Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àpẹẹrẹ Àtàtà Tó Yẹ Ká Fara Wé ni Jésù

Àpẹẹrẹ Àtàtà Tó Yẹ Ká Fara Wé ni Jésù

Àpẹẹrẹ Àtàtà Tó Yẹ Ká Fara Wé ni Jésù

ṢÓ O fẹ́ káyé ẹ dáa, kó o sì máa láyọ̀? Àpọ́sítélì Pétérù ṣàlàyé bá a ṣe lè ṣe é. Ó kọ̀wé pé: “Kristi . . . jìyà fún yín, ó fi àwòkọ́ṣe sílẹ̀ fún yín kí ẹ lè tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ rẹ̀ pẹ́kípẹ́kí.” (1 Pétérù 2:21) Láìsí àníàní, torí pé bí Jésù Kristi ṣe lo ìgbésí ayé ẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀, ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun tá a lè kẹ́kọ̀ọ́ lára rẹ̀. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù, tá a sì ń fara wé e, ó dájú pé ayé wa máa dáa, a sì máa láyọ̀. Ẹ jẹ́ ká wá ṣàyẹ̀wò àwọn ànímọ́ tí ọkùnrin títóbi lọ́lá yìí ní fínnífínní, ká sì wo bí fífara wé e ṣe lè ṣe wá láǹfààní.

Jésù gbé ìgbésí ayé tó wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù sọ pé òun ò ní “ibi kankan láti gbé orí” òun lé, kì í wá ṣe pé ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìgbádùn du ara ẹ̀ tàbí kó wá ní káwọn èèyàn máa gbé irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀. (Mátíù 8:20) Ó lọ síbi ayẹyẹ. (Lúùkù 5:29) Bí Bíbélì ṣe ròyìn rẹ̀, iṣẹ́ ìyanu àkọ́kọ́ tí Jésù ṣe, ìyẹn sísọ tó sọ omi di ògidì wáìnì níbi ìgbéyàwó kan jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe ẹni tó máa ń ya ara ẹ̀ láṣo tàbí ẹni tó máa ń fìgbádùn du ara ẹ̀. (Jòhánù 2:1-11) Síbẹ̀, Jésù jẹ́ ká mọ ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nígbèésí ayé rẹ̀. Ó sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 4:34.

Ṣó o ti ṣàyẹ̀wò ìgbésí ayé ẹ dáadáa láti mọ bó o ṣe lè wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì nípa tara àti nípa tẹ̀mí?

Jésù ṣe é sún mọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó lọ́yàyà tó sì dùn ún bá rìn ni Jésù. Kì í bínú táwọn èèyàn bá gbé àwọn ìṣòro wọn wá sọ́dọ̀ ẹ̀ tàbí tí wọ́n bi í láwọn ìbéèrè tó ń pinni lẹ́mìí. Lọ́jọ́ kan táwọn èrò yí Jésù ká, obìnrin kan tó ti ń ṣàìsàn fún ọdún méjìlá [12] fọwọ́ kan aṣọ ẹ̀ kó lè rí ìwòsàn. Kàkà kí Jésù láálí obìnrin yẹn torí ìwà ọ̀yájú làwọn míì máa ka ohun tó ṣe yẹn sí, ńṣe ló fohùn jẹ́jẹ́ sọ fún un pé: “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.” (Máàkù 5:25-34) Ọkàn àwọn ọmọdé pàápàá máa ń balẹ̀ tí wọ́n bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀, wọn ò bẹ̀rù pé kò ní rí tàwọn rò. (Máàkù 10:13-16) Ó máa ń túra ká tó bá ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, kì í sì í fọ̀rọ̀ bò fún wọn. Ẹ̀rù ò sì ba àwọn náà láti sún mọ́ ọn.—Máàkù 6:30-32.

Ṣó rọrùn fáwọn èèyàn láti sún mọ́ ìwọ náà?

Ó máa ń ṣàánú àwọn èèyàn. Ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Jésù tó ta yọ jù lọ ni bó ṣe máa ń fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn rora ẹ̀ wò, tó sì máa ń fẹ́ ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Àpọ́sítélì Jòhánù sọ pé nígbà tí Jésù rí Màríà tó ń sunkún nítorí àbúrò rẹ̀ tó kú, Jésù “kérora nínú ẹ̀mí, ó sì dààmú,” ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí da omijé.” Àwọn tó ń rí Jésù á ti mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ ìdílé yẹn gan-an, ìfẹ́ yìí sì jinlẹ̀ débi pé ojú ò tì í láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀. Ẹ ò rí i pé àánú tí Jésù ní ló jẹ́ kó jí ọ̀rẹ́ rẹ̀ dìde!—Jòhánù 11:33-44.

Ìgbà kan tún wà tí ọkùnrin kan tí ò lè gbé láàárín ìlú nítorí àrùn ẹ̀tẹ̀ tó ní bẹ Jésù pé: “Olúwa, bí ìwọ bá sáà ti fẹ́ bẹ́ẹ̀, ìwọ lè mú kí èmi mọ́.” Bí Jésù ṣe dáhùn tù ú lára gan-an, Bíbélì sọ pé: “Ní nína ọwọ́ rẹ̀, ó fọwọ́ kàn án, ó wí pé: ‘Mo fẹ́ bẹ́ẹ̀. Kí ìwọ mọ́.’” (Mátíù 8:2, 3) Kì í ṣe torí àtimú àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ nìkan ni Jésù ṣe ń wo àwọn èèyàn sàn. Ó fẹ́ sọ ẹkún wọn dayọ̀ ni. Gbogbo ohun tí Jésù máa ń ṣe bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ tá a sábà máa ń rántí dáadáa mu, ohun tó sọ ni pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, ẹ máa ṣe bákan náà sí wọn.”—Lúùkù 6:31.

Ṣé ìwà ẹ máa ń fi hàn pé lóòótọ́ lo láàánú àwọn èèyàn lójú?

Jésù máa ń lóye àwọn èèyàn, ó sì máa ń fòye mọ tinú wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ò dẹ́ṣẹ̀ kankan, kò retí pé káwọn míì jẹ́ ẹni pípé tàbí kó máa ṣe bí ẹni tó sàn ju àwọn ẹlòmíì lọ, ó sì máa ń lóye ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an kó tó ṣe ohunkóhun nípa ọ̀ràn kan. Nígbà kan, obìnrin kan táwọn èèyàn “mọ̀ sí ẹlẹ́ṣẹ̀” fi hàn pé òun nígbàgbọ́ nínú Jésù, ó sì fi ìmoore hàn nípa fífi omijé ojú rẹ̀ nu ẹsẹ̀ Jésù. Jésù ò lé e dà nù, ìyẹn sì ya ẹni tó gba Jésù lálejò lẹ́nu gan-an, torí pé ó ti dá obìnrin náà lẹ́bi nínú ọkàn rẹ̀. Àmọ́, torí Jésù mọ̀ pé ohun tí obìnrin náà ń ṣe ti ọkàn rẹ̀ wá, kò dá a lẹ́bi nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀ ó sọ fun un pé: “Ìgbàgbọ́ rẹ ti gbà ọ́ là; máa bá ọ̀nà rẹ lọ ní àlàáfíà.” Torí pé Jésù ò jágbe mọ́ obìnrin náà, ó ṣeé ṣe kíyẹn ti mú kí obìnrin náà fi ẹ̀ṣẹ̀ tó ń dá tẹ́lẹ̀ sílẹ̀.—Lúùkù 7:37-50.

Ṣẹ́ni tó máa ń tètè gbóríyìn fúnni làwọn èèyàn mọ̀ ẹ́ sí àbí ẹni tó máa ń yára bẹnu àtẹ́ luni?

Kì í ṣojúsàájú, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn. Jésù nífẹ̀ẹ́ Jòhánù ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ bóyá torí pé wọ́n mọwọ́ ara wọn àti pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé mọ̀lẹ́bí ni wọ́n. a Síbẹ̀, ìyẹn ò sọ pé kó máa ṣojúsàájú tàbí kó máa ṣojú rere sí i ju àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kù lọ. (Jòhánù 13:23) Kódà, nígbà tí Jòhánù àti ọmọ ìyá rẹ̀ Jákọ́bù, béèrè fún ipò tó dáa jù lọ nínú Ìjọba Ọlọ́run, Jésù sọ fún wọn pé: “Jíjókòó yìí ní ọ̀tún mi tàbí ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni.”—Máàkù 10:35-40.

Kò sígbà tí Jésù kì í fọ̀wọ̀ àwọn èèyàn wọ̀ wọ́n. Kì í ṣe ẹ̀tanú sáwọn èèyàn báwọn kan ṣe máa ń ṣe nígbà tó wà láyé. Bí àpẹẹrẹ, ojú yẹpẹrẹ làwọn ọkùnrin fi máa ń wo àwọn obìnrin. Síbẹ̀ Jésù buyì tó tọ́ fáwọn obìnrin. Ìgbà tí Jésù máa kọ́kọ́ sọ fáwọn èèyàn pé òun ni Mèsáyà, obìnrin ará Samáríà tí kì í tiẹ̀ ṣe Júù ni Jésù sọ fún, bẹ́ẹ̀ àwọn Júù kórìíra àwọn ará Samáríà, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ pé wọ́n máa kí wọn. (Jòhánù 4:7-26) Nígbà tí Jésù sì jíǹde àwọn obìnrin ló tún fún láǹfààní láti jẹ́ kó kọ́kọ́ rí òun.—Mátíù 28:9, 10.

Ṣó o kì í ṣojúsàájú tí nǹkan bá dà ẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ ẹ̀yà míì, tí wọ́n ń sọ èdè tó yàtọ̀ sí tìẹ, tí wọn kì í ṣe ọkùnrin tàbí obìnrin bíi tìẹ tàbí tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè míì?

Ó ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmọ àti ẹ̀gbọ́n. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Jósẹ́fù, alágbàtọ́ Jésù ti kú nígbà tí Jésù ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé iṣẹ́ káfíńtà ni Jésù ń ṣe kó lè máa gbọ́ bùkátà ìyá rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀. (Máàkù 6:3) Nígbà tó fẹ́ gbẹ́mìí mì, ó fa ìyá rẹ̀ lé Jòhánù ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ́wọ́ kíyẹn lè máa bójú tó o.—Jòhánù 19:26, 27.

Ṣó o lè fara wé Jésù nípa bíbójútó ojúṣe ẹ nínú ìdílé gẹ́gẹ́ bó ṣe yẹ?

Ọ̀rẹ́ àtàtà ni Jésù. Àwọn ọ̀rẹ́ Jésù mọ̀ pé kò sẹ́lẹgbẹ́ ẹ̀. Lọ́nà wo? Kò pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tì kìkì nítorí pé wọ́n ṣàṣìṣe, kò sì pa wọ́n tì kódà nígbà tí wọ́n ń ṣàṣìṣe kan náà léraléra. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ kì í sábà ṣe ohun tó dùn mọ́ ọn nínú. Àmọ́ ó fi hàn pé ọ̀rẹ́ àtàtà lòun nípa wíwo àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní dípò táá fi máa ronú pé èèyàn burúkú ni wọ́n. (Máàkù 9:33-35; Lúùkù 22:24-27) Kì í fi tipátipá sọ pé kí wọ́n gba èrò tòun, kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń fún wọn láyè láti sọ tinú wọn.—Mátíù 16:13-15.

Lékè gbogbo ẹ̀, Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀. (Jòhánù 13:1) Báwo ló ṣe nífẹ̀ẹ́ wọn tó? Ó sọ pé: “Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó tóbi ju èyí lọ, pé kí ẹnì kan fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.” (Jòhánù 15:13) Ṣé nǹkan míì tún wá tó ṣeyebíye tẹ́nì kan lè fún àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ ju ẹ̀mí òun fúnra ẹ̀ lọ?

Ṣó o kì í pa àwọn ọ̀rẹ́ rẹ tì kódà nígbà tí wọ́n bá ṣohun tó dùn ẹ́ tí wọ́n sì múnú bí ẹ?

Ó nígboyà, ó sì máa ń ṣọkàn akin. Jésù yàtọ̀ pátápátá sí àwòrán ọkùnrin aláàárẹ̀ tí kò lókun nínú táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì fi máa ń ṣàpèjúwe rẹ̀. Àwọn Ìwé Ìhìn Rere ṣàpèjúwe Jésù gẹ́gẹ́ bí akọni ọkùnrin. Ẹ̀ẹ̀méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù lé àwọn oníṣòwò jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. (Máàkù 11:15-17; Jòhánù 2:14-17) Nígbà táwọn jàǹdùkú kan wá mú “Jésù ará Násárétì,” ẹ̀rù ò bà á láti yọjú sí wọn kó lè dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. Ó fìgboyà sọ pé: “Èmi ni ẹni náà. Nítorí náà, bí ó bá jẹ́ pé èmi ni ẹ ń wá, ẹ jẹ́ kí àwọn wọ̀nyí máa lọ.” (Jòhánù 18:4-9) Abájọ tó fi jẹ́ pé nígbà tí Pọ́ńtù Pílátù rí bí Jésù ṣe ṣọkàn akin nígbà tí wọ́n fàṣẹ ọba mú un tí wọ́n sì ń fìyà jẹ ẹ́, ó sọ pé: “Wò ó! Ọkùnrin náà!”—Jòhánù 19:4, 5.

Ṣó o máa ń ṣọkàn akin tó o sì máa ń fìgboyà ṣohun tó tọ́ nígbà tó bá yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀?

Àwọn ànímọ́ tó ta yọ yìí àtàwọn míì ló jẹ́ kí Jésù jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà tó yẹ ká fara wé. Tá a bá jẹ́ kí ìwà rẹ̀ nípa lórí wa, ayé wa máa dáa, a sì máa jẹ́ aláyọ̀. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pétérù fi rọ àwa Kristẹni pé ká máa tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí. Ṣó o máa ń sapá láti fara wé Jésù bó bá ti lè ṣeé ṣe tó?

Ó Kọjá Ẹni Tá A Kàn Lè Fara Wé

Jésù kọjá ẹni tá a kàn máa fara wé. Ó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Yàtọ̀ sí pé Jésù jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, tíyẹn sì ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wa láti sún mọ́ Ọlọ́run, ó tún jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn olóòótọ́ láti jogún ìyè.—Jòhánù 3:16.

Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé ìdí tóun fi wá sáyé, ó sọ pé: “Ọmọ ènìyàn ti wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́, kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Bí Jésù ṣe fi ẹ̀mí ara rẹ̀ rúbọ jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn láti gbádùn ìyè ayérayé. Kí lẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní láti ṣe ká lè jàǹfààní nínú ìràpadà yẹn. Jésù ṣàlàyé pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.

Ó dájú pé gbígba ìmọ̀ nípa Jésù sínú, fífara wé ọ̀nà tó gbà gbé ìgbé ayé ẹ̀ àti lílo ìgbàgbọ́ nínú ikú ìrúbọ tó kú ni Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa ká tó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun. A rọ̀ ẹ́ pé kó o wáyè láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ orísun irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀, kó o sì sapá láti máa fi ohun tó o bá kọ́ sílò, bí Jésù ti ṣe. b

Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé ẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa, ó sì jẹ́ ká mọ irú èèyàn tó yẹ káwa náà jẹ́. Ikú ìrúbọ ẹ̀ lè gbà wá lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tí ẹ̀ṣẹ̀ fà. (Róòmù 6:23) Ẹ wo bí nǹkan ì bá ti burú tó fún wa ká ní kò sí ipa ribiribi tí Jésù Kristi kó nítorí wa! Má ṣe jẹ́ kí kòókòó jàn-ánjàn-án ìgbésí ayé yìí dí ẹ lọ́wọ́ débi tó ò fi ní ráyè ronú nípa Jésù Kristi, kó o sì fara wé ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọmọ ìyá kan náà ni Sàlómẹ̀, ìyá Jòhánù àti Màríà, ìyá Jésù. Fi wé Mátíù 27:55, 56 pẹ̀lú Máàkù 15:40 àti Jòhánù 19:25.

b Tó o bá fẹ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa ìtàn ìgbésí ayé Jésù, wo ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

◼ Jésù kì í ṣojúsàájú, ó sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn

◼ Ọ̀rẹ́ àtàtà ni kódà títí dójú ikú

◼ Ó nígboyà

Ṣó o máa ń sapá láti fara wé Jésù bó bá ti lè ṣeé ṣe tó?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Jésù wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì . . .

ó ṣe é sún mọ́ . . .

ó máa ń ṣàánú àwọn èèyàn