Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Ni Wọ́n Kọ Sínú Ìwé Mímọ́ Bá A Ṣe Mọ̀ Pé Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Mọ̀wé Kọ
Ọ̀rọ̀ Tí Jésù Sọ Ni Wọ́n Kọ Sínú Ìwé Mímọ́ Bá A Ṣe Mọ̀ Pé Àwọn Kristẹni Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Mọ̀wé Kọ
LÁTI àìmọye ọdún sẹ́yìn làwọn onígbàgbọ́ ti ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ka àwọn ìwé kan tó wà lára àwọn ìwé tó lókìkí jù lọ. Bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé yìí ni wọ́n tún ń yànnàná ohun tó wà nínú wọn. Àwọn ìwé tá à ń sọ yìí làwọn èyí tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tí ọ̀pọ̀ máa ń pè ní Májẹ̀mú Tuntun. Ohun tó wà nínú àwọn ìwé yìí pẹ̀lú àwọn ìwé yòókù nínú Bíbélì ti nípa tó pọ̀ lórí ọ̀ràn ayé yìí. Wọ́n wà lára ohun tó ń pinnu nǹkan táráyé gbà pé ó tọ́ àtèyí tí wọ́n gbà pé kò tọ́, àti irú ìwà tó bójú mu láwùjọ. Àwọn òǹkọ̀wé máa ń kọ̀wé nípa wọn, bẹ́ẹ̀ sì làwọn oníṣẹ́ ọnà máa ń fẹ́ yàwòrán nípa wọn. Èyí tó wá ṣe pàtàkì jù níbẹ̀ ni pé àwọn ìwé yìí ti ran àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti Jésù, ó sì ṣeé ṣe kíwọ náà wà lára àwọn tí wọ́n ti ràn lọ́wọ́.—Jòhánù 17:3.
Kì í ṣe gbàrà tí Jésù kú ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere àtàwọn ìwé yòókù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Ó hàn gbangba pé ó tó ọdún méje sí mẹ́jọ lẹ́yìn tí Jésù kú kí Mátíù tó kọ Ìhìn Rere rẹ̀, ó sì tó ọdún márùndínláàádọ́rin lẹ́yìn ikú Jésù kí Jòhánù tó kọ tiẹ̀. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣàkọsílẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù àtohun tó ṣe, tí àṣìṣe kankan ò sì wọ̀ ọ́? Ó ṣe kedere pé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run ló darí wọn. (Jòhánù 14:16, 26) Àmọ́ báwo wá ni àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ṣe di èyí táwọn míì náà rí gbà láìyingin débi tó fi wá di ara Ìwé Mímọ́?
Ṣé “Púrúǹtù Paraku” Ni Wọ́n?
Láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn làwọn kan ti ń sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ò ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tí Jésù ṣe tó sì fi kọ́ni, pé ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ni wọ́n fi sọ ọ́ fáwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan tó máa ń ṣèwádìí nípa Bíbélì sọ pé: “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù kó tó di pé àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere ṣẹ̀ṣẹ̀ wá kọ àwọn ọ̀rọ̀ Jésù sílẹ̀. Kó tó dìgbà tí wọ́n kọ ọ́ sílẹ̀ yìí, ohun tí wọ́n bá fẹnu sọ fáwọn èèyàn náà ni wọ́n máa a Wọ́n tún sọ pé ní gbogbo ìgbà tí wọ́n ṣì ń fi àwọn ẹ̀kọ́ Jésù ṣe ọ̀rọ̀ àtẹnudẹ́nu tí wọn ò tíì kọ ọ́ sílẹ̀, wọ́n ti ní láti fi àlàyé tiwọn kún un tàbí kí wọ́n ti gbé e gba ibòmíì tàbí kí àbùmọ́ ti wọ̀ ọ́. Wọ́n ní àbárèbábọ̀ èyí ni pé àwọn ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀.
mọ̀ nípa Jésù.” Àwọn olùṣèwádìí kan tiẹ̀ sọ pé “púrúǹtù paraku ni” àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù.Èrò míì táwọn kan lára àwọn olùṣèwádìí Bíbélì fara mọ́ ni pé, báwọn rábì ayé ìgbà yẹn ṣe máa ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ làwọn Júù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn tó bá Jésù rìn náà ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ Jésù. Wọ́n ní bí wọ́n ṣe ń kọ́ni ni pé wọ́n á ní káwọn èèyàn máa ka àkọ́sórí ní àkàtúnkà, wọ́n sì ní èyí ló jẹ́ kí ohun tí wọ́n fi ọ̀rọ̀ ẹnu kọ́ àwọn èèyàn péye. Àmọ́ ṣé ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi kọ́ni? Ipa wo ni ìwé kíkọ kó nínú bí ìtàn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù kò ṣe dohun ìgbàgbé? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò lè fi gbogbo ẹnu sọ bọ́rọ̀ náà ṣe jẹ́, àmọ́ ó ṣeé ṣe kí ìwé kíkọ ṣe bẹbẹ nínú rẹ̀.
Ìwé Kíkọ Ò Ṣàjèjì Láyé Ìgbà Yẹn
Ní ọ̀rúndún kìíní, onírúurú èèyàn ló mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Nígbà tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Alan Millard, tó jẹ́ onímọ̀ nípa èdè Hébérù àti èdè táwọn ìran ọmọ Ṣémù ń sọ látijọ́, ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, ó ní: “Nílé lóko ni wọ́n ti ń fi èdè Gíríìkì, Hébérù àti Árámáíkì ṣàkọsílẹ̀ nǹkan, torí náà onírúurú èèyàn láwùjọ ló ń fàwọn èdè náà kọ̀wé.” Ó fi kún un pé: “Bí nǹkan ṣe rí lágbègbè ibi tí Jésù ti ṣiṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ nìyẹn.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n Millard fèsì sí ọ̀rọ̀ táwọn kan sọ pé “púrúǹtù làwọn èèyàn tó wà lágbègbè ibi tí wọ́n ti kọ” àwọn ìwé Ìhìn Rere. Ó ní: “Ohun tí wọ́n sọ yẹn kò lè jóòótọ́ [torí pé] ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn káàkiri àgbègbè yẹn jẹ́ àwọn tó mọ̀ọ́kọ
mọ̀ọ́kà . . . Torí náà, a máa rí lára àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ tí wọ́n á ṣàkọsílẹ̀ ohun tí wọ́n gbọ́, bóyá torí tí wọ́n bá fẹ́ lò ó tàbí torí kí wọ́n lè jẹ́ káwọn míì náà mọ̀ ọ́n.”Ó ṣe kedere pé wàláà tí wọ́n fi ìda pa ojú rẹ̀ pọ̀ dáadáa nígbà yẹn téèyàn lè rí lò láti kọ nǹkan sílẹ̀. A rí àpẹẹrẹ èyí ní orí kìíní ìwé Lúùkù. Ìgbà kan wà tí wòlíì Sekaráyà dẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ mọ́, wọ́n wá ń bi í léèrè orúkọ tó fẹ́ kí ọmọ rẹ̀ jẹ́. Ẹsẹ 63 níbẹ̀ sọ pé: “Ó sì béèrè fún wàláà kan [ó ní láti fọwọ́ ṣàpèjúwe ni], ó sì kọ ọ́ pé: ‘Jòhánù ni orúkọ rẹ̀.’” Àwọn ìwé tó ń túmọ̀ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sọ pé “wàláà” yẹn lè jẹ́ pátákó kan tí wọ́n fi ìda pa ojú rẹ̀, tó dà bíi síléètì. Ọ̀kan lára àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn tiẹ̀ lè ní wàláà yẹn lọ́wọ́, tíyẹn á sì mú kí wọ́n tètè rí ohun tí Sekaráyà máa kọ nǹkan sí.
Àpẹẹrẹ míì tún wà tó jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn mohun tó ń jẹ́ wàláà tí wọ́n fi ń kọ̀wé nígbà yẹn, téyìí sì jẹ́ ẹ̀rí pé wọ́n ń lò ó. A kà á nínú ìwé Ìṣe pé àpọ́sítélì Pétérù ń bá àwọn èrò sọ̀rọ̀ níbi tẹ́ńpìlì, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ ronú pìwà dà . . . kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́.” (Ìṣe 3:11, 19) Gbólóhùn náà, ‘pa rẹ́’ wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó túmọ̀ sí “pa ohun tá a kọ rẹ́, nù ún nù.” Ìwé kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ inú Májẹ̀mú Tuntun, ìyẹn The New International Dictionary of New Testament Theology ṣàlàyé pé: “Èrò tí gbólóhùn yìí ń gbé síni lọ́kàn níbẹ̀ yẹn ni pé kéèyàn fi ohun kan pa ojú wàláà ìkọ̀wé rẹ́ kó bàa lè rí i lò nígbà míì. Ó sì dà bíi pé ohun tí gbólóhùn yẹn máa ń gbé síni lọ́kàn láwọn ibòmíì tí wọ́n ti lò ó nìyẹn.”
Ohun tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere fi hàn pé àwọn tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn ní láti jẹ mọ́ ìwé kíkọ wà lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àtàwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni Mátíù àti Sákéù tí wọ́n jẹ́ agbowó orí (Mátíù 9:9; Lúùkù 19:2); ọ̀kan lára àwọn alága sínágọ́gù (Máàkù 5:22); ọ̀gágun (Mátíù 8:5); Jòánà, aya ọkùnrin kan tí Hẹ́rọ́dù Áńtípà fi ṣe alámòójútó (Lúùkù 8:3); tó fi mọ́ àwọn akọ̀wé, àwọn Farisí àti Sadusí pẹ̀lú àwọn ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn. (Mátíù 21:23, 45; 22:23; 26:59) Kò sí àní-àní pé ọ̀pọ̀ nínú àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù yòókù mọ̀wé kọ, àfàìmọ̀ kó má tiẹ̀ jẹ́ gbogbo wọn pàápàá.
Akẹ́kọ̀ọ́, Olùkọ́ àti Òǹkọ̀wé Ni Wọ́n
Táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bá máa lè kọ́ àwọn èèyàn, kì í ṣohun tí Jésù sọ nìkan ni wọ́n ní láti mọ̀, wọ́n tún ní láti mọ bí Òfin àtàwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ṣe ṣẹ sí Kristi lára. (Ìṣe 18:5) Ẹ wá jẹ́ ká fiyè sí ohun tí Lúùkù sọ pé ó ṣẹlẹ̀ níbi ìpàdé kan tí Jésù bá méjì nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe kété lẹ́yìn tó jíǹde. Kí ni Jésù ṣe? “Bẹ̀rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Mósè àti gbogbo àwọn Wòlíì, ó túmọ̀ àwọn nǹkan tí ó jẹmọ́ ara rẹ̀ nínú gbogbo Ìwé Mímọ́ fún wọn.” Kò pẹ́ sígbà yẹn tó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kóra jọ pé: “‘Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ mi tí mo sọ fún yín nígbà tí mo ṣì wà pẹ̀lú yín, pé gbogbo ohun tí a kọ̀wé rẹ̀ nípa mi nínú òfin Mósè àti nínú àwọn Wòlíì àti àwọn Sáàmù ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ.’ Ó wá ṣí èrò inú wọn payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́ láti mòye ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́.” (Lúùkù 24:27, 44, 45) Lẹ́yìn ìgbà yẹn, àwọn ọmọ ẹ̀yìn yẹn “rántí” ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fún wọn.—Jòhánù 12:16.
Ìtàn yìí fi hàn pé àwọn àpọ́sítélì àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù ti ní láti kẹ́kọ̀ọ́ jinlẹ̀ dáadáa kí wọ́n sì ṣèwádìí nínú Ìwé Mímọ́ kí wọ́n tó lè mọ ẹ̀kún Lúùkù 1:1-4; Ìṣe 17:11) Lórí kókó yìí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Harry Y. Gamble, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀kọ́ ìsìn nílé ẹ̀kọ́ gíga University of Virginia, kọ̀wé pé: “Kò lè sí iyè méjì pé látìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀ la ti ń ráwọn Kristẹni díẹ̀ tàbí púpọ̀ tí wọ́n fi ara wọn jin kíkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti wíwá ìtumọ̀ ohun tó wà nínú rẹ̀. Èyí ń mú kí wọ́n rí àwọn ẹ̀rí látinú rẹ̀ tó fi hàn pé ẹ̀sìn tòótọ́ ni ẹ̀sìn Kristẹni, wọ́n sì ń wá ọ̀nà báwọn á ṣe máa fi ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ yẹn wàásù nípa ẹ̀sìn Kristẹni.”
rẹ́rẹ́ ìtumọ̀ ohun tí wọ́n rí tí wọ́n sì gbọ́ lọ́dọ̀ Jésù Kristi Olúwa wọn àtàwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i. (Gbogbo èyí fi hàn pé dípò kó jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹnu lásán làwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù á fi máa tan ẹ̀kọ́ Jésù kálẹ̀, wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n ń kàwé, wọ́n sì ń kọ̀wé. Akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́ àti òǹkọ̀wé ni wọ́n. Pàtàkì jù lọ ibẹ̀ ni pé wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí tó gbẹ́kẹ̀ lé ẹ̀mí mímọ́ láti darí wọn. Jésù mú un dá wọn lójú pé “ẹ̀mí òtítọ́ náà” máa ‘mú gbogbo ohun tóun ti sọ fún wọn padà wá sí ìrántí wọn.’ (Jòhánù 14:17, 26) Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí wọ́n rántí àwọn ohun tí Jésù ṣe àtohun tó sọ, tó fi mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ gígùn, irú bí Ìwàásù Lórí Òkè, ó sì tún mú kí wọ́n lè kọ ọ́ sílẹ̀. (Mátíù orí 5 sí 7) Ẹ̀mí yìí tún tọ́ wọn sọ́nà débi tí wọ́n fi lè ṣàkọsílẹ̀ bí nǹkan ṣe ń rí lọ́kàn Jésù láwọn ìgbà míì àtàwọn ohun tó sọ nínú àdúrà.—Mátíù 4:2; 9:36; Jòhánù 17:1-26.
Torí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí iyèméjì pé àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere gbọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu àwọn èèyàn, tí wọ́n sì tún ka àwọn ìwé, Jèhófà Ọlọ́run tó ju ohun gbogbo lọ, téèyàn sì lè gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá ni orísun ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi dá wa lójú hán-únhán-ún pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí,” àti pé ó lè kọ́ wa, ó sì lè tọ́ wa sọ́nà nínú ṣíṣe ohun tínú rẹ̀ dùn sí.—2 Tímótì 3:16.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo àpótí náà “Ṣé Púrúǹtù Làwọn Àpọ́sítélì?” lójú ìwé 15.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 14]
Àwọn tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wọn ní láti jẹ mọ́ ìwé kíkọ wà lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run mú kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ rántí àwọn ohun tí Jésù ṣe tó sì sọ, ó sì tún mú kí wọ́n lè kọ ọ́ sílẹ̀
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ṣé Púrúǹtù Làwọn Àpọ́sítélì?
Nígbà táwọn alákòóso àtàwọn àgbà ọkùnrin Jerúsálẹ́mù “rí àìfọ̀rọ̀-bọpo-bọyọ̀ Pétérù àti Jòhánù, tí wọ́n sì róye pé wọ́n jẹ́ àwọn ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe kàyéfì.” (Ìṣe 4:13) Ṣé àwọn tí kò mọ̀wé tàbí púrúǹtù làwọn àpọ́sítélì lóòótọ́? Nígbà tí Bíbélì The New Interpreter’s Bible ń sọ̀rọ̀ lórí ohun tí wọ́n sọ yìí, ó sọ pé: “Ó dà bíi pé kò yẹ ká gbà pé bọ́rọ̀ yẹn ṣe rí ni wọ́n ṣe sọ ọ́ yẹn, bíi pé Pétérù [àti Jòhánù] kò kàwé kankan àti pé [wọn] ò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ohun tí wọ́n kàn ń fi gbólóhùn yẹn sọ ni pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀ gbọọrọ ló wà nínú ipò táwọn tó ń gbẹ́jọ́ yẹn àtàwọn àpọ́sítélì wà láwùjọ.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Wàláà kan tí wọ́n fi ìda pa ojú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ohun èlò ìkọ̀wé ní ọ̀rúndún kìíní tàbí ìkejì Sànmánì Kristẹni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
“Ó sì béèrè fún wàláà kan, ó sì kọ ọ́ pé: ‘Jòhánù ni orúkọ rẹ̀’”
[Credit Line]
© British Museum/Art Resource, NY