Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Fẹ́ràn Ìdájọ́ Òdodo

Ó Fẹ́ràn Ìdájọ́ Òdodo

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ó Fẹ́ràn Ìdájọ́ Òdodo

Hébérù 10:26-31

ṢÉ ẸNÌ kan ti fọwọ́ ọlá gbá ẹ lójú rí, tónítọ̀hún mú un jẹ, tí kò sì kábàámọ̀ ohun tó ṣe? Ìwà ìrẹ́nijẹ ò rọrùn láti mú mọ́ra, pàápàá tó bá jẹ́ pé ẹnì kan tó yẹ kó nífẹ̀ẹ́ rẹ, kó sì bìkítà nípa rẹ ló hu irú ìwà ọ̀hún sí ẹ. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú ìwà yìí? a Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra onírúurú ìwà ìrẹ́nijẹ. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ fún wa pé Ọlọ́run máa fìyà jẹ àwọn tó bá ń sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà tí wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ láti ṣe ohun tó tọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó wà nínú ìwé Hébérù 10:26-31.

Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí a bá mọ̀ọ́mọ̀ sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà lẹ́yìn rírí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́ gbà, kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.” (Ẹsẹ 26) Ìwà tó burú jáì làwọn tí wọ́n bá ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ ń hù. Kí nìdí? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá kì í ṣe torí wọ́n jẹ́ aláìpé. Wọ́n ti sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà. Ìdí kejì ni pé, ńṣe ni wọ́n ń mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀. Ìwà ìbàjẹ́ ti wọ̀ wọ́n lẹ́wù torí ó ti pẹ́ tí wọ́n ti ń dẹ́ṣẹ̀. Ìdí kẹta ni pé, kì í ṣe àìmọ̀kan ló ń mú kí wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n ní “ìmọ̀ pípéye” nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó fẹ́.

Kí ni èrò Ọlọ́run nípa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó kọ̀ láti ronú pìwà dà? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kò tún sí ẹbọ kankan tí ó ṣẹ́ kù fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́.” Ẹ̀bùn ìràpadà tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Kristi fún aráyé wà fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tá à ń dá torí pé a jẹ́ aláìpé. (1 Jòhánù 2:1, 2) Àmọ́, ńṣe làwọn tó ń dẹ́ṣẹ̀ láìronú pìwà dà ń fi hàn pé àwọn ò mọyì ẹ̀bùn tó ṣeyebíye yìí. Ọlọ́run kà á sí pé wọ́n “ti tẹ Ọmọ [òun] mọ́lẹ̀,” wọ́n sì “ka ẹ̀jẹ̀ májẹ̀mú tí a fi sọ [Jésù] di mímọ́ sí ohun yẹpẹrẹ.” (Ẹsẹ 29) Bí wọ́n ṣe ń hùwà yìí fi hàn pé wọn ò ka Jésù sí nǹkan kan, wọ́n sì ń wo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ “bí ohun tí kò níye lorí” ju ẹ̀jẹ̀ àwọn èèyàn aláìpé lọ. (Ìtumọ̀ Today’s English Version) Kò yẹ káwọn ẹ̀dà tí ò moore Ọlọ́run yìí jàǹfààní kankan nínú ẹbọ ìràpadà Kristi.

Kí ló yẹ káwọn èèyàn búburú máa retí? Ọlọ́run onídàájọ́ òdodo ti ṣèlérí pé: “Tèmi ni ẹ̀san; èmi yóò san èrè iṣẹ́.” (Ẹsẹ 30) Káwọn tó ń pa ọmọnìkejì wọn lẹ́kún jayé gba ìkìlọ̀ yìí: Ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ò ní lọ láìjìyà. Lọ́pọ̀ ìgbà, orí ara wọn ni wọ́n máa fi ń ru ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá. (Gálátíà 6:7) Bópẹ́ bóyá, wọ́n á bá Ọlọ́run níbẹ̀ nígbà tó bá wá pa gbogbo àwọn arẹ́nijẹ tó wà láyé yìí run. (Òwe 2:21, 22) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ó jẹ́ ohun akúnfẹ́rù láti ṣubú sí ọwọ́ Ọlọ́run alààyè.”—Ẹsẹ 31.

Ó tù wá nínú láti mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run ò fàyè gba ẹ̀ṣẹ̀ àmọ̀ọ́mọ̀dá, ọkàn wa sì balẹ̀ pé Ọlọ́run máa tó gbèjà wa, pàápàá àwọn táwọn èèyàn tó ti di ògbólógbòó nínú ìwà ìbàjẹ́ ti hàn léèmọ̀. Nítorí náà, ọkàn wa balẹ̀ pé a lè fìjà fún Ọlọ́run jà torí pé ó kórìíra gbogbo onírúurú ìwà àìṣòdodo.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àlàyé síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà wà lójú ìwé 106 sí 114 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.