Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹlẹ́dàá Tó Yẹ Ká Fọpẹ́ Fún

Ẹlẹ́dàá Tó Yẹ Ká Fọpẹ́ Fún

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ẹlẹ́dàá Tó Yẹ Ká Fọpẹ́ Fún

Ìṣípayá 4:11

KÍ LÈRÒ ẹ nípa ìbéèrè yìí, ‘Kí nìdí tá a fi wà láàyè?’ Àwọn tó nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n ti ṣe wàhálà gan-an láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, síbẹ̀ wọn ò tíì rí i. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ ní tàwọn tó gba òtítọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run, Orísun Ìwàláàyè. (Sáàmù 36:9) Wọ́n mọ̀ pó nídìí tí Ọlọ́run fi dá wa, ìyẹn ló sì wà nínú ìwé Ìṣípayá 4:11. Ẹ jẹ́ ká wo báwọn ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ wọ̀nyẹn ṣe ṣàlàyé ìdí tá a fi wà láàyè.

Jòhánù kọ̀wé nípa àwọn ẹ̀dá ọ̀run tí wọ́n pa ohùn wọn pọ̀ láti fògo fún Ọlọ́run nípa sísọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Jèhófà nìkan lọpẹ́ yẹ, òun nìkan ló sì yẹ ká fún nírú ògo bẹ́ẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé òun “ni ó dá ohun gbogbo.” Kí ló wá yẹ kíyẹn mú káwọn ẹ̀dá ẹ̀ tó lọ́pọlọ ṣe?

Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti “gba” ògo, ọlá àti agbára. Kò sí àníàní pé kò sẹ́ni tó ní ògo, ọlá àti agbára tó Ọlọ́run láyé àti lọ́run. Àmọ́, èyí tó pọ̀ jù lára aráyé ni ò gbà pé òun ni Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo. Síbẹ̀, àwọn èèyàn kan ti rí i pé kedere ni “àwọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí” wà lára àwọn ohun tó dá. (Róòmù 1:20) Ìdí nìyẹn tí ọkàn wọn tó kún fún ìmọrírì fi sún wọn láti fi ògo àti ọlá fún Jèhófà. Wọ́n ń wàásù fáwọn tó fẹ́ mọ àwọn ẹ̀rí tó wà pé Jèhófà ló dá ohun gbogbo lọ́nà ìyanu àti pé ó lẹ́tọ̀ọ́ pé ká bọ̀wọ̀ fún un lọ́nà tí ò láfiwé.—Sáàmù 19:1, 2; 139:14.

Báwo wá ni Jèhófà ṣe ń gba agbára látọ̀dọ̀ àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀? Ká sòótọ́, kò sí ẹ̀dá kankan tó lè fún Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé lágbára. (Aísáyà 40:25, 26) Síbẹ̀, nítorí pé Ọlọ́run dá wa ní àwòrán rẹ̀, dé ìwọ̀n àyè kan àwa náà ti láwọn ànímọ́ kan tí Ọlọ́run ní, agbára sì jẹ́ ọ̀kan lára irú àwọn ànímọ́ bẹ́ẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la mọrírì ohun tí Ẹlẹ́dàá wa ti ṣe fún wa, ó yẹ ká lo agbára àti okun wa láti fi ògo àti ọlá fún un. Bá a ṣe ń sin Jèhófà Ọlọ́run, à ń fi hàn pé a ò fẹ́ máa fi gbogbo okun wa lépa ìfẹ́ tara wa nìkan, àmọ́ a mọ̀ pé òun ló lẹ́tọ̀ọ́ láti gba gbogbo agbára wa.—Máàkù 12:30.

Kí wá nìdí tá a fi wà láàyè gan-an? Apá tó gbẹ̀yìn ìwé Ìṣípayá 4:11 dáhùn ìbéèrè yẹn, ó ní: “Nítorí ìfẹ́ rẹ ni [gbogbo ìṣẹ̀dá] ṣe wà, tí a sì dá wọn.” Àwa kọ́ la dá ara wa. Torí pé Ọlọ́run fẹ́ ká wà láàyè la ṣe wà láyé. Torí náà, téèyàn bá gbé ìgbésí ayé fún ìfẹ́ tiẹ̀ nìkan, ìgbésí ayé onítọ̀hún ò nítumọ̀. Ká tó lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn, kọ́wọ́ wa sì tẹ àwọn ohun tá à ń wá, a ní láti kọ́ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́ ká sì máa gbé ìgbésí ayé wa níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. Ìgbà yẹn la tó lè rí ìdí tí Ọlọ́run fi dá wa sáyé tá a sì wà láàyè.—Sáàmù 40:8.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 31]

NASA, ESA, àti A. Nota (STScI)