Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere

Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere

Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Bàbá Rere

“Ẹ̀yin baba, ẹ má ṣe rorò sí àwọn ọmọ yín, kí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn má baà bá wọn.”—Kólósè 3:21, Ìròhìn Ayọ̀.

BÁWO làwọn bàbá ṣe lè ṣe é tí wọn ò fi ní máa rorò sáwọn ọmọ wọn? Ó ṣe pàtàkì pé káwọn bàbá mọ̀ pé ojúṣe kékeré kọ́ làwọn ní. Ìwé ìròyìn kan tó máa ń ṣàlàyé nípa ìrònú ẹ̀dá sọ pé: “Ọwọ́ táwọn bàbá bá fi mú àwọn ọmọ wọn máa ń nípa lórí bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn ọmọ wọn àti ọ̀nà táwọn ọmọ náà ń gbà ronú ju ohunkóhun mìíràn lọ, ìdí tọ́ràn sì fi rí bẹ́ẹ̀ ò rọrùn láti ṣàlàyé.”

Kí ni ojúṣe àwọn bàbá? Nínú ọ̀pọ̀ ìdílé, ojú tí wọ́n fi ń wo bàbá ni pé òun ló máa ń fìyà jẹ àwọn ọmọ tí wọ́n bá ṣẹ̀. Ọ̀pọ̀ àwọn ìyá ló máa ń sọ fáwọn ọmọ tó bá hùwà tí kò tọ́ pé, ‘Ìwọ jẹ́ kí bàbá ẹ dé, á fojú ẹ réèmọ̀!’ Ká sòótọ́, káwọn ọmọ lè dàgbà dẹni tó mọnú rò, wọ́n nílò ìbáwí tó bọ́gbọ́n mu, wọ́n sì ní láti mọ̀ pé táwọn òbí àwọn bá ti sọ̀rọ̀, wọn ò ní kó o jẹ. Àmọ́ jíjẹ́ bàbá rere kọjá gbogbo èyí tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí.

Ó bani nínú jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo bàbá ló lẹ́ni tí wọ́n lè fara wé kí wọ́n lè jẹ́ bàbá rere. Ìdílé tí ò ti sí bàbá ni wọ́n ti tọ́ àwọn ọkùnrin kan dàgbà. Nígbà míì sì rèé, àwọn bàbá kan máa ń le koko mọ́ àwọn ọmọ wọn bóyá torí pé bí bàbá tiwọn náà ṣe tọ́ wọn dàgbà nìyẹn. Báwo nirú àwọn bàbá bẹ́ẹ̀ ṣe lè gbara wọn lọ́wọ́ irú àwọn àṣà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n lè di bàbá rere?

Ibì kan wà táwọn bàbá ti lè rí ìmọ̀ràn tó bá àkókò mu tó sì ṣeé fọkàn tán tí wọ́n bá fẹ́ jẹ́ bàbá rere. Ìmọ̀ràn tó dáa jù lọ lórí ọ̀ràn ìdílé wà nínú Bíbélì. Ìmọ̀ràn tó wà níbẹ̀ kọjá ìmọ̀ ọgbọ́n orí èèyàn lásán, bẹ́ẹ̀ kì í yanjú ìṣòro kan kó wá fi dá ìṣòro míì sílẹ̀. Ọgbọ́n Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì ló wà nínú Ìwé Mímọ́, òun sì ni Ẹni tó dá ìdílé sílẹ̀. (Éfésù 3:14, 15) Tó o bá jẹ́ bàbá, ó máa dáa kó o gbé àwọn ohun tí Bíbélì sọ nípa ọmọ títọ́ yẹ̀ wò. a

Ó ṣe pàtàkì pé kéèyàn jẹ́ bàbá rere, kì í ṣe nípa títọ́jú àwọn ọmọ àti mímọ ẹ̀dùn ọkàn wọn nìkan ni, àmọ́ ó tún kan ríràn wọ́n lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run. Ó máa rọrùn gan-an fún ọmọ tó sún mọ́ bàbá rẹ̀ tí bàbá rẹ̀ sì fẹ́ràn gidigidi láti sún mọ́ Ọlọ́run kó sì ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. Ó ṣe tán, Bíbélì ti jẹ́ kó yé wa pé bíi Bàbá ni Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa jẹ́ sí wa. (Aísáyà 64:8) Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan mẹ́fà táwọn ọmọ nílò látọ̀dọ̀ bàbá wọn. Bá a bá ṣe ń sọ̀rọ̀ lórí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan mẹ́fà wọ̀nyí la ó máa jíròrò àwọn ìlànà Bíbélì tó lè ran àwọn bàbá lọ́wọ́ láti fún àwọn ọmọ wọn láwọn nǹkan tí wọ́n nílò.

Àwọn Ọmọ Fẹ́ Kí Bàbá Àwọn Fẹ́ràn Àwọn

Jèhófà ti fàpẹẹrẹ tó pé lélẹ̀ fáwọn tó fẹ́ di bàbá rere. Nígbà tí Bíbélì ń ṣàlàyé bọ́rọ̀ Jésù, àkọ́bí Ọmọ Ọlọ́run, ṣe rí lọ́kàn Bàbá rẹ̀, ó ní: “Baba nífẹ̀ẹ́ Ọmọ.” (Jòhánù 3:35; Kólósè 1:15) Kì í ṣẹ̀ẹ̀kan kì í ṣẹ̀ẹ̀mejì tí Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ mọ̀ pé òun fẹ́ràn rẹ̀, òun sì fọwọ́ sáwọn nǹkan tó ń ṣe. Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi, Jèhófà sọ̀rọ̀ látọ̀run, ó ní: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” (Lúùkù 3:22) Jésù ò fìgbà kankan ṣiyèméjì pé bóyá ni Bàbá òun fẹ́ràn òun. Kí làwọn bàbá lè rí kọ́ lára Ọlọ́run?

Ẹ máa sọ fáwọn ọmọ yín pé ẹ fẹ́ràn wọn. Kelvin, bàbá ọlọ́mọ márùn-ún sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni mo máa ń gbìyànjú láti jẹ́ káwọn ọmọ mi mọ̀ pé mo fẹ́ràn wọn, kì í ṣe pé mo kàn máa ń sọ pé mo fẹ́ràn wọn nìkan ni, àmọ́ mo tún máa ń jẹ́ kó hàn nínú ìwà mi pé mo nífẹ̀ẹ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Èmi náà máa ń wọ ìtẹ́dìí fún wọn mo sì máa ń wẹ̀ fún wọn.” Yàtọ̀ síyẹn, ó yẹ kẹ́ ẹ tún jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ̀ pé ẹ gba tiwọn. Torí náà, kò ní dáa kẹ́ ẹ máa rí sí wọn ṣáá, kó wá lọ jẹ́ pé gbogbo ìgbà lẹ máa máa bá wọn wí. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni kẹ́ ẹ máa gbóríyìn fún wọn dáadáa. Donizete, bàbá àwọn ọmọbìnrin méjì tí ò tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún sọ pé: “Àwọn bàbá gbọ́dọ̀ máa wá ọ̀nà láti gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn.” Táwọn ọmọ yín bá mọ̀ pé ẹ gba tiwọn, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn níyì lójú yín. Ìyẹn sì lè jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.

Àwọn Ọmọ Fẹ́ Kí Bàbá Àwọn Jẹ́ Àpẹẹrẹ Rere Fáwọn

Ìwé Jòhánù 5:19 sọ pé, “kìkì ohun tí [Jésù] rí tí Baba ń ṣe” ló ń ṣe. Kíyè sí pé ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ni pé Jésù rí ohun tí Baba “ń ṣe,” òun náà sì ń ṣe bẹ́ẹ̀. Báwọn ọmọ náà ṣe sábà máa ń ṣe nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, tí bàbá bá ń fọ̀wọ̀ wọ ìyàwó ẹ̀ tó sì ń fi hàn pé òun mọyì ẹ̀, tí ọmọkùnrin tó bí bá dàgbà òun náà á máa fọ̀wọ̀ wọ àwọn obìnrin á sì máa mọyì wọn. Àwọn ọmọkùnrin nìkan kọ́ ni ìwà àwọn bàbá máa ń nípa lé lórí, torí ìwà àwọn bàbá tún máa ń sọ ojú táwọn ọmọbìnrin wọn á fi máa wo àwọn ọkùnrin.

Ṣó máa ń ṣòro fáwọn ọmọ ẹ láti tọrọ àforíjì? Àpẹẹrẹ bàbá tún ṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn yìí. Kelvin rántí pé nìgbà kan àwọn ọmọkùnrin òun méjì fọ́ kámẹ́rà olówó ńlá kan. Inú bí Kelvin débi pé ó fìbínú fọwọ́ gba tábìlì kan tí tábìlì náà sì pín sí méjì. Nígbà tó yá, ohun tí Kelvin ṣe yẹn ò dùn mọ́ ọn nínú, ó sì tọrọ àforíjì lọ́wọ́ gbogbo wọn, títí kan ìyàwó rẹ̀, ó ní kí wọ́n máà bínú pé òun ṣinú bí. Ó mọ̀ lọ́kàn ẹ̀ pé àwọn ọmọ òun kẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tóun ṣe yẹn torí pé kì í ṣòro fún wọn láti tọrọ àforíjì.

Àwọn Ọmọ Máa Ń Fẹ́ Wà Níbi Tínú Wọn Á Ti Máa Dùn

“Ọlọ́run aláyọ̀” ni Jèhófà. (1 Tímótì 1:11) Abájọ tí inú Jésù, Ọmọ rẹ̀, fi máa ń dùn láti wà lọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀. Ìwé Òwe 8:30 tún jẹ́ ká lóye irú àjọṣe tó wà láàárín Jésù àti Bàbá rẹ̀, ó ní: “Mo wá wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ [Bàbá] gẹ́gẹ́ bí àgbà òṣìṣẹ́, . . . tí mo ń yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ níwájú rẹ̀ ní gbogbo ìgbà.” Àjọṣe Bàbá sọ́mọ wo ló tún kọjá èyí!

Àwọn ọmọ yín nílò ibi tínú wọn á ti máa dùn. Tẹ́ ẹ bá ń wáyè láti máa bá wọn ṣeré inú wọn á máa dùn. Àárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ wọn máa gún tí wọ́n bá ń bára wọn ṣeré. Felix ní kò sírọ́ ńbẹ̀. Ó ní ọmọkùnrin kan tí ò tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún, ohun tó sọ ni pé: “Wíwá àkókò láti bá ọmọ mi ṣeré túbọ̀ máa ń jẹ́ káàárín wa gún. A jọ máa ń tayò, a máa ń lọ bá àwọn ọ̀rẹ́ ṣeré, a sì máa ń lọ gbafẹ́ láwọn ibi tó gbádùn mọ́ni. Èyí ti jẹ́ kí ilé wa tòrò, ó sì ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ra wa.”

Ó Yẹ Kẹ́ Ẹ Kọ́ Àwọn Ọmọ Yín Nípa Ọlọ́run

Bàbá Jésù kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. Abájọ tí Jésù fi lè sọ pé: “Àwọn ohun náà tí mo . . . gbọ́ láti ọ̀dọ̀ [Bàbá] ni mo ń sọ nínú ayé.” (Jòhánù 8:26) Lójú Ọlọ́run, bàbá ló ni ojúṣe láti kọ́ àwọn ọmọ lọ́nà tó yẹ kí wọ́n máa hùwà, òun náà ló sì yẹ kó kọ́ wọn nípa Ọlọ́run. Ọ̀kan lára àwọn ojúṣe tẹ́ ẹ ní gẹ́gẹ́ bíi bàbá ni láti gbin àwọn ìlànà tó tọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ yín. Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ yìí gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ṣì wà lọ́mọ ọwọ́. (2 Tímótì 3:14, 15) Ọmọkùnrin Felix ṣì kéré gan-an nìgbà tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ka àwọn ìtàn Bíbélì sí i létí. Àwọn ìtàn tó dùn tó sì láwọn àwòrán tó rẹwà títí kan àwọn ìtàn tó wà nínú Ìwé Ìtàn Bíbélì ni Felix máa ń sọ fún ọmọ rẹ̀. b Bí ọmọkùnrin Felix ṣe ń dàgbà ni Felix tún yan àwọn ìwé míì tó dá lórí Bíbélì tó sì bá ọjọ́ orí ọmọ náà mu kó lè máa fi kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́.

Donizete sọ pé: “Kò rọrùn láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a máa ń ṣe nínú ìdílé wa gbádùn mọ́ni. Ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí máa fi hàn nínú ìwà wọn pé àwọn mọyì ìjọsìn Ọlọ́run, torí àwọn ọmọ máa ń tètè mọ̀ táwọn òbí ò bá ṣe ohun tí wọ́n ń kọ́ wọn.” Carlos tó láwọn ọmọkùnrin mẹ́ta sọ pé: “A máa ń ṣèpàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti jíròrò àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìdílé wa. Èmi, ìyàwó mi àti gbogbo àwọn ọmọ wa ló láǹfààní láti sọ ohun tá a máa jíròrò nínú ìpàdé náà.” Kelvin náà máa ń wáyè láti bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run níbikíbi tí wọ́n bá wà, ohun tí wọ́n bá sì ń ṣe lọ́wọ́ kì í dí wọn lọ́wọ́ láti sọ̀rọ̀. Èyí rán wa létí ohun tí Mósè sọ, ó ní: “Kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí mo ń pa láṣẹ fún ọ lónìí sì wà ní ọkàn-àyà rẹ; kí ìwọ sì fi ìtẹnumọ́ gbìn wọ́n sínú ọmọ rẹ, kí o sì máa sọ̀rọ̀ nípa wọn nígbà tí o bá jókòó nínú ilé rẹ àti nígbà tí o bá ń rìn ní ojú ọ̀nà àti nígbà tí o bá dùbúlẹ̀ àti nígbà tí o bá dìde.”—Diutarónómì 6:6, 7.

Àwọn Ọmọ Yín Nílò Ìbáwí

Àwọn ọmọ yín nílò ìbáwí kí wọ́n lè dàgbà dẹni tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́, kí wọ́n sì lè dàgbà di ọmọlúwàbí. Àwọn òbí kan máa ń ronú pé táwọn ò bá tíì na àwọn ọmọ wọn, káwọn fìyà jẹ wọ́n, tàbí káwọn sọ̀rọ̀ gbá wọn lórí, àwọn ò tíì bá wọn wí. Àmọ́ Bíbélì jẹ́ kó yé wa pé bíbá ọmọ wí ò ní ká rorò mọ́ wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, àwọn òbí ní láti fìwà jọ Jèhófà, kí wọ́n máa fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí. (Hébérù 12:4-11) Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀yin, baba, ẹ má ṣe máa sún àwọn ọmọ yín bínú, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní títọ́ wọn dàgbà nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà.”—Éfésù 6:4.

Nígbà míì, ó lè pọn dandan pé kẹ́ ẹ fìyà jẹ àwọn ọmọ yín. Àmọ́, ó yẹ kí ọmọ tẹ́ ẹ bá fìyà jẹ mọ ìdí tóun fi ń jìyà. Ìyà táwọn òbí máa fi jẹ ọmọ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí táá jẹ́ kọ́mọ náà máa ronú pé òun ò já mọ́ nǹkan kan. Bíbélì ò fọwọ́ sí lílu àwọn ọmọ nílùkulù, torí ìyẹn lè ṣe wọ́n léṣe. (Òwe 16:32) Kelvin sọ pé: “Nígbà tí mo bá rí i pó pọn dandan kí n bá àwọn ọmọ mi wí lórí àwọn ọ̀ràn tó le, mo máa ń jẹ́ kó yé wọn pé torí mo fẹ́ràn wọn ni mo ṣe fẹ́ bá wọn wí.”

Ẹ Ní Láti Dáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín

Ẹ ní láti dáàbò bo àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ àwọn nǹkan tó lè nípa tí ò dáa lórí wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ tó lè sọ wọ́n dìdàkudà. Ó bani nínú jẹ́ pé “àwọn ènìyàn burúkú” tó fẹ́ bayé àwọn ọmọ tí ò dákan mọ̀ jẹ́ wà nínú ayé yìí. (2 Tímótì 3:1-5, 13) Báwo lẹ ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ yín? Ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì rèé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” (Òwe 22:3) Tẹ́ ẹ bá fẹ́ dáàbò bo àwọn ọmọ yín, ẹ gbọ́dọ̀ máa wà lójúfò sáwọn nǹkan tó lè ṣe wọ́n ní jàǹbá. Ẹ máa fòye mọ àwọn nǹkan tó lè dá wàhálà sílẹ̀, kẹ́ ẹ sì máa ṣàwọn nǹkan tó bá pọn dandan láti dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tẹ́ ẹ bá gba àwọn ọmọ yín láyè láti máa lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, ẹ máa rí i dájú pé wọ́n lè lò ó láìséwu. Ohun tó tiẹ̀ máa dáa jù ni pé kí kọ̀ǹpútà náà wà ní gbangba kẹ́ ẹ lè máa mójú tó bí wọ́n ṣe ń lò ó.

Àwọn bàbá gbọ́dọ̀ múra àwọn ọmọ wọn sílẹ̀ fáwọn jàǹbá tí wọ́n lè dojú kọ nínú ayé yìí, kí wọ́n sì kọ́ wọn láwọn ohun tí wọ́n lè ṣe láti dáàbò bo ara wọn. Ṣáwọn ọmọ yín mọ ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́nì kan bá fẹ́ bá wọn ṣèṣekúṣe nígbà tẹ́ ò bá sí nítòsí? c Àwọn ọmọ yín gbọ́dọ̀ mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa lo àwọn ẹ̀yà ara wọn tó máa ń wà lábẹ́ aṣọ àti bí kò ṣe yẹ kí wọ́n lò wọ́n. Kelvin sọ pé: “Mi ò kí ń fi kíkọ́ àwọn ọmọ mi láwọn nǹkan wọ̀nyí sílẹ̀ fẹ́nikẹ́ni, kódà mi ò kì í fi sílẹ̀ fáwọn olùkọ́ wọn pàápàá. Mo mọ̀ pé ojúṣe mi ni láti kọ́ àwọn ọmọ mi nípa ìbálòpọ̀ àti ewu tó wà nínú káwọn àgbàlagbà fipá bá ọmọdé ṣèṣekúṣe.” Gbogbo àwọn ọmọ Kelvin ló dàgbà láìséwu, wọ́n sì ti ní ìdílé aláyọ̀ báyìí.

Ẹ Máa Wá Ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run

Ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ táwọn bàbá lè fún àwọn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ àwọn bàbá sì ṣe pàtàkì lórí ọ̀ràn yìí. Donizete sọ pé: “Àwọn bàbá gbọ́dọ̀ máa fi hàn nínú ìwà wọn pé àjọṣe àwọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ àwọn lógún gan-an, àgàgà nígbà tí wọ́n bá níṣòro tàbí tí nǹkan ò bá fi bẹ́ẹ̀ rọrùn fún wọn. Nírú àwọn àkókò bẹ́ẹ̀, bàbá gbọ́dọ̀ fi hàn pé òun gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Tẹ́ ẹ bá ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún oore Rẹ̀ nígbà tẹ́ ẹ bá ń gbàdúrà pa pọ̀, ìyẹn á jẹ́ káwọn ọmọ yín mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti fi Ọlọ́run ṣe Ọ̀rẹ́ wọn.”

Ó dáa ná, kí wá ni àṣírí jíjẹ́ bàbá rere? Ẹ máa wá ìrànlọ́wọ́ ẹni tó mọ ọmọ tọ́ jù lọ, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Tẹ́ ẹ bá ń tọ́ àwọn ọmọ yín níbàámu pẹ̀lú àwọn ìtọ́sọ́nà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹ máa rí i pé ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 22:6 máa ṣẹ sáwọn ọmọ yín lára, ó ní: “Nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.”

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe bàbá làwọn ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí dìídì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, púpọ̀ lára àwọn ìlànà tó wà níbẹ̀ wúlò fáwọn ìyá pẹ̀lú.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

c Àlàyé síwájú sí i nípa báwọn òbí ṣe lè dáàbò bo àwọn ọmọ wọn nítorí àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe wà nínú Jí! October–December 2007, ojú ìwé 3 sí 11, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Bàbá gbọ́dọ̀ fàpẹẹrẹ rere lélẹ̀ fáwọn ọmọ rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Bàbá gbọ́dọ̀ máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ nípa Ọlọ́run

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwọn ọmọ yín nílò ìbáwí tó máa fi hàn pé ẹ fẹ́ràn wọn