“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn
“Wò Ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà!”
ẸNU ya Màríà gidigidi nígbà tó rí ọkùnrin àlejò kan tó wọlé wá. Àlejò náà kò béèrè bàbá tàbí ìyá rẹ̀. Màríà gan-an ló wá wá! Ó dá Màríà lójú pé kì í ṣe Násárétì ìlú wọn yìí ni àlejò náà ti wá. Nítorí pé ìlú wọn kéré, wọ́n tètè máa ń dá àlejò mọ̀ yàtọ̀. Ọ̀gbẹ́ni yìí kàn tiẹ̀ dá yàtọ̀ pátápátá ni. Bó sì ṣe kí Màríà ṣàjèjì. Ó ní: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.”—Lúùkù 1:28.
Ibi tí Bíbélì ti bẹ̀rẹ̀ ìtàn Màríà tó jẹ́ ọmọbìnrin Hélì, ọmọ ìlú Násárétì ní Gálílì nìyẹn. Àkókò tó ní láti ṣe ìpinnu pàtàkì ní ìgbésí ayé rẹ̀ ni Bíbélì bẹ̀rẹ̀ ìtàn rẹ̀. Àfẹ́sọ́nà Jósẹ́fù, ọkùnrin káfíńtà kan, tí kì í ṣe ọlọ́rọ̀, àmọ́ tó jẹ́ olóòótọ́ èèyàn, ni Màríà. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó ti pinnu bó ṣe máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Ìyẹn ni pé yóò ti fọkàn sí i pé ìyàwó ilé lòun á jẹ́, tóun á máa ran Jósẹ́fù ọkọ òun lọ́wọ́, táwọn á sì jọ máa bójú tó ìdílé àwọn. Àfi bí àlejò yìí ṣe dé tó wá gbé iṣẹ́ ńlá kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lé e lọ́wọ́, èyí sì jẹ́ iṣẹ́ pàtàkì kan tó máa yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà.
Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu pé, Bíbélì kò sọ ohun púpọ̀ fún wa nípa Màríà. Bí àpẹẹrẹ, kò sọ̀rọ̀ púpọ̀ nípa bí wọ́n ṣe tọ́ Màríà dàgbà àti irú ìwà tó ní, bẹ́ẹ̀ ni kò sọ ohunkóhun nípa ìrísí rẹ̀. Síbẹ̀ náà, ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́.
Ká lè mọ irú ẹni tí Màríà jẹ́, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀ gan-an, ká má ro ti onírúurú ẹ̀kọ́ tí ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ń kọ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn nípa Màríà. Ẹ jẹ́ ká mọ́kàn kúrò lórí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà yàwòrán rẹ̀, bí wọ́n ṣe ń fín àwòrán rẹ̀ sárá nǹkan àtàwọn ère rẹ̀ tí wọ́n ń mọ. Ẹ jẹ́ ká sì tún mọ́kàn kúrò lórí àwọn àlàyé àti ẹ̀kọ́ ìsìn tó lọ́jú pọ̀ tó mú káwọn èèyàn gbé obìnrin onírẹ̀lẹ̀ yìí sí ipò tó ga fíofío, tí wọ́n ń pè é láwọn orúkọ oyè kàǹkà-kàǹkà bí “Ìyá Ọlọ́run” àti “Ọbabìnrin Ọ̀run.” Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, a ó lè mọ irú ìgbàgbọ́ tó ní, àti bá a ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ rẹ̀.
Áńgẹ́lì Kan Wá Sọ́dọ̀ Màríà
Ó ṣeé ṣe kó o ti mọ̀ pé, kì í ṣe èèyàn lásán ni àlejò tó wá sọ́dọ̀ Màríà. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì ni. Nígbà tó sọ fún Màríà pé ó jẹ́ “ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga,” ọ̀rọ̀ náà “yọ ọ́ lẹ́nu gidigidi,” ìkíni náà sì yà á lẹ́nu gan-an torí kò gbọ́ irú ẹ̀ rí. (Lúùkù 1:29) Ta ló ṣojú rere sí i lọ́nà gíga? Màríà kò retí pé èèyàn kankan máa ṣe irú ojú rere bẹ́ẹ̀ sóun. Ṣùgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run ni áńgẹ́lì yìí sọ pé ó ṣojú rere sí i. Ìyẹn sì ṣe pàtàkì lójú Màríà. Síbẹ̀, kò tìtorí pé òun ti rí ojú rere Ọlọ́run kó wá máa gbéra ga. Táwa náà bá ń wá ojú rere Ọlọ́run, tá ò fi ìgbéraga ka ara wa sẹ́ni tó ti rí ojú rere rẹ̀, a óò rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kan kọ́, èyí tí ọ̀dọ́mọbìnrin tó ń jẹ́ Màríà yìí mọ̀ dáadáa. Ẹ̀kọ́ náà ni pé, Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó nífẹ̀ẹ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀, ó sì tì wọ́n lẹ́yìn.—Jákọ́bù 4:6.
Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Màríà ní yẹn gan-an ló sì yẹ ẹ́, torí pé àǹfààní tí Màríà lè má ronú kàn rí ni áńgẹ́lì náà sọ pé ó máa ní. Áńgẹ́lì yìí ṣàlàyé pé, ó máa bí ọmọ kan tó máa dẹni pàtàkì jù lọ nínú ọmọ aráyé. Gébúrẹ́lì sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run yóò sì fi ìtẹ́ Dáfídì baba rẹ̀ fún un, yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lórí ilé Jékọ́bù títí láé, kì yóò sì sí òpin fún ìjọba rẹ̀.” (Lúùkù 1:32, 33) Màríà mọ ìlérí tí Ọlọ́run ti ṣe fún Dáfídì ní èyí tó ju ẹgbẹ̀rún ọdún kan ṣáájú ìgbà yẹn dáadáa, pé ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ máa ṣàkóso títí láé. (2 Sámúẹ́lì 7:12, 13) Ìyẹn ni pé ọmọ Màríà ló máa jẹ́ Mèsáyà táwọn èèyàn Ọlọ́run ti ń retí láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún!
Láfikún sí i, áńgẹ́lì náà sọ fún Màríà pé ọmọ rẹ̀ ni wọn yóò máa pè ní “Ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ.” Báwo ni obìnrin tó jẹ́ èèyàn ṣe máa bí ọmọ Ọlọ́run? Báwo ni Màríà tiẹ̀ ṣe máa bímọ pàápàá? Lóòótọ́, òun àti Jósẹ́fù ń fẹ́ra sọ́nà, àmọ́ wọn kò tíì ṣègbéyàwó. Ohun tó ń jà gùdù lọ́kàn Màríà yìí ló mú kó béèrè pé: “Báwo ni èyí yóò ṣe rí bẹ́ẹ̀, níwọ̀n bí èmi kò ti ń ní ìbádàpọ̀ kankan pẹ̀lú ọkùnrin?” (Lúùkù 1:34) Kíyè sí i pé Màríà kò kà á sí nǹkan ìtìjú láti sọ pé òun kò tíì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin rí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó mọyì bí kò ṣe bára rẹ̀ jẹ́. Lóde òní, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ń wọ́nà àtiní ìbálòpọ̀ káwọn lè tètè kúrò nípò wúńdíá kíákíá, tí wọ́n á sì máa fi àwọn tí kò bá tíì ní ìbálòpọ̀ ṣẹlẹ́yà. Lóòótọ́, ayé yìí ti yí padà, àmọ́ Jèhófà kò yí padà o. (Málákì 3:6) Ó mọyì àwọn tó ń tẹ̀ lé ìlànà ìwà rere rẹ̀ lóde òní, bó ṣe mọyì rẹ̀ nígbà ayé Màríà.—Hébérù 13:4.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Màríà jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run, síbẹ̀ ẹ̀dá aláìpé ni. Báwo ló ṣe máa wá bí ọmọ pípé, Ọmọ Ọlọ́run? Gébúrẹ́lì ṣàlàyé pé: “Ẹ̀mí mímọ́ yóò bà lé ọ, agbára Ẹni Gíga Jù Lọ yóò sì ṣíji bò ọ́. Nítorí ìdí èyí pẹ̀lú, ohun tí a bí ni a ó pè ní mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run.” (Lúùkù 1:35) Ohun tó bá jẹ́ mímọ́, jẹ́ ohun tí kò lábàwọ́n, tó mọ́ lóló, tó sì jẹ́ ọlọ́wọ̀. Àmọ́ bó ti sábà máa ń rí, ńṣe ni àwọn ọmọ máa ń jogún àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn. Ṣùgbọ́n, Jèhófà máa ṣe iṣẹ́ ìyanu kan nínú ọ̀ràn ti Màríà. Ó máa fi ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ láti ọ̀run sínú ilé ọlẹ̀ Màríà, yóò sì wá fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ‘ṣíji bo Màríà.’ Èyí ni kò ní jẹ́ kí ọmọ náà jogún ẹ̀ṣẹ̀ kankan. Ǹjẹ́ Màríà gba ìlérí áńgẹ́lì yìí gbọ́? Èsì wo ni Màríà sì fún áńgẹ́lì náà?
Èsì Tí Màríà Fún Gébúrẹ́lì
Ó ṣòro fáwọn tí kò gbà pé irú iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀, títí kan àwọn kan tó ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì, láti gbà pé wúńdíá lè bímọ láìjẹ́ pé ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnikẹ́ni. Pẹ̀lú bí wọ́n ṣe kàwé tó, òótọ́ ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere yìí ò yé wọn. Ìyẹn, ohun tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ, pé: “Lọ́dọ̀ Ọlọ́run kò sí ìpolongo kankan tí yóò jẹ́ aláìṣeéṣe.” (Lúùkù 1:37) Màríà gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ tí Gébúrẹ́lì sọ, torí pé ọ̀dọ́mọbìnrin tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lágbára ni. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé Màríà kàn gba gbogbo ohun tí áńgẹ́lì náà sọ fún un láìronú lé e. Gẹ́gẹ́ bí onílàákàyè èèyàn, Màríà nílò ẹ̀rí tó máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà túbọ̀ dá a lójú. Gébúrẹ́lì náà sì múra tán láti jẹ́ kí Màríà rí ẹ̀rí tó túbọ̀ dájú. Ó sọ̀rọ̀ Èlísábẹ́tì, ìbátan Màríà kan tó jẹ́ àgbàlagbà tí wọ́n ti mọ̀ lágàn látọjọ́ pípẹ́ fún un. Ó ní, Ọlọ́run ti jẹ́ kó lóyún lọ́nà ìyanu!
Wàyí o, kí ni Màríà máa ṣe? Iṣẹ́ tó máa ṣe ti wà nílẹ̀, ó sì ti láwọn ẹ̀rí tó jẹ́ kó dá a lójú pé Ọlọ́run máa ṣe gbogbo ohun tí Gébúrẹ́lì sọ fún un. Ká má rò pé kò yẹ kó bẹ̀rù o, pé kò sóhun tó nira ńbẹ̀. Nítorí, ó gbọ́dọ̀ ro ti àdéhùn
tó ti wà láàárín òun àti Jósẹ́fù. Ó lè rò ó pé, ṣé Jósẹ́fù ṣì máa gbà láti fẹ́ òun tó bá gbọ́ pé òun ti lóyún? Yàtọ̀ síyẹn, iṣẹ́ tó jọ pé ó kani láyà ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ yìí. Ìwàláàyè ẹni tó ṣeyebíye jù nínú gbogbo ìṣẹ̀dá ló máa wà níkùn Màríà táá máa gbé kiri, ìyẹn ọmọ tó jẹ́ ọmọ ọ̀wọ́n fún Ọlọ́run! Ó ní láti bójú tó o nígbà tó bá wà lọ́mọ ọwọ́, kó sì rí i dájú pé òun dáàbò bò ó nínú ayé burúkú yìí. Iṣẹ́ ńláǹlà ni!Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó jẹ́ onígboyà tó sì jẹ́ olóòótọ́ pàápàá lọ́ tìkọ̀ láti tẹ́wọ́ gbà iṣẹ́ tó kani láyà lọ́wọ́ Ọlọ́run. Mósè sọ pé òun ò mọ́rọ̀ sọ dáadáa débi tóun máa fi jẹ́ agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run. (Ẹ́kísódù 4:10) Ní ti Jeremáyà, ó ní “ọmọdé lásán” lòun, pé òun ti kéré jù láti ṣiṣẹ́ bàǹtà-banta tí Ọlọ́run gbé lé òun lọ́wọ́. (Jeremáyà 1:6) Àní ńṣe ni Jónà tiẹ̀ sá fi iṣẹ́ tí Ọlọ́run rán an sílẹ̀! (Jónà 1:3) Màríà wá ńkọ́?
Bí Màríà ṣe fi ìrẹ̀lẹ̀ sọ̀rọ̀, tó sì múra tán láti ṣègbọràn jẹ́ ẹ̀kọ́ fáwọn èèyàn látìgbà yẹn wá títí dòní. Ó sọ fún Gébúrẹ́lì pé: “Wò ó! Ẹrúbìnrin Jèhófà! Kí ó ṣẹlẹ̀ sí mi ní ìbámu pẹ̀lú ìpolongo rẹ.” (Lúùkù 1:38) Ipò ẹrúbìnrin ló rẹ̀yìn jù nínú gbogbo ìránṣẹ́ inú ilé, nítorí ọ̀gá rẹ̀ ló máa ń pinnu bó ṣe máa lo ìgbésí ayé rẹ̀. Ojú tí Màríà fi wo ara rẹ̀ níwájú Jèhófà, Ọ̀gá rẹ̀ tó ga jù nìyẹn. Ó mọ̀ pé mìmì kan ò lè mi òun lọ́dọ̀ Jèhófà, torí pé Jèhófà kì í fàwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin sílẹ̀, àti pé yóò bù kún òun tóun bá ṣe gbogbo ohun tóun lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ńlá yìí.—Sáàmù 18:25.
Nígbà míì, Ọlọ́run máa ń ní ká ṣe ohun kan tó dà bíi pé ó le tàbí tó tiẹ̀ jọ pé kò lè ṣeé ṣe lójú wa. Àmọ́ ṣá, nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó jẹ́ ká rí ìdí tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé òun, ká fi ara wa sọ́wọ́ rẹ̀ bí Màríà ti ṣe. (Òwe 3:5, 6) Ṣé a óò ṣe bẹ́ẹ̀? Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, yóò san wá lẹ́san, ìyẹn á sì jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa nínú rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i.
Màríà Lọ Kí Èlísábẹ́tì
Ọ̀rọ̀ tí Gébúrẹ́lì sọ nípa Èlísábẹ́tì kan Màríà gbọ̀ngbọ̀n. Àbí ta ni ì bá tún lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Màríà yìí bíi ti Èlísábẹ́tì? Kíá, Màríà gbéra, ó lọ sí ẹkùn ilẹ̀ olókè ńláńlá ti Júdà, ìyẹn sì jẹ́ ìrìn àjò tó lè gba ọjọ́ mẹ́ta tàbí mẹ́rin. Nígbà tí Màríà délé Èlísábẹ́tì àti Sekaráyà àlùfáà, Jèhófà tún fi kún àwọn ẹ̀rí tí Màríà ti ní tẹ́lẹ̀ láti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ túbọ̀ lágbára sí i. Bí Èlísábẹ́tì ṣe gbọ́ ìkíni Màríà, bẹ́ẹ̀ ló kíyè sí i pé ọmọ inú ilé ọlẹ̀ òun fò fáyọ̀. Èlísábẹ́tì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, èyí tó mú kó pe Màríà ní “ìyá Olúwa mi.” Ọlọ́run fi han Èlísábẹ́tì pé ọmọ Màríà máa di Olúwa rẹ̀, ìyẹn Mèsáyà. Ọlọ́run tún mí sí i láti yin Màríà fún ìṣòtítọ́ rẹ̀, ó ní: “Aláyọ̀ pẹ̀lú ni obìnrin náà tí ó gbà gbọ́.” (Lúùkù 1:39-45) Dájúdájú, gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí fún Màríà ló máa ṣẹ!
Màríà náà wá sọ̀rọ̀. Ọlọ́run sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà lákọọ́lẹ̀ nínú Lúùkù 1:46-55. Ọ̀rọ̀ yìí lọ̀rọ̀ Màríà tó gùn jù nínú Bíbélì, ó sì jẹ́ ká mọ irú ẹni tó jẹ́. Ó jẹ́ ká rí i pé ẹni tó moore tó sì lẹ́mìí ìmọrírì ni. Èyí hàn nínú bó ṣe yin Jèhófà fún àǹfààní jíjẹ́ ìyá Mèsáyà tí Jèhófà fi jíǹkí rẹ̀. Ó fi bí ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe lágbára tó hàn, nítorí ó sọ pé Jèhófà ń rẹ agbéraga àti alágbára sílẹ̀, ó sì ń ran àwọn ẹni rírẹlẹ̀ àti tálákà tó ń fẹ́ sìn ín lọ́wọ́. Ó tún fi bí ìmọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn. Àwọn kan díwọ̀n rẹ̀ pé, ó ju ogún ẹsẹ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó tọ́ka sí!
Ó ṣe kedere pé Màríà máa ń ṣàṣàrò gan-an nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Síbẹ̀, ó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀, ó sì lo Ìwé Mímọ́ láti fi ṣàlàyé ara rẹ̀ dípò táá fi máa sọ èrò tara rẹ̀. Irú ẹ̀mí yẹn náà lọmọ tó fi oyún inú rẹ̀ bí ní nígbà tó dàgbà. Ọmọ náà sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòhánù 7:16) Ó yẹ káwa náà bi ara wa pé: ‘Ǹjẹ́ èmi náà ní irú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Àbí tinú mi ni mò ń ṣe, tí mo sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní èrò tara mi?’ Ní ti Màríà, a mọ ohun tó jẹ́ ìdáhùn rẹ̀.
Oṣù mẹ́ta gbáko ni Màríà lò lọ́dọ̀ Èlísábẹ́tì, tó ń gba ìṣírí, tóun náà sì ń fún Èlísábẹ́tì níṣìírí. (Lúùkù 1:56) Ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin méjèèjì yìí rán wa létí irú ohun tó yẹ káwọn ọ̀rẹ́ máa ṣe fúnra wọn. Tá a bá yan ọ̀rẹ́ lára àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa tọkàntọkàn, ó dájú pé ìyẹn á jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i, a ó sì túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run. (Òwe 13:20) Níkẹyìn, àkókò tó fún Màríà láti padà sílé. Kí ni Jósẹ́fù máa ṣe tó bá gbọ́ pé Màríà ti lóyún?
Màríà àti Jósẹ́fù
Ó dájú pé Màríà kò ní dúró dìgbà tóyún rẹ̀ á fi yọ kó tó sọ fún Jósẹ́fù. Ṣùgbọ́n kó tó sọ fún un, ó lè ti máa ronú nípa ohun tí ọkùnrin tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run, tó sì jẹ́ ọmọlúwàbí yìí máa ṣe tó bá gbọ́. Síbẹ̀ náà, ó lọ bá Jósẹ́fù ó sì sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà á kó ìdààmú bá Jósẹ́fù gan-an. Ó jọ pé ó fẹ́ gba ọ̀rọ̀ Màríà olólùfẹ́ rẹ̀ gbọ́, àmọ́ irú ohun tó sọ yìí kò ṣẹlẹ̀ rí. Bíbélì kò sọ àwọn èrò tó wá sí Jósẹ́fù lọ́kàn lórí ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó pinnu láti kọ̀ ọ́ sílẹ̀, torí pé ojú àwọn tó ti ṣègbéyàwó ni wọ́n fi ń wo àwọn tó bá ń fẹ́ ara wọn sọ́nà láyé ìgbà yẹn. Síbẹ̀, Jósẹ́fù kò fẹ́ dójú tì í ní gbangba, kò sì fẹ́ kí wọ́n fìyà jẹ ẹ́. Nítorí náà, ó fẹ́ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní bòókẹ́lẹ́. (Mátíù 1:18, 19) Ó dájú pé yóò dun Màríà bí ìṣẹ̀lẹ̀ tírú ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí yẹn ṣe kó ìdààmú bá ọkùnrin tó ṣọmọlúwàbí yìí. Síbẹ̀, Màríà kò torí ìyẹn bọkàn jẹ́.
Jèhófà kò jẹ́ kí Jósẹ́fù ṣe ohun tó rò pé ó dáa jù láti ṣe lórí ọ̀ràn yẹn. Lójú àlá, áńgẹ́lì Ọlọ́run sọ fún Jósẹ́fù pé ọ̀nà ìyanu ni Màríà gbà lóyún lóòótọ́. Ìtura gbáà lèyí á mà jẹ́ fún Jósẹ́fù o! Òun náà wá ṣe ohun tí Màríà ti ṣe níbẹ̀rẹ̀, ìyẹn ni pé ó tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Ó fẹ́ Màríà sílé, ó sì múra tán láti tẹ́wọ́ gba ojúṣe àrà ọ̀tọ̀ náà, ìyẹn títọ́ Ọmọ Jèhófà.—Mátíù 1:20-24.
Ó yẹ káwọn tọkọtaya àtàwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà kẹ́kọ̀ọ́ lára tọkọtaya, tó gbé ayé ní ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn yìí. Ó dájú pé bí Jósẹ́fù ṣe ń rí i tí ìyàwó rẹ̀ ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìyá, inú rẹ̀ á máa dùn pé áńgẹ́lì Jèhófà tọ́ òun sọ́nà. Jósẹ́fù ti ní láti rí ìdí tó fi yẹ kéèyàn máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nígbà tó bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. (Sáàmù 37:5; Òwe 18:13) Ó dájú pé, ńṣe ni Jósẹ́fù á máa fara balẹ̀ ṣe àwọn ìpinnu rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé, á sì jẹ́ onínúure.
Ṣùgbọ́n kókó wo la rí dì mú nínú bí Màríà ṣe múra tán láti fẹ́ Jósẹ́fù? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jósẹ́fù lè má kọ́kọ́ fi gbogbo ara gba ohun tí Màríà sọ gbọ́, síbẹ̀ Màríà ní sùúrù, ó sì fọkàn tán an pé òun ló máa jẹ́ olórí ìdílé wọn. Ó dájú pé, èyí á ti jẹ́ kí Màríà gan-an rí i pé ó dáa kéèyàn máa ní sùúrù, ẹ̀kọ́ nìyẹn sì jẹ́ fáwọn obìnrin Kristẹni lóde òní. Níkẹyìn, ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí á ti jẹ́ kí Jósẹ́fù àti Màríà mọ bí jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ pọ̀ fàlàlà láìsí àbòsí ti ṣe pàtàkì tó.
Ohun tó dára jù làwọn tọkọtaya yìí fi ṣe ìpìlẹ̀ ìdílé wọn. Àwọn méjèèjì ló nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ju ohunkóhun mìíràn, wọ́n sì fẹ́ láti jẹ́ òbí tó ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ṣe fẹ́. Dájúdájú wọ́n máa rí ọ̀pọ̀ ìbùkún, àmọ́ wọ́n á tún bá ọ̀pọ̀ ìpèníjà pàdé. Wọ́n máa ní láti tọ́ Jésù, ẹni tó máa dàgbà di ọkùnrin títóbilọ́lá jù lọ láyé yìí.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ìfẹ́ Ọlọ́run ló yẹ kéèyàn fi ṣe ìpìlẹ̀ ìgbéyàwó