Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Tó O Bá Dé Etí Odò Coco, Yà Sápá Ọ̀tún”

“Tó O Bá Dé Etí Odò Coco, Yà Sápá Ọ̀tún”

Lẹ́tà kan Láti Orílẹ̀-Èdè Nicaragua

“Tó O Bá Dé Etí Odò Coco, Yà Sápá Ọ̀tún”

“WÀÁ nílò ọkọ̀ tó lè rìn lójú ọ̀nà gbágungbàgun, wàá tún nílò jáàkì ńlá tó lè gbé ọkọ̀ tó wúwo, wàá sì rọ epo sínú àwọn kẹ́ẹ̀gì dání. Ní in lọ́kàn pé wàá wọnú ẹrọ̀fọ̀ tó máa mu táyà ọkọ̀ rẹ tán o. Tó o bá dé etí odò Coco, yà sápá ọ̀tún.”

Ẹnì kan tá a jọ jẹ́ míṣọ́nnárì ló sọ̀rọ̀ yìí. Ká má purọ́, ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Síbẹ̀, láàárọ̀ ọjọ́ Tuesday kan báyìí, mo bọ́ sójú ọ̀nà láti lọ bá àwọn ará wa ṣe àpéjọ ní Wamblán, ìlú kékeré kan tó wà lápá àríwá orílẹ̀-èdè Nicaragua.

Mo ti jí bọ́ sọ́nà láti ìdájí, ọkọ̀ akẹ́rù ńlá mi ni mo gbé lọ. Ọkọ̀ yìí ti ń gbó àmọ́ ṣe ló ṣì ń lọ geerege ní òpópónà títẹ́jú tó la àárín àwọn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kọjá. Nígbà tí mo dé ìlú Jinotega, mo gba ọ̀nà eléruku kan táwọn ará ibẹ̀ ń pè ní feo, tó túmọ̀ sí burẹ́wà. Kí n tó kúrò ní ìlú yẹn, mo rí àwọn ilé ìtajà méjì kan, tórúkọ wọn ń jẹ́ Ìyanu Ọlọ́run àti Àjíǹde.

Kọ́lọkọ̀lọ báyìí lójú ọ̀nà rí, béèyàn sì ṣe ń pọ́n òkè lá máa da fíríì. Ṣe ni mo rọra ń lọ díẹ̀díẹ̀ bí mo ṣe ń já sí kòtò já sí gegele. Bí mo ṣe ń lọ lójú ọ̀nà, mo rí adágún odò gígùn kan tó dákẹ́ rọ́rọ́ sí àfonífojì òkè gíga kan tí àwọsánmà bò. Látinú kùrukùru tó gba ojú ọjọ́ yẹn, mo ń wo àwọn igi olódòdó tí wọ́n tò sáàárín àwọn igi míì, irú àfòmọ́ kan tó jẹ́ òdòdó sì lọ́ mọ́ wọn.

Níbi kọ́nà kan báyìí, ṣíún ló kù kí ọkọ̀ mi kọ lu ọkọ̀ akérò kan tó gba gbogbo ọ̀nà kan. Ńṣe ni ọkọ̀ yìí ń rú èéfín lọ tùù táwọn táyà rẹ̀ sì ń ta òkúta bó ṣe ń lọ. Lorílẹ̀-èdè Nicaragua níbí, èèyàn máa rí àwọn ọkọ̀ akérò tí wọ́n kọ oríṣiríṣi orúkọ ìnagijẹ àwọn ewèlè awakọ̀ tó ń wà wọ́n sára gíláàsì wọn. Lára orúkọ tí wọ́n máa ń kọ ni Aṣẹ́gun, Àkekèé, Òjòlá tàbí Ọdẹ.

Nígbà tó fi máa di ọjọ́kanrí, mo ti dé Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Pantasma. Mo rí ilé kan níbẹ̀ tí wọ́n fi pákó kọ́, wọn ò rẹ́ ilẹ̀ àyíká rẹ̀, àmọ́ wọ́n gbá a mọ́ tónítóní. Ohun tí mo rí níbi ilé yẹn dà bí àwòrán tá a máa ń rí nínú àwọn ìwé ayé àtijọ́. Mo rí bàbá àgbàlagbà kan tó jókòó sórí bẹ́ǹṣì, ajá kan tó sùn sábẹ́ igi, màlúù méjì tí wọ́n wà lábẹ́ àjàgà tí wọ́n so kẹ̀kẹ́ tó ní táyà onígi mọ́. Ní ìlú kékeré kan, mo rí omilẹgbẹ àwọn ọmọ ilé ìwé tí wọ́n ń jáde látinú ilé ìwé kan. Wọ́n wọ aṣọ aláwọ̀ búlúù tó jẹ́ aṣọ ilé ìwé wọn, wọ́n sì ya bo ojú pópó bí ìgbà tí ìgbì òkun bá ya wá sétíkun.

Oòrùn mú gan-an nígbà tí mo fi máa dé ìlú Wiwilí níbi tí mo ti tajú kán rí odò Coco. Alagbalúgbú odò yìí ṣàn gba ìlú náà kọjá láti apá òkè dé apá ìsàlẹ̀. Bí mo ṣe débẹ̀, mo rántí bí wọ́n ṣe júwe ọ̀nà fún mi, mo bá yà sọ́tùn-ún. Ìrìn nǹkan bíi kìlómítà mẹ́tàdínlógójì ni mo rìn lójú ọ̀nà tó léwu yìí kí n tó lè dé ìlú Wamblán.

Ó tó bí odò pẹ́ṣẹ́pẹ́ṣẹ́ mẹ́jọ tàbí mẹ́sàn-án tí ọkọ̀ mi ń rọ́ lù bí mo ṣe ń lọ lójú ọ̀nà gbágungbàgun yẹn. Níbi tí mo ti ń gbìyànjú láti yàgò fáwọn kòtò tó wà lójú ọ̀nà eléruku tí mò ń gbà lọ, mo tu eruku díẹ̀ sókè. Bó bá jẹ́ pé àwọn ará ibẹ̀ nìyẹn ṣẹlẹ̀ sí, wọ́n á sọ pé, “Mo bulẹ̀ jẹ.” Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín, mo dé òpin ọ̀nà yẹn níbi tí ìlú Wamblán tí mo ń lọ wà. Inú àfonífojì kan báyìí tí igi yí gbogbo ibẹ̀ ká ni ìlú yẹn wà.

Lọ́jọ́ kejì, ó dà bíi pé aago mẹ́rin ààbọ̀ ni gbogbo ará ìlú yẹn ti jí. Àwọn àkùkọ tó ń kọ láìdáwọ́dúró tètè jí mi lọ́jọ́ yẹn, torí náà mo dìde ńlẹ̀, mo sì rìn lọ rìn bọ̀ lójú pópó wọn. Ìtasánsán búrẹ́dì alágbàdo tí wọ́n ń pè ní tortilla tó wà lórí ààrò ti gba gbogbo orí òkè.

Àwọn ayàwòrán ibẹ̀ ya àwọn àwòrán Párádísè sára ògiri káàkiri ibẹ̀, ó sì lẹ́wà gan-an. Mo tún rí àwọn àmì tó ń polówó ọtí ẹlẹ́rìndòdò lára àwọn ṣọ́ọ̀bù tó wà ní kọ̀rọ̀, èyí tí wọ́n ń pè ní pulperías. Mo sì tún rí àwọn ìwé àlẹ̀mógiri tó ń polongo ìlérí táwọn ìjọba mẹ́tà tó ti kọjá ti ṣe. Mo tún wá rí àwọn ṣáláńgá tí wọ́n fi páànù kọ́ níta.

Nígbà tí mo kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, mo kí wọn pé “Adiós” ní èdè Nicaragua. Àwọn èèyàn ń rẹ́rìn-ín músẹ́ wọ́n sì ń kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. A ní láti gbóhùn sókè ketekete bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ nítorí pé kà-ko-kà-ko tí pátákò àwọn ẹṣin àti ìbaaka ń dùn bí wọ́n ṣe ń lọ tí wọ́n ń bọ̀ kò jẹ́ ká gbọ́ràn.

Nígbà tó dìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Friday, àwọn tó wá ṣe àpéjọ ti ń dé pẹ̀lú ìdílé wọn. Bá a ṣe ráwọn tó fẹsẹ̀ rìn wá la ráwọn tó gun ẹṣin wá la sì tún ráwọn tó wọ mọ́tò ńlá wá. Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin kéékèèké kan tiẹ̀ fẹsẹ̀ rìn fún wákàtí mẹ́fà, bàtà rọ́bà sì ni wọ́n wọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdó olóró tó lè pa wọ́n lára wà níbi tí wọ́n ti ń ré odò kọjá, síbẹ̀ wọ́n kọjá, wọn ò sì tún bẹ̀rù eṣúṣú tó lè máa bù wọ́n jẹ nínú odò tó pa rọ́rọ́ yẹn. Oúnjẹ díẹ̀ làwọn kan tí wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn gbé dání, wọn ò ní ju ìrẹsì tí wọ́n fi ọ̀rá ẹlẹ́dẹ̀ sí lọ. Kí ni gbogbo wọn wá ṣe níbí yìí?

Wọ́n wá kí wọ́n tún lè mú un dá ara wọn lójú pé ọjọ́ iwájú wọn máa dára jù báyìí lọ. Wọ́n wá gbọ́ àlàyé Bíbélì tá a fẹ́ ṣe fún wọn. Wọ́n tún wá láti múnú Ọlọ́run dùn.

Nígbà tó wá di ọjọ́ Sátidé tá a ti ń retí, àwọn tó wà ní àwùjọ yìí ju ọ̀ọ́dúnrún [300] lọ. Wọ́n jókòó sórí bẹ́ǹṣì àti àga oníke. Àwọn ìyá àbúrò ń fọ́mọ wọn lóúnjẹ. Àwọn ẹlẹ́dẹ̀ ń kùn hùnrùn-hùnrùn, bẹ́ẹ̀ làwọn òròmọdìyẹ ń ké ṣíoṣío ní oko tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tá a ti fẹ́ ṣe àpéjọ.

Bí ojú ọjọ́ ṣe ń gbóná sí i, ooru yẹn wá fẹ́ kọjá àfaradà. Síbẹ̀, àwọn tó wà láwùjọ tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́ sí gbogbo ìmọ̀ràn àti ìtọ́ni tí wọ́n ń gbọ́. Wọ́n ń fojú bá àwọn olùbánisọ̀rọ̀ lọ bí wọ́n ṣe ń ka ẹsẹ Bíbélì, lásìkò orin wọ́n ń kọ orin tá a gbé karí Bíbélì, wọ́n sì ń fetí sílẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sáwọn àdúrà tí wọ́n ń gbà látorí pèpéle.

Lẹ́yìn ìpàdé ọjọ́ yẹn, mo lọ dúró síbi táwọn ará tó kù wà, mo sì bá àwọn ọmọdé ṣeré. Èmi àti àwọn ògowẹẹrẹ yìí wá jíròrò ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀ nínú nǹkan tí wọ́n gbọ́ nípàdé. Mo fi àwòrán àwọn ìràwọ̀ ojú sánmà hàn wọ́n nínú kọ̀ǹpútà mi. Àwọn ọmọ yẹn ń rẹ́rìn-ín, inú àwọn òbí wọn sì ń dùn.

Àfi bíi pé kí àpéjọ yẹn má parí mọ́, àmọ́ oníkálùkù ní láti padà sílé. Àárọ̀ ọjọ́ kejì ni mo kúrò níbẹ̀, àwọn ohun tí mo ti rí níbẹ̀ ò sì kúrò lọ́kàn mi, ìfẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi tuntun yìí sì wà lọ́kàn mi pẹ̀lú. Mo pinnu láti fara wé wọn, kí n mọ bá a ṣeé nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, kí n sì máa dúró de Ọlọ́run.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn ará wa rìnrìn àjò tọmọtọmọ láti ibi tó jìnnà torí àpéjọ tí wọ́n wá ṣe nílùú Wamblán