Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àṣìṣe Wọn Ni Mò Ń wá Ni Mo Bá Rí Òtítọ́

Àṣìṣe Wọn Ni Mò Ń wá Ni Mo Bá Rí Òtítọ́

Àṣìṣe Wọn Ni Mò Ń wá Ni Mo Bá Rí Òtítọ́

Gẹ́gẹ́ bí R. Stuart Marshall ṣe sọ ọ́

Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì sọ fún mi pé: “A kì í báwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀, torí Bíbélì ni wọ́n máa ń lò.” Ohun tó sọ yìí yà mí lẹ́nu gan-an, torí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ fún un pé kó bá mi fàwọn àṣìṣe tó wà nínú ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà han ìyàwó mi ni. Mo pinnu pé èmi náà á lọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí n lè ráwọn àṣìṣe wọ̀nyẹn kí n sì ṣàlàyé wọn fún ìyàwó mi.

MI Ò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́tàlélógójì [43] lọ nígbà tóhun tí mo sọ lókè yìí ṣẹlẹ̀. Mo fẹ́ fi ìmọ̀ tí mo ní nípa ìrònú ẹ̀dá àti ẹ̀kọ́ nípa ìsìn jẹ́ káwọn èèyàn rí i pé ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn ò tọ̀nà. Iléèwé àwọn Kátólíìkì ni mo lọ látìgbà tí mo ti bẹ̀rẹ̀ iléèwé àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ títí tí mo fi parí iléèwé gíga. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo gboyè jáde gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ní yunifásítì lọ́dún 1969, mo tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìrònú ẹ̀dá àti ẹ̀kọ́ nípa ìsìn torí dandan ni fẹ́ni tó bá ti lọ síléèwé Kátólíìkì, síbẹ̀ náà, mi ò kẹ́kọ̀ọ́ nípa Bíbélì rárá ní gbogbo ọdún tí mo lò níléèwé àwọn Kátólíìkì.

Nígbà tí mo kúrò níléèwé gíga, mo gbé Patricia McGinn, tóun náà jẹ́ Kátólíìkì, níyàwó. Ẹ̀yìn ìyẹn làwa méjèèjì gba oyè onípele kẹta jáde ní Yunifásítì Stanford. Ọdún 1977 la bí Stuart ọmọkùnrin wa, a sì kó lọ sí Sacramento, lágbègbè California, lórílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Fún ọdún mẹ́tàlélógún [23] tó tẹ̀ lé e, ìjọba ìpínlẹ̀ California ni mò ń bá ṣiṣẹ́. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ni mo wà, iṣẹ́ tèmi sì ni láti máa bójú tó ètò ìṣúnná owó àwọn iléèwé ìjọba. Òṣìṣẹ́ kára ni mí, mo sì máa ń jayé orí mi. Inú mi máa ń dùn láti tọ́ ọmọkùnrin wa sọ́nà bó ṣe ń dàgbà. Ìyàwó mi ọ̀wọ́n fòótọ́ inú dúró tì mí lákòókò yìí, èmi náà ò sì dá a dá àwọn nǹkan tó nílò.

25-Cent La Fi Wá Ìdáhùn Sáwọn Ìbéèrè Wa

Nígbà tí ọmọkùnrin wa pé ọmọ ọdún méjì, Patricia gba Bíbélì kan lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú wọn. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà ló ṣèrìbọmi. Mo máa ń ronú pé ìmọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ bí ọlidé àti ìfàjẹ̀sínilára kò jinlẹ̀ tó, àmọ́ mo fara mọ́ àwọn àlàyé tí wọ́n ṣe lórí àwọn kókó míì. Ó yà mí lẹ́nu pé lọ́jọ́ kan lọ́dún 1987, mo sọ ohun tó wà lọ́kàn mi ní gbangba nígbà tí wọ́n ní kí n kọ́kọ́ wá ṣàlàyé àbá kan tí mo fẹ́ dá fún ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà fáwọn aṣojú wọn àtàwọn ìgbìmọ̀ tó ń rí sọ́rọ̀ ẹ̀kọ́.

Yunifásítì tó wà ní California nílò owó láti díje pẹ̀lú àwọn ìpínlẹ̀ míì níbi ètò kan tí ìjọba àpapọ̀ ti ṣe láti fún ẹni tó bá borí ní àǹfààní láti ṣe iṣẹ́ ẹ̀rọ kan tó máa ná wọn tó bílíọ̀nù mẹ́fà owó dọ́là. Ohun tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ káwọn tó bá borí nínú ìdíje náà ṣe ni ohun èlò tí wọ́n lè máa fi ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan bíi bọ́ǹbù átọ́míìkì. Mo sọ fún ìjọba ìpínlẹ̀ náà pé mi ò fọwọ́ sí owó tí Yunifásítì yẹn béèrè fún, torí pé mi ò rí àǹfààní kankan tó máa ṣe fún ètò ọrọ̀ ajé ìpínlẹ̀ náà. Nígbà táwọn aláṣẹ Yunifásítì náà máa fèsì, wọ́n rán àwọn méjì tó ti gba àmì ẹ̀yẹ Nobel nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́ físíìsì, pé kí wọ́n wá ṣàlàyé ìdí tọ́ràn ò fi rí bẹ́ẹ̀ fáwọn aṣòfin. Àwọn méjèèjì ṣàlàyé bí ohun tí ìjọba àpapọ̀ ní kí wọ́n ṣe yẹn ṣe máa fi kún ìmọ̀ àwọn tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa sáyẹ́ǹsì. Ọ̀kan nínú wọn sọ pé ó lè jẹ́ káwọn èèyàn mọ ìpilẹ̀ṣẹ̀ àgbáálá ayé wa. Èkejì sọ pé ó lè jẹ́ ká mọ ìgbà táwọn ohun ẹlẹ́mìí ti wà lórí pílánẹ́ẹ̀tì wa.

Alága ìgbìmọ̀ náà yíjú sí mi.

Ó wá bi mí pé: “Ṣó o rò pé bílíọ̀nù mẹ́fà owó dọ́là ti pọ̀ jù láti ṣe ohun tó máa lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n ti kà sílẹ̀ yìí?”

Mo wá sọ fún un pé: “Mo gbà pé àwọn ìbéèrè tí wọ́n kà sílẹ̀ wọ̀nyẹn ṣe pàtàkì. Àmọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń wá sílé mi láràárọ̀ Sátidé, wọ́n sì fún mi ní ìwé ìròyìn kan tí mo fi 25-cent ṣètìlẹ́yìn fún, ìwé yẹn sì máa dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè tí wọ́n kà sílẹ̀ yìí. Ta ló sì mọ̀ bóyá ìdáhùn tá a máa rí nínú ìwé tá a máa fi 25-cent ṣètìlẹ́yìn fún yìí máa dáa ju èyí tá a máa rí nínú ẹ̀rọ tí wọ́n fẹ́ tìtorí ẹ̀ fún wa ní bílíọ̀nù mẹ́fà owó dọ́là.”

Gbogbo àwọn tó wà nínú yàrá náà, títí kan àwọn méjì tí wọ́n ti fi àmì ẹ̀yẹ Nobel dá lọ́lá, ló bú sẹ́rìn-ín. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbìmọ̀ aṣòfin fọwọ́ sí i pé kí wọ́n fún wọn lówó láti lọ ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe, kò sẹ́ni tó sọ pé kò sọ̀rọ̀ nínú nǹkan tí mo sọ lọ́jọ́ yẹn.

Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, ohun kan bẹ̀rẹ̀ sí í ṣẹlẹ̀ nílé mi tó yẹ kí n bójú tó. Lẹ́yìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ Patricia lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtohun tó yẹ kó mọ̀ nípa ètò wọn fún ọdún mẹ́fà, ó pinnu pé òun fẹ́ máa lo àkókò púpọ̀ sí i láti wàásù, ìyẹn sì dùn mí gan-an. Torí ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé kò ní lè máa lo àkókò tó pọ̀ tó láti máa ṣiṣẹ́ ní yunifásítì mọ́. Bí ọlọ́pọlọ èèyàn bíi tiẹ̀ ṣe lè ṣe irú ìpinnu yẹn jẹ́ kí nǹkan tojú sú mi. Mo ṣe gbogbo ohun tí mo lè ṣe láti jẹ́ kó yí ìpinnu ẹ̀ pa dà, àmọ́ pàbó ni gbogbo ẹ̀ já sí.

Mo wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tí mo rò pó nímọ̀ nípa Bíbélì jù mi lọ, torí mo rò pé ó máa rọrùn fún un láti jẹ́ kí ìyàwó mi rí i pé ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kọ́ àwọn èèyàn ò bá ohun tó wà nínú Bíbélì mu. Mo mọ̀ pé tó bá ti lè rí àṣìṣe kan péré nínú ẹ̀kọ́ wọn, ìyàwó mi á bẹ̀rẹ̀ sí í kọminú sáwọn tó kù. Ohun tí mo lè ṣe láti yí ìyàwó mi lọ́kàn pa dà nìyẹn, torí ọlọ́gbọ́n èèyàn ni. Mo lọ bá àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì témi àti Patricia ń lọ tẹ́lẹ̀. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí mo lọ bà á ni mo sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Nígbà tí àlùfáà náà kọ̀ láti bá ìyàwó mi sọ̀rọ̀, mo wá rí i pé èmi fúnra mi ni mo máa bẹ̀rẹ̀ sí í wá àwọn àṣìṣe wọ̀nyẹn tí máa sì sọ fún Patricia, bí mo tiẹ̀ mọ̀ pó máa gbà mí lákòókò díẹ̀.

Bí Mo Ṣe Ń Wá Àwọn Àṣìṣe Wọn

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló wú mi lórí jù lọ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí mo kà ni èyí tí Aísáyà sọ nípa ìṣubú Bábílónì ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún méjì [200] ọdún ṣáájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó wáyé, bó ṣe sọ pé Kírúsì ló máa ṣẹ́gun rẹ̀ tó sì ṣàlàyé bó ṣe darí Odò Yúfírétì gba ibòmíì kó lè ráyè ṣẹ́gun Bábílónì. (Aísáyà 44:27–45:4) Ọdún mélòó kan ṣáájú àkókò yìí, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìṣubú Bábílónì nígbà tí mo wà ní kíláàsì kan tí wọ́n ti ń kọ́ wa láwọn ọ̀nà téèyàn lè gbà jagun. Mo tún kẹ́kọ̀ọ́ pé ọgọ́rùn-ún méjì ọdún [200] ṣáájú ni wòlíì Dáníẹ́lì ti sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ọba alágbára kan tó máa jẹ lórílẹ̀-èdè Gíríìsì tí ìjọba rẹ̀ sì máa pín sí mẹ́rin lẹ́yìn tó bá ti kú, tí wọn ò sì ní lágbára bíi tiẹ̀. (Dáníẹ́lì 8:21, 22) Mo rántí pé nígbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ìtàn tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn níléèwé, ohun tí wọ́n ló ṣẹlẹ̀ sí Alẹkisáńdà Ńlá gan-an nìyẹn. Èmi fúnra mi wá ṣèwádìí nípa àwọn nǹkan wọ̀nyí, mo sì wá rí i pé àwọ́n wòlíì ti sọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Bíbélì káwọn nǹkan wọ̀nyẹn tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́.

Bí mo ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí tó, ni mo ṣe ń nígbàgbọ́ tó kún pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, nǹkan ò sì rí bẹ́ẹ̀ ní gbogbo ọdún tí mo fi kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn Kátólíìkì. Kí ni màá wá ṣe pẹ̀lú ìmọ̀ tí mo ní yìí? Mo pinnu láti ya ìgbésí ayé mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. (Aísáyà 43:10) Ọdún méjì lẹ́yìn témi àti àlùfáà yẹn sọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ni mo ṣèrìbọmi, ìyẹn lọ́dún 1991. Ọdún tó tẹ̀ lé e ni ọmọkùnrin wa náà ṣèrìbọmi.

Nítorí ohun tá a ti mọ̀ báyìí, a yí àwọn ìpinnu wa pa dà. Ohun àkọ́kọ́ tí mo ṣe lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi ni ètò ọlọ́dún márùn-ún kan tó máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ìyàwó mi láti kọ̀wé fi iṣẹ́ olùkọ́ sílẹ̀ lọ́gbà yunifásítì tó bá ti pé ọmọ àádọ́ta [50] ọdún. Ó fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé, nígbà yẹn ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ó máa máa lo ẹgbẹ̀rún kan [1,000] wákàtí lọ́dún láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Bíbélì, tàbí nǹkan bíi wákàtí mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] lóṣooṣù. Nígbà tó fi máa di ọdún 1994, ó ti dín àwọn nǹkan tó ń ṣe kù débi pé ó ti lè sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Lára àwọn nǹkan tí mo kọ́kọ́ fojú sùn ni ṣíṣe dáadáa sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, kíkọ́wọ́ ti ìṣètò ìjọ débi tágbára mi bá mọ, àti lílo ìmọ̀ tí mo ní láti bójú tó ètò ìnáwó kíkọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba ládùúgbò wa.

Nígbà míì sì rèé, mo máa ń láǹfààní láti bá àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì. Lákòókò tí mò ń sọ yìí ni wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ gba obìnrin kan láti máa bójú tó ètò ìnáwó níbi iṣẹ́ wa, ìgbà tó yá ni mo mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni tẹ́lẹ̀, àmọ́ kò fi taratara ṣe é mọ́. Ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ìgbàgbọ́ tó ní nínú Bíbélì, ìyẹn sì ti jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹ̀ dẹnu kọlẹ̀. Inú mi dùn gan-an láti ràn án lọ́wọ́ kó lè pa dà máa fìtara sin Jèhófà. Nígbà tó pa dà sí ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Lọ́dún 1995, mo lọ sí àkànṣe ìpàdé àpérò kan níbi táwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tó ń rí sọ́ràn ẹ̀kọ́ àtàwọn ìgbìmọ̀ tó ń rí sọ́ràn àdúgbò ti fẹ́ jíròrò nípa ìwádìí kan tí ìjọba àpapọ̀ ṣètìlẹ́yìn fún. Alága ìgbìmọ̀ náà béèrè lọ́wọ́ aṣojú ìjọba àpapọ̀ pé kó ṣàlàyé ibi tí wọ́n ti báṣẹ́ dé lórí ẹ̀rọ tí wọ́n díje fún nígbà yẹn. Aṣojú ìjọba àpapọ̀ ṣàlàyé pé ìjọba ìpínlẹ̀ Texas ló borí nínú ìdíje náà, àwọn sì ni ìjọba àpapọ̀ gbé iṣẹ́ náà fún, àmọ́ fún ìdí mẹ́ta, wọn ò tíì lè parí iṣẹ́ náà títí di báyìí. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà ni wọ́n ti rí i pé iye tó máa ná àwọn láti parí iṣẹ́ náà ti fi bílíọ̀nù mẹ́ta lé sí i, ó ti wá di bílíọ̀nù mẹ́sàn-án owó dọ́là. Ìdí kejì ni pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ lo owó fáwọn nǹkan míì, pàápàá jù lọ fún ti ogun tó ń jà lórílẹ̀-èdè Ìráàkì látọdún 1991. Ìdí kẹta sì ni pé ìjọba àpapọ̀ ti wá rí i pé àwọn lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè nípa ìgbésí ayé lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, táwọn ò sì ní ná ju 25 cents lọ! Ó jọ pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti gbọ́ nípa àbá tí mo dá nígbà yẹn, ó sì ti wá dọ̀rọ̀ àgbà, bí ò ṣẹ láàárọ̀ dandan ni kó ṣẹ lọ́jọ́ alẹ́.

Bí gbogbo àwọn tó wà nípàdé náà ṣe bú sẹ́rìn-ín, àwọn kan nínú wọn wojú mí. Mo sọ̀rọ̀ láti jẹ́ káwọn tó wà nípàdé náà tún mọ̀ pé nǹkan tún ti yàtọ̀ báyìí, mo ní: “Ní báyìí, ẹ tiẹ̀ lè rí ìdáhùn náà lọ́fẹ̀ẹ́ tẹ́ ẹ bá ka ìwé ìròyìn náà.”

Ìgbésí Ayé Tó Nítumọ̀ Tó sì Tẹ́ni Lọ́rùn

Lẹ́yìn tí ìyàwó mi ti fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, a ṣe ètò ọlọ́dún márùn-ún fún èmi náà. Mo dọ́gbọ́n wádìí láwọn ilé iṣẹ́ míì tí ìjọba ń lò bóyá wọ́n lè jẹ́ kí n máa ṣàbọ̀ṣẹ́ torí mo fẹ́ máa lo àkókò púpọ̀ sí i láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Bíbélì. Ó yà mí lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n gbà mí láyè láti dín iye wákàtí tí mo fi ń ṣiṣẹ́ kù níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́. Lọ́dún 1998, èmi náà di aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

Láàárọ́ ọjọ́ kan, bémi àti ìyàwó mi ṣe ń múra láti lọ wàásù, wọ́n pè mí láti ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, New York lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Wọ́n ti fìgbà kan wádìí nípa àwọn tó ní àkànṣe iṣẹ́ ọwọ́ kan tí wọ́n sì máa fẹ́ wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì, torí náà ẹni tó pè mí béèrè bóyá màá fẹ́ láti wá ṣiṣẹ́ kan ní Brooklyn. Tọkàntọkàn ni mo fi sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Kò sì pẹ́ sígbà yẹn la lọ ṣiṣẹ́ ní oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn fún ọdún kan ààbọ̀. Nígbà tó yá mo ní láti fiṣẹ́ tí mò ń ṣe lọ́dọ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ California sílẹ̀ kí n lè ráyè parí iṣẹ́ tí mò ń ṣe ní oríléeṣẹ́ wa. Lẹ́yìn tá a parí iṣẹ́ yẹn, a yọ̀ǹda ara wa láti lọ ran àwọn tó ń kọ́ Gbọ̀ngàn Àpéjọ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè Fairfield, ní ìpínlẹ̀ California lọ́wọ́. A ta ilé wa tó wà ní Sacramento, a sì kó lọ sílé tó kéré síyẹn ní Palo Alto. Bí mo ṣe fiṣẹ́ sílẹ̀ ṣáájú àkókò jẹ́ ká rí ọ̀pọ̀ ìbùkún Jèhófà láyé wa. Látìgbà tí mo ti fiṣẹ́ sílẹ̀, a ti lọ ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Nàìjíríà, South Africa, Kánádà, Britain àti Jámánì.

Bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ràn wá lọ́wọ́, ṣìnkìn ni inú èmi àti ìyàwó mi máa ń dùn tá a bá rántí àwọn tá a ti kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Bíbélì. Ká sòótọ́, ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà ló ṣe mí láǹfààní jù lọ nínú gbogbo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí mo gbà. Kò sí ètò ẹ̀kọ́ tó kún rẹ́rẹ́ tó sì ń kọ́ni ní òtítọ́ nípa ìgbésí ayé bí èyí. Jèhófà ti kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Bíbélì lọ́nà tó máa gbà wọ̀ wọ́n lọ́kàn, tá á sì yí ìrònú wọn pa dà. Ohun tó jẹ́ kí n ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ nìyẹn. Èmi àti ìyàwó mi dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà fún ìgbésí ayé tá à ń gbádùn báyìí àti àǹfààní tó fún wa láti lo ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tá a ní láti sin Jèhófà Ọlọ́run, ọba aláṣẹ àgbáyé.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ló wú mi lórí jù lọ nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Èmi àti Patricia rèé lọ́jọ́ ìgbéyawó wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Inú wa máa ń dùn láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Bíbélì