Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé ògiri tó ṣeé fojú rí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ nínú Éfésù 2:11-15, nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ògiri kan tó ya àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí nípa?

Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Éfésù, ó sọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtàwọn “àjèjì.” Ó ní “ògiri” kan wà tó “ya” àwùjọ èèyàn méjèèjì nípa. (Éfésù 2:11-15) “Òfin àwọn àṣẹ” tí Ọlọ́run fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nípasẹ̀ Mósè ni Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí, àmọ́ bó ṣe lo “ògiri” lè mú káwọn tó bá ka ìwé rẹ̀ yìí rántí ògiri òkúta kan tó wà nínú tẹ́ńpìlì.

Tẹ́ńpìlì Jèhófà tó wà ní Jerúsálẹ́mù ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ní àwọn àgbàlá kan tó jẹ́ pé ó lójú àwọn èèyàn tó lè débẹ̀. Ẹnikẹ́ni ló lè wọ Àgbàlá Àwọn Kèfèrí, àmọ́ àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti wọ àwọn àgbàlá tẹ́ńpìlì. Ògiri òkúta aláràbarà kan, tí wọ́n sọ pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó mítà kan àtààbọ̀, tí wọ́n ń pè ní Sórégì, ni wọ́n fi pààlà sí Àgbàlá Àwọn Kèfèrí àtàwọn àgbàlá tẹ́ńpìlì. Òpìtàn kan ní ọ̀rúndún kìíní tó jẹ́ Júù tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Flavius Josephus sọ pé, wọ́n fi èdè Gíríìkì àti èdè Látìn fín ọ̀rọ̀ sára ògiri yìí láti fi kìlọ̀ fáwọn Kèfèrí pé kí wọ́n má ṣe kọjá ògiri yẹn kí wọ́n máa bàa wọ apá ibi mímọ́.

Wọ́n ti rí ọ̀kan lára ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n fín sára ògiri tó pààlà sí àgbàlá tẹ́ńpìlì yẹn. Ó kà pé: “Kí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè kankan má ṣe kọjá ohun ìdènà àti ọgbà yìí tó yí ibùjọsìn ká. Ẹnikẹ́ni tọ́wọ́ bá tẹ̀, òun ló ṣekú pa ara rẹ̀ o.”

Ó jọ pé ńṣe ni Pọ́ọ̀lù lo Sórégì yìí láti fi ṣàpẹẹrẹ májẹ̀mú Òfin Mósè, tó ti ya àwọn Júù àtàwọn Kèfèrí nípa tipẹ́tipẹ́. Ikú ìrúbọ tí Jésù kú fòpin sí májẹ̀mú Òfin, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ “pa ògiri tí ń bẹ ní àárín run.”

Kí nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá ni Bíbélì sábà máa ń tọ́ka sí, nígbà tó jẹ́ pé ẹ̀yà mẹ́tàlá ni wọ́n?

Ọ̀dọ́ àwọn ọmọkùnrin Jékọ́bù tí Ọlọ́run yí orúkọ rẹ̀ padà sí Ísírẹ́lì, làwọn ẹ̀yà tàbí ìdílé Ísírẹ́lì ti ṣẹ̀ wá. Jékọ́bù baba ńlá yìí ní àwọn ọmọkùnrin méjìlá. Orúkọ wọn ni: Rúbẹ́nì, Síméónì, Léfì, Júdà, Dánì, Náfútálì, Gádì, Áṣérì, Ísákárì, Sébúlúnì, Jósẹ́fù àti Bẹ́ńjámínì. (Jẹ́nẹ́sísì 29:32–30:24; 35:16-18) Mọ́kànlá nínú àwọn arákùnrin wọ̀nyí ni wọ́n fi orúkọ wọn sọ ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, àmọ́ kò sí ẹ̀yà tí wọ́n sọ lórúkọ Jósẹ́fù. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n fi orúkọ ọmọ Jósẹ́fù méjèèjì, Éfúráímù àti Mánásè, tí wọ́n kà sí olórí ẹ̀yà, sọ ẹ̀yà méjì. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì wá jẹ́ mẹ́tàlá. Kí wá nìdí tó fi jẹ́ pé ẹ̀yà méjìlá ni Bíbélì máa ń tọ́ka sí?

Ọlọ́run ya àwọn ọmọ Léfì sọ́tọ̀ lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, fún iṣẹ́ ìsìn nínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà àti nínú tẹ́ńpìlì tó wà lẹ́yìn náà. Nítorí náà, wọn kì í bá àwọn ẹ̀yà tó kù ṣe iṣẹ́ ológun. Jèhófà sọ fún Mósè pé: “Kìkì ẹ̀yà Léfì ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ forúkọ rẹ̀ sílẹ̀, iye wọn ni ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ kà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Kí ìwọ fúnra rẹ sì yan àwọn ọmọ Léfì sípò lórí àgọ́ ìjọsìn Gbólóhùn Ẹ̀rí àti lórí gbogbo nǹkan èlò rẹ̀ àti lórí gbogbo ohun tí ó jẹ mọ́ ọn.”—Númérì 1:49, 50.

Bákan náà, wọn ò pín àgbègbè kan pàtó fáwọn ọmọ Léfì ní Ilẹ̀ Ìlérí. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn ìlú tó jẹ́ méjì-dín-láàádọ́ta tó wà káàkiri ìpínlẹ̀ Ísírẹ́lì ni wọ́n pín fún wọn.—Númérì 18:20-24; Jóṣúà 21:41.

Fún ìdí méjì tá a sọ yìí, Bíbélì kì í sábà mẹ́nu kan àwọn ọmọ Léfì tó bá ń dárúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Nípa bẹ́ẹ̀, ẹ̀yà méjìlá ni wọ́n sábà máa ń sọ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́.—Númérì 1:1-15.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]

Ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí tó wà ní ìlú Istanbul