Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣóòótọ́ Làwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wà Nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere?

Ṣóòótọ́ Làwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wà Nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere?

Ṣóòótọ́ Làwọn Ọ̀rọ̀ Tó Wà Nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere?

“Ní báyìí, ó yẹ ká ti máa wo àwọn ìwé ìhìn rere bí ìtàn àròsọ táwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kọ.”—Ọ̀gbẹ́ni Burton L. Mack, ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu ẹ̀kọ́ Májẹ̀mú Tuntun ló sọ bẹ́ẹ̀.

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ lókè yìí nìkan kọ́ ló nírú èrò yìí. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ míì náà ti kọminú sáwọn ìwé Ìhìn Rere tí Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù kọ nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù àti iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe. Kí nìdí táwọn kan fi rò pé ìtàn àròsọ ló wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere? Ṣó yẹ kí èrò tí wọ́n ní mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì pé bóyá làwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere lè jóòótọ́? Jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀rí tó wà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé Ìhìn Rere.

Àwọn Kan Kọminú Sáwọn Ìwé Ìhìn Rere

Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] ọdún sẹ́yìn làwọn èèyàn ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kọminú sáwọn ìwé Ìhìn Rere lọ́nà tó lékenkà. Àmọ́, nǹkan bí igba [200] ọdún sẹ́yìn làwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan wá bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ́ńbẹ́lú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Wọ́n ní ìtàn àròsọ táwọn èèyàn kọ lásán ni, kì í ṣe ìwé tí Ọlọ́run mí sí. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n sọ pé ohun táwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere kọ ò ṣojú wọn, torí náà àwọn ò lè gbà pé òótọ́ lohun tí wọ́n kọ nípa Jésù. Wọ́n tún sọ pé, báwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́ta àkọ́kọ́ àti ọ̀nà tí wọ́n gbà kọ wọ́n ṣe jọra fi hàn pé ńṣe làwọn tó kọ wọ́n da ọ̀rọ̀ ara wọn kọ. Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ yìí tún sọ pé àwọn ò gbà pé lóòótọ́ ni Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, àwọn ò sì gbà pé lóòótọ́ ni Jésù jí dìde báwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣe sọ. Àwọn míì tiẹ̀ sọ pé Jésù ò gbé ayé rí pàápàá!

Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ yìí tún sọ pé, ó ní láti jẹ́ pé Máàkù ló kọ́kọ́ kọ ìwé Ìhìn Rere tiẹ̀, torí pé ohun tó fi yàtọ̀ sí ti Mátíù àti Lúùkù ò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Wọ́n tún sọ pé inú ìwé Máàkù ni Mátíù àti Lúùkù ti kọ ìwé Ìhìn Rere tiwọn, kí wọ́n tó wá fàwọn ìsọfúnni díẹ̀ kún un látinú ìwé kan táwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ń pè ní “Q” (ìyẹn ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ German náà Quelle, tó túmọ̀ sí “ibi tá a ti mú ọ̀rọ̀”). Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀gbẹ́ni A.F.J. Klijn tó máa ń ṣèwádìí lórí Bíbélì ṣe sọ, ńṣe làwọn àbá tó ti wá gbayé kan yìí ń “fàbùkù kan àwọn tó kọ̀wé Ìhìn Rere pé àwọn ìtàn táwọn kan ti kọ ni wọ́n fi kọ tiwọn.” Dájúdájú, ńṣe nirú èrò bẹ́ẹ̀ sọ àwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere di ẹni tó ń da ìwé àwọn ẹlòmíì kọ lórúkọ ara wọn tàbí ẹni tó ń kọ àwọn ìtàn àròsọ lásán. Àwọn ẹ̀kọ́ yìí sì ti sọ ìgbàgbọ́ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló dárí àwọn tó kọ Bíbélì dèyí tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀.—2 Tímótì 3:16.

Ṣóòótọ́ Làwọn Tó Kọ Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Da Ìwé Àwọn Ẹlòmíì Kọ?

Ṣé báwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́ta àkọ́kọ́ ṣe jọra fi hàn pé lóòótọ́ làwọn tó kọ ọ́ da ara wọn kọ́? Rárá o. Kí nìdí tọ́rọ̀ ò fi rí bẹ́ẹ̀? Ohun kan ni pé Jésù ti ṣèlérí fàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ máa ‘mú gbogbo ohun tí òun ti sọ fún wọn pa dà wá sí ìrántí wọn.’ (Jòhánù 14:26) Torí náà, kò yani lẹ́nu pé àwọn tó kọ àwọn ìwé Ìhìn Rere rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà tí wọ́n kọ sílẹ̀. Lóòótọ́, àwọn kan lára àwọn tó kọ Bíbélì lè ti ka ìwé táwọn míì kọ, kí wọ́n sì tọ́ka sí wọn, àmọ́ wọ́n á ti ní láti fẹ̀sọ̀ ṣèwádìí, kì í ṣe pé wọ́n joyè adàwékọ. (2 Pétérù 3:15) Yàtọ̀ síyẹn, ìwé kan tí wọ́n ṣe láti máa túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, ìyẹn The Anchor Bible Dictionary sọ pé: “Àṣà àtẹnudẹ́nu lè mú kí wọ́n há àwọn ọ̀rọ̀ kan tí Jésù sọ sórí kí wọ́n sì wá kọ ọ́ sílẹ̀ lọ́nà tó jọra.”

Lúùkù sọ pé òun ti bá àwọn tí ọ̀rọ̀ ṣojú wọn sọ̀rọ̀, òun sì ti “tọpasẹ̀ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpéye.” (Lúùkù 1:1-4) Ṣéyẹn wá túmọ̀ sí pé ẹni tó ń jí ìwé àwọn ẹlòmíì kọ tàbí ẹni tó ń kọ ìtàn àròsọ lásán ni Lúùkù? Rárá o! Lẹ́yìn tí awalẹ̀pìtàn kan tó ń jẹ́ William Ramsay ṣàyẹ̀wò ìwé tí Lúùkù kọ kínníkínní, ó sọ pé: “Ọ̀kan lára àwọn ògbóǹkangí nínú ìtàn kíkọ ni Lúùkù: kì í ṣe torí pé àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé nìkan ni, àmọ́ ó tún mọ bí wọ́n ṣe ń kọ ìtàn . . . Ó yẹ kó wà lára àwọn òpìtàn tó gbayì jù lọ.”

Ọ̀rọ̀ àwọn Bàbá Ìjọ ìjímìjí àti ti Ọ̀gbẹ́ni Origen tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán [1,700] ọdún sẹ́yìn, fi hàn pé àpọ́sítélì Mátíù ló kọ́kọ́ kọ ìwé Ìhìn Rere tiẹ̀. Ọ̀gbẹ́ni Origen sọ pé: “Mátíù ló kọ ìwé Ìhìn Rere àkọ́kọ́, ìyẹn Mátíù tó jẹ́ agbowó orí, tó wá di àpọ́sítélì Jésù Kristi. Àwọn aláwọ̀ṣe Júù ló kọ ìwé náà fún, èdè Hébérù ló si fi kọ ọ́.” Ó dájú pé, Mátíù tó jẹ́ àpọ́sítélì táwọn ọ̀rọ̀ náà sì ṣojú rẹ̀ ò ní lọ máa da ìwé Máàkù tọ́rọ̀ ò ṣojú rẹ̀ kọ. Kí ló wá dé tí wọ́n fi sọ pé inú ìwé Máàkù àti ìwé ìsọfúnni tí wọ́n pè ní “Q” ni Mátíù àti Lúùkù ti da ìwé tiwọn kọ?

Ṣé Máàkù Ló Kọ́kọ́ Kọ Ìwé Ìhìn Rere Tiẹ̀?

Ìwé atúmọ̀ èdè kan tó dá lórí Bíbélì, ìyẹn The Anchor Bible Dictionary, sọ pé èrò táwọn kan ní pé Máàkù ló kọ́kọ́ kọ ìwé Ìhìn Rere tiẹ̀, tí Mátíù àti Lúùkù sì wá dà á kọ kì í ṣe èrò tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣì gbà pé Máàkù ló kọ́kọ́ kọ ìwé Ìhìn Rere tiẹ̀ kí Mátíù àti Lúùkù tó wá kọ tiwọn, torí pé ìwé Máàkù fi díẹ̀ kún ju àwọn ìwé Ìhìn Rere tó kù lọ. Bí àpẹẹrẹ, ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún méjì [200] sẹ́yìn, Ọ̀gbẹ́ni Johannes Kuhn tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ta kú pé Máàkù ló kọ́kọ́ kọ ìwé Ìhìn Rere tiẹ̀. Kuhn sọ pé, bí kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀ ni “a jẹ́ pé ńṣe ni Máàkù kọ ìwé Ìhìn Rere tiẹ̀ lẹ́yìn tó ti ka ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù àti Lúùkù.”

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Ìhìn Rere Máàkù ló kúrú jù, kò yani lẹ́nu pé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó sọ, tó fi yàtọ̀ sí ti Mátíù àti Lúùkù ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé òun ni wọ́n kọ́kọ́ kọ. Bákàn náà, kì í ṣòótọ́ pé kò sóhun tí Máàkù fi kún ohun tí Mátíù àti Lúùkù kọ. Nínú àkọsílẹ̀ tó kún dáadáa, tó sì wọni lọ́kàn tí Máàkù kọ nípa iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù ṣe, ó ju ọgọ́sàn-án [180] ẹsẹ lọ tó fi ṣe àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé tó fani mọ́ra tí kò sí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù àti Lúùkù, ìyẹn ló sì mú kí ọ̀nà tó gbà kọ ìtàn ìgbésí ayé Jésù yàtọ̀ sí tàwọn tó kù.—Wo  àpótí tó wà lójú ìwé 13.

Ìwé Ìsọfúnni Wo Ni Wọ́n Pè Ní “Q”?

Kí la wá lè sọ nípa ìwé ìsọfúnni tí wọ́n pè ní “Q,” tí wọ́n sọ pé inú rẹ̀ ni Mátíù àti Lúùkù ti rí ohun tí wọ́n kọ? Ọ̀jọ̀gbọ́n kan nípa ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ James M. Robinson sọ pé: “Ó dájú pé ìwé “Q” nìwé tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú àwọn ìwé ẹ̀sìn Kristẹni.” Ọ̀rọ̀ yìí yani lẹ́nu gan-an torí pé kò síwèé tó ń jẹ́ “Q” lóde òní, kò sì sẹ́ni tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé ìwé náà ti wà rí! Bí kò ṣe sẹ́ni tó ní ìwé yìí lọ́wọ́ lónìí jẹ́ kàyéfì torí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ sọ pé ọ̀pọ̀ ẹ̀dà ìwé yìí ni wọ́n ti ní láti pín káàkiri nígbà yẹn. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn Bàbá Ìjọ ò fìgbà kan rí tọ́ka sí ìwé yìí.

Rò ó wò ná. Ó yẹ kí ìwé “Q” yìí ti wà, káwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì kín èrò náà lẹ́yìn pé ìwé Ìhìn Rere Máàkù ni wọ́n kọ́kọ́ kọ lóòótọ́. Bó ṣáà ṣe yẹ kọ́rọ̀ rí nìyẹn tó bá jẹ́ pé ṣe ni wọ́n dara wọn kọ. Torí náà, tírú ọ̀rọ̀ yìí bá délẹ̀, ó máa jẹ́ ìwà ọgbọ́n tá a bá fi òwe yìí sọ́kàn pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.

Òótọ́ Ọ̀rọ̀ Tó Ṣeé Gbára Lé Ló Wà Nínú Àwọn Ìwé Ìhìn Rere

Báwọn akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣe ń gbé onírúurú àbá tí ò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ jáde kò jẹ́ káwọn èèyàn fẹ́ láti ka àwọn ìwé Ìhìn Rere mọ́, àwọn ìwé wọ̀nyẹn ló sì sòótọ́ nípa Jésù àti iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe. Àwọn ìwé Ìhìn rere yìí fi hàn kedere pé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ò ka àkọsílẹ̀ nípa ìgbésí ayé Jésù, iṣẹ́ ìwàásù tó ṣe, ikú àti àjíǹde rẹ̀ sí ìtàn àròsọ. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn tọ́rọ̀ náà ṣojú wọn ló jẹ́rìí sóòótọ́ yìí. Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tó ṣe tán láti fara da inúnibíni àti ikú nítorí wọ́n fẹ́ fara wé Jésù mọ̀ pé, kò ní bọ́gbọ́n mú láti jẹ́ Kristẹni tó bá jẹ́ pé ìtàn àròsọ lásán ni iṣẹ́ ìwàásù tí Jésù ṣe àti àjíǹde rẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 15:3-8, 17, 19; 2 Tímótì 2:2.

Nígbà tí Ọ̀gbẹ́ni George W. Buchanan tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n lórí ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ń sọ̀rọ̀ nípa àríyànjiyàn tí àbá wọn, nípa ìwé Ìhìn Rere Máàkù àti abàmì ìwé tí wọ́n pè ní “Q” tí ò sí níbì kankan, dá sílẹ̀, ó ní: “Torí pé àwọn àbá wọ̀nyẹn làwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń fẹ́ láti lóye, wọn ò lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú àwọn ìwé náà.” Ohun tí ọ̀gbẹ́ni yìí sọ bá ìmọ̀ràn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún Tímótì mu pé kó má ṣe “fi àfiyèsí sí àwọn ìtàn èké àti sí àwọn ìtàn ìlà ìdílé, èyí tí kì í yọrí sí nǹkan kan, ṣùgbọ́n tí ń mú àwọn ìbéèrè fún ìwádìí jinlẹ̀ wá dípò pípín ohunkóhun fúnni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 1:4.

Àwọn ọ̀rọ̀ inú àwọn ìwé Ìhìn Rere ṣeé gbára lé. Òótọ́ ọ̀rọ̀ látẹnu àwọn tọ́rọ̀ ṣojú wọn ló wà ńbẹ̀. Àwọn tó kọ wọ́n ṣèwádìí jinlẹ̀. Wọ́n sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù Kristi. Nítorí náà, bíi ti Tímótì, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, tó sọ pé: “Máa bá a lọ nínú àwọn ohun tí o ti kọ́, tí a sì ti yí ọ lérò padà láti gbà gbọ́.” A nídìí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ láti gbà pé, “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí” títí kan àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin.—2 Tímótì 3:14-17.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

 Tó Bá Jẹ́ Pé Máàkù Ò Kọ Ìwé Ìhìn Rere Ni, A Ò Ní Mọ̀ Pé . . .

Jésù wò yí ká pẹ̀lú ìkannú, nítorí tí ó ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi sí yíyigbì ọkàn-àyà wọn (Máàkù 3:5)

Bóánágè ni orúkọ àpèlé Jòhánù àti Jákọ́bù (Máàkù 3:17)

obìnrin tí ó ní ìṣàn ẹ̀jẹ̀ yẹn ti ná gbogbo ohun àmúṣọrọ̀ rẹ̀ (Máàkù 5:26)

Hẹrodíà di kùnrùngbùn sí Jòhánù Olùbatisí àti pé Hẹ́rọ́dù bẹ̀rù Jòhánù ó sì pa á mọ́ láìséwu (Máàkù 6:19, 20)

Jésù pe àwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n wá sinmi díẹ̀ (Máàkù 6:31)

àwọn Farisí máa ń fọ ọwọ́ wọn títí dé ìgúnpá (Máàkù 7:2-4)

Jésù gbé àwọn ọmọdé sí apá rẹ̀ (Máàkù 10:16)

Jésù ní ìfẹ́ fún ọ̀dọ́ alákòóso náà (Máàkù 10:21)

Pétérù, Jákọ́bù, Jòhánù àti Áńdérù béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ níkọ̀kọ̀ (Máàkù 13:3)

ọ̀dọ́kùnrin kan fi ẹ̀wù aṣọ ọ̀gbọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ sẹ́yìn (Máàkù 14:51, 52)

Yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, àpèjúwe kan àti iṣẹ́ ìyanu méjì tí Jésù ṣe wà nínú ìwé Ìhìn Rere Máàkù tí kò sí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere tó kù.—Máàkù 4:26-29; 7:32-37; 8:22-26.

Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì wà nínu ìwé Ìhìn Rere Máàkù tí kò sí nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere tó kù. Ó dájú pé a máa túbọ̀ mọyì ìwé Ìhìn Rere Máàkù tá a bá wáyè ṣàṣàrò dáadáa lórí irú àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó ṣe pàtàkì wọ̀nyí.