Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Májẹ̀mú Láéláé Gbọ́?

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Májẹ̀mú Láéláé Gbọ́?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Gba Májẹ̀mú Láéláé Gbọ́?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, wọ́n sì gbà pé Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun ṣe pàtàkì. Àmọ́, ó rọ̀ wọ́n lọ́rùn láti máa pe àwọn apá méjèèjì wọ̀nyí lọ́nà tó túbọ̀ bá a mu, ìyẹn “Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù” àti “Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì” torí pé àwọn èdè wọ̀nyẹn ni wọ́n fi kọ wọ́n látilẹ̀ wá.

Àmọ́ ṣá o, àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni kan máa ń lọ́ra láti gba àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Májẹ̀mú Láéláé gbọ́. Wọ́n ní ọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run òǹrorò kan tó fọwọ́ sógun, ìpànìyàn àtàwọn nǹkan burúkú míì ló wà níbẹ̀ ìyẹn sì yàtọ̀ sí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́, tó níwà rere tó wà nínú Májẹ̀mú Tuntun. Àwọn míì sì sọ pé torí pé ọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn àwọn Júù ló kúnnú Májẹ̀mú Láéláé, àwọn ò rò pó bá ẹ̀sìn Kristẹni mu. Àmọ́, tá a bá wo ọ̀rọ̀ yìí lójú ìwòye ohun tó wà nínú ìwé Diutarónómì 12:32 níbi tí Ọlọ́run fúnra ẹ̀ ti sọ pé a ò gbọ́dọ̀ fi kún ọ̀rọ̀ òun tàbí ká yọ kúrò níbẹ̀, ṣé a lè sọ pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn lẹ́sẹ̀-ńlẹ̀ tó láti mú ká pa nǹkan bí ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin Bíbélì tì?

Lọ́dún 50 Sànmánì Kristẹ́ni, nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù bẹ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Tẹsalóníkà wò lórílẹ̀ èdè Gíríìsì, “ó . . . bá wọn fèrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ́, ó ń ṣàlàyé, ó sì ń fi ẹ̀rí ìdánilójú hàn nípasẹ̀ àwọn ìtọ́ka pé ó pọndandan kí Kristi jìyà, kí ó sì dìde kúrò nínú òkú.” (Ìṣe 17:1-3) Àwọn kan lára àwọn tó fetí sí Pọ́ọ̀lù di Kristẹni, ó sì gbóríyìn fún wọn, ó ní: “Nígbà tí ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tí ẹ gbọ́ láti ọ̀dọ̀ wa, ẹ tẹ́wọ́ gbà á, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹsalóníkà 2:13) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ṣèbẹ̀wò yìí, ó dájú pé ìwé Ìhìn Rere Mátíù nìkan ni wọ́n ṣì kọ lára àwọn ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì. Torí náà, ó dájú pé àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni “Ìwé Mímọ́” tí Pọ́ọ̀lù lò láti “fi ẹ̀rí ìdánilójú” han àwọn èèyàn wọ̀nyẹn.

Ká sòótọ́, ó tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ogún [320] ìgbà táwọn tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì fa ọ̀rọ̀ yọ ní tàrààtà látinú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó sì tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ àti àádọ́rùn-ún [890] ìgbà tí wọ́n lo díẹ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé “gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Èyí fi hàn kedere pé àwọn tó gba odindi Bíbélì gbọ́ lónìí máa ń jàǹfààní tó kọ yọyọ.

Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run fi ṣí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ payá ní ṣíṣẹ̀-n-tẹ̀lé ló wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sì ni ìpìlẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú rẹ̀. Nítorí náà, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ò sọ àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù di òkú ọ̀rọ̀. Herbert H. Farmer tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nípa ìjọsìn ní Cambridge University sọ pé “tá a bá fẹ́ lóye àwọn ìwé Ìhìn Rere àfi ká kọ́kọ́ kà nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, bó ṣe wà nínú Májẹ̀mú Láéláé.”

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ò nílò àtúnṣe. Síbẹ̀, “ipa ọ̀nà àwọn olódodo [ṣì ń] dà bí ìmọ́lẹ̀ mímọ́lẹ̀ yòò, tí ń mọ́lẹ̀ síwájú àti síwájú sí i, títí di ọ̀sán gangan.” (Òwe 4:18) Bí Ọlọ́run ṣe fi Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú Bíbélì túbọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ ṣe kedere, ìyẹn ò sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù di òkú ọ̀rọ̀. “Àsọjáde Jèhófà [tó máa wà] títí láé” ni gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì.—1 Pétérù 1:24, 25.