Ìdí Tí Wọ́n Fi Pe Tonílé Tàlejò
Ìdí Tí Wọ́n Fi Pe Tonílé Tàlejò
“KÍ NI wọ́n ń ṣe níbẹ̀ gan-an?” Ohun táwọn tó ń wakọ̀ kọjá níwájú ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Mogale City (Krugersdorp), nítòsí Johannesburg, lórílẹ̀-èdè South Africa, máa ń bi ara wọn nìyẹn. Ìdí nìyẹn táwọn Ẹlẹ́rìí fi pinnu láti pe tonílé tàlejò wá sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ní October 12 àti 13, ọdún 2007. Ìdí méjì ni wọ́n tìtorí ẹ̀ pè wọ́n; wọ́n fẹ́ kí tonílé tàlejò rí i pé irọ́ gbuu lohun táwọn èèyàn ń sọ kiri nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì fẹ́ kí wọ́n rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà láti ti iṣẹ́ tí Jésù Kristi pa láṣẹ lẹ́yìn.—Mátíù 28:19, 20.
Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà kọ àwọn ọ̀rọ̀ sára pátákó ńlá kan tí wọ́n gbé sẹ́nu ọ̀nà láti kí àwọn èèyàn káàbọ̀, wọ́n sì fún àwọn aládùúgbò níwèé ìkésíni. Wọ́n fìwé pe àwọn oníṣòwò àtàwọn mọ̀lẹ́bí wọn náà. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Àwọn àlejò tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tó wá wo àwọn ilé tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] lọ.
Ohun tó gbàfiyèsí àwọn èèyàn jù lọ ni ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá kan, ìyẹn MAN Roland Lithoman web-offset press, tó lè tẹ ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn [90,000] ìwé ìròyìn ní wákàtí kan. Ńṣe làwọn àlejò tún lanu nígbà tí wọ́n rí ibi tá a ti ń di àwọn ẹrù tá a máa ń kó ránṣẹ́ sáwọn ìjọ wa àti ibi tá a ti ń di ìwé pọ̀, tí wọ́n sì gbọ́ pé ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń kó ránṣẹ́ sáwọn ìjọ lójoojúmọ́ ju ẹrù ọkọ̀ akóyọyọ méjì lọ. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ẹ̀ka iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ya àwọn àwòrán tó dùn ún wò lójú, ọ̀kan lára àwọn àwòrán náà ní wọ́n fi ṣàlàyé àwọn ìyípadà tó ti wáyé ní ẹ̀ka ìtẹ̀wé látìgbà tí wọ́n ti ń lo ẹ̀rọ ọlọ́wọ́ tí wọ́n ń pè ní Gutenberg láti tẹ̀wé títí dìgbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í lo ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n ń pè ní MAN Roland Lithoman rotary press. Àwòrán míì tí wọ́n fi han àwọn àlejò ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ń tún ẹ̀ka náà àtàwọn àyíká rẹ̀ ṣe. Bí àpẹẹrẹ, apá kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lára ẹ̀rọ ìgbàlódé tí wọ́n fi ń tẹ̀wé kì í jẹ́ kí atẹ́gùn tí ò dáa àtàwọn òórùn burúkú wọnú yàrá ìtẹ̀wé, asẹ́ kan sì wà lára ẹ̀rọ náà tó máa ń kó àwọn èérún bébà jọ kó bàa lè rọrùn láti kó dà nù.
Ìwé ìròyìn kan ládùúgbò náà gbé àpilẹ̀kọ kan jáde, wọ́n sọ pé “òjíṣẹ́ tó ti yara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà” làwọn ọgọ́rùn-ún méje [700] tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Ó tún sọ̀rọ̀ nípa “ìmọ́tótó àti bí wọ́n ṣe ń ṣe gbogbo nǹkan láì fàkókò ṣòfò” ní ẹ̀ka ìtẹ̀wé. Ọkùnrin kan tí kò gba tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Nígbà tó pa dà délé, ó kọ lẹ́tà kan sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, ohun tó kọ rèé: “Ẹ kú oríire o. Kì í ṣe gbogbo ìgbà lèèyàn máa ń ṣàṣeyọrí lọ́nà tó ta yọ bí èyí.”
Ọ̀pọ̀ lára àwọn àlejò náà ló mọyì bí wọ́n ṣe gba àwọn láyè láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà, ó sì yà wọ́n lẹ́nu láti rí i pé ẹ̀ka ọ́fíìsì náà ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ọgọ́rùn-ún kan àti mọ́kànléláàádọ́ta [151] èdè, tí wọ́n sì ń tẹ̀wé fún méjìdínlógún [18] lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní gúúsù àti àárín gbùngbùn Áfíríkà. Àwọn èèyàn lè ṣèbẹ̀wò sí èyíkéyìí lára àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà káàkiri ayé nígbà táwọn òṣìṣẹ́ bá ń ṣiṣẹ́ lọ́wọ́. Ó máa dáa tó o bá béèrè ìgbà tó o lè ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ìwé ìkésíni
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Báwọn àlejò ṣe ń dé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Mogale City, lórílẹ̀-èdè South Africa
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ìgbàlódé tí wọ́n ń pè ní MAN Roland Lithoman web-offset press
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀ka tí wọ́n ti ń di ìwé pọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Ẹ̀ka tó ń kówèé ránṣẹ́