“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run”
INÚ RERE. Àánú. Ìdáríjì. Ìfẹ́. Ó ṣeni láàánú pé ìwọ̀nba làwọn tó ń fàwọn ànímọ́ wọ̀nyí ṣèwà hù lónìí. Ìwọ ńkọ́? Ṣó ti ṣe ẹ́ rí pé pẹ̀lú bó o ṣe ń gbìyànjú tó láti máa fàwọn ànímọ́ yìí ṣèwà hù, pàbó ló ń já sí? Tó o bá ti rora ẹ pin, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé àwọn ìwàkiwà tó ti di bárakú tàbí ohun ìbànújẹ́ kan tó ṣẹlẹ̀ sí ẹ sẹ́yìn ò ní jẹ́ kó o lè fàwọn ànímọ́ tó máa jẹ́ káwọn èèyàn sún mọ́ ẹ wọ̀nyẹn ṣèwà hù. Síbẹ̀, òótọ́ kan tó fi wá lọ́kàn balẹ̀ tí Bíbélì kọ́ wa ni pé, Ẹlẹ́dàá wa mọ̀ pé fífi àwọn ànímọ́ dáadáa wọ̀nyí ṣèwà hù ò kọjá agbára wa.
Ọ̀rọ̀ Ọlọrun gba àwọn Kristẹni tòótọ́ níyànjú pé: “Nítorí náà, ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (Éfésù 5:1) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn fi hàn pé Ọlọ́run ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn tó ń sìn ín. Lọ́nà wo? Jèhófà Ọlọ́run dá èèyàn ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 27) Ọlọ́run tipa bẹ́ẹ̀ dá àwọn ànímọ́ bíi tirẹ̀ mọ́ àwa èèyàn. a Nítorí náà, nígbà tí Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “di aláfarawé Ọlọ́run,” ńṣe ló dà bíi pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ń sọ fún wọn pé: ‘Mo gba ẹ̀rí yín jẹ́. Mo mọ̀ lóòótọ́ pé aláìpé ni yín, àmọ́ ẹ ṣì lè fìwà jọ mí dé àyè kan.’
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run tá a lè máa fi ṣèwà hù? Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣáájú Éfésù 5:1 àtèyí tó tẹ̀ lé e dáhùn ìbéèrè yìí. Kíyè sí i pé “nítorí náà” ni Pọ́ọ̀lù fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó ti sọ pé ká fara wé Ọlọ́run. Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù ti ń bọ́rọ̀ bọ̀ láti ẹsẹ tó ṣáájú níbi tó ti sọ̀rọ̀ nípa inú rere, ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti ìdáríjì. (Éfésù 4:32; 5:1) Lẹ́yìn náà, nínú ẹsẹ tó tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n fara wé Ọlọ́run, ó sọ pé kí wọ́n máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn látọkàn wá. (Éfésù 5:2) Ká sòótọ́, tó bá dọ̀rọ̀ ká finú rere hàn sáwọn èèyàn, ká ṣàánú wọn, ká dárí jì wọ́n fàlàlà, ká sì nífẹ̀ẹ́ wọn, Jèhófà Ọlọ́run ni àpẹẹrẹ tó ta yọ jù lọ tá a lè fara wé.
Kí nìdí tó fi yẹ ká fẹ́ láti dà bí Ọlọ́run? Kíyè sí ohun pàtàkì tó máa jẹ́ ká fẹ́ dà bí Ọlọ́run nínú ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù, ó ní: “Ẹ di aláfarawé Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí í ṣe olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” Ọ̀rọ̀ yìí mà wọni lọ́kàn o. Jèhófà ń fojú ọmọ tó fẹ́ràn gan-an wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Bí ọmọkùnrin kékeré kan ṣe máa ń fẹ́ láti dà bíi bàbá rẹ̀ gẹ́lẹ́, làwọn Kristẹni tòótọ́ ṣe máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti dà bíi Bàbá wọn ọ̀run.
Jèhófà ò fipá mú àwọn èèyàn láti fara wé òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fún wa lómìnira láti máa ṣe ohun tó bá wù wá. Nítorí náà, ọwọ́ rẹ ló kù sí bóyá wàá máa fara wé Ọlọ́run tàbí o ò ní fara wé e. (Diutarónómì 30:19, 20) Àmọ́, má gbàgbé pé fífi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run ṣèwà hù ò kọjá agbára rẹ. Kó o tó lè fara wé Ọlọ́run, o gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ mọ irú ẹni tó jẹ́. Bíbélì máa jẹ́ kó o mọ gbogbo ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa Ọlọ́run àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ tí ò láfiwé. Àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí kò láfiwé sì ti jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa fara wé e.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìwé Kólósè 3:9, 10 jẹ́ ká mọ̀ pé dídá tá a dá wa ní àwòrán Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìwà àbínibí. Bíbélì rọ àwọn tó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn pé kí wọ́n máa fi “àkópọ̀ ìwà tuntun” ṣèwà hù, èyí tó máa sọ wọ́n “di tuntun . . . ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán [Ọlọ́run] tí ó dá” wọn.