Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bó Ṣe Máa Ń Dunni Tó Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú

Bó Ṣe Máa Ń Dunni Tó Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú

Bó Ṣe Máa Ń Dunni Tó Nígbà Téèyàn Ẹni Bá Kú

Lọ́jọ́ Tuesday, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù keje ọdún 2007, lọ́wọ́ aago méje alẹ́, jàǹbá kan ṣẹlẹ̀ ní pápákọ̀ òfuurufú tó wà ní àárín gbùngbùn ìlú São Paulo. Pápákọ̀ yìí làwọn èèyàn máa ń lò jù lórílẹ̀-èdè Brazil. Ọkọ̀ òfuurufú akérò kan tó ń balẹ̀ lọ́wọ́ níbẹ̀ ló yọ̀ tẹ̀rẹ́ kúrò lójú ọ̀nà tó wà fáwọn ọkọ̀ òfuurufú. Ó wá la ojú pópó tí mọ́tò ń gbà kọjá, ó sì lọ rọ́ lu ìsọ̀ ńlá tí wọ́n ń já ẹrù ọkọ̀ òfuurufú sí. Ó tó igba èèyàn tó kú nínú jàǹbá náà.

JÀǸBÁ yìí ni wọ́n ní ó burú jù nínú jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú tó ti ń ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Brazil. Àwọn téèyàn wọn sì kú nínú jàǹbá náà kò ní gbàgbé ẹ̀ láé. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Claudete wà lára àwọn téèyàn rẹ̀ kú nínú jàǹbá ọ̀hún. Ńṣe ló ń wo tẹlifíṣọ̀n lọ́wọ́ nígbà tó gbọ́ ìròyìn jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú náà. Renato ọmọ rẹ̀ wà nínú ọkọ̀ òfuurufú yẹn. Ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n péré ni, ó sì ń múra àtigbéyàwó lóṣù kẹwàá. Obìnrin yìí ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù alágbèéká, àmọ́ kò ṣeé ṣe. Ó ṣubú lulẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún àsun-ùndá.

Àfẹ́sọ́nà obìnrin kan tó ń jẹ́ Antje kú sínú jàǹbá mọ́tò lóṣù January, ọdún 1986. Nígbà tó gbọ́ ìròyìn yẹn, ńṣe lorí ẹ̀ kọ́kọ́ fò lọ. Ó sọ pé: “Mi ò kọ́kọ́ gbà gbọ́. Mo ní ó ní láti jẹ́ pé mò ń lá àlá burúkú kan ni, pé màá ta jí láìpẹ́, màá sì rí i pé kò ṣẹlẹ̀ lóòótọ́. Jìnnìjìnnì bò mí, inú sì ń kan mí burúkú-burúkú. Ṣe ló dà bíi pé ẹnì kan gbá mi lẹ́ṣẹ̀ẹ́ níkùn.” Odindi ọdún mẹ́ta tó tẹ̀ lé e ni Antje fi ní ìdààmú ọkàn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lé lógún ọdún tí jàǹbá yẹn ti ṣẹlẹ̀, jìnnìjìnnì ṣì máa ń bò ó nígbàkúùgbà tó bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn.

Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ò lè ṣàlàyé bí ọkàn ẹnì kan ṣe máa ń dà rú tó téèyàn rẹ̀ bá kú lójijì. Lára ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé kí orí èèyàn fò lọ, kó má gbà pé òótọ́ ni, kó má mọ nǹkan kan lára mọ́, kí ọkàn rẹ̀ pòrúurùu bí ẹni tí kò nírètí. Kódà, ká tiẹ̀ ní a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé èèyàn wa kan máa kú, bóyá torí pé ó ti pẹ́ tó ti ń ṣàìsàn, ìbànújẹ́ ṣì lè dorí èèyàn kodò síbẹ̀síbẹ̀. Kò sẹ́ni tó lè sọ pé téèyàn òun kan bá kú, kò ní dun òun rárá. Ìyá Nanci kú lọ́dún 2002, lẹ́yìn àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ. Síbẹ̀, lọ́jọ́ tí ìyá rẹ̀ kú, ṣe ni Nanci jókòó sílẹ̀ẹ́lẹ̀ ní ilé ìwòsàn láìmọ ibi tó wà mọ́. Ó dà bíi pé ayé yìí ò yé e mọ́ rárá. Ọdún márùn-ún ti kọjá báyìí, síbẹ̀, Nanci ṣì máa ń sunkún nígbà tó bá rántí màmá rẹ̀.

Ọ̀jọ̀gbọ́n Holly G. Prigerson sọ pé: “Téèyàn ẹni bá kú, kò sí béèyàn ṣe lè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn pátápátá, ńṣe lèèyàn kàn máa ń gba kámú.” Téèyàn rẹ bá ti kú rí, bóyá lójijì tàbí o ti mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ó máa kú, o lè máa rò ó pé: ‘Ṣé kò burú láti bọkàn jẹ́? Báwo lèèyàn ṣe lè borí ẹ̀dùn ọkàn téèyàn ẹni bá kú? Ǹjẹ́ mo tún lè padà rí èèyàn mi tó kú yìí?’ Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí yóò jíròrò àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn míì tó o lè ní.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

EVERTON DE FREITAS/AFP/Getty Images