Nípa Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sáwọn Èèyàn
Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù
Nípa Bó Ṣe Yẹ Ká Máa Hùwà Sáwọn Èèyàn
Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ onínúure?
Ǹjẹ́ o máa ń ṣe dáadáa sáwọn èèyàn, kódà nígbà tí wọn ò bá ṣe dáadáa sí ọ? Tá a bá fẹ́ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù, a ní láti jẹ́ onínúure sáwọn èèyàn, àní sí àwọn tó kórìíra wa pàápàá. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá nífẹ̀ẹ́ àwọn tí wọ́n ń nífẹ̀ẹ́ yín, ìyìn wo ni ó jẹ́ fún yín? Nítorí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pàápàá a máa nífẹ̀ẹ́ àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ wọn. . . . Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín . . . , ẹ ó sì jẹ́ ọmọ Ẹni Gíga Jù Lọ, nítorí pé ó jẹ́ onínúrere sí àwọn aláìlọ́pẹ́ àti àwọn ẹni burúkú.”—Lúùkù 6:32-36; 10:25-37.
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa dárí jini?
Nígbà tá a bá dẹ́ṣẹ̀, a fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá. Jésù kọ́ wa pé ó yẹ ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dárí jì wá. (Mátíù 6:12) Àmọ́, Jésù tún sọ pé Ọlọ́run ò ní dárí jì wá tá ò bá ń dárí ji àwọn tó ṣẹ̀ wá. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín ọ̀run yóò dárí jì yín pẹ̀lú; nígbà tí ó jẹ́ pé, bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.”—Mátíù 6:14, 15.
Kí ló lè mú kí ìdílé jẹ́ aláyọ̀?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù kò gbéyàwó, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ nǹkan lọ́dọ̀ rẹ̀ nípa bá a ṣe lè mú kí ìdílé láyọ̀. Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ìṣe rẹ̀, ó fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa láti máa tẹ̀ lé. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó mẹ́ta wọ̀nyí:
1. Ọkọ ní láti nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ̀. Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fáwọn ọkọ. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Dé ìwọ̀n wo ni Jésù sọ pé káwọn ọmọ ẹ̀yìn òun nífẹ̀ẹ́ ara wọn? Ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín.” (Jòhánù 13:34) Bíbélì ní káwọn ọkọ máa lo ìlànà yìí nígbà tó sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un. . . . Lọ́nà yìí, ó yẹ kí àwọn ọkọ máa nífẹ̀ẹ́ àwọn aya wọn gẹ́gẹ́ bí ara àwọn fúnra wọn. Ẹni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ aya rẹ̀ nífẹ̀ẹ́ ara rẹ̀, nítorí pé kò sí ènìyàn kankan tí ó jẹ́ kórìíra ara òun fúnra rẹ̀; ṣùgbọ́n a máa bọ́ ọ, a sì máa ṣìkẹ́ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti ń ṣe sí ìjọ.”—Éfésù 5: 25, 28, 29.
2. Ọkọ àti aya ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn. Kéèyàn ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe aya tàbí ọkọ ẹni jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, ó sì máa ń tú ìdílé ká. Jésù sọ pé: “Ẹ kò ha kà pé . . . ‘Nítorí ìdí yìí ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan’? Tí ó fi jẹ́ pé wọn kì í ṣe méjì mọ́, bí kò ṣe ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀. . . . Mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè, tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.”—Mátíù 19:4-9.
3. Àwọn ọmọ ní láti máa tẹrí bá fún àwọn òbí wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni pípé ni Jésù táwọn òbí rẹ̀ sì jẹ́ aláìpé, ó ṣègbọràn sí wọn. Bíbélì sọ nípa Jésù nígbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá pé: “Ó sì bá [àwọn òbí rẹ̀] sọ̀ kalẹ̀ lọ, wọ́n sì wá sí Násárétì, ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ wọn.”—Lúùkù 2:51; Éfésù 6:1-3.
Kí nìdí tó fi yẹ ká máa fi ìlànà wọ̀nyí sílò?
Jésù sọ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó ní: “Bí ẹ bá mọ nǹkan wọ̀nyí, aláyọ̀ ni yín bí ẹ bá ń ṣe wọ́n.” (Jòhánù 13:17) Tá a bá fẹ́ máa bá a nìṣó láti jẹ́ Kristẹni tòótọ́, a ní láti máa fi ìmọ̀ràn tí Jésù fún wa sílò nípa bó ṣe yẹ ká máa hùwà sáwọn èèyàn. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.
Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, wo orí 14 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àkàwé tí Jésù sọ nípa ọmọ onínàákúnàá kọ́ wa pé ó ṣe pàtàkì gan-an ká jẹ́ onínúure ká sì máa dárí jini.—Lúùkù 15:11-32.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ọkọ àti aya ní láti jẹ́ olóòótọ́ sí ara wọn