Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Akọni Oníjà Kọnfú Tọwọ́ Ìjà Bọlẹ̀

Akọni Oníjà Kọnfú Tọwọ́ Ìjà Bọlẹ̀

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-Èdè Gánà

Akọni Oníjà Kọnfú Tọwọ́ Ìjà Bọlẹ̀

IRÚ ẹni tí mo rò pó jẹ́ kọ́ ni mo bá a nígbà tí mo rí i. Aṣọ funfun fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tó kọjá orúnkún ló wọ̀, èèyàn pẹ́lẹ́ńgẹ́ ni, bẹ́líìtì dúdú tó dè dúró sẹpẹ́ sí i níbàdí, ọwọ́ ẹ̀ le wá, ó fẹsẹ̀ dilẹ̀ mú ṣinṣin, ó ti ṣe tán láti bẹ̀rẹ̀ sí í ja kọnfú. Ojú ẹ rorò, ìpéǹpéjú ẹ̀ nàró bó ṣe ń wọ̀ọ́kán tààràtà. Ojú ẹ̀ le, ó sì ń dẹ́rù bààyàn, ó hàn lójú ẹ̀ pé akọni ọkùnrin ni.

Kí n tó ṣẹ́jú pẹ́, ó ti gbéra láti bẹ̀rẹ̀ sí í jà. Ló bá nawọ́ sókè, nígbà tó máa gbọ́wọ́ ẹ̀ wálẹ̀ báyìí, àfi gbòlà! Nígbà tí mo sì máa wolẹ̀, ó ti fọwọ́ lásán gé pákó tó wà nílẹ̀ sí méjì. Kò pẹ́ ló tún fò sókè, nígbà tó sì máa balẹ̀ báyìí ẹ̀ṣẹ́ ló dì ru ẹni tí wọ́n jọ ń jà, tíyẹn sì ń pa rìdàrìdà. Ṣé ọkùnrin tó ní ká máa wá kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rèé?

Nígbà tó yá, mo lọ bá a, mo bọ̀ ọ́ lọ́wọ́, mo ní: “Ṣé ẹ̀yin ni Kojo? Wọ́n ní ẹ fẹ́ ká máa wá kọ́ yín lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ó gbá ọwọ́ mi mú, ó rẹ́rìn-ín músẹ́ sí mi, ó sì kí mi tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Ojú ẹ̀ tó ń tu bí iná tẹ́lẹ̀ ti wá rọlẹ̀, kò sì bani lẹ́rù mọ́, ńṣe ló wá dà bíi tẹni tó fẹ́ wádìí ọ̀rọ̀. Ó dá mi lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, màá fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́. Ìgbà wo la máa bẹ̀rẹ̀?”

Lọ́jọ́ tá a bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́, iwájú ìta ilé ẹ̀ la jókòó sí, Bíbélì àtàwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì wà lọ́wọ́ wa. Ibi tá a wà yìí tutù dáadáa, kò sì sáriwo. Àwa mẹ́ta la wà níbẹ̀: Kojo, èmi àti ọ̀bọ Kojo. Ọ̀bọ yìí máa ń ṣeré gan-an, kò sì sẹ́ni tó máa rí i tí ò ní rẹ́rìn-ín. Kò ga ju àpótí ìjókòó lọ, irun pupa wà lórí ẹ̀ bíi fìlà, irun funfun sì wà ní àgbọ̀n ẹ̀ bí irùngbọ̀n arúgbó. Ara ọ̀bọ yìí ò balẹ̀, ńṣe ló ń du bébà àti báírò mọ́ wa lọ́wọ́, tó sì ń tọwọ́ ẹ̀ ráńdú bọ̀ wá lápò láti wá nǹkan tó lè rì bọnu. Bíi ti òbí tó ti mọ̀ pé ọmọdé ò lè ṣe kó má ṣe bí ọmọdé, Kojo ò jẹ́ kí ọ̀bọ yìí pín ọkàn ẹ̀ níyà, ńṣe ló kọjú mọ́ ohun tó ń kọ́. Àwọn ìbéèrè tó ń bi mí fi hàn pé ó ń ronú, ó sì ṣe tán láti kẹ́kọ̀ọ́. Bóyá ìjà kọnfú tó ń jà ló jẹ́ kó wá já fáfá, torí kì í fẹ́ gba ohunkóhun gbọ́ àyàfi téèyàn bá fi Ìwé Mímọ́ kan ti àlàyé rẹ̀ lẹ́yìn.

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí mò ń ṣe pẹ̀lú ẹ̀ ń tẹ̀ síwájú dáadáa. Àmọ́ nígbà tó yá, mo rí i pé ohun kan ń jà gùdù lọ́kàn ẹ̀, ó sì ń dà á láàmú gan-an. Ó sọ fún mi pé: “Ohun kan ṣoṣo tí mo fẹ́ràn láyé yìí ni kọnfú.” Mo mọ̀ lóòótọ́ pé lọ́kàn ẹ̀ lọ́hùn-ún, ó fẹ́ràn kọnfú gan-an, torí ó ti fara sí i dáadáa ó sì ti mọwọ́ ẹ̀ gan-an. Kò tíì ju ọmọ ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] lọ tó ti mọwọ́ kọnfú débi pé ó ti gba àmì ẹ̀yẹ bẹ́líìtì dúdú tí wọ́n máa ń fún àwọn akọni nínú ìjà náà, ṣàṣà sì làwọn tó máa ń dépò yìí, kódà àwọn míì lè máà débẹ̀ tí wọ́n á fi kú, gbogbo èyí fi hàn pé ó fẹ́ràn kọnfú lóòótọ́.

Kò dá mi lójú pé Kojo lè fi ìjà kọnfú sílẹ̀. Mo ronú pé òun fúnra ẹ̀ ti mọ̀ pé bí òun ṣe ń ja kọnfú, tóun sì ń fọwọ́ àti ẹsẹ̀ òun ṣàwọn èèyàn léṣe ò bá ìfẹ́ tó wà láàárín àwọn Kristẹni tòótọ́ mu, torí irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ a jẹ́ kó máa gba tàwọn ẹlòmíì rò, kó sì máa ṣàánú àwọn èèyàn. Síbẹ̀, mo mọ̀ pé òtítọ́ Bíbélì ti rọ àwọn tó le ju tiẹ̀ lọ lọ́kàn. Tí ọkàn Kojo náà bá jẹ́ ọkàn títọ́, ó dájú pé agbára Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa jẹ́ kóun náà rọ̀. Mo ní láti ní sùúrù.

Lọ́sàn-án ọjọ́ kan tí oòrùn ń mú ganrínganrín, a ka ẹsẹ Bíbélì kan nígbà tá a fẹ́ parí ìkẹ́kọ̀ọ́ wa, ẹsẹ Bíbélì yẹn ró kìì lọ́kàn Kojo bí ìgbà tá à bá sọ pé ẹni tó ń bá jà gbá a lẹ́ṣẹ̀ẹ́ tagbáratagbára. Òun fúnra ẹ̀ ló ka ẹsẹ Bíbélì náà, ó ní: “Jèhófà tìkára rẹ̀ ń ṣàyẹ̀wò olódodo àti ẹni burúkú, dájúdájú, ọkàn rẹ̀ kórìíra ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” (Sáàmù 11:5) Nígbà tó kà á tán, ó rọra ń sọ fúnra ẹ̀ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá nífẹ̀ẹ́ ìwà ipá.” Ojú ẹ̀ tó máa ń le tó sì máa ń dẹ́rù báni tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wálẹ̀. Ó wò mí lójú, ó sì rẹ́rìn-ín músẹ́, ó ní: “Mo ti mohun tí màá ṣe.”

Iṣẹ́ témi àti Kojo fẹ́ràn gan-an la wá ń ṣe báyìí, olùkọ́ tí kì í gbowó oṣù ni wá, à ń fáwọn èèyàn tó bá máa fetí sílẹ̀ sí wa nítọ̀ọ́ni látinú Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́. A ti ṣèlérí fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Luke pé a máa dé ọ̀dọ̀ ẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ kan.

Àárín ọjà kan tí ò fi bẹ́ẹ̀ láyè la gbà lọ sílé Luke, èrò sì ń wọ́ tìrítìrí láàárín ọjà náà. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ṣọ́ọ̀bù kéékèèké, ìsọ̀ àtàwọn tó pàtẹ ọjà wọn sílẹ̀ ló tò lọ sójú ọ̀nà: oríṣiríṣi ata gígún tó ga gèlèmọ̀ nínú bàsíà, apẹ̀rẹ̀ tòmátì tó ti pọ́n, igbá ilá, àwọn tó ń ta rédíò, agboòrùn, ọṣẹ ìfọṣọ, wíìgì obìnrin, àwọn nǹkan ìdáná àtàwọn àlòkù bàtà àti aṣọ ló wà lọ́jà náà. Àwọn ọmọbìnrin gbé bàsíà sórí, wọ́n ń kiri oúnjẹ aládùn tó ń gbóná fẹlifẹli. Wọ́n rọra ń gba àárín àwọn èrò kọjá, wọ́n sì ń jẹ́ kí ọ̀fun àwọn tébi ń pa máa dá tòlótòló pẹ̀lú ọbẹ̀ àti ata díndín tí wọ́n ti fi ẹja dúdú tí wọ́n yan, alákàn àti ìgbín sè. Àwọn ajá, ewúrẹ́ àti adìyẹ rọra ń gba abẹ́ àwọn èèyàn kọjá. Àwọn rédíò ń pariwo, àwọn onímọ́tò ń tẹ fèrè mọ́tò wọn, àwọn èèyàn náà sì ń hó gèè, ariwo gba inú ọjà kan.

Ọ̀nà tó dọ̀tí kan la gbà kúrò láàárín ariwo ọjà ìlú náà, ìgbà tó yá la dé ilé tó ti gbó kan tí wọ́n gbé àkọlé kan tí ò hàn dáadáa tí wọ́n kọ “Long Journey Spot” sí síwájú ìta ẹ̀. Luke, tó ṣẹ̀ṣẹ̀ lé díẹ̀ lọ́mọ ogún [20] ọdún ti dúró sẹ́nu ọ̀nà ilé náà, ó sì pè wá wọlé sábẹ́ ibòji. Kò fi bẹ́ẹ̀ sáyè ní yàrá tí Luke ń gbé, torí ẹ̀gbọ́n ẹ̀ obìnrin tó ń ṣiṣẹ́ oníṣègùn ti to àwọn àpò àti àpótí tó fi kó ewé, egbò, èèpo igi àtàwọn nǹkan tó fi ń ṣe àgbo sí nínú yàrá náà. Ọgbọ́n àbáláyé ni ẹ̀gbọ́n Luke fi ń ṣe àwọn àgbo gbogbo-nìṣe tó ń fáwọn èèyàn lò, ó máa ń gún àwọn kan, ó sì máa ń se àwọn míì. Luke ti ń retí wa. Ó ti gbá àwọn èérún ewé àti egbòogi tó wá nílẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ó sì ti gbé àpótí ìjókòó mẹ́ta síbẹ̀ fún wa. Àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wa, a sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Kojo ló ń kọ́ Luke lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ńṣe ni mo jókòó tí mo fọwọ́ lẹ́rán tí mo sì ń tẹ́tí sí báwọn ọkùnrin méjèèjì ṣe ń jíròrò bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé ìdí táráyé fi ń jìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Kojo fẹ́ bá Luke ṣí ẹsẹ Bíbélì kan, ńṣe ni mo kàn ń wo báwọn ọwọ́ akọni ọkùnrin yìí ṣe rọra ń ṣí àwọn ojú ìwé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ yìí síbi tí wọ́n fẹ́ kà. Ìgbà yẹn ni mo rántí pé ìjà àjàkú-akátá làwọn ọwọ́ wọ̀nyí máa ń jà nígbà kan. Èyí jẹ́ kí n rí i pé lóòótọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè gba àwọn ìwàkiwà tó kúnnú ayé yìí lọ́wọ́ èèyàn kó sì wá jẹ́ kónítọ̀hún dẹni tó ń fàwọn ànímọ́ rere bí ìfẹ́ àti àánú ṣèwà hù. Àṣeyọrí tó kàmàmà lèyí.

Nígbà tá à ń pa dà lọ sílé, a lọ bá ọkùnrin kan tó jókòó sábẹ́ igi máńgòrò sọ̀rọ̀. Ó fara balẹ̀ tẹ́tí sí Kojo bó ṣe ṣí Bíbélì tó sì ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan fún un. Àmọ́, nígbà tí ọkùnrin náà wá mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wá, ńṣe ló fò dìde tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo mọ́ wa, ó ní: “Mi ò gba tẹ̀yin èèyàn wọ̀nyí fún nǹkan kan!” Fún ìṣẹ́jú díẹ̀, mo rí i pé inú ti bẹ̀rẹ̀ sí í bí Kojo. Àmọ́, kò pẹ́ tára ẹ̀ fi rọra wálẹ̀ wọ̀ọ̀, tó sì kúrò níwájú ọkùnrin yẹn. Báwa méjèèjì sì ṣe fibẹ̀ sílẹ̀ nìyẹn.

Bá a ṣe ń rìn lọ lójú ọ̀nà ni Kojo fẹnu kò mí létí, tó sì rọra sọ fún mi pé: “Ńṣe lọkàn mi ń lù kìì-kìì bó ṣe ń sọ̀rọ̀ sí wa lẹ́ẹ̀kan. Ṣẹ́ ẹ mọ nǹkan tí ǹ bá ti ṣe fún ọkùnrin yẹn?” Mo rẹ́rìn músẹ́, mo sì dáhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀.” Òun náà rẹ́rìn-ín, a sì ń bá ìrìn àjò wa lọ.