Ǹjẹ́ Ohunkóhun “Lè Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”?
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ǹjẹ́ Ohunkóhun “Lè Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”?
GBOGBO èèyàn ló ń fẹ́ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ òun. Ká sòótọ́, ọkàn wa máa ń balẹ̀ gan-an tá a bá mọ̀ pé àwọn ẹbí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa fẹ́ràn wa. Àmọ́, ó dunni pé àjọṣe àárín àwa ọmọ èèyàn jẹ́ ohun tó gbẹgẹ́, tó sì lè yí padà láìròtẹ́lẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́, ẹbí tàbí ojúlùmọ̀ lè ṣẹ̀ wá, wọ́n lè pa wá tì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kọ̀ wá sílẹ̀. Àmọ́, ẹnì kan wà tí ìfẹ́ rẹ̀ sí wa kì í ṣá. Ẹni náà ni Jèhófà Ọlọ́run, ìwé Róòmù 8:38, 39 sì sọ ohun tó wúni lórí nípa irú ìfẹ́ tó ní sáwọn olùjọ́sìn rẹ̀.
Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé, òun “gbà gbọ́ dájú” pé kò sí ohun tó lè “yà wá kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí kì í ṣe fún ara rẹ̀ nìkan o, ó kàn “wá,” ìyẹn gbogbo àwa tá a ń sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀. Kí kókó ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lè yéni kedere, ó sọ àwọn ohun tí kò lè yí ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń fi tọkàntọkàn sìn ín padà.
“Kì í ṣe ikú tàbí ìyè.” Ìfẹ́ tí Jèhófà ní sáwọn èèyàn rẹ̀ kì í dópin nígbà táwọn èèyàn náà bá kú. Nítorí pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wọn, kì í gbàgbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tí wọ́n bá tiẹ̀ kú, ó sì máa jí wọn dìde sínú ayé tuntun òdodo rẹ̀ tó ń bọ̀. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Àmọ́ kó tiẹ̀ tó dìgbà yẹn, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ kì í yẹ̀, láìka ohun tó wù kó ṣẹlẹ̀ sí wọn nínú ayé yìí sí.
“Tàbí àwọn áńgẹ́lì tàbí àwọn ìjọba.” Àwọn alágbára tàbí àwọn aláṣẹ lè yí èrò rere téèyàn ní nípa ẹnì kan padà, àmọ́ kò sẹ́ni tó lè yí èrò rere tí Jèhófà ní sẹ́nì kan padà. Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára, bí áńgẹ́lì tó di Sátánì kò lè yí Ọlọ́run lọ́kàn padà kó má nífẹ̀ẹ́ àwọn olùjọsìn rẹ̀ mọ́. (Ìṣípayá 12:10) Bẹ́ẹ̀ náà làwọn ìjọba tó bá ń ta ko àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ṣe lè yí ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ padà.—1 Kọ́ríńtì 4:13.
“Tàbí àwọn ohun tí ó wà níhìn-ín nísinsìnyí tàbí àwọn ohun tí ń bọ̀.” Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ kò lè ṣá láéláé. Kò sóhun tó lè ṣẹlẹ̀ sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nísinsìnyí tàbí lọ́jọ́ iwájú tó lè mú kí Ọlọ́run má nífẹ̀ẹ́ wọn mọ́.
“Tàbí àwọn agbára.” Pọ́ọ̀lù ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn alágbára lọ́run àti láyé, ìyẹn “àwọn áńgẹ́lì” àti “àwọn ìjọba,” àmọ́ ní báyìí, ó tọ́ka sí “àwọn agbára.” Onírúurú ọ̀nà la lè gbà túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lò yìí. Àmọ́, ohun yòówù kó túmọ̀ sí, ohun tó dájú ni pé: Kò sí agbára kankan lọ́run tàbí láyé tó lè mú kí Jèhófà má nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́.
“Tàbí ibi gíga tàbí ibi jíjìn.” Kò sípò táwọn èèyàn Jèhófà wà tí Jèhófà kò ní nífẹ̀ẹ́ wọn, ì báà jẹ́ inú ìdùnnú tàbí ìbànújẹ́.
“Tàbí ìṣẹ̀dá èyíkéyìí mìíràn.” Pọ́ọ̀lù lo ọ̀rọ̀ tó tọ́ka sí ẹ̀dá èyíkéyìí náà láti fi hàn dájú pé, kò sóhun tó lè ya àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà kúrò nínú ìfẹ́ Ọlọ́run.
Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sáwọn tó gbà á gbọ́ kò dà bí ìfẹ́ àwa èèyàn tó lè yí padà tàbí kó ṣá. Ìfẹ́ Ọlọ́run kì í yí padà, títí láé ni. Ó dájú pé mímọ̀ tá a mọ èyí ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ká sì máa sa gbogbo ipá wa láti fi hàn pé àwa náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.