Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Mọ̀la?

Ta Ló Mọ̀la?

Ta Ló Mọ̀la?

“Èmi ni Olú Ọ̀run . . . Ẹni tí ó ń ti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ sọ paríparí òpin, tí ó sì ń ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn sọ àwọn nǹkan tí a kò tíì ṣe.”—Aísáyà 46:9, 10.

LÁKÒÓKÒ tọ́ràn ayé ò dúró sójú kan yìí, àwọn ọ̀mọ̀ràn tó ń kíyè sí ohun tó ń lọ lágbo òṣèlú, ètò ọrọ̀ ajé àti láwùjọ ń sapá kí wọ́n lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń ṣàyẹ̀wò ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé àwọn kan ń wá gbogbo ọ̀nà láti mọ bọ́jọ́ ọ̀la àwọn ṣe máa rí, wọ́n ń wo ìràwọ̀, wọ́n tún ń ṣèwádìí lọ́dọ̀ àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn. Àmọ́ ohun tírú wọn máa ń bá bọ̀ kì í sábàá tẹ́ wọn lọ́rùn. Ṣóhun tó wá túmọ̀ sí ni pé kò sí béèyàn ṣe lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáyé yìí, sáwọn ìdílé wa àtàwa fúnra wa? Tá a bá wò ó lọ wò ó bọ̀, ṣẹnikẹ́ni tiẹ̀ wà tó lè mọ bọ́jọ́ ọ̀la ṣe máa rí gan-an?

Nínú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè sọ fún Aísáyà wòlíì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bá a ṣe kọ ọ́ sókè yìí, Jèhófà jẹ́ ká mọ̀ pé òun lágbára láti sọ bọ́jọ́ ọ̀la ṣe máa rí. Nípasẹ̀ Aísáyà, Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un ṣe máa dòmìnira kúrò nínú ìgbèkùn àwọn ará Bábílónì àti bí wọ́n ṣe máa pa dà wá tún Jerúsálẹ́mù àti tẹ́ńpìlì tó wà níbẹ̀ kọ́. Ṣé bó ṣe sọ àsọtẹ́lẹ̀ yẹn gẹ́lẹ́ ló ṣe ní ìmúṣẹ? Ní nǹkan bí igba [200] ọdún ṣáájú ni Aísáyà ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Kírúsì lorúkọ ẹni tó máa ṣẹ́gun ìlú Bábílónì, bó sì ṣe rí nìyẹn. Yàtọ̀ síyẹn, Aísáyà ṣàpèjúwe ọgbọ́n tí Kírúsì máa dá, ó ní ńṣe ló máa darí Odò Yúfírétì tó dáàbò bo ìlú Bábílónì gba ibòmíì. Kódà, ó sọ pé ara ohun tó máa mú kó rọrùn fún Kírúsì láti ṣẹ́gun nígbà tó bá kógun ja Bábílónì ni pé, wọ́n máa gbàgbé láti ti àwọn ẹnu ọ̀nà onílẹ̀kùn méjì tó wọ ìlú Bábílónì.—Aísáyà 44:24–45:7.

Tá a bá fi bí Ọlọ́run ṣe lágbára tó láti mọ ọjọ́ ọ̀la wé tèèyàn, ó máa ṣe kedere pé kò séèyàn tó mọ̀la. Ọlọ́gbọ́n Ọba Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Má ṣògo nípa ọ̀la, nítorí ìwọ kò mọ ohun tí ọjọ́ kan yóò bí.” (Òwe 27:1) Ọ̀rọ̀ yẹn ṣì jóòótọ́ títí dòní olónìí. Kò sí ẹ̀dá èèyàn kankan tó lè mọ bọ́jọ́ ọ̀la òun ṣe máa rí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ tẹlòmíì. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi yàtọ̀? Ó mọ ohun gbogbo nípa gbogbo nǹkan tó dá pátápátá, tó fi mọ́ ìwà àtohun tó wà lọ́kàn àwa èèyàn. Tó bá wu Ọlọ́run láti mọ báwọn èèyàn kan tàbí orílẹ̀-èdè kan ṣe máa hùwà gẹ́lẹ́, ó máa mọ̀ ọ́n. Ó tún ní gbogbo agbára láti jẹ́ káwọn nǹkan ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. Tó bá tipasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ pé ohun kan máa ṣẹlẹ̀, ńṣe ló máa ń di “Ẹni tí ń mú kí ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ, àti Ẹni tí ń mú ìmọ̀ràn àwọn ońṣẹ́ rẹ̀ ṣẹ pátápátá.” (Aísáyà 44:26) Jèhófà Ọlọ́run nìkan ṣoṣo lẹni tó lè ṣe bẹ́ẹ̀ ní tòdodo.

Ó ju ọgọ́rùn-ún méje [700] ọdún lọ tí Aísáyà ti gbé láyé kí wọ́n tó bí Jésù tó jẹ́ Mèsáyà. Síbẹ̀, Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ nípa dídé Mèsáyà. Àmọ́, láti nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún sẹ́yìn, àwọn tó ń ṣàríwísí ohun tó wà nínú Bíbélì ti sọ pé èrú wà nínú ìwé Aísáyà. Wọ́n ní ohun tí Aísáyà sọ kì í ṣe àsọtẹ́lẹ̀. Wọ́n sọ pé ẹ̀yìn táwọn nǹkan wọ̀nyẹn ti ṣẹlẹ̀ tán ló ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ wọ́n sílẹ̀. Ṣóòótọ́ ni? Lọ́dún 1947, àwọn ọ̀mọ̀wé kan rí ẹ̀dà ìwé Aísáyà àtàwọn àkájọ ìwé àtayébáyé míì nínú hòrò kan létí Òkun Òkú. Àwọn ọ̀mọ̀wé tó ṣàyẹ̀wò rẹ̀ rí i pé ó ti ju ọgọ́rùn-ún [100] ọdún lọ tí wọ́n ti kọ ìwé yìí kí wọ́n tó bí Mèsáyà, ìyẹn Kristi tí ìwé náà sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀. Èyí fi hàn pé Bíbélì lè jẹ́ ká mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú!

Kò lè jẹ́ ọgbọ́n orí Aísáyà àtàwọn míì tó kọ Bíbélì ni wọ́n fi sọ àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n “sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí ẹ̀mí mímọ́ ti ń darí wọn.” (2 Pétérù 1:21) Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí, a máa jíròrò kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbèésí ayé Jésù, bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀. A máa wá ṣàyẹ̀wò àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ tẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ wa àti ọjọ́ iwájú.