún wà ńbẹ̀? (Òwe 21:2)
․․․․․
Àwọn ipò wo lèèyàn lè ti bínú kéèyàn sì jàre, kí nìdí tí kò fi dáa rárá bí ‘ìbínú Kéènì ṣe gbóná’?
․․․․․
Nínú àwọn ipò wo ni owú jíjẹ ti dára, àmọ́ kí nìdí tí owú tí Kéènì jẹ kò fi dára? (1 Ọba 19:10)
․․․․․
Kí ni Kéènì ì bá ti ṣe láti “kápá” ìbínú rẹ̀?
․․․․․
MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Ìbínú.
․․․․․
Owú jíjẹ.
․․․․․
Bó o ṣe lè “kápá” àwọn èrò tí kò dára.
․․․․․
KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․