Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó O Máa Ń Jowú? Òjòwú Làwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù

Ṣó O Máa Ń Jowú? Òjòwú Làwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ṣó O Máa Ń Jowú? Òjòwú Làwọn Ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù

JẸ́ KÁ sọ̀rọ̀ nípa ohun tó túmọ̀ sí láti jowú. Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti fẹ́ràn ẹni táwọn èèyàn bá pè léèyàn dáadáa, tí wọ́n sọ pé ó rẹwà tàbí tó já fáfá? a— Bó ṣe máa ń ṣàwọn òjòwú nìyẹn.

Àwọn ọmọ lè bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ara wọn, táwọn òbí bá ń fi hàn pé àwọn fẹ́ràn ọmọ kan ju àwọn tó kù lọ. Bíbélì sọ nípa ìdílé kan tí owú ti dá wàhálà ńlá sílẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo wàhálà tó dá sílẹ̀ nínú ìdílé yẹn àti ẹ̀kọ́ tá a lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀.

Jósẹ́fù ni ọmọkùnrin kọkànlá tí Jékọ́bù bí, àwọn ọbàkan rẹ̀ sì jowú rẹ̀. Ṣó o mọ ohun tó fà á?— Ìdí ni pé Jékọ́bù, bàbá wọn fẹ́ràn Jósẹ́fù ju àwọn tó kù lọ. Bí àpẹẹrẹ, Jékọ́bù ṣe ẹ̀wù kan tó nílà, tó sì lẹ́wà gan-an fún Jósẹ́fù. Jékọ́bù dìídì fẹ́ràn Jósẹ́fù “nítorí pé òun ni ọmọkùnrin ọjọ́ ogbó rẹ̀” àti pé òun ni ọmọ àkọ́kọ́ tí Rákélì aya rẹ̀ ọ̀wọ́n bí fún un.

Bíbélì sọ pé, ‘nígbà táwọn arákùnrin rẹ̀ wá rí i pé bàbá àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo àwọn tó kù lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra Jósẹ́fù.’ Lọ́jọ́ kan, Jósẹ́fù sọ fáwọn aráalé rẹ̀ pé nínú àlá kan tóun lá, gbogbo àwọn ẹ̀gbọ́n òun títí kan bàbá òun ló forí balẹ̀ fóun. Bíbélì sọ pé, “àwọn arákùnrin rẹ̀ . . . bẹ̀rẹ̀ sí jowú rẹ̀,” kódà bàbá rẹ̀ bá a wí pé ó sọ irú àlá bẹ́ẹ̀ jáde.—Jẹ́nẹ́sísì 37:1-11.

Nígbà tí Jósẹ́fù wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wà lọ́nà jíjìn níbi tí wọ́n ti ń tọ́jú àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́ bàbá wọn. Jékọ́bù wá rán Jósẹ́fù pé kó lọ wo àlááfíà àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ṣó o mọ ohun tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ń rò nígbà tí wọ́n rí i tó ń bọ̀ lọ́ọ̀ọ́kán?— Wọ́n fẹ́ pa á! Ṣùgbọ́n Rúbẹ́nì àti Júdà ò fẹ́ kí wọ́n pa á.

Nígbà táwọn oníṣòwò kan ń kọjá lọ sí ilẹ̀ Íjíbítì, Júdà sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a tà á.” Bí wọ́n sì ṣe tà á nìyẹn. Lẹ́yìn náà, wọ́n pa ewúrẹ́ kan, wọ́n sì ri ẹ̀wù Jósẹ́fù sínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà. Nígbà tí wọ́n fi ẹ̀wù náà han bàbá wọn, ó figbe ta pé: “Ẹranko ẹhànnà abèṣe ti ní láti pa á jẹ!”—Jẹ́nẹ́sísì 37:12-36.

Nígbà tó yá, Fáráò ọba Íjíbítì fẹ́ràn Jósẹ́fù. Ìdí tó fi fẹ́ràn rẹ̀ ni pé Ọlọ́run jẹ́ kí Jósẹ́fù lè ṣàlàyé ìtúmọ̀ àwọn àlá méjì tí Fáráò lá. Àkọ́kọ́ lára àwọn àlá náà ni tàwọn abo màlúù méje tó sanra dáadáa, táwọn màlúù méje tó gbẹ sì ń tẹ̀ lé wọn. Èkejì ni tàwọn ṣírí ọkà méje tó tóbi dáadáa àti ṣírí ọkà méje tó tín-ín-rín. Jósẹ́fù sọ pé ohun táwọn àlá méjèèjì yìí túmọ̀ sí ni pé, oúnjẹ máa pọ̀ dáadáa fún ọdún méje, ìyàn sì máa mú gan-an lọ́dún méje tó máa tẹ̀ lé e. Fáráò wá yan Jósẹ́fù sípò láti máa tọ́jú oúnjẹ pa mọ́ láwọn ọdún tí oúnjẹ máa pọ̀ gan-an yẹn, kí wọ́n lè múra sílẹ̀ de ìgbà tí ìyàn máa mú.

Nígbà tí ìyàn bẹ̀rẹ̀ sí mú, àwọn aráalé Jósẹ́fù tó ń gbé lọ́nà jíjìn ò rí oúnjẹ jẹ. Jékọ́bù rán àwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù mẹ́wàá pé kí wọ́n wá oúnjẹ lọ sílùú Íjíbítì. Ọ̀dọ̀ Jósẹ́fù ni wọ́n ti fẹ́ wá ra oúnjẹ, àmọ́ wọn ò dá a mọ̀. Jósẹ́fù ò jẹ́ káwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mọ̀ pé òun ni àbúrò wọn, ó dán wọn wò, ó sì wá rí i pé wọ́n ti kábàámọ̀ ìwà ìkà tí wọ́n hù sí òun. Lẹ́yìn ìyẹn ni Jósẹ́fù ṣẹ̀ṣẹ̀ wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun ni. Inú wọn dùn gan-an láti tún rí ara wọn lẹ́ẹ̀kan sí i!—Jẹ́nẹ́sísì orí 40 sí 45.

Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ nípa owú jíjẹ nínú ìtàn Bíbélì yìí?— Owú jíjẹ lè dá wàhálà ńlá sílẹ̀, kódà ó lè mú kẹ́nì kan fẹ́ ṣe ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò rẹ̀ léṣe! Jẹ́ ká ka Ìṣe 5:17, 18 àti Ìṣe 7:54-59, ká sì wá rí ohun táwọn èèyàn ṣe sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù torí wọn jowú wọn.— Ṣó o wá rídìí tí kò fi yẹ ká máa jowú nínú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán yìí?—

Ọmọ àádọ́fà [110] ọdún ni Jósẹ́fù nígbà tó kú. Ó láwọn ọmọ, àwọn ọmọ yìí bímọ, àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ yìí sí tún bí àwọn ọmọ. Ó dájú pé Jósẹ́fù á máa kọ́ wọn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, kí wọ́n má sì máa jowú ara wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 50:22, 23, 26.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá ń kàwé yìí fún ọmọ kékeré, àmì (—) tó wà lẹ́yìn àwọn ìbéèrè kan ń sọ fún ẹ pé kó o dánu dúró, kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tẹnu ẹ̀.

Ìbéèrè:

○ Kí ló túmọ̀ sí láti máa jowú?

○ Kí làwọn ẹ̀gbọ́n Jósẹ́fù ṣe nítorí pé wọ́n jowú?

○ Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi dárí ji àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀?

○ Kí la lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?