Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìgbéyàwó Ká?

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìgbéyàwó Ká?

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Máa Ń Tú Ìgbéyàwó Ká?

OHUN tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò ni pé “bí ọkọ tàbí ìyàwó bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀sìn míì, ìgbéyàwó wọn ti fẹ́ tú ká nìyẹn.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ohun táwọn èèyàn máa ń sọ fẹ́ni tí ọkọ tàbí ìyàwó ẹ̀ bá pinnu láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Àmọ́, ṣé gbogbo ìgbà lọ̀rọ̀ máa ń rí báyìí ṣá?

Ká sòótọ́, ó lè ṣàjèjì lára nígbà tí ọkọ tàbí ìyàwó èèyàn bá bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀sìn míì tàbí tó bẹ̀rẹ̀ sí í kọminú sáwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn tí wọ́n ti jọ ń ṣe tẹ́lẹ̀, tó sì wá pinnu láti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ẹ̀sìn míì. Ó lè jẹ́ kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàníyàn nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀, kó máa ronú pé ọkọ tàbí ìyàwó òun ti já òun kulẹ̀, ó sì lè bẹ̀rẹ̀ sí í kórìíra rẹ̀.

Lọ́pọ̀ ìgbà, ìyàwó ló máa ń kọ́kọ́ rídìí tó fi yẹ kóun máa ṣe ẹ̀sìn míì. Tí ìyàwó rẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, báwo nìyẹn ṣe lè nípa lórí ìgbéyàwó yín? Tó bá sì jẹ́ pé ìwọ ìyàwó lò ń ka ìwé yìí, tó o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí lo lè ṣe láti dín àníyàn tó ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn ọkọ rẹ kù?

Bó Ṣe Ń Ṣàwọn Ọkọ

Orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ni Mark ń gbé, ó sì ti tó ọdún méjìlá [12] tó ti gbéyàwó nígbà tí ìyàwó ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó sọ pé: “Ìgbéyàwó aláyọ̀ ni mo ní, iṣẹ́ tí mò ń ṣe sì tẹ́ mi lọ́rùn. Nǹkan ń lọ dáadáa fún mi. Kò pẹ́ ni ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbà yẹn ni mo tó mọ̀ pé ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbésí ayé mi máa tó yí pa dà. Bí ìyàwó mi ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ nínú Bíbélì ò kọ́kọ́ bá mi lára mu, nígbà tó tún wá sọ fún mi pé òun ti pinnu láti ṣèrìbọmi kóun sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ńṣe lọ̀rọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí lórí rú.”

Mark bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ẹ̀sìn tí ìyàwó òun ṣẹ̀ṣẹ̀ rí yìí ló máa tú ìgbéyàwó àwọn ká. Ó ṣe é bíi kó ní kó máà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́, kó sì sọ fún un pé kò gbọ́dọ̀ ní nǹkan kan-án ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́. Àmọ́, kàkà kí Mark ṣèpinnu láìronú jinlẹ̀, ó fàkókò díẹ̀ sílẹ̀ láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ sí ìgbéyàwó Mark?

Mark sọ pé: “Inú mi dùn pé ìgbéyàwó wa ti túbọ̀ láyọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ńṣe ni nǹkan túbọ̀ ń dáa sí i láti nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tí ìyàwó mi ti ṣèrìbọmi tó sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Kí lo jẹ́ kí ìgbéyàwó wọn kẹ́sẹ járí? Mark sọ pé: “Tí mo bá ronú pa dà sẹ́yìn, olórí ohun ti mo lè sọ pé ó jẹ́ kí ìgbéyàwó wa kẹ́sẹ járí ni bí ìyàwó mi ṣe ń fàwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì ṣèwà hù. Gbogbo ìgbà ló máa ń ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti bọ̀wọ̀ fún mi.”

Ìmọ̀ràn Látọ̀dọ̀ Àwọn Ìyàwó Tó Ti Ṣàṣeyọrí

Tó bá jẹ́ ìyàwó ilé ni ẹ́, tó o sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí lo lè ṣe láti dín àníyàn tó ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn ọkọ ẹ kù? Ka nǹkan táwọn obìnrin, tó wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé, wọ̀nyí sọ.

Sakiko, láti orílẹ̀-èdè Japan: “Ó ti tó ọdún mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31] tí mo ti ṣègbéyàwó, mo sì ti bímọ mẹ́ta. Ọdún kejìlélógún [22] rèé tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà míì, kì í rọrùn láti gbé pẹ̀lú ọkọ mi tóhun tó gbà gbọ́ yàtọ̀ sí tèmi. Àmọ́, mo ṣiṣẹ́ kára láti máa fàwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì ṣèwà hù pé kí n ‘yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.’ (Jákọ́bù 1:19) Mo máa ń gbìyànjú láti ṣe dáadáa sí ọkọ mi, mo sì máa ń ṣe àwọn nǹkan tó bá fẹ́, tí ò bá ṣáà ti ta ko àwọn ìlànà Bíbélì. Èyí ló sì jẹ́ kí ìgbéyàwó wa kẹ́sẹ járí.”

Nadezhda, láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà: “Ó ti tó ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] tí mo ti ṣègbéyàwó, ọdún kẹrìndínlógún [16] rèé tí mo ti ṣèrìbọmi, tí mo sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mi ò rò pé ọkọ mi ló yẹ kó jẹ́ olórí ìdílé. Mo máa ń fẹ́ dá ìpinnu tèmi ṣe. Àmọ́, mo ti wá rí i pé bí mo ṣe ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù ti pa kún ayọ̀ ìdílé wa, ó sì ti túbọ̀ jẹ́ kí ilé wa tòrò. (1 Kọ́ríńtì 11:3) Díẹ̀díẹ̀ ló wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọrùn fún mi láti máa gbọ́ràn sí ọkọ mi lẹ́nu, òun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í ríyàtọ̀ nínú bí mo ṣe ń hùwà.”

Marli, láti orílẹ̀-èdè Brazil: “Ó ti tó ọdún mọ́kànlélógún [21] tí mo ti ṣègbéyàwó, mo sì ti láwọn ọmọ méjì. Ọdún kẹrìndínlógún [16] rèé tí mo ti ṣèrìbọmi, tí mo sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ìfẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ni pé káwọn tọkọtaya máa wà pa pọ̀, kí wọ́n má sì tú ká. Torí náà, mo gbìyànjú láti jẹ́ ìyàwó rere lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ mi, mò ń sọ̀rọ̀ mo sì ń hùwà lọ́nà tó máa múnú Jèhófà àti ọkọ mi dùn.”

Larisa, láti orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà: “Ìgbà tí mo di Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní nǹkan bí ọdún mọ́kàndínlógún [19] sẹ́yìn ni mo ṣẹ̀ṣẹ̀ rí i pé ohun tó ṣe pàtàkì jù fún mi ni pé kí n yí ìgbésí ayé mi pa dà. Ọkọ mi ti rí bí Bíbélì ṣe ràn mí lọ́wọ́ láti jẹ́ aya rere, ìyẹn sì ti wá jẹ́ kí n mọyì rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọkọ rere. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, a máa ń jiyàn lórí bá a ṣe fẹ́ tọ́ àwọn ọmọ wa, àmọ́ a ti yanjú ìyẹn báyìí. Ọkọ mi ti gbà káwọn ọmọ mi máa tẹ̀ lé mi lọ sáwọn ìpàdé wa, torí ó ti wá mọ̀ pé ohun tó máa ṣe wọ́n láǹfààní ni wọ́n ń kọ́ wọn níbẹ̀.”

Valquíria, láti orílẹ̀-èdè Brazil: “Ó ti tó ọdún mọ́kàndínlógún [19] tí mo ti ṣègbéyàwó, mo sì ti ní ọmọ kan. Ọdún kẹtàlá [13] rèé tí mo ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀, ọkọ mi ò fẹ́ kí n máa wàásù. Àmọ́, mo kọ́ bí mo ṣe lè fohùn tútù fèsì sóhun tó ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, kí n sì jẹ́ kó rí i pé Bíbélì ti nípa tó dáa lórí ọ̀nà tí mo gbà ń gbé ìgbésí ayé mi. Nígbà tó yá, baálé mi náà rí bó ti ṣe pàtàkì tó fún mi láti máa wàásù. Ní báyìí, ó ń ṣe gbogbo ohun tó bá lè ṣe láti máa tì mí lẹ́yìn lórí ohun tó bá ti jẹ mọ́ ìjọsìn mi. Nígbà tí mo bá fẹ́ lọ darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láwọn ọ̀nà jíjìn, ó máa ń fi mọ́tò gbé mi lọ, á sì dúró síta títí tí mo fi máa ṣe tán.”

Ohun Rere Ló Máa Gbẹ̀yin Ẹ̀

Tí ọkọ tàbí ìyàwó rẹ bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, má ṣe bẹ̀rù pé ìgbéyàwó yín máa tú ká. Bí ọ̀pọ̀ ọkọ àtìyàwó níbi gbogbo lágbàáyé ti ṣe mọ̀ báyìí, ohun rere ló máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀kọ́ Bíbélì, ó sì máa ń nípa tó dáa lórí ìgbéyàwó.

Ọkọ kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ tó wà lọ́kàn ẹ̀ pé: “Nígbà tí ìyàwó mi di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, gbogbo nǹkan ló tojú sú mi, àmọ́ mo ti wá rí i pé àwọn ìyípadà tí mo ṣe ò tó àǹfààní tá à ń jẹ báyìí.” Ohun tí ọkùnrin míì sọ nípa ìyàwó ẹ̀ rèé: “Bí ìyàwó mi ṣe ń fòótọ́ inú ṣe nǹkan, tí kò yẹsẹ̀ lórí àwọn ìpinnu tó ti ṣe, tí kò sì fọ̀bẹ ẹ̀yìn jẹ mí níṣu, ti jẹ́ kí n fẹ́ràn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gan-an. Ìgbéyàwó wa ti túbọ̀ dáa sí i nítorí àwọn nǹkan tí ẹ̀sìn tó ń ṣe báyìí ti mú kó gbà gbọ́. A máa ń dárí ji ara wa, a sì ti jọ gbà pé ẹ̀kùrọ́ ni alábàákú ẹ̀wà.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Báwo Ni Ìgbéyàwó Ṣe Ṣe Pàtàkì Tó Lójú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ pé Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí ni Bíbélì. Torí náà ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi ń mú gbogbo nǹkan tó sọ nípa ìgbéyàwó. Wo ìdáhùn Bíbélì sáwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

Ṣóòótọ́ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gba àwọn ará ìjọ wọn nímọ̀ràn láti kọ ọkọ tàbí ìyàwó wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí arákùnrin èyíkéyìí bá ní aya tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí obìnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi obìnrin náà sílẹ̀; àti obìnrin tí ó ní ọkọ tí kò gbà gbọ́, síbẹ̀ tí ọkùnrin náà fara mọ́ bíbá a gbé, kí ó má fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 7:12, 13) Àṣẹ yìí gan-an làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé.

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fọwọ́ sí i pé kí ìyàwó tó jẹ́ ará ìjọ wọn má máa gbọ́ tọkọ ẹ̀ torí pé kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Rárá o. Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin aya, ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:1, 2.

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn ará ìjọ wọn pé àṣẹ ọkọ ló ṣe pàtàkì jù? Rárá o. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.” (1 Kọ́ríńtì 11:3) Ìyàwó ilé tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olórí ìdílé. Àmọ́, àṣẹ ọkọ kọ́ ló ṣe pàtàkì jù. Nítorí pé ọkọ náà ṣì wà lábẹ́ àṣẹ Ọlọ́run àti Kristi. Nítorí náà, tí ọkọ bá pàṣẹ pé kí ìyàwó òun ṣe ohun tó tẹ òfin Ọlọ́run lójú, ìyàwó tó jẹ́ Kristẹni máa “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn ará ìjọ wọn pé èèwọ̀ ni ìkọ̀sílẹ̀? Rárá o. Jésù Kristi sọ pé: “Mo wí fún yín pé ẹnì yòówù tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, bí kò ṣe lórí ìpìlẹ̀ àgbèrè [ìṣekúṣe], tí ó sì gbé òmíràn níyàwó, ṣe panṣágà.” (Mátíù 19:9) Nítorí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba ọ̀rọ̀ Jésù gbọ́ pé tọkọtìyàwó lè kọra wọn sílẹ̀ bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣe panṣágà. Àmọ́, wọ́n tún gbà gbọ́ dáadáa pé tọkọtìyàwó ò gbọ́dọ̀ tìtorí àwọn nǹkan tí ò lẹ́sẹ̀-ńlẹ̀ kọra wọn sílẹ̀. Wọ́n máa ń gba àwọn ará ìjọ wọn níyànjú pé kí wọ́n máa tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ọkùnrin yóò fi baba rẹ̀ àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì fà mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan. . . . Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.”—Mátíù 19:5, 6.