Omijé Nínú Ìgò Awọ
Omijé Nínú Ìgò Awọ
ÌSÁǸSÁ ni ọ̀dọ́kùnrin náà. Ìrora ọkàn àti ìdààmú bá a, ojú rẹ̀ sì kún fún omijé. Ó ké pe Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé kó yọ́nú sóun kó sì ṣàánú òun, ó bẹ̀ ẹ́ pé: “Fi omijé mi sínú ìgò awọ rẹ.” (Sáàmù 56:8) Dáfídì ni ọkùnrin yẹn, òun ló sì wá jọba lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà tó yá. Àmọ́ kí ni ìgò awọ tí Dáfídì sọ? Báwo sì ni Ọlọ́run ṣe lè fi omijé wa sínú ìgò awọ?
Dáfídì mọ ìgò awọ dáadáa. Omi, epo, wáìnì tàbí bọ́tà ni wọ́n sábà máa ń rọ sínú rẹ̀. Àwọn darandaran tó wà ní aṣálẹ̀ Sàhárà, àwọn bíi Tuareg, ṣì ń lo ìgò awọ tí wọ́n fi odindi awọ ewúrẹ́ kan tàbí ti àgùntàn kan ṣe. Irú àwọn ìgò bẹ́ẹ̀ máa ń gba omi púpọ̀, ó sinmi lórí bí ẹran tí wọ́n lo awọ rẹ̀ bá ṣe tóbi tó. Ìgò awọ kì í jẹ́ kí omi tútù tí wọ́n bá rọ sínú rẹ̀ tètè gbóná, kódà ní aṣálẹ̀ níbi tí oòrùn ti máa ń gbóná janjan. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ràkúnmí ni wọ́n máa fi ń gbé ìgò awọ kiri láyé àtijọ́. Àmọ́ lóde òní, o lè rí i tí wọ́n so ó mọ́ iwájú àwọn ọkọ̀ tó lè rin ọ̀nà gbágungbàgun!
Ọ̀rọ̀ tó wọni lọ́kàn tí Dáfídì sọ nípa ìgò awọ yìí lè nítumọ̀ fún àwa pẹ̀lú. Lọ́nà wo? Bíbélì ṣàlàyé pé Sátánì ló ń ṣàkóso ayé yìí, ó sì ní “ìbínú ńlá” ní ọjọ́ wa. Nítorí èyí ni ègbé ńláǹlà fi bá ayé. (Ìṣípayá 12:12) Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ní ẹ̀dùn ọkàn bíi ti Dáfídì, tí ìrònú wọn ò já gaara, tí wọ́n sì ń jìyà, pàápàá àwọn tó ń gbìyànjú láti múnú Ọlọ́run dùn. Ṣé bó ṣe ń ṣe ẹ́ nìyẹn? Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ń bá a nìṣó láti máa fìgboyà hùwà títọ́ bí wọ́n tiẹ̀ ń “sunkún.” (Sáàmù 126:6) Ó lè dá wọn lójú pé Bàbá wọn ọ̀run ń rí àwọn àdánwò tó ń dójú kọ wọ́n, ó sì tún mọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn. Ó mọ ìrora tó ń dé bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó ń rántí omijé àti ìjìyà wọn tàánútàánú, bí ìgbà tá a bá sọ pé ó ń tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ sínú ìgò awọ rẹ̀.