Bí Ìgbàgbọ́ Mi Ṣe Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro
Bí Ìgbàgbọ́ Mi Ṣe Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Fara Da Ìṣòro
Gẹ́gẹ́ bí Soledad Castillo ṣe sọ ọ́
Láwọn ìgbà kan, ìdánìkanwà ì bá ti mú kí ìgbésí ayé mi dojú rú, àmọ́ mo rù ú là. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [34], ọkọ mi kú. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà ni bàbá mi ṣaláìsí. Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn tí bàbá mi kú ni dókítà sọ fún mi pé ọmọkùnrin kan ṣoṣo tí mo bí ní àrùn kan tí kò gbóògùn.
SOLEDAD lorúkọ mi, “Ìdánìkanwà” sì ni ìtúmọ̀ rẹ̀. Èyí lè dà bí orúkọ kan tó ṣàjèjì, àmọ́ Ọlọ́run ò fi mí sílẹ̀ nígbà kankan. Nígbà tí mo bá níṣòro mo gbà gbọ́ pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi, ‘tó ń di ọwọ́ mi mú kí n má bàa fòyà.’ (Aísáyà 41:13) Ẹ jẹ́ kí n ṣàlàyé bí mo ṣe rù ú là nígbà tí mo láwọn ìṣòro, àti báwọn ìṣòro wọ̀nyẹn ṣe jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà.
Mo Láwọn Ìṣòro Díẹ̀ Àmọ́ Mo Láyọ̀
Ìlú Barcelona, lórílẹ̀-èdè Sípéènì ni wọ́n bí mi sí, ní May 3, ọdún 1961, èmi nìkan ṣoṣo sì làwọn òbí mi, José àti Soledad, bí. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́sàn-án ni màmá mi kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó ti pẹ́ tí Màmá ti ń wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tí wọ́n ní nípa ẹ̀sìn, àmọ́ ìdáhùn tí wọ́n fún wọn ní ṣọ́ọ̀ṣì ò tẹ́ wọn lọ́rùn. Lọ́jọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì wá sílé wa, wọ́n sì fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè náà. Tayọ̀tayọ̀ ni Màmá fi gbà pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Kò pẹ́ rárá tí màmá mi fi ṣèrìbọmi tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà ní bàbá mi ṣèrìbọmi táwọn náà sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kò pẹ́ sígbà náà tí Eliana, ìyẹn arábìnrin tó kọ́ màmá mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi kíyè sí pé èmi pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì kéré nígbà yẹn, arábìnrin Eliana sọ pé òun á bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo dúpẹ́ pé arábìnrin Eliana ràn mí lọ́wọ́, màmá mi náà sí fún mi níṣìírí, ìyẹn ló jẹ́ kí n lè ṣèrìbọmi nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá [13].
Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ìgbà gbogbo ni mo máa ń gbàdúrà sí Jèhófà, pàápàá jù lọ nígbà tí mo bá fẹ́ ṣàwọn ìpinnu kan. Ká sòótọ́, mo láwọn ìṣòro díẹ̀ nígbà tí mò ń bàlágà. Nínú ìjọ tí mo wà, mo lọ́rẹ̀ẹ́ tó pọ̀, èmi àtàwọn òbí mi sì mọwọ́ ara wa gan-an. Lọ́dún 1982, mo fẹ́ arákùnrin Felipe, ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun náà sì ń fẹ́ láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Jèhófà bíi tèmi.
Bá A Ṣe Tọ́ Ọmọ Wa Láti Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà
Lẹ́yìn ọdún márùn-ún tí mo ṣègbéyàwó, mo bí ọmọkùnrin arẹwà kan tá a pe orúkọ rẹ̀ ní Saúl. Inú èmi àti ọkọ mi dùn gan-an nígbà tá a bí ọmọ wa yìí. Ohun tá à ń retí ni pé kí Saúl dàgbà láìsí àìlera kankan, kó sì dẹni tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.
Èmi àti ọkọ mi máa ń bá ọmọ wa sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà lọ́pọ̀ ìgbà, a máa ń jẹun pa pọ̀, a jọ máa ń lọ sáwọn ibi ìgbafẹ́, a sì jọ máa ń ṣeré ìdárayá. Saúl máa ń fẹ́ láti tẹ̀ lé bàbá ẹ̀ lọ wàásù fáwọn èèyàn, bàbá ẹ̀ sì ràn án lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù nígbà tó ṣì kéré, ó kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń tẹ aago ẹnu ọ̀nà, ó sì máa ń ní kó fáwọn èèyàn ní ìwé pélébé.Saúl tètè lóye àwọn ohun tá à ń kọ́ ọ, ó sì mọ̀ pé a nífẹ̀ẹ́ òun. Nígbà tó fi máa pé ọmọ ọdún mẹ́fà, ó ti ń bá wa jáde ìwàásù dáadáa. Ó máa ń fẹ́ tẹ́tí sáwọn ìtàn Bíbélì, inú ẹ̀ sì máa ń dùn tá a bá ti fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó bẹ̀rẹ̀ iléèwé ló ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìpinnu kéékèèké kan níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ Bíbélì tó ní.
Àmọ́, nígbà tí Saúl pé ọmọ ọdún méje, nǹkan ṣàdédé yí pa dà bírí nínú ìdílé wa. Ọkọ mi ní kòkòrò àrùn kan nínú ẹ̀dọ̀fóró rẹ̀. Oṣù mọ́kànlá ni àrùn yìí fi dá ọkọ mi dùbúlẹ̀, kò lè ṣiṣẹ́ rárá, orí bẹ́ẹ̀dì ló sì máa ń wà. Nígbà tó yá, ọkọ mi kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlógójì [36].
Mo ṣì máa ń sunkún tí mo bá rántí ọdún tí nǹkan le koko yẹn. Mò ń wo ọkọ mi títí tí àrùn yẹn fi gbẹ̀mí ẹ̀, kò sì sí nǹkan tí mo lè ṣe sí i. Ní gbogbo àkókò tí ọkọ mi fi ń ṣàìsàn yẹn, mo gbìyànjú láti fún un níṣìírí, bó tiẹ̀ jẹ́ pé lọ́kàn mi, mo mọ̀ pé ìrètí mi nípa irú ìgbésí ayé ìdílé tí mo fẹ́ ti wọmi. Mo máa ń ka àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí Bíbélì sí i létí, èyí sì fún wa lókun láwọn ìgbà tá ò lè lọ sáwọn ìpàdé Kristẹni. Nígbà tó kú, gbogbo nǹkan tojú sú mi.
Síbẹ̀, Jèhófà ò fi mí sílẹ̀. Ìgbà gbogbo ni mo máa ń bẹ̀ ẹ́ pé kó fún mi ní ẹ̀mí rẹ̀. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé èmi àti ọkọ mi gbádùn àwọn ọdún tá a fi wà pa pọ̀, àti bó ṣe dá mi lójú pé mo máa pa dà rí ọkọ mi nígbà àjíǹde. Mo bẹ Ọlọ́run pé kó ràn mí lọ́wọ́ kínú mi lè máa dùn tí mo bá ń rántí àwọn nǹkan témi àti ọkọ mi ti ṣe pa pọ̀, mo sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fún mi ní ọgbọ́n tí màá fi lè tọ́ ọmọ wa dàgbà di Kristẹni tòótọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìbànújẹ́ sorí mi kodò, Ọlọ́run tù mí nínú.
Àwọn òbí mi àtàwọn tá a jọ wà nínú ìjọ dúró tì mí gbágbáágbá. Síbẹ̀, èmi fúnra mi ni mo gbọ́dọ̀ máa kọ́ Saúl ọmọ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí n sì kọ́ ọ láti sin Jèhófà. Ọ̀gá mi níbi iṣẹ́ nígbà kan ní kí n wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ọ́fíìsì, àmọ́ iṣẹ́ ìmọ́tótó ló wù mí ṣe, torí kí n lè máa ráyè lo àkókò púpọ̀ sí i pẹ̀lú ọmọ mi tó bá ti ń ti iléèwé dé.
Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan jẹ́ kí n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí n tọ́ Saúl ní ọ̀nà Ọlọ́run, ó ní: “Tọ́ ọmọdékùnrin ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí yóò tọ̀; nígbà tí ó bá dàgbà pàápàá, kì yóò yà kúrò nínú rẹ̀.” (Òwe 22:6) Ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ kí ọkàn mi balẹ̀ pé tí mo bá sa gbogbo ipá mi láti tọ́ ọmọ mi dàgbà ní ọ̀nà Ọlọ́run, Jèhófà máa bù kún ìsapá mi. Lóòótọ́ mo yẹ àwọn iṣẹ́ kan tó lè máa mówó wọlé dáadáa sílẹ̀ kí n lè lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú ọmọ mi, èyí sì jẹ mí lógún ju kíkó ọrọ̀ jọ.
Nígbà tí Saúl pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá [14], bàbá mi kú. Ìbànújẹ́ sorí Saúl kodò gidigidi, nítorí pé ikú bàbá mi tún mú kó ní irú ẹ̀dùn
ọkàn tó ní nígbà tí bàbá rẹ̀ kú. Bàbá mi pẹ̀lú fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀, nítorí pé ó fẹ́ràn Jèhófà. Lẹ́yìn tí bàbá mi kú, Saúl wá gba kámú pé nígbà tó ti jẹ́ pé òun nìkan lọkùnrin nínú ìdílé wa báyìí, òun lóun á gba iṣẹ́ bíbójú tó ìyà òun àti ìyá-ìyá òun.Àrùn Jẹjẹrẹ Bá Saúl Fínra
Oṣù mẹ́jọ lẹ́yìn ikú bàbá mi, Saúl bẹ̀rẹ̀ sí ṣàárẹ̀ gidigidi, dókítà tó ń tọ́jú wa sì sọ fún mi pé kí n gbé e lọ sílé ìwòsàn kan ládùúgbò wa. Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ àyẹ̀wò, àwọn dókítà sọ fún mi pé Saúl ní oríṣi àrùn jẹjẹrẹ kan tí wọ́n ń pè ní leukemia. a
Fún ọdún méjì àtààbọ̀ lẹ́yìn náà, ńṣe ni Saúl ń pàrà ilé ìwòsàn nítorí àrùn jẹjẹrẹ náà, tó sì ń gba ìtọ́jú oníkẹ́míkà táwọn dókítà lo láti gbógun ti àìsàn náà. Lẹ́yìn ìtọ́jú olóṣù mẹ́fà táwọn dókítà fún un, àrùn yìí fi í sílẹ̀ fún nǹkan bí ọdún kan àbọ̀. Lẹ́yìn èyí ni àrùn jẹjẹrẹ náà tún bẹ̀rẹ̀ pa dà, wọ́n tún fún un ní ìtọ́jú oníkẹ́míkà fún ìgbà díẹ̀, èyí jẹ́ kó bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀ ẹ́ gan-an. Lẹ́yìn ìtọ́jú yìí, àrùn jẹjẹrẹ náà tún fi í sílẹ̀ fúngbà díẹ̀ ló bá tún bẹ̀rẹ̀ pa dà, àmọ́ Saúl ò lókun nínú mọ́ láti gba ìtọ́jú oníkẹ́míkà yìí lẹ́ẹ̀kẹta. Saúl ti ya ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ó sọ pé òun fẹ́ ṣèrìbọmi kóun sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ó kú nígbà tó lé díẹ̀ lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17].
Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn dókítà máa ń dábàá pé káwọn fa ẹ̀jẹ̀ sí Saúl lára káwọn lè pẹ̀rọ̀ sí ìtọ́jú oníkẹ́míkà tó ń gbà, nítorí pé ìtọ́jú náà lágbára gan-an ni. Àmọ́, ó dájú pé gbígba ẹ̀jẹ̀ sára kọ́ ló máa wo àrùn yẹn sàn. Nígbà táwọn dókítà kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àrùn jẹjẹrẹ yìí, èmi àti Saúl ti ṣàlàyé kedere fún wọn pé a ò fẹ́ ìtọ́jú tó máa la gbígba ẹ̀jẹ̀ sára lọ, torí pé a fẹ́ ṣègbọràn sí òfin Jèhófà láti ta “kété . . . sí ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:19, 20) Bí mi ò tiẹ̀ sí níbẹ̀, Saúl máa ń fi dá àwọn dókítà lójú pé òun fúnra òun lòun ṣèpinnu lórí ọ̀rọ̀ yìí. (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 31.)
Nígbà tó yá, àwọn dókítà wá rí i pé bí Saúl tiẹ̀ kéré lọ́jọ́ orí, ó lóye irú àìsàn tó ń ṣe é dáadáa, ó sì mọ ohun tó lè yọrí sí. Àwọn Dókítà náà gbà pẹ̀lú ìpinnu tá a ṣe, wọ́n sì fún Saúl ní ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ń rọ̀ wá ṣáá pé ká yí ìpinnu wa pa dà. Orí mi máa ń wú gan-an tí mo bá ń gbọ́ bí Saúl ṣe ń ṣàlàyé fáwọn dókítà nípa ìdí tóun ò fi ní gba ẹ̀jẹ̀. Kò sí àníàní pé ó ti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.
Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn tá a kọ́kọ́ mọ̀ pé Saúl ní àrùn jẹjẹrẹ ni ìwé Sún Mọ́ Jèhófà jáde nípàdé àgbègbè tá a ṣe nílùú Barcelona. Ìwé yìí ṣeyebíye gan-an ni, ó gbé wa ró, òun ni kò sì jẹ́ ká yẹhùn nínú ìpinnu wa láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nígbà tí nǹkan nira fún wa, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò mọ ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́la. Gbogbo ìgbà tí mo fi ń dúró tì í nílé ìwòsàn la jọ máa ń ka ìwé náà pa pọ̀. Lẹ́yìn ìgbà tá a sì tún dojú kọ àwọn ipò líle koko kan, a máa ń rántí ohun tá a kà nínú ìwé náà. Ìgbà yẹn gan-an ni ohun tó wà ní Aísáyà 41:13 tó wà níbẹ̀rẹ̀ ìwé yẹn ní ìtumọ̀ gidi sí wa. Ó sọ pé: “Èmi, Jèhófà Ọlọ́run rẹ, yóò di ọwọ́ ọ̀tún rẹ mú, Ẹni tí ń wí fún ọ pé, ‘Má fòyà. Èmi fúnra mi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.’”
Ìgbàgbọ́ Saúl Wú Àwọn Èèyàn Lórí
Ìwà àgbà tí Saúl ní àti ẹ̀mí tó ní pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa wú àwọn dókítà àtàwọn nọ́ọ̀sì tó wà nílé ìwòsàn Vall d’Hebrón lórí gan-an. Gbogbo àwọn tó tọ́jú rẹ̀ ló fẹ́ràn rẹ̀ gan-an. Látìgbà náà ni ẹni tó jẹ́ ọ̀gá nínú bíbójútó ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ nílé ìwòsàn náà ti ń tọ́jú àwọn ọmọdé tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ní àrùn jẹjẹrẹ, ó sì gbóṣùbà fún wọn gan-an. Ó rántí bí Saúl ò ṣe jẹ́ kí ohun tó gbà gbọ́ bọ́ mọ́ ọn lọ́wọ́, bó ṣe nígboyà lójú ikú, àti bó ṣe lérò tó dáa nípa ìgbésí ayé. Àwọn nọ́ọ̀sì tó tọ́jú Saúl sọ fún un pé, nínú gbogbo
àwọn tó ti wá ń gbàtọ́jú nínú wọ́ọ̀dù tí Saúl wà, òun ló ṣe dáadáa jù. Wọ́n ní kò ṣàròyé rí, ó sì tún máa ń pa àwọn èèyàn lẹ́rìn-ín, kódà nígbà tó ku díẹ̀ kó kú pàápàá.Obìnrin kan tó máa ń fìwà àwọn èèyàn mọ ohun tí wọ́n ń rò sọ fún mi pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọdé tí wọ́n ní irú àrùn tí ò gbóògùn bẹ́ẹ̀ kì í fẹ́ ṣe ohun táwọn dókítà àtàwọn òbí wọn bá ni kí wọ́n ṣe torí ara tó ń ni wọ́n àti bí nǹkan ṣe máa ń tojú sú wọn. Àmọ́, obìnrin náà kíyè sí pé ọ̀rọ̀ Saúl ò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ó yà á lẹ́nu pé ọkàn Saúl balẹ̀ ó sì máa ń túra ká. Èyí fún èmi àti Saúl láǹfààní láti wàásù fún obìnrin náà nípa ohun tá a gbà gbọ́.
Mo tún rántí bí Saúl ṣe ran arákùnrin kan lọ́wọ́ nínú ìjọ wa. Ó ti tó ọdún mẹ́fà tí àárẹ̀ ọkàn ti ń bá arákùnrin yìí fínra, ó sì ti lo oògùn sí ohun tó ń ṣe é yìí, àmọ́ pàbó ló já sí. Ọ̀pọ̀ ìgbà sì ni arákùnrin yìí máa ń sùn ti Saúl nílé ìwòsàn kó lè máa bójú tó o. Ó sọ fún mi pé bí Saúl ṣe ṣe nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ ń bá a fínra wú òun lórí gan-an. Ó kíyè sí pé pẹ̀lú bí Saúl ò ṣe lókun nínú tó, ó gbìyànjú láti fún gbogbo àwọn tó bá wá kí i níṣìírí. Arákùnrin yìí wá sọ pé: “Bí Saúl ò ṣe sọ̀rètí nù fún mi níṣìírí láti máa fara da àárẹ̀ ọkàn mi.”
Ó ti tó ọdún mẹ́ta báyìí tí Saúl ti kú. Mo ṣì ní ẹ̀dùn ọkàn síbẹ̀. Ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi, àmọ́ Ọlọ́run ti fún mi ní, “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7) Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, bó ti wù kí ìṣòro èèyàn le tó, a ṣì lè rí nǹkan kan tó ṣàǹfààní níbẹ̀. Bí mo ṣe ń fara da ẹdùn ọkàn tí ikú ọkọ mi, bàbá mi àti ọmọ mi ti fà ti jẹ́ kí n máa gba tàwọn ẹlòmíì rò, ó sì ti jẹ́ kí n mọ bó ṣe máa ń ṣàwọn tó ń jìyà. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, mo ti wá túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Mi ò fòyà rárá nípa ọjọ́ ọ̀la, torí pé Bàbá mi ọ̀run ṣì ń ràn mí lọ́wọ́. Ó ṣì ń dì mí lọ́wọ́ mú.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Saúl ní àrùn kan tí wọ́n ń pè ní lymphoblastic leukemia. Ó jẹ́ oríṣi àrùn jẹjẹrẹ kan tó máa ń ba àwọn sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ jẹ́.
[Àpótì/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
KÍ LÈRÒ Ẹ?
Ó ṣeé ṣe kó o ti gbọ́ pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbẹ̀jẹ̀ sára. Kí lo rò pó fà á?
Ọ̀pọ̀ máa ń ṣi ìpinnu tó bá Ìwé Mímọ́ mu yìí lóye. Nígbà míì, àwọn èèyàn máa ń rò pé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fẹ́ tọ́jú ara wa nígbà tá a bá ń ṣàìsàn tàbí pé ẹ̀mí ò jọ wá lójú. Irọ́ funfun lèyí. Gbogbo ohun tó bá gbà làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe láti tọ́jú ara wa, àwọn ọmọ àtàwọn ìyàwó wa lọ́nà tó dáa jù lọ, àmọ́ gbogbo ìtọ́jú tá a máa ń gbà kì í la ẹ̀jẹ̀ lọ. Kí nìdí?
Ìpinnu tá a ṣe bá òfin pàtàkì kan tí Ọlọ́run fún ìran èèyàn mu. Kò pẹ́ lẹ́yìn Ìkún-omi ọjọ́ Nóà ni Ọlọ́run fún Nóà àtàwọn mọ̀lẹ́bí ẹ̀ lómìnira láti máa jẹ ẹran. Àmọ́, Ọlọ́run fún wọn ní ìkìlọ̀ kan: Wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 9:3, 4) Ọ̀dọ̀ Nóà ni gbogbo èèyàn tó wà láyé lónìí ti ṣẹ̀ wá, torí náà òfin yẹn kan gbogbo wa. Ọlọ́run ò fìgbà kankan fagi lé òfin yìí. Ẹgbẹ̀rin [800] ọdún lẹ́yìn tí Ìkún-omi ọjọ́ Nóà ṣẹlẹ̀, Ọlọ́run tún fìdí òfin yìí múlẹ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó jẹ́ kó yé wọn pé ohun mímọ́ ni ẹ̀jẹ̀ àti pé ọkàn gbogbo ẹran ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. (Léfítíkù 17:14) Ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún lẹ́yìn náà làwọn àpọ́sítélì pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “ta kété sí . . . ẹ̀jẹ̀.”—Ìṣe 15:29.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóye dáadáa pé kò sí béèyàn ṣe lè sọ pé òun ń ta kété sí ẹ̀jẹ̀, tó bá ń gbẹ̀jẹ̀ sára. Ìdí nìyẹn tá a fi máa ń fi dandan lé e pé ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ la máa gbà. Ìpinnu tó bá Ìwé Mímọ́ mu tá a ṣe gan-an ló máa ń jẹ́ ká rí ìtọ́jú tó dáa jù lọ gbà lọ́pọ̀ ìgbà. Abájọ táwọn kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà fi máa ń sọ pé ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ làwọ́n fẹ́.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Èmi àti ọkọ mi Felipe pẹ̀lú Saúl ọmọ wa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]
Àwọn òbí mi, José àti Soledad
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Saúl rèé, nígbà tó ku oṣù kan kó kú