Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Ro Ìgbẹ̀yìn Ọ̀rọ̀

Máa Ro Ìgbẹ̀yìn Ọ̀rọ̀

Máa Ro Ìgbẹ̀yìn Ọ̀rọ̀

NÍNÚ ìrìn àjò ìgbésí ayé, ọ̀pọ̀ ìpinnu lèèyàn máa ń ṣe. Ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kéèyàn máa ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ kó tó ṣèpinnu èyíkéyìí. Àwọn kan ti kábàámọ̀ gidigidi nítorí ìpinnu tí wọ́n ṣe. Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti sọ nígbà kan rí pé, ‘Ká ní mo mọ̀ pé ohun tó máa gbẹ̀yìn ẹ̀ rèé, ǹ bá má ṣe é rárá.’

Arìnrìn-àjò tó mòye máa ń fẹ́ mọ ibi tí gbogbo ọ̀nà tó fẹ́ tọ̀ máa já sí. Ó lè lo àwòrán afinimọ̀nà kó sì béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ àwọn tó mọ àgbègbè yẹn dáadáa. Yóò tún máa ṣàkíyèsí àwọn àmì tó bá rí lójú ọ̀nà. Báwo nìwọ ṣe lè mọ ọ̀nà tó dára jù tó yẹ kó o tọ̀ nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ? Nígbà kan, Ọlọ́run tipasẹ̀ Mósè sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ì bá ṣe pé wọ́n gbọ́n! Nígbà náà, wọn ì bá fẹ̀sọ̀ ronú lórí èyí. Wọn ì bá ronú nípa òpin wọn ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀.”—Diutarónómì 32:29.

Ìmọ̀ràn Tó Dára Jù lọ

Kò yẹ ká máa méfò nípa ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn ìrìn àjò ìgbésí ayé àwa èèyàn. Ọlọ́run tó mọwá-mẹ̀yìn ló wà ní ipò tó dára jù láti fún gbogbo àwa èèyàn nímọ̀ràn lórí ọ̀nà tó dára jù láti tọ̀ nígbèésí ayé wa. Ó ti rí ọ̀pọ̀ ọ̀nà táwọn èèyàn ti gbà, ó sì ti rí ìgbẹ̀yìn wọn. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀nà ènìyàn ń bẹ ní iwájú Jèhófà, ó sì ń ṣàgbéyẹ̀wò gbogbo òpó ọ̀nà rẹ̀.”—Òwe 5:21.

Jèhófà máa ń bójú tó àwọn tó fẹ́ràn rẹ̀. Ó ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, Bíbélì, sọ ọ̀nà tó dára jù lọ fún wọn láti máa tọ̀. Ó sọ pé: “Èmi yóò mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, èmi yóò sì fún ọ ní ìtọ́ni nípa ọ̀nà tí ìwọ yóò máa tọ̀. Dájúdájú, èmi yóò fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.” Nítorí náà, kó o tó fẹsẹ̀ lé ọ̀nà èyíkéyìí nígbèésí ayé rẹ, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kó o gba ìmọ̀ràn látọ̀dọ̀ Jèhófà, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un ti ṣe. Ó gbàdúrà pé: “Mú mi mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn.”—Sáàmù 32:8; 143:8.

Téèyàn bá gba ọ̀nà tí arìnrìn-àjò tó mòye tó sì ṣeé fọkàn tán bá júwe fúnni, ọkàn ẹni lè balẹ̀ pé kò séwu. Èèyàn ò ní máa ṣàníyàn nípa ibi tí ọ̀nà náà máa já sí. Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó tọ́ òun sọ́nà, ó sì tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Èyí mú kó ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Dáfídì sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀ lọ́nà tó ń mórí ẹni wú ní Sáàmù kẹtàlélógún. Ó ní: “Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn mi. Èmi kì yóò ṣaláìní nǹkan kan. Ó ń mú mi dùbúlẹ̀ ní pápá ìjẹko tí ó kún fún koríko; ó ń darí mi lẹ́bàá àwọn ibi ìsinmi tí ó lómi dáadáa. Ó ń tu ọkàn mi lára. Ó ń ṣamọ̀nà mi ní àwọn òpó ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ ń rìn ní àfonífojì ibú òjìji, èmi kò bẹ̀rù ohun búburú kankan.”—Sáàmù 23:1-4.

Kí Ló Máa Jẹ́ Ìgbẹ̀yìn Wọn?

Nígbà tí ọkàn lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù, ìyẹn Ásáfù tàbí ọ̀kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ń sọ nípa ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ̀, ó ní, ẹsẹ̀ òun “fẹ́rẹ̀ẹ́ yà kúrò lọ́nà” òtítọ́. Kí nìdí? Ìdí ni pé ó rí i pé àwọn aláìṣòótọ́ ń láásìkí, ó sì ṣe ìlara “àlàáfíà àwọn ènìyàn burúkú.” Lójú rẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé àwọn aláìṣòótọ́ yóò máa wà ní “ìdẹ̀rùn fún àkókò tí ó lọ kánrin.” Ohun tó wá burú jù ni pé, ẹni tó kọ sáàmù yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá ni ọgbọ́n tiẹ̀ wà nínú rírìn ní ọ̀nà òdodo.—Sáàmù 73:2, 3, 6, 12, 13.

Nígbà tó yá ẹni tó kọ sáàmù yìí wọnú ibùjọsìn Jèhófà. Ó wá gbàdúrà sí Jèhófà, ó sì ronú lórí ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni ibi náà. Ó ní, “mo fẹ́ láti fi òye mọ ọjọ́ ọ̀la wọn.” Nígbà tó ronú dáadáa lórí ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn àwọn tóun ń ṣe ìlara wọn, ó wá mọ̀ pé “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́” ni àwọn èèyàn náà wà, àti pé Ọlọ́run yóò “mú wọn wá sí òpin wọn nípasẹ̀ ìpayà òjijì!” Kí wá lẹ́ni tó kọ sáàmù yìí sọ nípa ọ̀nà tóun ń tọ̀? Ó sọ pé: “Lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ [Jèhófà] yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.”—Sáàmù 73:17-19, 24.

Nígbà tí ẹni tó kọ sáàmù yìí ronú lórí ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn àwọn tó kó ọrọ̀ jọ nípasẹ̀ èrú àti àìṣòótọ́, ó wá dá a lójú pé ọ̀nà tó dára lòun ń tọ̀. Ohun tó fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi.” Àǹfààní tó wà nínú sísúnmọ́ Jèhófà Ọlọ́run pọ̀ gan-an.—Sáàmù 73:28.

“Mọ Ibi Tí Ò Ń Lọ”

Lóde òní, àwa náà lè wà ní àwọn ipò kan tó lè gba pé ká ṣèpinnu, bíi tẹni tó kọ sáàmù yẹn. Wọ́n lè fi iṣẹ́ kan tó máa tètè mówó wọlé lọ̀ wá, ó sì lè jẹ́ ìgbéga lẹ́nu iṣẹ́, tàbí kí wọ́n pè wá láti wá dara pọ̀ mọ́ àwọn kan nínú iṣẹ́ kan tó máa mú owó rẹpẹtẹ wọlé. Òótọ́ ni pé kò sẹ́ni tó lè fọwọ́ sọ̀yà nípa ohun tó máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn iṣẹ́ kan téèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ dáwọ́ lé. Síbẹ̀ náà, ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu pé kó o fara balẹ̀ ronú nípa ohun tó lè jẹ́ ìgbẹ̀yìn ìpinnu èyíkéyìí tó o bá ṣe? Kí làwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó yọrí sí? Ṣé iṣẹ́ tó o fẹ́ ṣe yẹn máa gba pé kó o kúrò nílè, tó sì ṣeé ṣe kí èyí fa wàhálà fún ọkọ tàbí aya rẹ, tàbí ìwọ fúnra rẹ? Ṣé iṣẹ́ yẹn ò ní mú kó o máa bá àwọn oníwàkiwà rìn, bóyá àwọn alábàáṣiṣẹ́ rẹ, àwọn tó o bá pàdé ní òtẹ́ẹ̀lì tàbí níbòmíì? Tó o bá fara balẹ̀ wo ọ̀nà tó o fẹ́ tọ̀, wàá lè ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Sólómọ́nì Ọba sọ pé: “Mọ ibi tí ò ń lọ.”—Òwe 4:26, Contemporary English Version.

Gbogbo wa pátá ló yẹ ká ronú lórí ìmọ̀ràn yẹn, àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ lọ̀rọ̀ yìí kàn jù. Ẹ wo àpẹẹrẹ ọ̀dọ́kùnrin kan tó lọ yá fídíò kan, tó sì mọ̀ pé apá kan wà nínú fídíò náà tó lè mú kí ọkàn ẹni máa fà sí ìbálòpọ̀. Ọ̀dọ́kùnrin náà sọ pé lẹ́yìn tóun wo fídíò náà tán, ó wá ń ṣe òun bíi pé kóun ní ìbálòpọ̀. Nígbà tí kò sì lè mára dúró mọ́, ó gba ọ̀dọ̀ aṣẹ́wó kan tó ń gbé nítòsí ilé rẹ̀ lọ, ó sì ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Níkẹyìn, ìdààmú ọkàn bá ọ̀dọ́mọkùnrin yìí, ẹ̀rí ọ̀kan rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí i dà á láàmù, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa àìsàn tó ṣeé ṣe kóun ti kó lára aṣẹ́wó yẹn. Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa irú ohun tí ọ̀dọ́mọkùnrin yìí ṣe, ó ní: “Lójijì, ó ń tọ obìnrin náà lẹ́yìn, bí akọ màlúù tí ń bọ̀ àní fún ìfikúpa.” Ó mà ṣe o, nǹkan ì bá má rí báyìí fún ọ̀dọ́kùnrin yẹn, ká ní ó ti ro ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà.—Òwe 7:22, 23.

Tẹ̀ Lé Àwọn Àmì Tó Ń Fini Mọ̀nà

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn ló máa gbà pé kò bọ́gbọ́n mu téèyàn ò bá tẹ̀ lé àwọn àmì tó ń fini mọ̀nà. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn kan kì í tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí wọ́n bá fún wọn nípa ìrìn àjò ìgbésí ayé, tí kò bá ti bá ohun tí wọ́n fẹ́ mu. Wo àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan nígbà ayé Jeremáyà. Nígbà kan, orílẹ̀-èdè yẹn fẹ́ ṣe ìpinnu kan. Jèhófà Ọlọ́run wá sọ fún wọn pé: “Ẹ béèrè fún àwọn òpópónà ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, ibi tí ọ̀nà tí ó dára wà nísinsìnyí; ẹ sì máa rìn ín.” Àmọ́, ńṣe làwọn èèyàn olóríkunkun yẹn sọ pé àwọn “kì yóò rìn” ní ọ̀nà yẹn. (Jeremáyà 6:16) Kí ni ìgbẹ̀yìn orí kunkun tí wọ́n ṣe yẹn? Lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Bábílónì pa ìlú Jerúsálẹ́mù run pátápátá, wọ́n sì kó àwọn èèyàn ibẹ̀ lọ sí oko ẹrú ní Bábílónì.

Téèyàn bá kọ̀ tí kò tẹ̀ lé àwọn àmì afinimọ̀nà tí Ọlọrun ń fún wa, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kì í dáa rárá. Bíbélì gbà wá níyànjú pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.”—Òwe 3:5, 6.

Àwọn kan lára ìkìlọ̀ Ọlọ́run lè dà bí àmì kan tó ní àkọlé náà, “Má Wọ Ibí Yìí.” Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Má wọ ipa ọ̀nà àwọn ẹni burúkú, má sì rìn tààrà lọ sínú ọ̀nà àwọn ẹni búburú.” (Òwe 4:14) Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà eléwu tá a gbọ́dọ̀ yẹra fún nínú Òwe 5:3, 4. Ó ní: “Ètè àjèjì obìnrin ń kán tótó bí afárá oyin, òkè ẹnu rẹ̀ sì dùn mọ̀nràn-ìn mọnran-in ju òróró lọ. Ṣùgbọ́n ohun tí ó máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ korò bí iwọ; ó mú bí idà olójú méjì.” Ìgbádùn làwọn kan ka níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aṣẹ́wó tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn sí. Àmọ́, àgbákò ló máa ń yọrí sí nígbẹ̀yìn, téèyàn ò bá tẹ̀ lé àmì tó ń sọ fúnni pé “Má Wọ Ibí Yìí,” ìyẹn àwọn àmì tó ń jẹ́ ká mọ àwọn ìwà tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́.

Kó o tó fẹsẹ̀ lé ọ̀nà kan, kọ́kọ́ bi ara rẹ pé, ‘Kí ló máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn rẹ̀?’ Tó o bá dúró díẹ̀ tó o sì ronú lórí ohun tó ṣeé ṣe kó jẹ́ “ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀” náà, èyí lè mú kó o yẹra fún ṣíṣe àwọn nǹkan tó o máa kábàámọ̀ nígbẹ̀yìn. Lára àwọn nǹkan tó lè jẹ́ ìgbẹ̀yìn rẹ̀ téèyàn bá kọ̀ tí kò tẹ̀ lé àwọn àmì afinimọ̀nà tí Ọlọ́run ń fún wa nìwọ̀nyí: Kíkó àrùn éèdì àtàwọn àrùn míì téèyàn ń kó nípasẹ̀ ìbálòpọ̀, oyún ẹ̀sín, ìṣẹ́yún, àjọṣe tí kò dára mọ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn, àti ẹ̀rí ọkàn tó ń dani láàmú. Lọ́nà tó ṣe kedere, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó máa gbẹ̀yìn àwọn oníṣekúṣe. Ó ní, wọn “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

“Èyí Ni Ọ̀nà”

Nígbà míì, ó máa ń ṣòro láti mọ ohun tó máa gbẹ̀yìn ọ̀nà kan téèyàn fẹ́ tọ̀. A mà dúpẹ́ o, pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa ó sì ń fún wa láwọn ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere! Jèhófà sọ pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 30:21) Kí ni ìgbẹ̀yìn ọ̀nà tí Jèhófà ń fi hàn wá? Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà náà há tí kò sì rọrùn láti gbà, Jésù sọ pé ọ̀nà tó lọ sí ìyè ni.—Mátíù 7:14.

Dúró díẹ̀ kó o ronú nípa ọ̀nà tó ò ń tọ̀ báyìí. Ṣé ọ̀nà tó tọ́ ni? Kí ló máa gbẹ̀yìn rẹ̀? Gbàdúrà sí Jèhófà pé kó tọ́ ẹ sọ́nà? Wo ‘àwòrán afinimọ̀nà,’ ìyẹn Bíbélì, kó lè tọ́ ẹ sọ́nà. O tiẹ̀ lè rí i pé ó yẹ kó o béèrè ọ̀nà lọ́wọ́ arìnrìn-àjò kan tó mòye, ìyẹn ẹni tó ti ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run tipẹ́tipẹ́. Tó o bá sì rí i pé ó yẹ kó o yí ọ̀nà rẹ padà, ńṣe ni kó o ṣe bẹ́ẹ̀ láìjáfara.

Ọkàn arìnrìn-àjò kan sábà máa ń balẹ̀ tó bá rí àmì afinimọ̀nà tó jẹ́ kó mọ̀ pé òun wà lójú ọ̀nà tó tọ́. Tó o bá ti ṣàyẹ̀wò ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ, tó o sì wá rí i pé ọ̀nà òdodo lò ń tọ̀, ńṣe ni kó o máa tẹ̀ síwájú. O máa tó dé ibi tí èrè tó pọ̀ jù lọ wà nínú ìrìn àjò náà.—2 Pétérù 3:13.

Ọ̀nà yòówù kó o gbà, ibì kan ló máa já sí. Tó o bá dé òpin ọ̀nà tó ò ń tọ̀ yìí, ibo nìwọ máa já sí? Kò ní dáa rárá tó o bá lọ dé òpin rẹ̀ tán, tó o wá ń kábàámọ̀ pé: ‘Ǹ bá sì ti mọ̀ kí n má gba ọ̀nà yìí o!’ Nítorí náà, kó o tó fẹsẹ̀ lé ọ̀nà mìíràn nínú ìrìn àjò ìgbésí ayé rẹ, bi ara rẹ pé, ‘Kí ló máa jẹ́ ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ yìí?’

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kí Ló Máa Jẹ́ Ìgbẹ̀yìn Ọ̀rọ̀ Yìí?

Àwọn ọ̀dọ́ sábà máa ń dojú kọ ìdẹwò láti ṣe àwọn nǹkan tó dà bíi pé ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn máa ń ṣe. Díẹ̀ lára àwọn ipò táwọn ọ̀dọ́ lè bá ara wọn rèé:

Ẹni kan sọ pé sùẹ̀gbẹ̀ ni ẹ́, o ò tó bẹ́ẹ̀ láti mu sìgá yìí.

Olùkọ́ kan ń gbà ẹ́ níyànjú pé kó o lọ kàwé sí i ní yunifásítì, torí ó fẹ́ kó dáa fún ẹ.

Wọ́n pè ẹ́ síbi àríyá kan tó jẹ́ pé oríṣiríṣi ọtí lílé àti oògùn olóró ló máa wà níbẹ̀.

Ẹnì kan sọ fún ẹ pé kó o fi ìsọfúnni nípa ara rẹ ránṣẹ́ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì.

Ọ̀rẹ́ rẹ kan pè ẹ́ pé kó o wá wo eré kan tó ní ìwà ipá tàbí ìṣekúṣe nínú.

Tó o bá dojú kọ ìdẹwò láti ṣe èyíkéyìí lára àwọn ohun tá a sọ yìí, kí lo máa ṣe? Ṣé wàá kàn gbà láti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ni, àbí wàá fara balẹ̀ rò ohun tó lè jẹ ìgbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ náà? Á dáa kó o bi ara rẹ pé: “Ṣé [ẹnì] kan lè wa iná jọ sí oókan àyà rẹ̀, síbẹ̀síbẹ̀ kí ẹ̀wù rẹ̀ gan-an má sì jóná? Tàbí kẹ̀, ṣé [ẹnì] kan lè rìn lórí ẹyín iná, kí ẹsẹ̀ rẹ̀ pàápàá má sì jó?”—Òwe 6:27, 28.