Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí táwọn Júù fi máa ń bẹ̀rẹ̀ Sábáàtì nírọ̀lẹ́?
Nígbà tí Jèhófà fáwọn èèyàn rẹ̀ lófin nípa Ọjọ́ Ètùtù, ó sọ pé: “Ẹ kò sì gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ èyíkéyìí ní ọjọ́ náà gan-an . . . Sábáàtì ìsinmi pátápátá ni fún yín . . . Láti ìrọ̀lẹ́ sí ìrọ̀lẹ́ ní kí ẹ pa sábáàtì yín mọ́.” (Léfítíkù 23:28, 32) Àṣẹ yìí jẹ́ ká mọ̀ pé lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ nírọ̀lẹ́ làwọn Júù máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọjọ́ títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì. Èyí fi hàn pé ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sí ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì làwọn Júù fi ń ka ọjọ́.
Kíka ọjọ́ lọ́nà yìí jẹ́ àpẹẹrẹ tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ fi lélẹ̀. Àkọsílẹ̀ nípa ọjọ́ tí Bíbélì pè ní ọjọ́ àkọ́kọ́ ìṣẹ̀dá sọ pé: “Alẹ́ sì wá wà, òwúrọ̀ sì wá wà, èyí ni ọjọ́ kìíní.” Bí Bíbélì sì ṣe ka àwọn “ọjọ́” tó tẹ̀ lé ọjọ́ àkọ́kọ́ ìṣẹ̀dá náà nìyẹn, “alẹ́” ló ti bẹ̀rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:5, 8, 13, 19, 23, 31.
Kì í ṣàwọn Júù nìkan ló ń ka ọjọ́ lọ́nà yìí. Báwọn ará Áténì, àwọn ará Numidia àtàwọn ará Fòníṣíà ṣe ń ka ọjọ́ tiwọn náà nìyẹn. Àmọ́ ìgbà tí oòrùn bá yọ làwọn ará Bábílónì máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í ka ọjọ́ tiwọn, nígbà tó jẹ́ pé òru làwọn ará Íjíbítì àtàwọn ará Róòmù máa ń bẹ̀rẹ̀ sí í kà á, bá a ṣe ń kà á lónìí. Àmọ́ ṣá o, títí dòní olónìí, ìgbà tóòrùn bá wọ̀ làwọn Júù máa ń bẹ̀rẹ̀ ọjọ́ Sábáàtì tiwọn, títí dìgbà tóòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ kejì.
Kí ni “ìrìn ọjọ́ sábáàtì” kan?
Lẹ́yìn táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti rí bó ṣe lọ sọ́run látorí Òkè Ólífì, wọ́n pa dà sí Jerúsálẹ́mù, ìrìn àjò náà sì gbà wọ́n ní “ìrìn ọjọ́ sábáàtì kan.” (Ìṣe 1:12) Nígbà yẹn, arìnrìn-àjò kan lè rin ọgbọ̀n [30] kìlómítà tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lọ́jọ́ kan. Àmọ́ Òkè Ólífì ò jìnnà sí Jerúsálẹ́mù. Torí náà, kí ni “ìrìn ọjọ́ Sábáàtì kan”?
Ọjọ́ Sábáàtì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi máa ń sinmi lẹ́nu iṣẹ́ wọn. Wọn ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ tanná rárá nínú ilé wọn lọ́jọ́ yẹn. (Ẹ́kísódù 20:10; 35:2, 3) Jèhófà pa á láṣẹ pé: “Kí ẹ wà ní ìjókòó olúkúlùkù ní àyè rẹ̀. Kí ẹnikẹ́ni má ṣe jáde kúrò ní àdúgbò rẹ̀ ní ọjọ́ keje.” (Ẹ́kísódù 16:29) Òfin yìí máa jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ráyè sinmi kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn, kí wọ́n lè túbọ̀ fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run.
Torí pé ìlànà tó wà nínú Òfin Jèhófà yìí kò tẹ́ àwọn rábì, tó máa ń rin kinkin mọ́ òfin, lọ́rùn, wọ́n gbé òfin tara wọn kalẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣòfin nípa béèyàn ṣe lè rìn jìnnà tó lọ́jọ́ Sábáàtì láti lọ jọ́sìn. Nígbà tí ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, ìyẹn Cyclopedia of Biblical, Theological, and Ecclesiastical Literature, máa ṣàlàyé lórí ọ̀rọ̀ yìí, ó sọ pé: “Lára àwọn òfin kànńpá tí wọ́n ṣe nípa Sábáàtì ni pé . . . , ọmọ Ísírẹ́lì kankan ò gbọ́dọ̀ rìn ju iye kìlómítà pàtó kan lọ lọ́jọ́ Sábáàtì, èyí tí wọ́n ń pè ní ìrìn ọjọ́ Sábáàtì kan.” Wọ́n ní wọn ò gbọ́dọ̀ rìn ju ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ìgbọ̀nwọ́ lọ, ìyẹn nǹkan bíi kìlómítà kan.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Bí Jerúsálẹ́mù ṣe rí rèé téèyàn bá wò ó látorí Òkè Ólífì