Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdí Tí Dáfídì Ò Fi Bẹ̀rù

Ìdí Tí Dáfídì Ò Fi Bẹ̀rù

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ìdí Tí Dáfídì Ò Fi Bẹ̀rù

ṢÉ Ẹ̀RÙ ti bà ẹ́ rí?— a Ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ̀rù máa ń bà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kí lo lè ṣe tẹ́rù bá ń bà ẹ́?— O lè sá lọ sọ́dọ̀ ẹnì kan tó jù ẹ́ lọ tó sì lágbára jù ẹ́ lọ. Ó tiẹ̀ lè jẹ́ ọ̀dọ̀ dádì tàbí mọ́mì ẹ lo máa sá lọ. A lè rí ẹ̀kọ́ púpọ̀ kọ́ lára Dáfídì nípa ọ̀dọ̀ ẹni tó yẹ ká wá ìrànlọ́wọ́ lọ. Ó kọrin sí Ọlọ́run pé: “Èmi, ní tèmi, yóò gbẹ́kẹ̀ lé ìwọ gan-an. . . . Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé; àyà kì yóò fò mí.”—Sáàmù 56:3, 4.

Ọ̀dọ̀ ta lo rò pé Dáfídì ti kẹ́kọ̀ọ́ láti má máa bẹ̀rù? Ṣé látọ̀dọ̀ àwọn òbí ẹ̀ ni?— Látọ̀dọ̀ wọn náà ni. Olóòótọ́ èèyàn ni Jésè, tó jẹ́ bàbá Dáfídì, ó sì tún jẹ́ baba ńlá Jésù Kristi, “Ọmọ Aládé Àlàáfíà” tí Ọlọ́run ṣèlérí. (Aísáyà 9:6; 11:1-3, 10) Óbédì ni bàbá Jésè, ìyẹn sì túmọ̀ sí pé òun ló bí bàbá Dáfídì. Ìwé kan wà nínú Bíbélì tá à ń fi orúkọ ìyá Óbédì pè. Ṣó o mọ orúkọ ìyá Óbédì?— Rúùtù ni, òun ni ìyàwó Bóásì, ó sì ń fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run.—Rúùtù 4:21, 22.

Kò sí àníàní pé Rúùtù àti Bóásì ti kú tipẹ́tipẹ́ kí wọ́n tó bí Dáfídì. Ó ṣeé ṣe kó o mọ orúkọ ìyá Bóásì, ìyẹn ìyá ńlá Dáfídì. Ìlú Jẹ́ríkò ló ń gbé nígbà yẹn, ó sì dáàbò bo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wá ṣe amí nílùú náà. Ó so okùn pupa kan mọ́ ojú fèrèsé, ìyẹn ló sì fi dáàbò bo ìdílé ẹ̀ nígbà tí odi Jẹ́ríkò fẹ́ wó. Kí lorúkọ obìnrin yẹn?— Ráhábù ni. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà, ó sì wá di àpẹẹrẹ rere tó yẹ káwa Kristẹni máa fara wé tó bá dọ̀rọ̀ ìgboyà.—Jóṣúà 2:1-21; 6:22-25; Hébérù 11:30, 31.

Ó dájú pé àwọn òbí Dáfídì ló kọ́ ọ láwọn nǹkan tó mọ̀ nípa àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà wọ̀nyẹn torí Ọlọ́run ti pàṣẹ fáwọn òbí láti máa kọ́ àwọn ọmọ wọn nírú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. (Diutarónómì 6:4-9) Nígbà tí àkókò tó, Ọlọ́run darí Sámúẹ́lì wòlíì rẹ̀ láti yan Dáfídì, tó jẹ́ ọmọkùnrin tó kéré jù lọ tí Jésè bí, láti jọba ní Ísírẹ́lì.—1 Sámúẹ́lì 16: 4-13.

Lọ́jọ́ kan, Jésè ní kí Dáfídì gbé oúnjẹ lọ fáwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ mẹ́ta, tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin, níbi tí wọ́n ti ń bá àwọn ará Filísínì, ọ̀tá Ọlọ́run jà. Nígbà tí Dáfídì débẹ̀, ó gbọ́ tí òmìrán kan tó ń jẹ́ Gòláyátì ń ṣáátá “àwọn [ọmọ] ogun Ọlọ́run alààyè.” Ẹ̀rù ń ba gbogbo wọn láti bá Gòláyátì jà. Sọ́ọ̀lù Ọba gbọ́ pé Dáfídì fẹ́ láti lọ gbéjà ko Gòláyátì, torí náà ó ní kí wọ́n lọ pè é wá fóun. Àmọ́, nígbà tí Sọ́ọ̀lù rí Dáfídì, ó sọ fún un pé: “Ọmọdékùnrin lásán-làsàn ni ọ.”

Dáfídì wá ṣàlàyé fún Sọ́ọ̀lù pé òun ti pa kìnnìún àti béárì kan tó fẹ́ pa àgùntàn àwọn rí. Ó wá sọ fún Sọ́ọ̀lù pé Gòláyátì máa “dà bí ọ̀kan nínú” àwọn ẹranko búburú tóun ti pa wọ̀nyẹn. Sọ́ọ̀lù wá sọ fún Dáfídì pé: “Máa lọ, kí Jèhófà fúnra rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ.” Dáfídì wá lọ ṣa òkúta márùn-ún tó jọ̀lọ̀ dáadáa, ó kó o sínú àpò tó máa ń gbé dání tó bá ń lọ ṣọ́ àwọn àgùntàn, ó sì mú kànnàkànnà rẹ̀ dání láti lọ bá òmìrán náà jà. Nígbà tí Gòláyátì rí i pé Dáfídì, tó jẹ́ ọmọ kékeré ló ń bọ̀ láti wá bá òun jà, ó kígbe pé: “Sáà máa bọ̀ lọ́dọ̀ mi, dájúdájú, èmi yóò sì fi ẹran ara rẹ fún àwọn [ẹyẹ].” Dáfídì fèsì pé: “Èmi ń bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà,” ó wá pariwo pé: “Dájúdájú, èmi yóò sì ṣá ọ balẹ̀.”

Dáfídì bá sáré lọ sọ́dọ̀ Gòláyátì, ó mú òkúta kan nínú àpò rẹ̀, ó sì fi sínú kànnàkànnà rẹ̀, bó ṣe ta á báyìí, ńṣe ló wọnú agbárí Gòláyátì lọ. Nígbà táwọn ará Filísínì rí i pé òmìrán yẹn ti kú, ẹ̀rù bà wọ́n, gbogbo wọn sì fẹsẹ̀ fẹ. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbá tẹ̀ lé wọn, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Ẹ ò ṣe kúkú ka ìtàn yìí pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé, bó ṣe wà nínú ìwé 1 Sámúẹ́lì 17:12-54.

Torí pé ọ̀dọ́ ni ẹ́, ẹ̀rù lè máa bà ẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan láti ṣègbọràn sáwọn àṣẹ Ọlọ́run. Ọ̀dọ́ ni Jeremáyà náà, ẹ̀rù sì kọ́kọ́ bà á, àmọ́ Ọlọ́run sọ fún un pé: “Má fòyà . . . nítorí ‘mo wà pẹ̀lú rẹ.’” Jeremáyà wá nígboyà, ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù bí Ọlọ́run ṣe sọ fún un. Bíi ti Dáfídì àti Jeremáyà, tí ìwọ náà bá gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹ̀rù ò ní máa bà ẹ́.—Jeremáyà 1:6-8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó o bá ń ka àpilẹ̀kọ yìí fáwọn ọmọdé, àmì (—) tó wà lẹ́yìn àwọn ìbéèrè kan ń rán ẹ létí pé kó o dánu dúró, kó o sì bi wọ́n láwọn ìbéèrè náà.

Ìbéèrè:

○ Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tí Gòláyátì ń ṣáátá àwọn ọmọ ogun Ọlọ́run?

○ Báwo ni Dáfídì ṣe ṣẹ́gun Gòláyátì?

○ Báwo làwa náà ṣe lè kọ́ láti má máa bẹ̀rù?