Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Maya Rí Òmìnira Tòótọ́ Gbà

Àwọn Maya Rí Òmìnira Tòótọ́ Gbà

Àwọn Maya Rí Òmìnira Tòótọ́ Gbà

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló mọ àwọn Maya nítorí àwọn àṣeyọrí tí wọ́n ṣe láyé àtijọ́. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn arìnrìn-àjò ló máa ń lọ sílùú Yucatán lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò lọ́dọọdún láti lọ wo àwọn ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó wà níbẹ̀, bí irú èyí tó wà ní Chichén Itzá àti Cobá. Kì í ṣe ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ ẹ̀rọ nìkan lọ̀pọ̀ èèyàn mọ àwọn Maya sí, wọ́n tún mọ̀ pé tó bá dọ̀rọ̀ ìwé kíkọ, ìmọ̀ ìṣirò àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà, ọ̀gá ni wọ́n. Àwọn ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwòrán sọ̀rọ̀, àwọn ló kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lo oódo nínú ìmọ̀ ìṣirò, àwọn ló sì kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í lo kàlẹ́ńdà tó ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti márùndínláàádọ́rin [365] ọjọ́ lórí, tó sì ní àwọn àtúnṣe bí irú toṣù February tó máa ń ní ọjọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [29] lọ́dún mẹ́rinmẹ́rin.

Àmọ́, ohun táwọn Maya máa ń ṣe tó bá dọ̀rọ̀ ẹ̀sìn yàtọ̀ pátápátá. Abọ̀rìṣà pọ́ńbélé ni wọ́n, lára àwọn òrìṣà tí wọ́n sì máa ń bọ ni àwọn ọlọ́run oòrùn, òṣùpá, òjò àti àgbàdo. Awòràwọ̀ paraku làwọn àlùfáà wọn. Díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe tí wọ́n bá ń jọ́sìn ni pé wọ́n má ń fín tùràrí, ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn máa ń dọ́gbẹ́ síra ẹ̀ lára, wọ́n máa ń tàjẹ̀ sílẹ̀, wọ́n sì máa ń fèèyàn rúbọ, pàápàá àwọn ọmọdé, àwọn ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn ẹrú.

Nígbà Táwọn Ará Sípéènì Dé

Ọ̀làjú tó ti fẹjú làwọn ará Sípéènì dé bá lọ́dọ̀ àwọn Maya níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún kẹrìndínlógún. Nǹkan méjì làwọn arìnrìn-àjò ará Sípéènì wọ̀nyí fi ṣe àfojúsùn wọn, àkọ́kọ́ ni pé wọ́n fẹ́ gbalẹ̀ kí wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fúnra wọn, ìkejì sì ni pé wọ́n fẹ́ sọ àwọn Maya wọ̀nyí di ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, kí wọ́n lè sọ wọ́n dòmìnira kúrò lọ́wọ́ àṣà àwọn kèfèrí. Ṣé òmìnira ẹ̀sìn tàbí oríṣi òmìnira míì tẹ àwọn Maya lọ́wọ́ lóòótọ́ lẹ́yìn táwọn ará Sípéènì gbàjọba mọ́ wọn lọ́wọ́?

Àwọn ará Sípéènì àtàwọn àlùfáà Kátólíìkì gba ilẹ̀ táwọn Maya ti máa ń pagbó tí wọ́n sì ti máa ń sunko látọdúnmọ́dún kí wọ́n lè fi ṣọ̀gbìn. Ìyà kékeré kọ́ lohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fi jẹ àwọn Maya, ìnira tó sì mú bá wọn ò kéré rárá. Àwọn ará Sípéènì wọ̀nyí tún gba àwọn kànga tó jẹ́ orísun omi tó wà nílùú Yucatán mọ́ àwọn Maya lọ́wọ́. Ìnira yẹn tún pọ̀ sí i nígbà tí ṣọ́ọ̀ṣì tún wá ní káwọn Maya máa sanwó orí lọ́dọọdún, wọ́n ní káwọn ọkùnrin máa san ríìlì a méjìlá àtààbọ̀, káwọn obìnrin sì máa san ríìlì mẹ́sàn láfikún sí owó orí tíjọba ń gbà lọ́wọ́ wọn. Àwọn ará Sípéènì tó nílẹ̀ níbẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ́ àwọn Maya wọ̀nyẹn jẹ, wọ́n gbà láti máa bá wọn sanwó orí tí ṣọ́ọ̀ṣì ní kí wọ́n máa san, wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí í fipá mú wọn ṣiṣẹ́ kí wọ́n lè san gbèsè tí wọ́n jẹ, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ àwọn Maya dẹrú.

Àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọ̀nyẹn tún máa ń gbowó fún àwọn ààtò ìsìn tí wọ́n bá ṣe irú bí ìrìbọmi, ìgbéyàwó àti ìsìnkú. Owó àwọn Maya ni ṣọ́ọ̀ṣì fi ń sọra rẹ̀ di ọlọ́rọ̀ torí pé wọ́n ń gba ilẹ̀, wọ́n ń gbowó orí, àtàwọn owó pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì lọ́wọ́ wọn. Wọ́n gbà pé onígbàgbọ́ nínú ohun asán àtàwọn tí ò lè dákan mọ̀ làwọn Maya. Torí náà àwọn àlùfáà àtàwọn yòókù gbà pé kò sóhun tó burú táwọn bá ń na àwọn Maya lẹ́gba láti bá wọn wí, kí wọ́n lè kọ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán sílẹ̀.

Àwọn Maya Gbógun Dìde

Ohun táwọn Maya kọ́kọ́ ṣe láti fi gbèjà ara wọn ni pé, wọ́n kọ̀ láti máa sanwó orí tí ṣọ́ọ̀ṣì ń gbà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mú àwọn ọmọ wọn kúrò láwọn iléèwé àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n kọ̀ láti máa lọ síbi tí wọ́n ti ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ katikísìmù, wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ láti máa lọ ṣiṣẹ́ oko. Àmọ́ ńṣe nìyẹn túbọ̀ jẹ́ kí wọ́n máa fìyà jẹ wọ́n. Lẹ́yìn táwọn ará Sípéènì ti jẹ gàba lé wọn lórí fún nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ọdún, gọngọ sọ lọ́dún 1847. Àwọn Maya gbógun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà dìde sáwọn ará Sípéènì.

Àwọn tó ń múpò iwájú nínú ìdìtẹ̀ yẹn fi àmì ìjọsìn kan tí wọ́n pè ní Àgbélébùú Tó Ń Sọ̀rọ̀ ru àwọn èèyàn sókè láti jà, àgbélébùú yìí làwọn tó máa ń sọ̀rọ̀ bí ọ̀sanyìn fi máa ń sọ fáwọn Maya pé ìjà àjàkú akátá ni kí wọ́n jà. Àjálù ńlá ni ogun yìí jẹ́ fáwọn Maya. Nígbà tógun náà fi máa parí lọ́dún 1853, nǹkan bí ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá àwọn Maya tó ń gbé nílùú Yucatán ló ti bógun lọ. Síbẹ̀, gbúngbùngbún àtàwọn ogun abẹ́lé ò kásẹ̀ nílẹ̀ fún odindi ọdún márùndínlọ́gọ́ta [55]. Àmọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn Maya gbara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Sípéènì, wọ́n sì wá ṣètò láti máa pín ilẹ̀ láì ṣojúsàájú. Òmìnira ẹ̀sìn wá ńkọ́?

Kò Sí Òmìnira Tòótọ́

Ìsìn Kátólíìkì táwọn ará Sípéènì tó jẹ gàba lé wọn lórí mú wá àti Ogun Kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà táwọn Maya jà kò fún wọn lómìnira tòótọ́. Ẹ̀sìn kan tó ń ṣe àmúlùmálà àṣà àwọn ará Sípéènì àtijọ́ àti àṣà ẹ̀sìn Kátólíìkì ti ìlú Róòmù ló wà níbẹ̀ báyìí.

Nígbà tí ìwé kan tó dá lórí bí ọ̀làjú ṣe dé sáàárín àwọn Maya, ìyẹn The Mayas—3000 Years of Civilization, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn Maya òde òní, ó ní: “Ìgbàgbọ́ ò ní ká má ṣorò ilé lọ̀rọ̀ àwọn Maya, wọ́n máa ń bọ àwọn òrìṣà àtayébáyé àtàwọn baba ńlá wọn lórí pápá gbalasa, nínú ihò ilẹ̀ àti lórí àwọn òkè . . . lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n ń jọ́sìn àwọn ẹni mímọ́ nínú ṣọ́ọ̀ṣì.” Torí náà, wọ́n gbà pé òrìṣà wọn tí wọ́n ń pè ní Quetzalcoatl tàbí Kukulcán dọ́gba pẹ̀lú Jésù, wọ́n sì gbà pé abo ọlọ́run oòrùn ni Màríà Wúńdíá. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n fi àgbélébùú rọ́pò igi ceiba mímọ́ tí wọ́n máa ń jọ́sìn, wọ́n sì máa ń bomi sórí àgbélébùú bíi pé igi tó wà láàyè ni. Dípò kí wọ́n gbé àwòrán Jésù sórí àwọn àgbélébùú báwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ṣe máa ń ṣe àwọn yẹtuyẹtu òdòdó igi ceiba ni wọ́n máa fi ń ṣe àgbélébùú wọn lọ́ṣọ̀ọ́.

Òmìnira Tòótọ́ Dé Nígbẹ̀yìngbẹ́yín!

Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ti bẹ̀rẹ̀ sí í fi taratara kọ́ àwọn Maya lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì fáwọn Maya lédè ìbílẹ̀ wọn, irú bí ìwé ìròyìn yìí, kí wọ́n lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún ìran èèyàn. Kí nìyẹn ti wá yọrí sí? Nígbà tá à ń kọ àpilẹ̀kọ yìí, àwọn Maya tó ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lédè ìbílẹ̀ wọn ti tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà [6,600], wọ́n sì ti dá ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó tó igba àti mọ́kànlélógójì [241] sílẹ̀ lágbègbè yẹn. Ṣó wá rọrùn fáwọn Maya láti kọ àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn sílẹ̀ kí wọ́n sì wá máa kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì?

Kò rọrùn rárá fún ọ̀pọ̀ àwọn tó jólóòótọ́ láàárín àwọn Maya. Marcelino àti Margarita ìyàwó ẹ̀ gbà pé ògbóǹkangí onísìn Kátólíìkì làwọn. Ọdọọdún ni wọ́n máa ń lọ júbà àgbélébùú, wọ́n máa ń gbé àgbélébùú yìí láti ṣọ́ọ̀ṣì lọ sílé wọn, tí wọ́n bá wá gbé e délé, wọ́n á pa ẹran láti fi rúbọ, wọ́n á sì jẹ ẹran tí wọ́n pa yẹn pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn. Nígbà tó yá làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n sọ pé: “A mọ̀ pé ẹ̀kọ́ òtítọ́ là ń kọ́ yìí, àmọ́ ẹ̀rù ń bà wá pé tá a bá lọ fi ẹ̀sìn tá à ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí èṣù á máa wá yọ wá lẹ́nu.” Àmọ́ wọn ò yé kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Marcelino sọ pé: “Díẹ̀díẹ̀ lẹ̀kọ́ òtítọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wọ̀ wá lọ́kàn. Ìyẹn ò sì jẹ́ ká bẹ̀rù mọ́ láti sọ àwọn nǹkan tá a ti kọ́ látinú Bíbélì fáwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ wa. Inú wa dùn gan-an báyìí pé a ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán tó ti sọ wá dẹrú tẹ́lẹ̀. Ohun tó kàn ń dùn wá ni pé a ò tètè bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. A fẹ́ rí i dájú pé a ṣiṣẹ́ kára láti dí gbogbo àkókó tá a ti fi ṣòfò yẹn nípa ṣíṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti sọ àwọn òtítọ́ àgbàyanu tó wà nínú Bíbélì fáwọn èèyàn.”

Tọkàntọkàn ni Alfonso, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rin [73] fi ń ṣe ìsìn Kátólíìkì. Ó máa ń ṣètò àwọn àjọ̀dún ìsìn nílùú ìbílẹ̀ rẹ̀, lára àwọn nǹkan tí wọ́n sì máa ń ṣe nígbà àjọ̀dún ìsìn náà ni pé wọ́n máa ń ṣe ayẹyẹ Máàsì, wọ́n máa ń jó, jíjẹ àti mímu sì máa ń wà níbẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá wá. Wọ́n sì tún máa ń fàwọn akọ màlúù jà níbẹ̀. Ó sọ pé: “Ọtí àmupara àti ìjà ló sábà máa ń gbẹ̀yìn àjọ̀dún yẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo máa ń gbádùn àwọn àjọ̀dún wọ̀nyẹn, mo mọ̀ lọ́kàn ara mi pé mò ń pàdánù nǹkan kan nínú ẹ̀sìn yẹn.” Alfonso gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fún un. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara ẹ̀ ti di hẹ́gẹhẹ̀gẹ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ní báyìí, ó ti fi gbogbo àwọn àṣà ẹ̀sìn tó ń ṣe tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, ó sì ti wá ń lo gbogbo àǹfààní tó bá ní láti máa sọ àwọn nǹkan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà gbọ́ fáwọn tó bá wá kí i nílé.

Àpẹẹrẹ díẹ̀ la mẹ́nu bà yìí lára ọ̀pọ̀ àwọn Maya tí wọ́n jólóòótọ́, tí wọ́n sì ti rí òmìnira ẹ̀sìn gbà lóòótọ́. Ó dá wa lójú pé ìran àwọn èèyàn tó kọ́ àwọn ilé aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tó wà ní Yucatán ṣì wà láàyè. Èdè wọn náà ni wọ́n ṣì ń sọ. Irú àwọn ilé táwọn baba ńlá wọn gbé lọ̀pọ̀ wọn ṣì ń gbé, ìyẹn àwọn ilé tí wọ́n kọ́ bí àtíbàbà tí wọ́n fi imọ̀ ọ̀pẹ ṣe ògiri àti òrùlé wọn, tí wọ́n sì wá fi amọ̀ rẹ́ ògiri ẹ̀. Wọ́n ṣì ń ṣọ̀gbìn àgbàdo àti òwú, wọ́n ṣì máa ń pagbó, wọ́n sì máa ń sunko kí wọ́n tó ṣọ̀gbìn. Àmọ́ ní báyìí, òótọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti sọ ọ̀pọ̀ àwọn Maya dòmìnira kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹ̀kọ́ èké táwọn onísìn ń kọ́ wọn àti ìgbàgbọ́ nínú ohun asán. Wọ́n mọyì òótọ́ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:32.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ríìlì lorúkọ owó táwọn ará Sípéènì ń ná tẹ́lẹ̀.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn àgbègbè táṣà àwọn Maya ayé àtijọ́ tàn dé

Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Mẹ́síkò

MẸ́SÍKÒ

Ìlú Yucatán

Chichén Itzá

Cobá

BELIZE

GUATEMALA

HONDURAS

EL SALVADOR

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Àwókù ìlú Chichén Itzá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Marcelino àti Margarita ìyàwó ẹ̀ ń wàásù ìhìn rere ní Yucatán