Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀kọ́ Tó Gbayé Kan

Ẹ̀kọ́ Tó Gbayé Kan

Ẹ̀kọ́ Tó Gbayé Kan

“Mo máa ń lálàá nípa iná ọ̀run àpáàdì! Mo lálàá pé wọ́n jù mí sínú iná, mo bá figbe ta látojú oorun. Àtìgbà yẹn ni mo ti máa ń sapá gidigidi kí n má bàa dẹ́ṣẹ̀.”—Arline.

ṢÓ O gbà gbọ́ pé ibi tí Ọlọ́run ti máa dá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lóró ni ọ̀run àpáàdì? Ọ̀pọ̀ ló gbà bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nínú ìwádìí tí ọ̀mọ̀wé kan ní Yunifásítì St. Andrews tó wà lórílẹ̀-èdè Scotland ṣe lọ́dún 2005, ó rí i pé tá a bá kó àlùfáà mẹ́ta jọ lórílẹ̀-èdè Scotland, ọ̀kan nínú wọn máa gbà pé àwọn tí kò bá ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run máa “jẹ̀ka àbámọ̀ títí láé nínú ọ̀run àpáàdì.” Àlùfáà kan nínú márùn-ún ló sì gbà pé àwọn tó máa wà ní ọ̀run àpáàdì máa joró.

Ìgbàgbọ́ nínú ọ̀run àpáàdì wọ́pọ̀ ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 2007 fi hàn pé ẹni méje nínú mẹ́wàá ló gbà gbọ́ nínú ọ̀run àpáàdì. Kódà, àwọn èèyàn ṣì gbà gbọ́ nínú ọ̀run àpáàdì láwọn orílẹ̀-èdè táwọn èèyàn ò ti fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn. Ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lórílẹ̀-èdè Kánádà lọ́dún 2004 fi hàn pé nǹkan bí ẹni mẹ́rin nínú mẹ́wàá ló gbà pé ọ̀run àpáàdì wà. Bákan náà, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nǹkan bí ẹni mẹ́ta nínú mẹ́wàá ló sọ pé ó dá àwọn lójú gbangba pé ọ̀run àpáàdì wà.

Ohun Táwọn Àlùfáà Fi Ń Kọ́ni

Ọ̀pọ̀ àlùfáà ni ò kọ́ àwọn èèyàn mọ́ pé Ọlọ́run máa ń fi iná dá àwọn èèyàn lóró nínú ọ̀run àpáàdì. Dípò ìyẹn, ohun tí wọ́n fi ń kọ́ni ò yàtọ̀ sóhun tó wà nínú ìwé ìsìn Kátólíìkì tí wọ́n ṣe lọ́dún 1994, ìyẹn Catechism of the Catholic Church, tó sọ pé: “Ìyà tó burú jù táwọn èèyàn máa jẹ ní ọ̀run àpáàdì ni pé wọn ò ní lè sún mọ́ Ọlọ́run títí láé.”

Síbẹ̀, ńṣe niye àwọn èèyàn tó gbà pé ìdálóró wà ní ọ̀run àpáàdì túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Àwọn tó sì ń fi ẹ̀kọ́ yìí kọ́ àwọn èèyàn sọ pé bó ṣe wà nínú Bíbélì nìyẹn. Ọ̀gbẹ́ni Albert Mohler tó jẹ́ ààrẹ ilé ẹ̀kọ́ Southern Baptist Theological Seminary sọ pé: “Òótọ́ pọ́ńbélé tó wà nínú Ìwé Mímọ́ ni.”

Kí Nìdí Tí Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Fi Ṣe Pàtàkì?

Tí ọ̀run àpáàdì bá jẹ́ ibi tí Ọlọ́run ti ń dá àwọn èèyàn lóró lóòótọ́, ó yẹ kó o bẹ̀rù rẹ̀. Àmọ́, tó bá jẹ́ pé irọ́ gbuu ni ẹ̀kọ́ yìí, a jẹ́ pé ńṣe làwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó ń kọ́ àwọn èèyàn láwọn ẹ̀kọ́ wọ̀nyẹn ń dà wọ́n lọ́kàn rú, tí wọ́n sì ń jẹ́ káwọn èèyàn máa bẹ̀rù láìnídìí. Wọ́n sì tún ń parọ́ mọ́ Ọlọ́run.

Kí ni Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, sọ nípa ẹ̀kọ́ yìí? Nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó máa tẹ̀ lé èyí, a máa lo àwọn Bíbélì táwọn èèyàn ń lò ní ṣọ́ọ̀ṣì láti fi dáhùn ìbéèrè mẹ́ta yìí: (1) Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ gan-an sẹ́ni tó bá kú? (2) Kí ni Jésù fi kọ́ni nípa ọ̀run àpáàdì? (3) Báwo ni mímọ òtítọ́ nípa ọ̀run àpáàdì ṣe lè nípa lórí rẹ?