Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé orí Àpáta Lò Ń Kọ́lé sí àbí orí Iyanrìn?

Ṣé orí Àpáta Lò Ń Kọ́lé sí àbí orí Iyanrìn?

Ṣé orí Àpáta Lò Ń Kọ́lé sí àbí orí Iyanrìn?

ṢÓ O máa ń gbádùn kíka Bíbélì? Ṣó o tiẹ̀ máa ń wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, kò sí àníàní pé àwọn ẹ̀kọ́ tó o ti kọ́ á ti jẹ́ kó o mọ ìdí tíṣòro fi kúnnú ayé yìí. (Ìṣípayá 12:9, 12) Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹsẹ Bíbélì ti tù ẹ́ nínú nígbà ìṣòro, ó sì ti jẹ́ kó o mọ̀ pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.—Sáàmù 145:14; 147:3; 2 Pétérù 3:13.

Ohun pàtàkì kan tó yẹ káwọn tó bá fẹ́ di ọmọlẹ́yìn Kristi ṣe ni pé kí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó péye látinú Bíbélì. Àmọ́, ṣéyẹn nìkan ni wọ́n máa ṣe? Rárá o. Káwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ Kristẹni tòótọ́, pàápàá nígbà tí nǹkan kan bá ń dán ìgbàgbọ́ wọn wò, ohun pàtàkì kan wà tó tún yẹ kí wọ́n ṣe. Kí nìyẹn? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò Ìwàásù Orí Òkè, ìyẹn àsọyé tí Jésù sọ lórí òkè Gálílì.—Mátíù 5:1, 2.

Wọ́n Dán Ilé Méjì Wò

Ṣó o mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Ìwàásù Orí Òkè? Àkọsílẹ̀ nípa ìwàásù táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹní mowó yìí wà nínú àwọn Ìwé Ìhìn Rere ti Mátíù àti Lúùkù. (Mátíù 5:1-7:29; Lúùkù 6:20-49) Ogún [20] ìṣẹ́jú péré lèèyàn máa fi kà á. Ó ju ìgbà ogún [20] lọ tí Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nígbà tó ń sọ àsọyé yẹn, àwọn àkànlò èdè tó wà níbẹ̀ sì ju àádọ́ta [50] lọ. Àkànlò èdè kan tó ní í ṣe pẹ̀lú bí wọ́n ṣe kọ́ ilé méjì kan ta yọ nínú àwọn àkànlò èdè tí Jésù lò níbẹ̀ torí pé ìyẹn ni Jésù fi parí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tó o bá lóye bí àpèjúwe tí Jésù fi parí ọ̀rọ̀ yẹn ti ṣe pàtàkì tó, ìyẹn á ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ bó o ṣe lè máa bá a nìṣó láti jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, láìka àwọn nǹkan tó lè máa dán ìgbàgbọ́ ẹ wò sí.

Jésù sọ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí ó sì ń ṣe wọ́n ni a ó fi wé ọkùnrin olóye, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì bì lu ilé náà, ṣùgbọ́n kò ya lulẹ̀, nítorí a ti fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ sọlẹ̀ sórí àpáta ràbàtà. Síwájú sí i, gbogbo ẹni tí ń gbọ́ àwọn àsọjáde tèmi wọ̀nyí, tí kì í sì í ṣe wọ́n ni a ó fi wé òmùgọ̀ ọkùnrin, ẹni tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí iyanrìn. Òjò sì tú dà sílẹ̀, ìkún omi sì dé, ẹ̀fúùfù sì fẹ́, wọ́n sì kọlu ilé náà, ó sì ya lulẹ̀, ìwólulẹ̀ rẹ̀ sì pọ̀.”—Mátíù 7: 24-27.

Ọkùnrin Kan “Tí Ó Walẹ̀ Jìn”

Òótọ́ ọ̀rọ̀ tó ṣe pàtàkì wo ni Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ nígbà tó sọ àpèjúwe nípa àwọn ọkùnrin méjì tó kọ́lé? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn dáadáa. Kí lo kíyè sí nípa àwọn ilé méjèèjì yẹn? Ilé méjèèjì ni àjálù dé bá. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n rí bákan náà. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀gbẹ́ ara wọn ni wọ́n wà. Àmọ́, orí iyanrìn ni wọ́n kọ́ ọ̀kan sí nígbà tí wọ́n kọ́ ìkejì sórí àpáta. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní ọkùnrin ọlọ́gbọ́n náà “walẹ̀ jìn” lọ síbi tí àpáta wà. (Lúùkù 6:48) Ìyẹn ni ò jẹ́ kí mìmì kankan mi ilé ọkùnrin ọlọgbọ́n yẹn.

Kí ni Jésù fẹ́ láti tẹnu mọ́? Kì í ṣe torí àtisọ bí ilé yẹn ṣe rí, ibi tó wà tàbí bí àjálù yẹn ṣe le tó ni Jésù fi sọ àpèjúwe yẹn, àmọ́ ó fẹ́ tẹnu mọ́ ohun táwọn ọkùnrin tó kọ́ ilé wọ̀nyẹn ṣe. Ọ̀kan lárá wọn walẹ̀ jìn, nígbà tí ìkejì ò ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo lo ṣe lè máa walẹ̀ jìn bíi ti ọkùnrin ọlọgbọ́n yẹn? Jésù fúnra rẹ̀ sọ ìdí tó fi sọ àpèjúwe yẹn nígbà tó sọ pé: “Èé ṣe tí ẹ fi wá ń pè mí ní ‘Olúwa! Olúwa!’ ṣùgbọ́n tí ẹ kò ṣe àwọn ohun tí mo wí? Olúkúlùkù ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, tí ó sì gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ mi, tí ó sì ṣe wọ́n, èmi yóò fi ẹni tí ó jọ hàn yín: Ó dà bí ọkùnrin kan . . . tí ó walẹ̀ jìn, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ sórí àpáta ràbàtà.”—Lúùkù 6:46-48.

Ká sòótọ́, téèyàn bá kàn ń gbọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì tàbí tó kàn ń dá ka Bíbélì nílé, ṣe ló dà bí ìgbà téèyàn ń kọ́lé sórí iyanrìn torí pé èèyàn ò nílò láti walẹ̀ jìn, kó tó ṣèyẹn. Àmọ́ kò rọrùn láti fàwọn ẹ̀kọ́ Kristi ṣèwà hù. Ó ń béèrè pé kéèyàn walẹ̀ jìn dáadáa bí ìgbà tó fẹ́ kọ́lé sórí àpáta.

Nítorí náà, fífi àwọn ohun tó o bá gbọ́ ṣèwà hù ló máa pinnu bóyá wàá lè máa bá a nìṣó láti máa jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi. Tó o bá ń fàwọn ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ látinú Bíbélì ṣèwà hù lójoojúmọ́, ṣe ni wàá dà bí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tó walẹ̀ jìn. Torí náà, ó yẹ kí gbogbo ẹni tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fara balẹ̀ béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé: ‘Ṣé mo kàn máa ń gbọ́rọ̀ ni, àbí mo máa fi ń ṣèwà hù? Ṣé mo kàn máa ń ka Bíbélì tí mo sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ ni, àbí mo máa ń fàwọn àṣẹ tó wà nínú Bíbélì sọ́kàn nígbà tí mo bá fẹ́ ṣèpinnu?’

Àǹfààní Tó Wà Nínú Wíwalẹ̀ Jìn

Gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí José. Àwọn òbí ẹ̀ kọ́ ọ láti máa fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù, àmọ́ òun fúnra ẹ̀ ò kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. José sọ pé: “Nígbà tí mo kúrò nílé, mò ń gbìyànjú láti máa ṣe dáadáa, àmọ́ ẹgbẹ́ búburú ni mò ń kó. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró, mò ń ṣèṣekúṣe, mo sì máa ń bá àwọn èèyàn jà.”

Nígbà tó yá, José pinnu láti yíwà ẹ̀ pa dà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì. Ó ní: “Nǹkan kan tó mú ki n yí pa dà ni ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè, mo kà á, mo sì lóye ẹ̀ dáadáa. Àmọ́, ó gbà mí lákòókò díẹ̀, láti yí ìwà mi àti bí mo ṣe ń gbé ìgbésí ayé mi pa dà. Ẹ̀rù kọ́kọ́ ń bà mí, torí mi ò mọ nǹkan táwọn tí mò ń bá rìn máa sọ nípa mi, àmọ́ mo borí ìbẹ̀rù yẹn. Mi ò purọ́ mọ́, mi ò sọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ò dáa jáde lẹ́nu mọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo wá kẹ́kọ̀ọ́ gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ pé, téèyàn ò bá wayé máyà, téèyàn sì ń fàwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù, ó máa láyọ̀ tí ò lópin.”—Mátíù 5:3-12.

Àǹfààní wo lo máa wá rí níbẹ̀, tó o bá ń walẹ̀ jìn láti kọ́lé sórí àpáta, ìyẹn tó o bá ń fi tọkàntọkàn fàwọn ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù? Jésù sọ pé: “Nígbà tí ìkún omi dé, odò ya lu ilé yẹn, ṣùgbọ́n kò lágbára tó láti mì ín, nítorí kíkọ́ tí a kọ́ ọ dáadáa.” (Lúùkù 6:48) Ó dájú pé, tó o bá kọ́ ara ẹ dáadáa, tó o sì ń fàwọn ohun tó o kọ́ ṣèwà hù, àwọn àdánwò tó dà bí ìjì ò ní ba ìgbàgbọ́ ẹ jẹ́, mìmì kankan ò tiẹ̀ ní mì ẹ́ pàápàá. Ìyẹn mà tuni nínú o!

Jákọ́bù, ọmọ ẹ̀yìn Jésù tó tún jẹ́ ọbàkan rẹ̀, mẹ́nu ba àǹfààní míì tó wà fáwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń fàwọn ohun tí wọ́n ń kọ́ látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù lóòótọ́. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan . . . Ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:22-25.

Ó dájú pé, àwọn tó ń fàwọn ìmọ̀ràn Bíbélì ṣèwà hù máa ń láyọ̀ lóòótọ́. Irú ayọ̀ yìí, ló ń jẹ́ káwọn ọmọlẹ́yìn Kristi lágbára láti lè máa fojú winá àwọn àdánwò, tó dà bí ìjì, tó ń dán ìgbàgbọ́ wọn wò, tó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ bóyá tọkàntọkàn làwọ́n fi ń sin Ọlọ́run tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.

Kí Ni Wàá Ṣe?

Nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè, ó tẹnu mọ́ ọn pé èèyàn ò lè máa jọ́sìn Jèhófà Ọlọ́run, kó tún máa mú ìjọsìn míì mọ, àmọ́ ṣe lèèyàn máa pinnu èyí tóun bá fẹ́ ṣe nínú méjèèjì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù kọ́ni pé ṣe lèèyàn máa pinnu bóyá òun fẹ́ kójú òun mú ọ̀nà kan tàbí kí gbogbo ara òun ṣókùnkùn, bóyá èèyàn máa fẹ́ ṣe ẹrú fún Ọlọ́run tàbí fún ọrọ̀, tàbí bóyá èèyàn máa fẹ́ láti rin ọ̀nà tóóró tàbí ọ̀nà gbòòrò. (Mátíù 6:22-24; 7:13, 14) Lẹ́yìn ìyẹn ló wá fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ làǹfààní láti ṣe yíyàn míì nígbà tó sọ àpèjúwe nípa àwọn ọkùnrin méjì tó kọ́lé níparí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní wọ́n lè yàn láti hùwà bí ọlọgbọ́n tàbí kí wọn ṣe bí òmùgọ̀.

Tó o bá ń fi tọkàntọkàn fàwọn ẹ̀kọ́ tó ò ń kọ́ látinú Bíbélì ṣèwà hù, ìwà ọgbọ́n lò ń hù yẹn. Ó dájú pé, tó o bá ń bá a nìṣó láti máa walẹ̀ jìn kó o lè kọ́lé sórí àpáta, ọ̀pọ̀ àǹfààní lo máa rí níbẹ̀ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 10:25.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Fífi àwọn ohun tá à ń kọ́ ṣèwà hù ló máa pinnu bóyá a máa lè kojú àdánwò